Ìròyìn nípa Ìjàmbá
Ní àwọn ìlú tí ó wà lábẹ́ ìṣàkóso Assad ní ilẹ̀ Syria, àwọn alákòóso sọ báyìí pé ‘kò sí èni tí ó ní àrùn kòrónà’
Láti tẹnpẹlẹ mọ́ ìṣàkóso, sáà Assad ṣe ohun gbogbo tí ó lè ṣe ní ti ìkọ̀jálẹ̀ wí pé kò sí COVID-19 ní àwọn agbègbè tí ó wà lábẹ̀ ìṣàkóso rẹ̀.
Ìgbàgbọ́ ọba kan nínú ewé àtegbó fún ìwòsàn COVID-19 f'ara gbún ìmọ̀-ìjìnlẹ̀ l'órílẹ̀-èdè Nàìjíríà
Ọba orílẹ̀-èdè Nàìjíríà yìí nígbàgbọ́ nínú ewé àtegbó fún àwòtán COVID-19. Àmọ́ fífi Ògún gbárí láìfẹ̀rìílàdìí lórí Twitter fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ olùbárìn lè ṣini lọ́kàn — ó sì léwu — fún àwọn ènìyàn.
Àwọn Iléèjọsìn ní Greece àti Àríwá Macedonia kọ̀ láti yí ọwọ́ àwọn ìlànà-ìsìn wọn padà k'ó ba má fàyè gba àjàkálẹ̀ àrùn COVID-19 t'ó ń ràn ká
Ìlànà ìsìn tí a mọ̀ sí Jíjẹara àti mímu ẹ̀jẹ̀ Olúwa tàbí Oúnjẹ Ìkẹyìn ní èyí tí àwọn ọmọ lẹ́yìn Krístì tí ó ń tẹ̀lé ìlànà ìsìn àtijọ́ yóò máa pín wáìnì tí a ti sọ di mímọ́ mu pẹ̀lú ṣíbí kan náà, àwọn Ìjọ Àgùdàá máa ń jẹ ẹ̀bẹ àkàrà fẹ́lẹ́fẹ́lẹ́ tí wọ́n fi ẹnu gbà lọ́wọ́ àlùfáà.
Àwọn ọmọ Bangladeshi lo ẹ̀rọ-alátagbà fi gbógun ti àjàkálẹ̀ àìsàn ibà-ẹ̀fọn
Pẹ̀lú ìkéde àti ètò tí kò tó nǹkan láti ọ̀dọ̀ ìjọba, àwọn ènìyàn ti ń kọrí sí ẹ̀rọ-alátagbà lọ láti k’ẹ́kọ̀ọ́ àti kéde nípa ibà-ẹ̀fọn