Ìròyìn tó ṣẹ̀ṣẹ̀ jáde

Ọ̀rọ̀ Ààbò Ẹ̀rọ-ayárabíàṣá…ní èdè wa. Àwọn Àbá láti ọwọ́ onígbèjà èdè Yorùbá lórí ẹ̀rọ-ayárabíàṣá ní orílẹ̀-èdè Nàìjíríà

Ohùn Tó-ń-dìde  1 Èrèlé 2023

"Àǹfààní fún àwọn elédè Yorùbá ò tó nítorí kò sí àwọn ohun àmúlò ìdánilẹ́kọ̀ọ́ orí ẹ̀rọ-ayárabíàṣá wọ̀nyí ní èdè abínibí wọn, èyí tí ó dákun àìsí àṣà ààbò orí ẹ̀rọ-ayárabíàṣá tó péye láàárín àwùjọ náà."

‘Ìkòròdú bois’ ṣàfihàn bí àwọn gbàgede ẹ̀rọ-ayélujára ṣe ń ṣe ìgbélárugẹ àwọn eré àgbéléwò orílẹ̀-èdè Nàìjíríà káàkiri àgbáyé

  10 Ṣẹẹrẹ 2023

Pẹ̀lú irinṣẹ́ tí kò tó àti àwọn àmúlò irinṣẹ́ orí ẹ̀rọ-ayárabíàṣá, ikọ̀ ‘Ìkòròdù Bois’ ṣe ìsínjẹ àti àwàdà àwọn eré Hollywood àti Nollywood tí ó ti di èrò yà wá á wò ó kárí ayé lórí àwọn gbàgede ìbáraẹnidọ́rẹ̀ẹ́.

Fún Ayẹyẹ Àìsùn Ọdún Tuntun àwọn Ilé-Ìwé ní Moscow, àwọn orin kan ò bójúmu

Ìkùrìrì RuNet  31 Ọ̀pẹ 2022

Ní àpapọ̀, àtòjọ náà ní àwọn olórin àti ẹgbẹ́ eléré 29. Díẹ̀ nínú wọn, bíi Little Big àti Manizha, ti ṣojú orílẹ̀-èdè Russia rí ní ìdíje Eurovision fún ọdún púpọ̀ látẹ̀yìnwá. Gbogbo wọn pata ni wọ́n bu ẹnu àtẹ́ lu ìkọlù orílẹ̀-èdè Russia sí Ukraine ní gbangba

Bí orílẹ̀-èdè Nàìjíríà ṣe kojú ìdábẹ́ Ọmọbìnrin èyí tí ó ń ṣe lemọ́lemọ́: Ìfọ̀rọ̀wánilẹ́nuwò kan pẹ̀lú Dókítà Chris Ugwu

  28 Ọ̀wẹwẹ̀ 2022

Abẹ́dídá máa ń yọrí sí ìrora tó lágbára, ṣíṣe àgbákò àrùn àìfojú rí, ẹ̀jẹ̀ yíya lọ́pọ̀lọpọ̀, àìle kápá ojú ilé ìtọ̀, làásìgbò ní ìgbà ìbímọ, ìpayà, àti ní ìgbà mìíràn, ikú pàápàá. Ní orílẹ̀-èdè Nàìjíríà, ẹkùn tí ìdábẹ́ fún ọmọbìnrin ti gbilẹ̀ jùlọ ni apá gúúsù-ìwọ̀ oòrùn àti gúúsù-ìlà oòrùn.

Di atúmọ̀ tàbí òǹkọ̀wé

Ẹ káàbọ̀ sí ibùdó Ohùn Àgbáyé ní èdè Yorùbá. Ìwọ náà lè darapọ̀ mọ́ wa, báwo? Kọ nípa araà rẹ sílẹ̀ níbí >>> "https://globalvoices.org/lingua/translator-application-form/"

Ìṣúra oṣooṣù

Aládàásí