Àwọn àjòjì tí wọ́n gba òmìnira sọ ìrírí wọn ní ọgbà ẹ̀wọ̀n Myanmar

A crowd greets a bus carrying prisoners released Thursday, November 17, 2022, from Insein Prison in Yangon, Myanmar.

Àwọn èrò ń kí ọkọ̀ akérò tí ó gbé àwọn ẹlẹ́wọ̀n tí a tú sílẹ̀ ní Ọjọ́bọ, oṣù kẹsàn-án ọdún 2022. Àwòrán àti àkọ́lé láti RFA. Àṣẹ-ẹ̀dà © 1998-2020, RFA, tí ó jẹ́ lílò pẹ̀lú ìgbàláàyé ti Radio Free Asia, 2025 M St. NW, Suite 300, Washington DC 20036. https://www.rfa.org.

Myanmar dá àwọn ẹlẹ́wọ̀n 5,774 sílẹ̀ lásìkò àyájọ́ ọjọ́ òmìnira wọn ní oṣù kọkànlá ọjọ́ 17, èyí tí ó ṣe ìsààmì ìbẹ̀rẹ̀ rògbòdìyàn ìtako òfin amúnisìn àwọn ará Britain ní 1920.

Lára àwọn tí ó rí ìdáríjì ni ọ̀pọ̀lọpọ̀ ajìjàgbara, àwọn òǹkọ̀wé, àwọn òṣìṣẹ́ ẹgbẹ́ òṣèlú ìjọba tí àná, àti àwọn àjòjì mẹ́rin, lára wọn ni Sean Turnell, ẹni tí í ṣe ọmọ orílẹ̀-èdè Australia tí ó tún jẹ́ onímọ̀ nípa ètò ọrọ̀ ajé, oníròhìn àti onítàn alálàyé ìṣẹ̀lẹ̀ Kubota Toru ẹni tí í ṣe ọmọ orílẹ̀-èdè Japan, Vicky Bowman tí ó jẹ́ aṣojú orílẹ̀-èdè British nígbà kan, àti Kyaw Htay Oo tí ó jẹ́ ọmọ orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà tí ó sì tún jẹ́ apákan ẹ̀yà Burma.

Ní ọjọ́ 18 oṣù kọkànlá, ẹgbẹ́ olùrànwọ́ fún àwọn ẹlẹ́wọ̀n òṣèlú Burma, ìyẹn Assistance Association of Political Prisoners-Burma (AAPP) ti ṣe àkọsílẹ̀ ìtúsílẹ̀ àwọn ẹlẹ́wọ̀n òṣèlú 72. Ṣùgbọ́n àwọn tí ó tó bí i 13,000 ṣì ń faṣọ pénpé roko ọba lọ́gbà ẹ̀wọ̀n, ọ̀pọ̀ nínú wọn ni wọ́n fi ṣìkún òfin mú nítorí kíkọ̀jálẹ̀ láti tẹ̀lé àwọn ológun tí ó fipá gba ìjọba ní oṣù kejì ọdún 2021.

Ìtúsílẹ̀ náà di àfiléde lẹ́yìn tí ìpolongo kárí ayé ọlọ́jọ́ pípẹ́ èyí tí ó ń pè fún ìdásílẹ̀ logba ẹ̀wọ̀n pàápàá jù lọ àwọn tí ó ń fi pẹ̀lẹ́kùtù kọ ìjọba ológun wáyé. Àsìkò yìí bọ́ sí ọ̀sẹ̀ kan náà tí àwọn olórí àgbáyé wá fún ìpàdé Ìfọwọ́sowọ́pọ̀ Ètò ọrọ̀-ajé Asia-Pacific Economic Cooperation nítòsí ní Thailand.

‘Apanirun àti òmùgọ̀’

Turnell, ẹni tí ó siṣẹ́ gẹ́gẹ́ bí i olùbádámọ̀ràn fún olórí Myanmar àti alámì ẹyẹ Nobel Laureate, Aung San Suu Kyi di títìmọ́lé ni wọ́n mú lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀ lẹ́yìn ìdìtẹ̀ gba ìjọba náà tí wọ́n sì fi ẹ̀sùn ìtasẹ̀ àgẹ̀rẹ̀ sófin nípasẹ̀ títú àṣìírí Myanmar kàn. Lẹ́yìn tí ó padà sí Sydney, ó kọ èrò rẹ̀ nípa àwọn adarí Myanmar sí orí Facebook:

Mo mọ̀ dájú pé bí mo ṣe ní ìrírí ayọ̀ ojútúnrarí pẹ̀lú ìyàwó mi àti àwọn mọ̀lẹ́bí mi, àwọn ènìyàn mílíọ̀nù 53 ní Myanmar túbọ̀ ń jìyà lábẹ́ ìṣàkóso ìjọba tí kò kójú òṣùwọ̀n tó láti ṣojú wọn bí a ṣe lérò. Ó jẹ́ ohun ìbànújẹ́ àti ohun ẹ̀rù pé àwọn ènìyàn rere tí mo ti bá pàdé níbikíbi ni irú àwọn apanirun àti òmùgọ̀ bẹ́ẹ̀ ń ṣe ìjọba lé lórí.

Nínú àtẹ̀jáde mìíràn tó tẹ̀lé e, ó kọ nípa ìdúpẹ́ rẹ̀ fún àwọn ará Myanmar:

Nígbà tí ìdúpẹ́ (àti àbùdá inú rere àti ìkóra ẹni ní ìjánu wọn) kò ṣe kókó. Àwọn ará Myanmar jẹ́ olùfaragbá ipò kìnínní àwọn jàǹdùkú tí ó ń ṣe ìjọba lórí i wọn. Ní ọ̀pọ̀ ìgbà ní àwọn ará Myanmar ‘olórí pípé’ ń fi ìwà rere wọn hàn sí mi láàárín àwọn ọjọ́ 650 tí mo lò lẹ́wọ̀n (àwọn tí ó tún wá nínú ewu ju èmi lọ). 

Mo ní àfojúdi fún àwọn ọ̀gágun Myanmar, ṣùgbọ́n fún àwọn ènìyàn Myanmar  kò sí ohun mìíràn ju àpọ́nlé àti ìfẹ́ lọ. 

Nínú ìfọ̀rọ̀wánilẹ́nuwò pẹ̀lú ìwé ìròyìn The Australian, ó sọ nípa ìrírí rẹ nínú:

Wọn kò fi iná mànàmáná bò mí lára, ṣùgbọ́n wọ́n jù mí sínú túbú ẹlẹ́gbin. Oúnjẹ tí wọ́n máa ń gbé wá fún mi [má ń wà] nínú garawa. Fún ọjọ́ 650, inú garawa ni mo ti ń jẹun.

Ní àsìkò òjò wẹliwẹli, òrùlé yóò máa jò a ó sì jókòó nígbà mìíràn lati àṣálẹ́ pẹ̀lú omi tí ó kàn ń dà láti orí òrùlé tí wà á sì di aṣọ àti ìbora rẹ mọ́ra kí ó má ba à tutù.

‘Ibi Ìnira’

Wọn mú Kubota ní oṣù keje nígbà tí ó ń ya àwòrán ìwọ́de èhónú kan ni Yangon. Wọ́n dájọ́ ẹ̀wọ̀n ọdún méje fún un fún rírú òfin ìṣòwò orí ẹ̀rọ ayárabíàṣá àti ọdún mẹ́ta fún rírọ ẹni àti rírú òfin ìrìnàjò sí ìlú mìíràn.

Nínú ìfọ̀rọ̀wánilẹ́nuwò pẹ̀lú TRT World, ìkànnì agbóhùnsáfẹ́fẹ́ ti ìjọba Turkey, Kubota sọ̀rọ̀ nípa bí wọ́n ṣe mú un, ìfọ̀rọ̀wánilẹ́nuwò nínú àgọ́ ọlọ́pàá kan, àti ipò tí ó wà nínú túbú ọgbà ẹ̀wọ̀n:

Ìfọ̀rọ̀wánilẹ́nuwò rẹ̀ lẹ́kùn-ún rẹ́rẹ́ lórí YouTube

‘Ìwà Àgàbàgebè’

Pẹ̀lú ìgbòmìnira ọ̀pọ̀lọpọ̀ ẹlẹ́wọ̀n, olùyànnàná àti ajàfẹ́tọ̀ọ́ ọmọ ènìyàn ń rọ àwùjọ òkèèrè láti túbọ̀ tẹ̀síwajú nínú ìgbẹnusọ fún ìdásílẹ̀ ọ̀gọ̀ọ̀rọ̀ àwọn ẹlẹ́wọ̀n tí wọ́n ń kojú oríṣìiríṣìi ẹ̀sùn fún títako ìgbàjọba ológun.

Akọ̀ròyìn Aung Zaw, Olótùú iléeṣẹ́ ìgbóhùnsáfẹ́fẹ́ olómìnira tí ìjọba gbẹ́sẹ̀ lé, The Irrawaddy, ṣe ìkìlọ̀ nípa ọgbọ́n àrékérekè àtijọ́ tí àwọn ológun àgbajọba ń lò:

… a gbọdọ̀ tún rí ìdáríjì fún ohun tí ó jẹ́: ìwà àgàbàgebè, tí kò fẹ́rẹ̀ẹ́ ju ọgbọ́n àrékérekè tí ó ti pẹ́ láti ọdún púpọ̀ sẹ́yìn èyí tí àwọn ìṣèjọba àtijọ́ àti àsìkò yìí ń lò. A kò gbọdọ̀ jẹ́ kí ó tàn wá jẹ.

Mo ti rí kí èyí wáyé ní àìmọye ìgbà ní àárín ọdún 30 sẹ́yìnMo sì tún ti rí i bí ó ṣe ń lu díẹ̀ nínú àwọn àwùjọ òkèèrè ní jìbìtì láti gbà pé ìfẹnukò pẹ̀lú ológun ṣe é ṣe. 

Akọ̀wé gbogbo-gbòò AAPP tí ó ń jẹ́ U Tate Naing fìdìí rẹ múlẹ̀ pé ọ̀pọ̀ nínú àwọn ẹlẹ́wọ̀n òṣèlú tí wọ́n gba òmìnira ní wọ́n rán lẹ́wọ̀n lábẹ́ àwọn ẹ̀sùn tí kò lórí tí kò sí nídìí. Ó ṣàpèjúwe ìdáríjì ọ̀pọ̀ ènìyàn náà gẹ́gẹ́ bí i “ẹ̀tàn”:

Gbogbo ẹ̀tàn yìí jẹ́ ìgbìyànjú láti dín ipá àwọn ológun ní àárín ìlú àti lágbàáyé kù,  kí ó ba lè túbọ̀ tẹ̀síwajú láti máa hu ìwà ìkà lọ́joojúmọ́ sí àwọn ènìyàn.

Ní báyìí, aṣojú pàtàkì ti Ẹgbẹ́ Gúúsù ìlà oòrùn orílẹ̀-èdè Asia (Association of Southeast Asian Nations) faramọ́ ìdàgbàsókè ní Myanmar bí i “ìfarajúwe tí ó ṣe kókó” lójúnà ìrànwọ́ ìṣàgbékalẹ̀ àwùjọ tí ó fi àyè gba ìtàkurọ̀sọ.

Bẹ̀rẹ̀ ìtàkùrọ̀sọ náà

Òǹkọ̀wé, jọ̀wọ́ àkọsílẹ̀ ìwọlé »

Ìlànà

  • Atukọ̀ yóò ṣ'àtúnwò gbogbo ìsọsí . Máà fi ìsọsíì rẹ sílẹ̀ ju ẹ̀rìnmejì lọ tàbí kí a kà á sí iṣẹ́-ìjẹ́-tí-a-o-fẹ́.
  • Jọ̀wọ́ fi ọ̀wọ̀ fún ẹlòmíràn . A ò ní fi àṣẹ sí ìsọsí ìkórìíra, ìṣekúṣe, àti ìdojú-ìjà-kọ ẹnikẹ́ni k.