Ohùn-kẹ́lẹ́kẹ́lẹ́: Ìlọ́wọ́sí àwọn ìlú apá Ìwọ̀-Oòrùn nínú ìkógunjàlú tí Russia gbé ko Ukraine

Ìròyìn yìí jẹ́ ara Ohùn-kẹ́lẹ́kẹ́lẹ́, tí í ṣe ìwé ìròyìn Civic Media Observatory ti Ohùn Àgbáyé. Mọ̀ sí í nípa ìlépa wa, ìlànà-iṣẹ́, àti àwọn ìwífún-alálàyé tí ó wà ní àrọ́wọ́tó fún gbogbo mùtúnmùwà. Fọwọ́sígbígba ìròyìn Ohùn-kẹ́lẹ́kẹ́lẹ́.

Lẹ́yìn tí Russia ti kógunjàlú Ukraine ní oṣù Èrèlé, ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn aṣíwájú èrò ìjọba tiwantiwa Russia ló fẹ̀sùn kan Yúróòpù lórí ipa tí ó kó nínú ogun náà. Wọ́n sọ wí pé púpọ̀ nínú àwọn orílẹ̀-èdè Yúróòpù ló ń gbe ìṣèjọba Russia lọ́wọ́ nípasẹ̀ ríra epo àti gáàsì Russia, bíbá Putin àti àwọn alábáàsepọ̀ rẹ̀ dọ́rẹ̀ẹ́, àti títa àwọn ohun-èlò ogun jíjà fún Russia pàápàá lẹ́yìn òfin-ìfìyàjẹni àgbáyé tí a gbé lé Russia ní ọdún 2014 fún kíkọlu Crimea.

Wọ́n fi ẹ̀sùn – ìdínbọ́n tí ó hàn kedere, tàbí àìmọ̀kan nípa ìhàlẹ̀ sáà Putin kan àwọn ìlú apá Ìwọ̀-Oòrùn  – èyí tí ó kó Ìṣọ̀kan Yúróòpù, ẹgbẹ́ òṣèlú Yúróòpù àti àwọn ìjọba orílẹ̀-èdè bí i U.K, Hungary, Germany, àti Italy, àti àwọn yòókù wọn papọ̀. Orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà àti NATO kọ́ ni wọ́n dojú àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí kọ.

Kí ló dé tí ó fi ṣe pàtàkì?

Àlàyé wọ̀nyí ń mú àtúnṣe bá àlàyé Manichea ti àwọn ẹ̀dá ewèlè àti àwọn akọni. Wọ́n ṣe ìrànlọ́wọ́ tí ó ṣí aṣọ lójú òtítọ́ nlá níbi tí ibi ti ní àsopọ̀ tí ó sì jẹ́ wí pé Russia nìkan kọ́ ni orílẹ̀-èdè tí a máa dá lẹ́bi fún àwọn ohun ìbẹ̀rù ti ogun tí ó wáyé ní Ukraine.

Àwọn ènìyàn tí ó bá àwọn ìlú apá Ìwọ̀-Oòrùn wí fún ìdíjú wọn pẹ̀lú ìgba Putin àti ìkógunjàlú tí Ukraine gbé ko Russia kò yọ ìlọ́wọ́sí Russia kúrò nínú ogun náà. Àwọn èrò wọ̀nyí wá láti ọ̀dọ̀ àwọn ajàfẹ́tọ̀ọ́ orílẹ̀-èdè Russia tó jẹ́ lókìkí, àwọn  akọ̀ròyìn, àti àwọn alákadá tí wọ́n ti fi gbogbo ìgbésí ayé wọn kọ́ ilé ẹ̀kọ́ tó dúró ṣinṣin, títan ìmọ̀ kálẹ̀, àti ìtako ìṣèjọba Putin. Ìtàkùrọ̀sọ náà nípa ìlọ́wọ́sí àwọn ìlú apá Ìwọ̀-Oòrùn ṣe àfikún ìjìnlẹ̀ sí òye orísun ogun náà.

Àwọn àlàyé tó ta kókó

1. “Àwọn orílè-èdè oníṣọ̀kan EU ṣe alátìlẹ́yìn fún Putin àti ìṣèjọba Russia”

Àwọn ibá-ìṣẹ̀lẹ̀ àlàyé yìí tí ó ṣe pàtàkì:

  • Àríyànjiyàn yìí dá lórí ìgbàgbọ́ wí pé oríṣiríṣi àwọn orílè-èdè Oníṣọ̀kan Yúróòpù ni wọ́n ń ṣe onígbọ̀wọ́ àti alátìlẹ́yìn fún ìṣèjọba Russia àti fún Putin tìkaraarẹ̀.
  • Ní àárín oṣù Kẹ́ta ní ọdún 2022, iléeṣẹ́ oníròyìn atọ́sẹ̀ olómìnira Investigate EU ṣe àtẹ̀jáde ìròyìn kan tí o ṣe àkọọ́lẹ̀ bí ìdásí mẹ́ta àwọn orílè-èdè EU ṣe ta ohun ìjà fún Russia fún bí ọdún kan kí wọ́n tó gbógunti Ukraine, pẹ̀lú ìfòfin de ìlò ohun ìjà ọdún 2014. Àwọn ìhìn mìíràn tún ti jẹ yọ, tí ó fi ìdí èrò ìlọ́wọ́sí aláìṣetààrà ológun Yúróòpù nínú ogún náà fún ìgbà pípẹ́ múlẹ̀ kí Russia tó kógun ja ilẹ̀ Ukraine nípa títa ohun èlò ìjà fún wọn.
  • Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ẹgbẹ́ tó ń ṣe ohun tó tọ́ nínú EU ni àwọn olówó ilẹ̀ Russia tí ṣe ìgbọ̀wọ́ àìlẹ́gbẹ́ fún, àfipẹ̀lú Marine Le Pen ni ilẹ̀ Faransé àti Tories ní UK. Bakan naa ni awọn àròyé àjọṣepọ̀ láàárín ètò ìṣèjọba Putin àti Trump. Nítorí náà, ó ní ìbáṣepọ pẹ̀lú ìṣèjọba Putin ó tún ṣe ìrànwọ́ fún un pẹ̀lú ìṣòtítọ́-inú àti owó gáàsì àti epo tún mú kí ìtakọ̀ lọ ilẹ̀ ní Russia lọ́nà pàtàkì.
Àwọn àpẹẹrẹ tó ń sàfihàn àlàyé yìí

Àlàyé yìí jẹ́ gbajúmọ̀ nínú àwọn àtẹ̀jáde ẹ̀rọ agbéròyìnjáde ti àwùjọ tó ń ṣàlàyé àwọn àìdunnú sí àwọn ìpinnu àwọn orílè-èdè Yúróòpù nípa ogun tó ń ṣẹlẹ̀ ní Ukraine. Lọ́nà mìíràn, àwọn aṣàmúlò kọ̀ọ̀kan gbàgbọ́ wí pé àwọn ẹgbẹ́ òṣèlú Yúróòpù ló ṣàtìlẹ́yìn fún ìṣèjọba Putin nípa gbígba owó àìmọ̀ Russia ọlọ́pọ̀lọpọ̀ ẹgbẹ̀rún-lọ́nà-ẹgbẹ̀rún owó Yúrò láti ṣàṣeyorí àfojúsùn ìṣèlú wọn, àwọn ìjọba Yúróòpù kọ̀ọ̀kan náà tún ṣe bẹ́ẹ̀ nípa mímú ìgbáralé gáàsì Russia pọ̀ si. Lọ́nà mìíràn, kò sí àtìlẹ́yìn tààrà fún àwọn ológun Ukraine, pàápàá jù lọ sí àpapọ̀ àìṣedéédé àwọn ọmọ Ukraine àti àwọn alátìlẹ́yìn Russia tó wà ní Ukraine.

Nínú ìfọ̀rọ̀wánilẹ́nuwò kan ní oṣù Òkúdù, olóṣèlú tí ẹkùn Russia kan àti alátakò Putin Lev Schlosberg gbé ìbéèrè nípa ìbáṣepọ̀ àwọn ìlú apá Ìwọ̀-Oòrùn pẹ̀lú ìṣèjọba Putin dìde. Ní tirẹ̀, bíbéèrè fún epo àti gáàsì Russia ló mú kí àwọn adarí ìlú apá Ìwọ̀-Oòrùn ṣe àìbìkítà sí èrò ìmúgbòròjá Vladimir Putin fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọdún. Schlosberg ló sọ pé “ìlú apá Ìwọ̀-Oòrùn ní ìpín tìrẹ nípa ìlọ́wọ́sí nínú ohun tó ṣẹlẹ̀ sí orílẹ̀-èdè wá”.

Ní ìbẹ̀rẹ̀ oṣù Òkudù, Olga Bakushinskaya, akọ̀ròyìn ọmọ Russia kan tí ó gba ìwé ọmọ òǹnilẹ̀ orílẹ̀-èdè Israeli, ṣàmúlò Facebook rẹ̀ láti gbé èrò rẹ̀ jáde lórí orísun ìkógunjàlú tí Russia gbé ko Ukraine. Àtẹ̀jáde rẹ̀ sọ̀rọ̀ nípa àrọ̀kọ kan tí onímọ̀ ìbáraẹnigbépọ̀ ọmọ Russia kan tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Grigory Yudin kọ nípa ìlọ́wọ́sí àwọn ìlú apá Ìwọ-oòrùn nínú ogun náà.

Nínú àròkọ̀ náà, Yudin kọ pé, “Putin kò dédé jáde látinú aginjù Siberia; ó ti ń ba àwọn ètò ìṣúná owó àgbáláaye àti àwọn bọ̀rọ̀kìnní jẹ́ fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọdún. Àwọn olówó rẹ̀ ti ń jẹ ìgbádùn ọrọ̀ àìnídàálẹ́kun àti ìyìn-ẹlẹ́tan káàkiri gbogbo àgbáyé fún ìgbà pípẹ́ tí wọ́n wá ṣe ìpinnu, láì ṣe pé kò nídìí, wí pé àwọn ni ọ̀gá gbogbo àgbáyé.”

Bakushinskaya kọ̀wé: “Nítorí náà, láì sí àní-àní ògbò ogúnléndé alágbede Russia kò jẹ́bi tó ògbò olóṣèlú Germany. Ìyàtọ̀ tó wà láàárín wọn ní pé wọ́n ti fagi lé ti àkọ́kọ́ wọn kò sì tún gbà á láyè láti ṣí àpò-ìkówópamọ́sí. Ní ti àwọn olóṣèlú, ó ti wà ní ṣíṣí owó Russia sì ti kún inú rẹ̀ fọ́fọ́.”

Pavel Chikov, agbẹjọ́rọ̀ ajàfẹ́tọ̀ọ́ ọmọ ènìyàn jàǹkànjàǹkàn kan tí ó ti ń ṣáájú nínú ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ẹjọ́ tí ó jẹ mọ́ ètò ìṣèlú, lo aṣàmúlò Facebook rẹ̀ láti gbé sọ nípa Ilé-ẹjọ́ Ẹ̀tọ́ Ọmọ-ènìyàn, tí ó lọ́ra láti ṣe ìpinnu lórí àwọn ẹjọ́ Russia nígbà tí Russia ṣì jẹ́ ọmọ ẹgbẹ́. Ní kété tí Russia kúrò nínú Ìgbìmọ̀ nítorí ogun náà, kíá ni ilé-ẹjọ́ náà jára mọ́ṣẹ́ bí ó bá jẹ́ àwọn ẹjọ́ tó jẹ mọ́ Russia. Pavel ń wòye ohun tí ìṣòro náà jẹ́: ó kọ “Ní àárín ọdún 5 láti oṣù Kẹta ọdún 2017, ó kéré tán ẹ̀sùn 5000 ló wá láti ọ̀dọ̀ àwọn alátakò ni wọ́n ti kọ sí ECHR. Ǹjẹ́ o mọ iye àwọn ìpinnu? Bóyá márùn-ún.”

Wo ohun tí ó bá a tan níbi sí i

2. “Àwọn orílẹ̀-èdè apá Ìwọ-oòrùn kò ṣe àtìlẹ́yìn tí ó tó fún èrò ìjọba àwaarawa”

Àwọn ibá-ìṣẹ̀lẹ̀ àlàyé yìí tí ó ṣe pàtàkì:

  • Ìrò pé akitiyan ọmọ Russia tí ó jẹ́ àtakò Putin àti àwọn elérò ìjọba tiwantiwa tiraka láti yege nítorí pé kò sí orílẹ̀ èdè tó ṣe àtìlẹ́yìn fún wọn tàbí ìgbésẹ̀ látọ̀dọ̀ àwọn ilẹ̀ mìíràn.
  • Ìwí pé Yúróòpù ṣe onígbọ̀wọ́ fún ìṣèjọba Putin nípa ti ìṣèlú àti ìṣúná ọrọ̀ ajé kò sì tún gbọ́ràn sí àwọn ajàfẹ́tọ̀ọ́ ọmọ ènìyàn àti àwọn aṣáájú atakò lẹ́nu.
  • Ìfẹ̀hónúhàn ìtako ìṣèjọba Putin tí ó lágbára bẹ̀rẹ̀ ní ọdún 2011 sí ọdún 2012. Nígbà náà, gẹ́gẹ́ bí àpèjúwe yìí, kò sí akitiyan orílẹ̀ èdè tàbí ìṣọ̀kan tó nífẹ̀ẹ́ sí ṣiṣẹ́ ìgbèlẹ́sẹ̀ fún àwọn tó ń tako ìṣèjọba náà ni ọ̀nà tó ní ìtumọ̀. Aṣáájú alátakò Russian Alexei Navalny ti ń ké sí àwọn ìlú apá Ìwọ-oòrùn láti fìyà jẹ àwọn olówò àti àwọn bọ̀rọ̀kìnní Russia fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọdún, ṣùgbọ́n nígbà tí Russia kojú ogun sí Ukraine ni ó tó wáyé. 

Nípa àwọn ìjẹníyà: 

Nípasẹ̀ àwọn àròkọ olóòtú àti àwọn ètò orí ẹ̀rọ amóhùnmáwòrán, ọ̀nà ìtànkálẹ̀ ìjọba orílẹ̀-èdè Russia ń gbìdánwò láti yí àwọn ọmọ Russia wí pé ìjẹniníyà àgbáyé kò ṣiṣẹ́. Ó ní àwọn òpó múléró méjì tí ó ń kópa nínú ọ̀rọ̀ yìí: 

  • “Àwọn ìfìyàjẹni máa ń pa àwọn ènìyàn lásán lára ju ìjọba lọ”: 

Ìwí náà ni pé àwọn ènìyàn lásán nílùú Russia, tí kì í ṣe ìjọba, ni ó ń rí ipa àìtó àwọn ọjà tòun iṣẹ́ tí ìjẹniníyà tí ó ti ara ìdáhùnsí ìkógunjàlú Ukraine àti ipa rẹ̀ láyé wọn ní oríṣìíríṣìí ọ̀nà jẹyọ. 

  • “Àwọn ìjẹniníyà àti àìtó dára fún ọrọ̀ ajé Russian”:

Ìrò wí pé ìjẹniníyà àwọn ìlú apá Ìwọ-oòrùn tí ó tẹ̀lé ìkógunjàlú tí Russia gbé ko Ukraine, àti àìtó oníbàárà àti ọjà ajẹmóléeṣẹ́ ńlá, yóò kan ṣe àǹfààní fún ètò ọrọ̀ ajé Russia àti ìṣelọ́pọ̀ ọjà Russia nípa mímú lágbára àti ìmúgbòrò sí i. Òpó yìí tún ṣe àfikún àwọn ìjẹniníyà àti àìtó dára fún àwọn ọmọ ìlú Russia fún onírúurú àwọn ìdí ẹ̀rọ ajẹ́mọ́báyéṣerí àti ajẹmọ́ṣẹ́ọkàn (ó ní ìlera tí ó pọ̀, ó mú wọn rí ìdí pàtàkì tí ó fi yẹ kí wọn ó padà sí orírun wọn” ó sì mú wọn rántí ayé Soviet, abbl.).

Àwọn àpẹẹrẹ tó ń ṣàfihàn àlàyé yìí 

Nínú àròkọ kan tí Meduza tẹ̀jádé, Grigoriy Yudin, onímọ̀ ìbáraẹnigbépọ̀ Russian dá ohun tí ó wà lókè sọ, tọ́ka wí pé àwọn olóṣèlú Yúróòpù ń gba ọ̀pọ̀lọpọ̀ owó lọ́wọ́ Putin, wọ́n bá a ń dọ́rẹ̀ẹ́, wọ́n sì máa ń dijú wọn sí àwọn ìwà búburú sáà náà fún èrè ètò ìṣúná owó. Bákan náà ni fún àwọn aṣáájú ilé-iṣẹ́ afòfingbéró tí ó jẹ́ kí ó di mímọ̀ wí pé wọ́n kò bìkítà nípa ogun náà, àti pé àwọn èrè tí wọ́n pàdánù nìkan ló jẹ wọ́n lógún. Àkọlé kókó ìròyìn rẹ̀ tuntun ni “Pagidarì, kì í ṣe nípa àwọn ará Russia,” èyí tí kò sí mú iṣẹ́ Russia kúrò fún ogun náà ṣùgbọ́n ó pe àpèjúwe wí pé Russia nìkan ni olùkópa tó yẹ ká dá lẹ́bi níjà.

Fún Yudin ní tirẹ̀, ìgbàgbọ́ tí wọ́n kókìkí rẹ̀ jù tí àwọn aṣáájú ìlú apá Ìwọ oòrùn dìmú — wí pé Russia kò yípadà rí àti wí pé ìjọba afipámúniṣìn ni lọ́jọ́ ọ̀la rẹ̀ — ni ohun tí ó ń fa ìdíwọ́ fún àyípadà. Láti kádìí rẹ̀, ó ní “Ìrètí kò lè farahàn níbí àyàfi tí àgbáyé bá mọ̀ pé Vladimir Putin àti ogun rẹ̀ ni àbájáde gbogbo àwọn ìdàgbàsókè àgbáyé ní àwọn ọdúnwàá tí ó ré kọjá. Kì í ṣe kí okòwò àgbáyé ni ó ni àkóso ẹ̀mí àwọn ọmọ Ukraine, kò sì kì í ṣe ohun ìpín àwọn onípìnín-ìdókòwò nìkan.” 

Natalia Gromova, ọmọ Russia kan tí ó jẹ́ òǹkọ̀wé, ṣe àríwísí àròkọ Yudin: “Òtítọ́ pé sáà ìṣèjọba Putin ti wúlò fún àgbáyé ti di mímọ̀ fún gbogbo ènìyàn fún ìgbà pípẹ́, wí pé kò sí irú ìfẹ̀hónúhàn náà, ikú àwọn akọ̀ròyìn, àwọn ajàfẹ́tọ̀ọ́ ọmọ ènìyàn, ìfipámúni, ìfipámúni, lílu ni láàárín ìlú – pàápàá kò sí ṣe ẹnikẹ́ni lókè òkun ní làálàá, òtítọ́ tún ni eléyìí. Dáná sun ara rẹ ní gbàgede ìlú, jẹ́ kí wọ́n fún ọ ní májèlé kí wọ́n sì pa ọ́ ní ìta gbangba ní ìṣojú gbogbo ọmọ aráyé – gáàsì àti èpò máa dé ní àsìkò tí ó tọ́.”

Wo àwọn àtòjọ ohun tí ó bá a tan níbi sí i:

Bẹ̀rẹ̀ ìtàkùrọ̀sọ náà

Òǹkọ̀wé, jọ̀wọ́ àkọsílẹ̀ ìwọlé »

Ìlànà

  • Atukọ̀ yóò ṣ'àtúnwò gbogbo ìsọsí . Máà fi ìsọsíì rẹ sílẹ̀ ju ẹ̀rìnmejì lọ tàbí kí a kà á sí iṣẹ́-ìjẹ́-tí-a-o-fẹ́.
  • Jọ̀wọ́ fi ọ̀wọ̀ fún ẹlòmíràn . A ò ní fi àṣẹ sí ìsọsí ìkórìíra, ìṣekúṣe, àti ìdojú-ìjà-kọ ẹnikẹ́ni k.