Ìròyìn asọ̀tàn nípa Ìfẹ̀hónúhàn
Ìròyìn nípa Ìfẹ̀hónúhàn
Fún Ayẹyẹ Àìsùn Ọdún Tuntun àwọn Ilé-Ìwé ní Moscow, àwọn orin kan ò bójúmu
Ní àpapọ̀, àtòjọ náà ní àwọn olórin àti ẹgbẹ́ eléré 29. Díẹ̀ nínú wọn, bíi Little Big àti Manizha, ti ṣojú orílẹ̀-èdè Russia rí ní ìdíje Eurovision fún ọdún púpọ̀ látẹ̀yìnwá. Gbogbo wọn pata ni wọ́n bu ẹnu àtẹ́ lu ìkọlù orílẹ̀-èdè Russia sí Ukraine ní gbangba
Ọlọ́pàá Orílẹ̀-èdè Indonesia mú akẹ́kọ̀ọ́ mẹ́fà tí ó na àsíá ‘Àyájọ́ òmìnira orílẹ̀-èdè Papua’ tí a gbẹ́sẹ̀lé sókè
Ọjọ́ kìnínní, oṣù Kejìlá, ọdún 2021 ni àwọn ènìyán kà sí Ọjọ́ Òmìnira orílẹ̀-èdè Ìwọ̀ Oòrùn Papua, sàmì àyájọ́ ọgọ́ta ọdún tí a kọ́kọ́ ta àsíá Ìràwọ̀ Òwúrọ̀ ní ìgbésẹ̀ láti gba òmìnira lọ́wọ́ ìjọba àmúnisìn Dutch
Ìlàkàkà láti fi òpin sí òkúrorò SARS ẹ̀ka ilé-isẹ́ ọlọ́pàá ilẹ̀ Nàìjííríà ń tẹ̀síwájú.
Ìbéèrè lórí ẹni tí ó ń darí àwọn Ọlọ́pàá àti ikọ̀ SARS kò tíì fi gbogbo ara rí ìdáhùn. Ìwé-òfin ilẹ̀ náà gbágbára ìdárí lé ààrẹ lọ́wọ́, ó sì gbé agbára àmójútó lé Ọ̀gá àgbà ilé iṣẹ́ Ọlọ́pàá lọ́wọ́.
COVID-19 ṣe àgbéǹde ìṣẹ̀lẹ̀-àtẹ̀yìnwá tó burú jáì nípa ìdánwò egbògi ní Ilẹ̀-Adúláwọ̀
Ilẹ̀-Adúláwọ̀ 'kì í ṣe yàrá ìṣàyẹ̀wò' fún egbògi àjẹsára COVID-19. Àríyànjiyàn tí ó dá lóríi ìṣẹ̀lẹ̀-àtẹ̀yìnwá tí ó burú jáì nípa fífi ọmọ ènìyàn ṣe ìdánwò àti fífọwọ́ọlá gbá ọmọ Ilẹ̀-Adúláwọ̀ lójú.
Àwọn òṣìṣẹ́ iléeṣẹ́ aṣẹ̀wùtà orílẹ̀-èdè Cambodia daṣẹ́sílẹ̀ látàrí àìsan owó ọ̀yà wọn lásìkò àjàkálẹ̀ COVID-19
"A kò leè jẹ́ k'áwọn agbanisíṣẹ́ ó wí àwáwí tí yóò f'àfàsẹ́yìn fówó ọ̀yà àwọn òṣìṣẹ́, nítorí àwọn òṣìṣẹ́ ti jẹ gbèsè, wọn kò sì gbọdọ̀ jáfara láti san owó wọn."
Ìrọ́lù ọlọ́pàá tí í mú ikú bá ‘ni ní Guinea bí Ààrẹ Alpha Condé ṣe kọ̀ láì gbé’ jọba sílẹ̀
Ìwà ipá ọlọ́pàá tí ó ń ṣekú pani ní Guinea bí ààrẹ ṣe gbèrò láti yí ìwé-òfin padà kí ó bá wà lórí ipò. Àwọn afẹ̀hónúhàn pa ẹni mẹ́fà àti ọlọ́pàá kan, ọ̀pọ́ sì fara pa.
Àdàwólulẹ̀ ilé ayé-àtijọ́ ọlọ́dún-un 150 fi àìkáràmáìsìkí ìjọba sí àwọn ibi àjogúnbáa Bangladesh hàn
"Ọnà ara ilé náà kọjá àfẹnusọ tí a kò le è rí lára àwọn ilé mìíràn ní àwọn agbègbè àtijọ́ọ Dhaka. Fún ìdí èyí, [kò] yẹ kí ilé náà di àdàwólulẹ̀."
Àwọn ọmọ ìbílẹ̀ Brazili ra ìpín ìdókòòwò ní iléeṣẹ́ reluwé láti bá a wí fún ìkùnà ojúṣe àyíkáa rẹ̀
Ìlépa alájọpín-ìdókòòwòo wọn kì í ṣe fún ti èrè ìdókòòwò, àmọ́ láti mú kí ohùn-un wọn ó dé etí ìgbọ́ àwọn olùdókòòwòo iléeṣẹ́ náà.
Àfilé iye owó fún gbígba ìwé ẹ̀rí ọmọ-ìlú-fún-ìrìnnà mú àwọn ọmọ Angola fi ẹ̀hónú hàn
Iye owó ìwé ẹ̀rí náà fò sókè láti owó dollar orílẹ̀-èdè US 8 sí 97.
Akẹ́kọ̀ọ́bìrin kan tí ó jẹ́ ọmọ Tibet-Canada rí ìkọlu lórí ayélujára lẹ́yìn tí ó já ewé olú borí nínú ìdìbò àjọ-ìgbìmọ̀ akẹ́kọ̀ọ́. Ó rò pé, Beijing ló yẹ á bá wí.
Chemi Lhamo dojú kọ onírúurú èsì ìdáyàjáni ní orí ẹ̀rọ-alátagbà láti ẹnu àwọn akẹ́kọ̀ọ́ òkè-òkun tí ó ń gbé ní gbùngbùn orílẹ̀-èdè China.