Àjọ tí ó ń rí sí ọ̀rọ̀ ẹ̀sìn ní Turkey ní àwọn obìnrin ò le dá nìkan rin ìrìn-àjò

 

Àwòrán láti ọwọ́ Jason Blackeye. Ó ṣe é lò lọ́fẹ̀ẹ́ lábẹ́ àṣẹ Unsplash.

Nígbà tí ó ń sọ̀rọ̀ lórí ìkànnì Diyanet TV, ẹni tí ó jẹ́ olùdámọ̀ràn fún Ìjọba àpapọ̀ lórí ọ̀rọ̀ ẹ̀sìn, Zeki Sayar, sọ ọ̀rọ̀ tí ó dá awuyewuye kan sílẹ̀, “àyàfi bí àwọn ọkọ tàbí àwọn ọmọkùnrin wọn bá tẹ̀lé wọn, kò bójú mu tó kí wọ́n dá rin ìrìn àjò tó bá ti ju ibùsọ̀ 9 lọ”. Òun nìkan sì kọ́ ni fátíwà àkọ́kọ́ tí àjọ tí ó ń rí sí ọ̀rọ̀ ẹ̀sìn ní ìlú Turkey ti fún-un-gun mọ́ àwọn obìnrin àti òmìnira wọn. Ní ìgbà kan sẹ́yìn, àjọ náà bu ẹnu àtẹ́ lu àwọn obìnrin fún ìrínisí wọn, ó tún rọ àwọn obìnrin láti fara mọ́ ìyà abẹ́lé, kódà ó tún sọ pé àwọn ọmọdékùnrin àti ọmọdébìnrin tí wọ́n bá ti bàlágà ni wọ́n ti tó ṣe ìgbéyàwó. Adarí àjọ náà, Ali Erbaş, dá àwọn akọ-abákọsùn àti abo abábosùn àti àwọn alágbèrè lẹ́bi ìtànkálẹ̀ àrùn COVID-19 tí ó sì tún mẹ́nu ba bí ìlú náà ṣe kùnà láti gbé àwọn ìgbésẹ aláàbò nígbà tí àjàkálẹ̀ náà bẹ̀rẹ̀.

Ìgbédìde Diyanet

Ẹ̀ka tí ó ń rí sí Ọ̀rọ̀ Ẹ̀sìn, àbí Diyanet, ni àjọ kan gbòógì tí ó ń rí sí dìdarí ọ̀pọ̀lọpọ̀ ètò tí ó bá ti jẹ mọ́ àwọn Mùsùlùmí ìlú náà — pẹ̀lú, ṣíṣe àkóso àwọn mọ́ṣálááṣí ti ìlú, yíyan àwọn lémọ́mù, fífi wàásí ọ̀sọ̀ọ̀sẹ̀ ṣọwọ́ kiri kí ìrun Jímọ̀ ó tó dé, kíkọ́ni ní àwọn ẹ̀kọ́ Kùránì, àti ṣíṣe ètò ìrìn àjò lọ sí Mẹ́kà, àti àwọn ojúṣe mìíràn.
Ojúṣe ẹ̀ka náà, tí wọ́n dá sílẹ̀ ní ọdún 1924 nínú ìlú náà tí gbòòrò tí ó sì ti gbilẹ̀ sí i bí ọdún ṣe n gorí ọdún, pàápàáá jùlọ ní sáà ẹgbẹ́ Ìdájọ́ àti Ìdàgbàsókè tí ó ń ṣe ìjọba lọ́wọ́. Ní àfikún sí ìṣúná tí ó gọbọi, Diyanet ti ṣe àṣeyọrí láti fọ́jú ààlà tó wà láàárín ìlú àti ẹ̀sìn. Ní oṣù Ògún ní ọdún 2021, Erbaş fara hàn ní ibi ayẹyẹ ṣíṣí gbọ̀ngán ilé-ẹjọ́ tuntun kan tí ó sì bá Ààrẹ Recep Tayyip Erdoğan ṣe ìrìn àjò kan lọ sí New York, nibi tí ó ti lọ ṣe àdúà sí ilé tuntun kan tí àwọn afọ̀rọ̀wérọ̀ tí ó ń ṣojú ilẹ̀ Turkey yóò máa gbé. Ní ọdún 2021 Erbaş tí dábàá pé kí ìṣàkóso ó wà lórí àwọn gbàgede ìbánidọ́rẹ́ẹ̀ àwọn ará ìlú láti lè mú kí ìṣàmúlò ó wà ní ìlànà tó bá tí ẹ̀sìn Ìsìláàmù mu.

Diyanet Foundation ni ó ń ṣe àmójútó Diyanet TV, ìkànnì móhùnmáwòrán ti ìgbìmọ̀ náà gan-an, àti fáfitì ẹlẹ́sìn Ìsìláàmù kan. Gẹ́gẹ́ bí ibùdó ìtakùn àgbáyé ìdásílẹ̀ náà ṣe sọ:

A dá a sílẹ̀ pẹ̀lú èròńgbà láti ṣe àtìlẹ́yìn fún àwọn iṣẹ́ ilé Aṣojú Ààrẹ fún Ọ̀rọ̀ Ẹ̀sìn, ṣíṣe ìtànkálẹ̀ àwọn iṣẹ́ ẹ̀sìn sí ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn ní àwùjọ àti láti ṣe ìgbédìde ìran tí yóò máa kópa nínú iṣẹ́ ẹ̀sìn, Turkey Diyanet Foundation ní ẹ̀ka 1,003 ní ìlú wa tí ó sì ní onírúurú ètò láti ẹ̀kọ́ sí àṣà, láti àwọn iṣẹ́ àwùjọ àti ètò inú rere sí àwọn iṣẹ́ ẹ̀sìn àti àwọn iṣẹ́ owó ìrànwọ́ ní ilẹ̀ òkèèrè ní ìlú 149 ní àgbáyé. Ó ti di ètò àjọ ara ìlú tó tóbi tí ó ń ṣiṣẹ́ ní agbègbè kan.

Àwọn ìtakò sí àwọn obìnrin

Fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọdún, àwọn aṣojú Diyanet ti ń fojú sí àwọn obìnrin lára lórí ìrínisí wọn, pínpín “àwọn ohun ṣíṣe” àti “àwọn ohun àìíṣe” fún ìjóbìnrin, àti yíyẹpẹrẹ àwọn obìnrin ní àwùjọ.

Ní ọdún 2008 nínú àtẹ̀jade tí ẹ̀ka náà fí léde lórí ibùdó ìtakùn àgbáyé rẹ̀, “àwọn ìyànjú” àtẹ̀léra ni ó ṣe àlàyé bí àwọn obìnrin ṣe gbọdọ̀ ṣe máa hùwà àti bí wọn ò ṣe gbọdọ̀ ṣe. Àwọn obìnrin “ní láti tún gbọdọ̀ máa ṣọ́ra ṣe, níwọ̀n ìgbà tó jẹ́ pé wọ́n ní àwọn ohun amárayágágá; [àwọn obìnrin] ní láti máa bo ara wọn dáadáa kí wọ́n má ba à á ṣí ẹ̀ṣọ́ ara àti ìrísí ara wọn síta fún àwọn àjèjì rí; [àwọn obìnrin] gbọdọ̀ máa sọ̀rọ̀ ní ọ̀nà tí kò ní dá ìyágágá sí ọkàn èèyàn àti pẹ̀lú àìgbẹ̀fẹ̀ àti àpọ́nlé tí kò ní jẹ́ kí àwọn ọkùnrin ó ṣì wọ́n gbọ́.” Àtẹ̀jáde náà, tí àkòrí rẹ̀ jẹ́ “Ìgbáyé Ìbálòpọ̀”, tún ṣèyànjú pé àwọn ọkùnrin àti obìnrin tí wọn kò bá tí ì so yìgì kò gbọdọ̀ jọ máa rìn ní ìta gbangba; kí àwọn obìnrin ó jìnnà sí ṣíṣe iṣẹ́ ní àwọn ibi-iṣẹ́ tí akọ àti abo ti ń ṣiṣẹ́, tí ó sì tún sọ pé ó “burú” kí àwọn obìnrin láti máa lo lọ́fíndà olóòórùn dídùn jáde kúrò ní ilé wọn.

Fún ọdún púpọ̀, ìtakò sí àwọn obìnrin ti pọ̀ jọjọ ju àtẹ̀yìnwá lọ. Ní ọdún tó kọjá, ọmọ ẹgbẹ́ àgbà ìgbìmọ̀ náà sọ wí pé kò bójú mu tó fún àwọn obìnrin láti máa wọ ṣòkòtò tọn-ọn-tín-ín-rín ní ìta gbangba. Níbi ìṣàpẹẹrẹ mìíràn, Ìmáàmù kan láti Ankara ṣàròyé pé àwọn obìnrin rí bí i “ẹran ní àwọn ìsọ̀ alápatà” bí wọ́n bá ń rìn kọjá ní títì. Òṣìṣẹ́ Diyanet mìíràn kan ló tún pe àwọn bàbá, ẹ̀gbọ́n àti àbúrò lọ́kùnrin, àti àwọn ọkọ sí àkíyèsí láti bá àwọn obìnrin wọn sọ̀rọ̀ kí wọ́n sì tọ́ wọn sọ́nà láti máa bo ara wọn. “Ìwòye Mùsùlùmí ni a nílò. (Wọ́n) ti bẹ̀rẹ̀ sí ní ṣí aṣọ tí ó bo ara wọn kúrò lára, wọ́n ń kọjá àyè tí wọ́n sì ń ṣe àwọn ohun hàráàmù. Mùsùlùmí kan ò le ṣe èyí,” bẹ́ẹ̀ ni wọ́n ní òṣìṣẹ́ náà ṣe sọ.

Ní 2020, nínú fátíwà tó tẹ̀lé ara wọn, ilé iṣẹ́ múfútí ti Diyanet rọ àwọn obìnrin tí ó bá ń bẹ̀rù ìpa ní ilé láti tọ àwọn àgbàlagbà lọ kí wọ́n le fi ọ̀rọ̀ dídùn bọ́ àwọn ọkọ wọn bí wọ́n bá ń mu tíì lọ́wọ́. Ní 2019 İhsan Şenocak, olùdásílẹ̀ Ilé Ìṣàyẹ̀wò nípa Ọgbọ́n àti Sáyẹ́nsì (IFAM), àjọ ẹlẹ́sìn ní ìlú Turkey, ló ṣe wáàsí kan níbi tí wọ́n tí ní ó wí pé, “àwọn ọmọbìnrin, àwọn ìyàwó, tí wọ́n ń wọ ṣòkòtò, tí wọ́n ń lọ sí fáfitì, tí wọ́n ń ṣe irun ojú wọn, ni wọn yóò bá ara wọn nínú iná.” Şenocak tún bu ẹnu àtẹ́ lu ìmúra àwọn obìnrin agbábọ́ọ̀lù folibọ́ọ̀lù níbi ayẹyẹ Òlímpíkì ilẹ̀ Tokyo ní ọdún 2021.

Ṣùgbọ́n kì í ṣe Diyanet nìkan ni ó tí ń polongo bíbu ẹnu àtẹ́ lu àwọn obìnrin. Erdoğan fúnra rẹ̀ gan-an ti sọ àwọn ọ̀rọ̀ ọ̀tẹ̀ ní àwọn ọdún sẹ́yìn, èyí tí dídá àbá pé àwọn ọkùnrin àti obìnrin ò kí ń ṣe ẹgbẹ́ra, pé àwọn obìnrin gbọdọ̀ jẹ́ abiyamọ, àti pé àwọn ẹbí gbọdọ̀ ní ó kéré jù ọmọ mẹ́ta, nígbà tí ẹgbẹ́ tí ó ń lo sáà lọ́wọ́ ti ń dábàá ṣíṣe gbèdéke fún ẹ̀tọ́ láti yọ oyún, egbòogi tí ó ń fọ àtọ̀ kúrò lára, àti iṣẹ́ abẹ. Ní ọdún 2012, Erdoğan tí ó jẹ́ adarí ìgbìmọ̀ ìjọba nígbà náà pé oyún ṣíṣẹ́ gẹ́gẹ́ bí i ìpànìyàn. Àti pé bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé oyún ṣíṣẹ́ tí ó fí di oyún ọ̀sẹ̀ 10 àti tí ó fi di ọ̀sẹ̀ 20 bí yóò bá mú ewu ìṣègùn dání ṣì bá òfin mu ní ilẹ̀ Turkey, ṣíṣe àwárí àwọn ilé ìwòsan tí yóò ṣe iṣẹ́ náà tí dá gẹ́gẹ́ bí i ẹni ń wá imí eégún ni.

Ní ọdún 2014, Erdoğan fẹ̀sùn kan àwọn ajàfẹ́tọ̀ọ́ abo pé ọ̀rọ̀ àti ṣíṣe abiyamọ kò yé wọn. Nígbà tí ó ń sọ̀rọ̀ níbi ìpàdé àpérò kan ní Istanbul, wọ́n ní ó wí pé, “Àwọn èèyàn kan nímọ̀ nípa èyí, nígbà tí àwọn kan ò lè mọ̀. O ò lè ṣàlàyé èyí fún àwọn ajàfẹ́tọ̀ọ́ abo nítorí pé wọn ò tilẹ̀ gba ohun tí ó ń jẹ́ ìṣabiyamọ rárá.” Ó tún wí pé gbígbé ọkùnrin àti obìnrin sí ẹ̀gbẹ́ ara wọn gẹ́gẹ́ bí i ọgba “kò bá ètò ìjénìyàn mu” àti pé àwọn obìnrin tí ó ń ṣiṣẹ́ kò “pọ̀ tó.”

Ní ọdún 2021, orílẹ̀-èdè Turkey fa ara rẹ̀ yọ ní ìtẹ̀lé òfin kúrò nínú Àjọ aṣàdéhùn ti Istanbul, àjọ olófin tó wà ní ìsopọ̀ tó ń rí sí ẹ̀tọ́ ọmọnìyàn ní Ìgbìmọ̀ ilẹ̀ Europe tí ó sì ń ṣe ìlérí láti bẹ́gi dínà, dáná òfin yá, àti láti pa ipá àti ìyà ilé ọkọ rẹ́ tí ó sì tún ń gbé ìmúdọ́gba akọ àti abo lárugẹ.

Fátíwà ẹ̀ka náà tó ṣẹ̀ṣẹ̀ jáde nípa gbèdéke lórí ìrìn àjò ni ó ti fa ọ̀pọ̀lọpọ̀ awuyewuye. Akọ̀ròyìn Bulent Mumay ló fi léde lórí Twitter rẹ̀ pé òfin ìrìnnà tuntun náà kò tilẹ̀ fẹ́ dí ìyàwó Erbaş lọ́wọ́ láti rin ìrìn àjò káàkiri ilẹ̀ Turkey láì ṣe pé ọkọ rẹ̀ tẹ̀lé e. Akọ̀wé Yilmaz Özdil bu ẹnu àtẹ́ lu ẹ̀ka náà pé wọn ò ní ìmọ̀ tó kún nínú àròkọ rẹ̀, ó kọ, “àfi ìgbà tó dí bí i ọdún 200 sẹ́yìn, kò sí ohun tí ó ń jẹ́ ìwọ̀n ibùsọ̀. Arákùnrin yìí tọpasẹ̀ ìwọ̀n ibùsọ̀ [ìjìnnà] sí ìgbà tí ẹ̀sìn Ìsìláàmú bẹ̀rẹ̀!” Òǹkọ̀wé náà tún tọ́ka sí àwọn lààmìlaaka obìnrin ilẹ̀ Turkey, láti orí asáré ìje ọkọ ayọ́kẹ́lẹ́ àkọ́kọ́ ìlú náà ní ọdún 1932 títí dé àwọn àwakọ̀ ojú òfuurufú àkọ́kọ́ rẹ̀, àwọn onímọ̀ ẹ̀rọ, àwọn apọ́nkè-ńlá, àti àwọn onímọ̀ nípa ìṣẹ̀dáyé àti àwọn ìsọ̀gbè ọ̀run. Síbẹ̀síbẹ̀, gẹ́gẹ́ bí òǹkọ̀wé náà ṣe kọ, bí ó tún tí jẹ́ ọdún 2023, “òṣùwọ̀n ìpààlà ti Diyanet kò ju ibùsọ̀ 90 lọ.” Àwọn mìíràn ti fi irú ìròrí báyìí tí Taliban. Ní ọdún 2021, Taliban ti ilẹ̀ Afghanistan ti fi òfin de àwọn obìnrin pé wọn ò gbọdọ̀ dá nìkan rin ìrìn àjò tó jù ibùsọ̀ 72 lọ.

Bẹ̀rẹ̀ ìtàkùrọ̀sọ náà

Òǹkọ̀wé, jọ̀wọ́ àkọsílẹ̀ ìwọlé »

Ìlànà

  • Atukọ̀ yóò ṣ'àtúnwò gbogbo ìsọsí . Máà fi ìsọsíì rẹ sílẹ̀ ju ẹ̀rìnmejì lọ tàbí kí a kà á sí iṣẹ́-ìjẹ́-tí-a-o-fẹ́.
  • Jọ̀wọ́ fi ọ̀wọ̀ fún ẹlòmíràn . A ò ní fi àṣẹ sí ìsọsí ìkórìíra, ìṣekúṣe, àti ìdojú-ìjà-kọ ẹnikẹ́ni k.