Ìròyìn nípa Ìṣèlú
Ọlọ́pàá Orílẹ̀-èdè Indonesia mú akẹ́kọ̀ọ́ mẹ́fà tí ó na àsíá ‘Àyájọ́ òmìnira orílẹ̀-èdè Papua’ tí a gbẹ́sẹ̀lé sókè
Ọjọ́ kìnínní, oṣù Kejìlá, ọdún 2021 ni àwọn ènìyán kà sí Ọjọ́ Òmìnira orílẹ̀-èdè Ìwọ̀ Oòrùn Papua, sàmì àyájọ́ ọgọ́ta ọdún tí a kọ́kọ́ ta àsíá Ìràwọ̀ Òwúrọ̀ ní ìgbésẹ̀ láti gba òmìnira lọ́wọ́ ìjọba àmúnisìn Dutch
Ní orílẹ̀-èdè Turkey, ẹgbẹẹgbẹ̀rún méjì àbọ̀ àwọn akẹ́kọ̀ọ́ ni wọ́n jókòó ṣe ìdánwò ìgbaniwọlẹ́ sí Ifásitì
Awuyewuye wà lórí ìdáwò ọdún yìí -- kò sì kín ṣe látàri àjàkálẹ̀ àrùn COVID-19.
Ní àwọn ìlú tí ó wà lábẹ́ ìṣàkóso Assad ní ilẹ̀ Syria, àwọn alákòóso sọ báyìí pé ‘kò sí èni tí ó ní àrùn kòrónà’
Láti tẹnpẹlẹ mọ́ ìṣàkóso, sáà Assad ṣe ohun gbogbo tí ó lè ṣe ní ti ìkọ̀jálẹ̀ wí pé kò sí COVID-19 ní àwọn agbègbè tí ó wà lábẹ̀ ìṣàkóso rẹ̀.
Àwọn obìnrin ní Nàìjíríà kojú àdó-olóró àgbẹ́sẹ̀léró àgbàwí ọ̀rọ̀ ìṣèlú lórí ẹ̀rọ-ayélujára
Fakhriyyah Hashim, ọ̀kan lára àwọn olùdásílẹ̀ ìpolongo #ArewaMeToo ní àríwá orílẹ̀ èdè Nàìjíríà sọ wí pé “Mo ti kọ́ ìfaradà.”
Ní Burundi, àwọn akọ̀ròyìn mẹ́rin tí a fi sátìmọ́lé ń dúró de ìpinnu ẹjọ́ kòtẹ́milọ́rùn
A fi ẹ̀sùn ìlọ́wọ́sí ìdúkokò mọ́ ààbò ìlú ni a fi kan àwọn akọ̀ròyìn mẹ́rin náà látàrí iṣẹ́-ìjẹ́ ẹ̀fẹ̀ lásán tí wọ́n fi ṣọwọ́ nígbà tí wọ́n kó ròyìn ẹgbẹ́ ọlọ́tẹ̀ kan jọ.
Twitter di pápá ìròyìn ayédèrú lásìkò Ìdìbò ọdún-un 2019 ní Nàìjíríà
Twitter di pápá ayédèrú ìròyìn ìtako ẹ̀yà kan àti ìsọkiri ṣáájú ìdìbò, lásìkò ìdìbò àti lẹ́yìn ìdìbò ti ọdún-un 2019 lórílẹ̀-èdèe Nàìjíríà
Ẹ̀rọ Alátagbà ni a fi gbé àwọn ìròyìn irọ́ àti ọ̀rọ̀ ẹlẹ́yàmẹyà jáde lásìkò ìdìbò orílẹ̀-èdèe Nàìjíríà
Ìbò ọdún-un 2019 orílẹ̀-èdèe Nàìjíríà rí àwọn ọ̀rọ̀ ìkórìíra ẹ̀yà tẹ̀gbintẹ̀gbin láìròtẹ́lẹ̀ nípasẹ̀ẹ ìròyìn ẹlẹ́jẹ̀ àti ọ̀nà ìtànkálẹ̀ ìròyìn lórí ayélujára, pabambarì lóríi gbàgede Twitter.
Ilé ẹjọ́ gíga Tanzania pa á láṣẹ fún ìfòpinsí ìsoyìgì láàárín àgbàlagbà àti ọmọdé láì wo ti ìgbésẹ̀ ìmúpadàa rẹ̀
Nínú oṣù Ọ̀wàrà 2019, Ilé-ẹjọ́ Gíga Tanzania ṣe ìdímú ṣinṣin ìdájọ́ láti fòpin sí ìgbéyàwó ọmọdé. Ìdájọ́ ilé ẹjọ́ náà jẹ́ atọ́ka sí ìfòpinsí àwọn àṣà tí ó ń mú ìpalára bá àwọn ọmọdébìnrin àti onírúurú ẹlẹ́yàmẹyà tòun ìfọwọ́rọ́sẹ́yìn àwọn ọmọdébìnrin.
Ààmì ìdánimọ̀ orílẹ̀ èdèe Jamaica tí Kanye West lò di awuyewuye tí ó dá fìrìgbagbòó lórí ‘ìsààmì’
"Ìṣàkóso ìjọba tó lọ kò rí ọrọ̀ tó wà nínú àwọn ààmìi orílẹ̀ èdèe ‘Jamaica’ tàbí èyí [tó dúró fún] orílẹ̀ èdè bíi àsíá ìlú àti ti ológun..."
Ìrọ́lù ọlọ́pàá tí í mú ikú bá ‘ni ní Guinea bí Ààrẹ Alpha Condé ṣe kọ̀ láì gbé’ jọba sílẹ̀
Ìwà ipá ọlọ́pàá tí ó ń ṣekú pani ní Guinea bí ààrẹ ṣe gbèrò láti yí ìwé-òfin padà kí ó bá wà lórí ipò. Àwọn afẹ̀hónúhàn pa ẹni mẹ́fà àti ọlọ́pàá kan, ọ̀pọ́ sì fara pa.