Fún Ayẹyẹ Àìsùn Ọdún Tuntun àwọn Ilé-Ìwé ní Moscow, àwọn orin kan ò bójúmu

Ní inú oṣù Ọpẹ́, ọdún 2022, àwọn tí wọ́n ń sọ èdè Russia lórí Twitter àti Telegram rí àtẹ̀ránṣẹ́ kan tí ó ń tàn kiri. Wọ́n gbé e kalẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ẹ̀dà àtẹ̀ránṣẹ́ tí a pín káàkiri láàárín àwọn ilé-ẹ̀kọ́ tí ó kalẹ̀ sí ìlú Moscow fún àwọn tí wọ́n ń ṣètò àwọn ayẹyẹ àìsùn Ọdún Tuntun èyí tí wọ́n ṣàtòjọ àwọn orin ẹgbẹ́ eléré Russia àti ti Ukraine tí “kò gbọdọ̀” jẹ́ kíkọ ní àsìkò irú ayẹyẹ bẹ́ẹ̀.

Níwọ̀n bí kò ṣe hàn kedere bí èyí bá jẹ́ ẹ̀dà àtẹ̀ránṣẹ́ kan ní tòótọ́, púpọ̀ nínú àwọn ẹ̀gbẹ́ eléré àti àwọn olórin tí a dárúkọ ní wọ́n wà nínú àtòjo ̣kan ti àwọn tí àjọdún orin wọn ti di èèwọ̀ lórílẹ̀-èdè Russia láti ìgbà tí Moscow ti ya bo orílẹ̀-èdè Ukraine, nítorí pé wọ́n rí àwọn ẹgbẹ́ eléré náà gẹ́gẹ́ bí èyí tí ó ń ṣe “àtakò-ìfẹ́-orílẹ̀-èdè” tàbí “àtakò-orílẹ̀-èdè-Russia.”

Ohùn Àgbáyé (Global Voices) yan àwọn orin díẹ̀ láti inú àtòjọ àwọn ẹgbẹ́ eléré tí a “fòfindè” fún ọ láti gbádùn.

Monetochka jẹ́ olórin láti ìlú Yekaterinburg, ìgboro orílẹ̀-èdè Russian tí ó ní mílíọ́nù 1.5 ènìyàn ní ẹkùn Urals. Ọmọ-ọdún 15 ni ó jẹ́ nígbà tí ó di gbajúgbajà pẹ̀lú àwọn orin tí́ ó kọ. Láti ìgbà náà, ó ti ṣe ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn àwo orin tí ó gbajúgbajà jáde. Ní́gbà tí ìkọlù orílẹ̀-èdè Russia sí Ukraine bẹ̀rẹ̀ ní inú oṣù Kejì, ọdún 2022, ó kúrò ní orílẹ̀-èdè náà, ó sì sọ̀ro láìfòyà tako ogun náà.

Èyí ni àwòrán-olóhùn rẹ̀ tuntun ti orin “Burn, burn.” (Jóná, jóná). Ó kọ ọ́ lórin pẹ́ “Jóná, orílẹ̀-èdè mi, jóná, ẹ máà dáwọ́ iná dúró,” tí ó ń sọ̀rọ̀ tako ohun ti orílẹ̀-èdè Russia ti dà.

Ọ̀kan lára àwọn ẹgbẹ́ eléré ilẹ̀ Ukraine tí ó gbajúgbajà jùlọ ni Okean Elzy. Ẹgbẹ́ eléré náà ti jẹ́ àpéjọwò lájọ orin lágbàáyé láti ọdún 1994, adarí rẹ̀ Svyatoslav Vakarchuk sì tún jẹ́ ajàfẹ́tọ̀-ọmọnìyàn lábala òṣèlú. Ní ọdún yìí, ẹgbẹ́ náà ti ṣe ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn àjọ̀dún orin nílẹ̀ Yúróòpù ní àtìlẹyìn fún orílẹ̀-èdè Ukraine. Orin àtijọ́ ni èyí ṣùgbọ́n ó lààmìlaaka ó sì tún bágbàmu: a pè é ní “Without fight” (Láìsíjà) ó sì dá lórí àìsọ̀rètínù ènìyàn láì fìjà pẹ́ẹ́ta.

Olórin mìíràn ni ònkọrin tàkaasúfèé Oxxxyimiron. Ó jẹ́ ọ̀kan nínú àwọn ìràwọ̀ ònkọrin ráàpù ọmọ orílẹ̀-èdè Russia tí ó gbajúgbajà jùlọ, ó sì máa ń kópa nínú àwọn ìfẹ̀họ́núhàn ìjàfẹ́tọ̀ọ́. Ó sì tún fìlù sílẹ̀ lẹ́yìn ìbẹ̀rẹ̀ ìkọlù náà. Orin yìí, tí a pè ní “Oida,” ń bu ẹnu àtẹ́ lu Putin àti ogun náà.

Ní àpapọ̀, àtòjọ náà ní àwọn olórin àti ẹgbẹ́ eléré 29. Díẹ̀ nínú wọn, bíi Little Big àti Manizha, ti ṣojú orílẹ̀-èdè Russia rí ní ìdíje Eurovision fún ọdún púpọ̀ látẹ̀yìnwá. Àwọn mìíràn jẹ́ orin ìgbàdégbà, bíi Boris Grebenschikov tàbí DDT rock band.  Gbogbo wọn pata ni wọ́n bu ẹnu àtẹ́ lu ìkọlù orílẹ̀-èdè Russia sí Ukraine ní gbangba.

Bẹ̀rẹ̀ ìtàkùrọ̀sọ náà

Òǹkọ̀wé, jọ̀wọ́ àkọsílẹ̀ ìwọlé »

Ìlànà

  • Atukọ̀ yóò ṣ'àtúnwò gbogbo ìsọsí . Máà fi ìsọsíì rẹ sílẹ̀ ju ẹ̀rìnmejì lọ tàbí kí a kà á sí iṣẹ́-ìjẹ́-tí-a-o-fẹ́.
  • Jọ̀wọ́ fi ọ̀wọ̀ fún ẹlòmíràn . A ò ní fi àṣẹ sí ìsọsí ìkórìíra, ìṣekúṣe, àti ìdojú-ìjà-kọ ẹnikẹ́ni k.