Ìròyìn nípa Ọrọ̀-Ajé àti Okòwò
Ilẹ̀-Adúláwọ̀ rí àbọ̀ ẹgbẹẹgbẹ̀rún-lọ́nà-ẹgbẹ̀rún owóo dollar láti ọ̀dọ̀ Ilé-ìfowópamọ́sí ńláńlá fún ìgbéfúkẹ́ Iléeṣẹ́ ọgbọ́n àtinudá
“Nítorí àìtó ìdókoòwò ń'nú iléeṣẹ́ ọgbọ́n àtinudá àti àṣà, Ilẹ̀-Adúláwọ̀ kò sí ń'nú ọjà iṣẹ́ ọpọlọ, àti ìdáraáwò ní àgbáyé," Benedict Oramah, ààrẹ Afreximbank ló sọ bẹ́ẹ̀.
Ilé ẹ̀kọ́ ìmọ̀ orin kíkọ kan ṣoṣo ní Zanzibar ti fẹ́ di títì pa
For the 1,800 talented students who have trained at the DCMA, this is the only musical home they know, where they can learn and grow as professional musicians and artists.
Ìrìn-àjò: Ìpẹ̀kun eré-ìdárayá fún Ọmọ-adúláwọ̀
Ó ṣòro fún Ọmọ-adúláwọ̀ láti ṣèrìnàjò jáde kúrò ní Ilẹ̀-adúláwọ̀ — ṣùgbọ́n bẹ́ẹ̀ náà ni ó nira láti rìrìnàjò láàárín ilẹ̀ náà.
Àdàwólulẹ̀ ilé ayé-àtijọ́ ọlọ́dún-un 150 fi àìkáràmáìsìkí ìjọba sí àwọn ibi àjogúnbáa Bangladesh hàn
"Ọnà ara ilé náà kọjá àfẹnusọ tí a kò le è rí lára àwọn ilé mìíràn ní àwọn agbègbè àtijọ́ọ Dhaka. Fún ìdí èyí, [kò] yẹ kí ilé náà di àdàwólulẹ̀."
Àwọn ọmọ ìbílẹ̀ Brazili ra ìpín ìdókòòwò ní iléeṣẹ́ reluwé láti bá a wí fún ìkùnà ojúṣe àyíkáa rẹ̀
Ìlépa alájọpín-ìdókòòwòo wọn kì í ṣe fún ti èrè ìdókòòwò, àmọ́ láti mú kí ohùn-un wọn ó dé etí ìgbọ́ àwọn olùdókòòwòo iléeṣẹ́ náà.