Ọ̀rọ̀ Ààbò Ẹ̀rọ-ayárabíàṣá…ní èdè wa. Àwọn Àbá láti ọwọ́ onígbèjà èdè Yorùbá lórí ẹ̀rọ-ayárabíàṣá ní orílẹ̀-èdè Nàìjíríà

Àwòrán-atọ́ka láti ọwọ́ Táíwò Tèmilolúwa John fún Rising Voices

Láti ọwọ́ María Alvarez Malvido àti Adéṣínà Ghani Ayẹni, (Ọmọ Yoòbá), èyí tí í ṣe láti ara iṣẹ́ ìwádìí rẹ̀ (Ọmọ Yoòbá) pẹ̀lú ìfọ̀wọ́sowọ́pọ̀ àkànṣe iṣẹ́ ìwádìí olólùkópa ti Rising Voices tí a pè ní “Àwọn ìhàlé fún àwọn ohun-èlò ìmọ̀-ẹ̀rọ tí ó ní ààbò lórí àwùjọ èdè abínibí àti èdè àdúgbo.

Kò sí ohun tí à ń fi èdè ṣe bí kò ṣe àgbọ́yé lọ, kò sì wá sí èdè kan tí ó lágbára ju èdè mìíìn lọ, ó dá lórí bí àwọn tí wọ́n ń lo èdè un bá ṣe tẹ́wọ́ gbà á, torí pé gbogbo wa pàápàá jù lọ ní ìhà ibi tí a wà yìí, a ti tẹ́wọ́ gba èdè Gẹ̀ẹ́sì, ni ó fi dà bí ẹni wí pé àwọn nǹkan mìíràn wà tí ó jẹ́ wí pé a ò lè ṣe láì lo èdè Gẹ̀ẹ́sì, kò rí bẹ́ẹ̀, a lè lo èdè Yorùbá pẹ̀lú àwọn nǹkan wọ̀nyí.

- Abẹ́rẹ́ Gbólóhùn – olùkópa ìwádìí.

Ìbòjú wo èdè náà ní ráńpẹ́ 

Yorùbá jẹ́ èdè tí wọ́n ń sọ ní Ìwọ̀ oòrùn ilẹ̀ Adúláwọ̀, pàápàá ní agbègbè Gúúsù ìwọ̀-oòrùn àti Àárín gbùngbùn orílẹ̀ èdè Nàìjíríà. Àwọn ọmọ ìbílẹ̀ Yorùbá ló ń sọ ọ́. Iye àwọn ènìyàn tí ó ń sọ Yorùbá fẹ́rẹ̀ẹ́ tó mílíọ̀nù 45, pẹ̀lú àfikún mílíọ̀nù 2 àwọn tí wọ́n fi ṣe èdè kejì. – Wikipedia

Ìdámọ̀: Èdè ìṣòwò – Nàìjíríà, Èdè orílẹ̀ – Benin

Ipò èdè: Ti agbègbè (2) – “Èdè náà jẹ́ lílò nínú ètò ẹ̀kọ́, ibi iṣẹ́, ìkànnì agbéròyìnkáyé, àti ìjọba ní àárín àwọn ẹ̀ka ìṣàkóso tí ó jẹ́ gbòógì ní orílẹ̀ èdè.” – EGIDS scale, Ethnologue

Àwọn ohun àmúlò nípa ààbò orí ẹ̀rọ-ayárabíàṣá ní èdè náà:

Àwọn ohun-èlò ààbò orí ẹ̀rọ-ayárabíàṣá ní èdè yìí:

  • Signal ❌
  • TOR ❌
  • Psiphon ❌

Èdè Yorùbá jẹ́ ọ̀kan lára àwọn èdè mẹ́tẹ̀ẹ̀ta tí wọ́n ń sọ jùlọ ní orílẹ̀-èdè Nàìjíríà, èyí tí ó lé ní ọ̀kẹ́ lọ́nà ẹgbẹ̀rún méjì ènìyàn ń sọ káàkiri àgbáyé. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn irinṣẹ́ orí ẹ̀rọ-ayélujára tí ó wà lórí èdè yìí kò tó nǹkan. Báwo ni èyí ṣe ní ipa lórí àǹfààní sí ìwífún fún àwọn elédè Yorùbá tí ó ń ṣàmúlò ẹ̀rọ-ayélujára? Ọ̀nà wo ni ó ń gbà mú ìdínkù bá àǹfààní sí ààbò orí ẹ̀rọ-ayárabíàṣá àti àwọn ohun-èlò ìdáààbòbò ibi-ìkọ̀kọ̀? Ìwọ̀nyí ni díẹ̀ lára àwọn ìbéèrè tí Adéṣínà Ghani Ayẹni, tí àwọn ènìyàn mọ̀ sí Ọmọ Yoòbá, gbéyẹ̀wò nínú àkànṣe iṣẹ́ ìwádìí “Ọ̀rọ̀ Ààbò Ẹ̀rọ-ayárabíàṣá: Àkọsílẹ̀ Àwọn Elédè Yorùbá lórí Ẹ̀rọ-ayélujára.”

Ọmọ Yoòbá jẹ́ àjàfẹ́tọ̀ọ́ èdè lórí ẹ̀rọ-ayárabíàṣá àti olùdásílẹ̀ Yobamoodua Cultural Heritage, àjọ tó ń ṣe akitiyan ìgbéǹde àti ìpamọ́ àwọn ohun àjogúnbá ajẹmáṣà àti ìṣe àwùjọ Yorùbá. Láti nǹkan bíi ọdún mẹ́wàá báyìí, ó ti kópa nínú ọ̀kan-ò-jọ̀kan ètò tí ó ń ṣe ìjíǹde èdè Yorùbá. Onírúurú àwọn akitiyan wọ̀nyí ni ó ti sún sí orí àwọn gbàgede orí ẹ̀rọ-ayárabíàṣá bíi ìyípadà àwọn èdè ibùdó-ìtakùn àgbáyé sí èdè mìíràn, ṣíṣe àtinúdá nǹkan sórí ayélujára, ṣíṣe ìtọ́jú àwọn ewì alohùn àwọn Yorùbá sórí ẹ̀rọ-ayélujára àti ìṣẹ̀dá àkójọpamọ́ èdè Yorùbá fún ìlò fún Ẹ̀rọ Ìmọ̀-tí-kìí-ṣe-tẹ̀dá-ọmọ-ènìyàn (AI).

“Wọ́n máa ń fi ọwọ́ rọ́ àwọn àwùjọ tí kò sọ èdè Gẹ̀ẹ́sì sẹ́yìn káàkiri àgbáyé ní àwọn gbàgede orí ẹ̀rọ-ayélujára bẹ́ẹ̀ sì ni àìdọ́gba yìí ti mú onírúurú ìfàsẹ̀yìn bá ìdàgbàsókè ìmọ̀ àwùjọ àti ìmọ̀ ìlò ẹ̀rọ-ayárabíàṣá.”

Ó sọ pẹ̀lú ìbéèrè kan: Ǹjẹ́ kín ni yóò ṣẹlẹ̀ nígbà náà sí àwọn aṣàmúlò ẹ̀rọ-ayélujára tí kò gbọ́ èdè Gẹ̀ẹ́sì?

Láti mọ̀ síi nípa àwọn ipa àwùjọ ẹ̀rọ-ayárabíàṣá tí àgbékalẹ̀ rẹ̀ dá lórí èdè Gẹ̀ẹ́sì, Ọmọ Yoòbá fi ọ̀rọ̀ wá àwọn ènìyàn mẹ́rin tí wọ́n ń lo èdè Yorùbá lórí àwọn gbàgede orí ẹ̀rọ-ayárabíàṣá tí ó sì ní ogunlọ́gọ̀ àwọn olólùfẹ́ lẹ́nu wo. Ọjọ́orí àwọn akópa wọ̀nyí ò ju ẹni ọdún 21 sí 45 lọ, ọkùnrin mẹ́ta àti obìnrin kan. Ó yẹ kí a yán an pé àwọn akópa mẹ́rẹ̀ẹ̀rin nínú ìwádìí náà ní àǹfààní sí ẹ̀rọ-ayélukára-bíi-ajere, bákan náà ni wọ́n ní àǹfààní sí àwọn ohun-èlò ìkọ́nilẹ́kọ̀ọ́, èyí tí kò rí bẹ́ẹ̀ fún gbogbo ènìyàn ní orílẹ̀-èdè Nàìjíríà. Gbogbo wọn ni ó ń ṣe ìgbélárugẹ èdè lọ́nà kan tàbí òmíràn ṣùgbọ́n ọ̀nà tí wọ́n ń gbà ṣe arugẹ wọ́n ṣọ̀tọ̀ọ̀tọ̀, àwọn ìrírí wọn sì yàtọ̀ pẹ̀lú: ọ̀kán jẹ́ sọ̀rọ̀sọ̀rọ̀ èdè Yorùbá àti olùkọ́ni, òmíràn jẹ́ ẹlẹ́ṣin àbáláyé Yorùbá (babaláwo) àti onímọ̀ nípa àṣà Yorùbá, ìkẹta jẹ́ akéwì, nígbà tí ẹni tí ó gbẹ̀yìn jẹ́ akéwì.

Àwọn ìrírí àti ojú ìwòye wọn pèsè àlàyé tí ó pọ̀ nípa bí àwọn ènìyàn lórí ẹ̀rọ-ayélujára ṣe ń ṣàmúlò àwọn ohun-èlò ìdáààbò àti àwọn ìgbésẹ̀ tí wọ́n ń gbé láti dáàbò bo ibi-ìkọ̀kọ̀ wọn lórí ẹ̀rọ-ayélukára-bíi-ajere. Àwọn ìbéèrè wọ̀nyí àti ẹ̀kọ́ tí ó sú yọ wá láti ara ìtọpinpin nípa àwọn ohun-àmúlò ẹ̀rọ-ayárabíàṣá ní èdè Yorùbá. Fún ìdí èyí, láti ní òye tí ó jinlẹ̀ nípa pàtàkì ìrìnàjò iṣẹ́ ìwádìí ìmọ̀-ẹ̀dá èdè yìí, ó ṣe pàtàkì kí a kọ́kọ́ wo ọ̀gangan ìṣẹ̀lẹ̀ àti ìtàn an rẹ̀.

Èdè Yorùbá

Àwùjọ tí ó ń sọ èdè Yorùbá lọ láti gúúsù ìlà-oòrùn orílẹ̀-èdè Nàìjíríà títí dé Ilẹ̀-Olómìnira Benin, Togo, àti àwọn apá kan ní Ghana. Gẹ́gẹ́ bí Ọmọ Yoòbá ṣe sọ:

“Gẹ́gẹ́ bíi ti ọ̀pọ̀ àwọn ènìyàn ọjọ́un, ohùn ẹnu ni ilé ìpamọ́ àṣà Yorùbá, àrọ́bá àti ìtàn àtẹnudẹ́nu ni a fi ń sọ àwọn ogunlọ́gọ̀ ìtàn ìrandíran láti ìran kan dé ìran mìíràn. Ayé ń lọ à ń tọ̀ ọ́, àyípadà dé ní ìbẹ̀rẹ̀pẹ̀pẹ̀ ọ̀rúndún kọkàndínlógún nípasẹ̀ iṣẹ́ àwọn Ajíhìnrere Ọmọlẹ́yìn Kríístì (CMS), tí wọ́n wá láti jíhìnrere àti sọ àwọn ènìyàn di ọmọlẹ́yìn Jésù, nítorí náà wọn ní láti ṣe àgbékalẹ̀ ìlànà àkọtọ́ kíkọ èdè Yorùbá sílẹ̀ fún ìrọ̀run iṣẹ́ wọn. Àgbékalẹ̀ àkọtọ́ èdè Yorùbá yìí wáyé ní ọdún 1884 gẹ́gẹ́ bí Bíbélì Yorùbá, iṣẹ́ ìtumọ̀ èdè tí ó bí ìwé atúmọ̀ èdè èyí tí ó ti rí ọ̀pọ̀lọpọ̀ àtúnṣe, àtúntẹ̀ àti àmúlò lọ́pọ̀ ìgbà láti ọwọ́ onírúurú àwọn ènìyàn tí wọ́n nífẹ̀ẹ èdè.”

Àkọsílẹ̀ àti ìgbésẹ̀ ìtàn àtẹ̀yìnwá èdè náà ni ó bí ìlànà àkọtọ́ èdè Yorùbá tí ó dá lórí ẹ̀ka-èdè Ọ̀yọ́, ó sì ti ń di lílò bẹ́ẹ̀ nínú ètò-ẹ̀kọ́ àti àwọn ohun ìgbéròyìnjáde gbogbo. Níkòpẹ́kòpẹ́, gẹ́gẹ́ bí Ọmọ Yoòbá ti ṣe ṣàlàyé nínú iṣẹ́ ìwádìí náà, mímú èdè Yorùbá wá sí ìbámu pẹ̀lú àwọn ohun-èlò orí ẹ̀rọ-ayárabíàṣá ti gba akitiyan oríṣìíríṣìí àti ọgbọ́n àtinudá ọ̀tun láti àkàta àwọn ọmọ Yorùbá lóríṣìiríṣìi. Ó ṣàlàyé pé: “Bí a bá fi wé èdè Gẹ̀ẹ́sì, títẹ ọ̀rọ̀ ní èdè Yorùbá dà bí iré-ìje tí kò ní òpin fún àwùjọ n tí kò ní òpin fún àwùjọ náà, èyí tí ó mú kí lílo èdè Yorùbá lórí ẹ̀rọ-ayárabíàṣá ó máa tó nǹkan.” Àwọn ìdíwọ̀ wọ̀nyí tí Ọmọ Yoòbá ṣàpèjúwe bíi iré ìje sísá tí ó túmọ̀ sí àwọn nǹkan ìhàlé àti irinṣẹ́ tí kò tó bíi àwọn pátákó-ìtẹ̀wé ẹ̀rọ-ayárabíàsá àti àwọn pátákó-ìtẹ̀wé elédè-púpọ̀ ti orí ẹ̀rọ-ayélujára bíi SwiftKey, GBoard, Nailangs tàbí KeyMan, èyí tí ó fàyè gba títẹ èdè Yorùbá lórí ẹ̀rọ ayárabíàsá nípa ṣíṣe àmúlò àtẹ̀papọ̀ ọmọ-ọ̀rọ̀ lórí pátákó.

Yorùbá àti àwọn ohun-èlò ẹ̀rọ-ayárabíàṣá

Ọmọ Yoòbá ṣe ìsọ̀níṣókí àwọn gbàgede tí àwọn olùsọ èdè Yorùbá ń lò láti fi èdè wọn ṣẹ̀dá àti pín ohun kan tàbí òmíràn lórí ẹ̀rọ-ayélujára, bí ìdíwọ́ tilẹ̀ wà fún títẹ èdè Yorùbá àti àwọn ìdènà ní orí gbàgede ẹ̀rọ ayárabíàsá tí ó fún èdè Gẹ̀ẹ́sì ní àǹfààní gẹ́gẹ́ bíi èdè ẹ̀rọ ayárabíàsá láti ìbẹ̀rẹ̀pẹ̀pẹ̀. Wọ́n tún mú òpó àti iṣẹ́ ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ — síbẹ̀síbẹ̀, àwọn ohùn, orin àti ewì wọn ti mú kí àpéròó wáyé ní orí àwọn gbàgede ìbánidọ́rẹ̀ẹ́ àwùjọ kan náà. Gbogbo wọn ni wọ́n sọ ohun tí ó mú wọn yan àwọn ohun-èlò àti àwọn gbàgede orí ìtakùn àgbáyé tí wọ́n ń lò nínú ọ̀kẹ́ àìmọye tó wà. Paríparí, wọ́n jẹ́ kí ó di mímọ̀ wí pé àwọn mọ Facebook àti Instagram lò tinútìta; àwọn mìíràn wà lórí Twitter, YouTube, àti TikTok, nígbà tí àwọn mìíràn ń lo WhatsApp fún ìbáraẹnisọ̀rọ̀.

Bí àpẹẹrẹ, ọ̀kán ní òun fẹ́ran láti lo YouTube àti Instagram nítorí ó fún òun láàyè láti gbé àwọn àwòrán-àtohùn sí i tí ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn yóò sì rí i, nígbà tí òun yan WhatsApp fún ìtàkùrọ̀sọ. Òmíràn yan Facebook, Instagram, Twitter, àti WhatsApp nítorí pé ó ṣàkíyèsí wí pé orí rẹ̀ ni ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn olùfẹ́ rẹ̀ẹ́ wà, ó lè kàn sí àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ àti pé wọ́n ní àwọn àbùdá tí ó rọrùn láti lò. Òmíràn ń lo WhatsApp, Facebook, Twitter, àti Tik-tok, gẹ́gẹ́ bí àwọn ohun-èlò tí ó ń mú ṣíṣẹ àgbéjáde orí ẹ̀rọ-ayélujára yá kánkán. Olùkópa kẹ́rin ṣàpèjúwe Facebook gẹ́gẹ́ bíi ààyò rẹ̀ nítorí pé ó máa ń fún un ní àǹfààní láti kàn sí àwọn tí ó ti rí fún ọjọ́ pípẹ̀, tàbí àwọn tí kò bá sọ̀rọ̀ fún ọjọ́ tí ó ti pẹ́. Instagram di ààyò òun nítorí iṣẹ́ rẹ̀ gẹ́gẹ́ bíi aránṣọ, láti ṣe àtẹ̀jáde àwọn aṣọ tí ó rán. TikTok “kàn wà fún eré,” nígbàtí Twitter jẹ́ ibi tí ó ti ń gba àwọn ìròyìn nípa ohun tí ó ń ṣẹlẹ̀ lọ́wọ́lọ́wọ́ àti àwọn ìròyìn yàjóyàjó.

Síwájú sí i, àwọn kan lára àwọn akópa dárúkọ Facebook àti WhatsApp gẹ́gẹ́ bíi àwọn gbàgede níbi tí àwọn ti lè bá àwọn ẹgbẹ́ tí ó rọ̀ mọ́ àwọn akitiyan ìsọjí èdè, gẹ́gẹ́ bíi Nigeria Poet Association, níbi tí wọ́n ti máa ń jíròrò lórí àwọn ọ̀rọ̀ tí ó jẹ mọ́ ewì, iṣẹ́-ọnà àti àṣà. Òmíràn wà nínú àwọn ìsọ̀wọ́ tí ó dá lórí ìgbélárugẹ ohun àjogúnbá àti èdè, àti ọmọ-ẹgbẹ́ Ẹgbẹ́ Akọ́mọlédè àti Àṣà ti Yorùbá, níbi tí wọ́n ti máa ń jíròrò lórí ọ̀rọ̀ tí ó jẹ mọ́ èdè Yorùbá àti ìdàgbàsókè àṣà. Àwọn yòókù wà nínú ẹgbẹ́ sọ̀rọ̀sọ̀rọ̀ akọnilẹ́kọ̀ọ́, tàbí ìsọ̀wọ́ àwọn akẹ́kọ̀ọ́ tí ó fẹ́ kàwé gboyè ẹlẹ́ẹ̀kejì nínú èdè Yorùbá ti Ifásitì Ìpínlẹ̀ Èkó, ẹgbẹ́ àwọn akọ̀ròyìn àti eléré ìtàgé ní orílẹ̀-èdè Nàìjíríà, RATTAWU, ẹgbẹ́ ìjíròrò nípa ìṣèlú àti àwọn ìsọ̀wọ́ akẹ́kọ̀ọ́ ti abẹ́ Àjọ Àwọn Ọ̀dọ́ oníṣẹ̀ṣe orílẹ̀-èdè Nàìjíríà (National Association of Ìṣẹ̀ṣe Youth).

Nínú àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ ajẹmẹ́rọ ayárabíàṣá yìí, kíni àwọn ìlànà tí àwọn ènìyàn wọ̀nyí ń lò láti ṣe àmúlò àwọn gbàgede wọ̀nyí ní ọ̀nà tí ó ní ààbò? Gẹ́gẹ́ bí a ti ṣe rí i nínú iṣẹ́ ìwádìí náà, àwọn ohun-èlò ìṣàkóso ọ̀rọ̀-ìfiwọlé ni ọ̀nà tí ó wọ́pọ̀ tí ó sì ní ààbò jù lọ. Ọ̀kán nínú àwọn olùkópa ṣàlàyé lẹ́kùnúnrẹ́rẹ́ ìlànà lílo ìfẹ̀rílàdìí ọlọ́nàméjì (two step verification) àti àwọn Àsopọ̀ Ìdákọ́ńkọ́ orí Ayélujára (VPNs). Síbẹ̀, kiní kan ṣoṣo tí àwọn akópa mẹ́rẹ̀ẹ̀rin náà sọ ní pé, bí-ó-ti-lẹ̀-jẹ́-pé àwọn gbàgede náà ní àwọn ààtò tí ó pèsè ìdáààbòbò, kò sí àrídájú pé wọ́n ní ààbò tí ó péye, tí ààbò náà sì wà lọ́wọ́ aṣàmúlò.

Gẹ́gẹ́ bí Ọmọ Yoòbá ṣe kọ ọ́ sílẹ̀, ọ̀kan lára àwọn akópa náà ṣàlàyé pé, “àwọn aṣàmúlò gbọ́dọ̀ ṣọ́ra fún àwọn nǹkan ìkọ̀kọ̀ tí wọ́n yóò máa fi sí orí ẹ̀rọ ayélujára àti ọ̀nà tí wọ́n ń gbà lò ó, nítorí pé kì í ṣe gbogbo ohun tí à ń ṣe ní ibi-ìkọ̀kọ̀ ayé ẹni ni ó yẹ láti gbé sí orí ẹ̀rọ-ayélujára.” Bákan náà, “ọ̀pọ̀lọpọ̀à wọn òǹṣàmúlò ni ó ń ṣera rẹ̀, bí wọ́n ṣe ń gbé ìrìnàjò wọn sórí ẹ̀rọ-ayélukára-bí-ajere ni wọ́n ń jẹ́ kí ayé mọ ibi tí àwọn wà.” Ní ọ̀rọ̀ olùkópa náà:

àwọn gbàgede wọ̀nyí ní ààbò, kò sì tún ní ààbò. Bí ó bá máa ní ààbò, bí kò sì ní ní ààbò, mo lérò wí pé ọwọ́ wa náà ni ààbò náà pọ̀ sí. Lákọ̀ọ́kọ́ nípa àwọn nǹkan tí àwa náà ń gbé sórí ayélujára, kì í ṣe gbogbo ohun tí a bá ń ṣe tí ó jẹ́ nǹkan ìkọ̀kọ̀ ni ó bá ayélujára mu. Púpò nínú wa ni ó máa ń ṣe àṣejù, nǹkan tí kò yẹ kí a gbé sórí ayélujára ni a máa ń fi síbẹ̀.

Ní ìwòye ti akópa mìíràn:

“ọ̀rọ̀ nípa àìláàbò di ọwọ́ òǹṣàmúlò àti ọ̀nà tí wọ́n gbà ṣàmúlò ẹ̀rọ-ayélujára, ààbò orí ẹ̀rọ-ayárabíàṣá sì bẹ̀rẹ̀ níbi ṣiṣẹ́ àdínkù sí irúfẹ́ àwọn ìwífún tí ó lè ṣàkóbá tàbí mú ìpalára wá fún òǹṣàmúlò lọ́jọ́ iwájú lórí ẹ̀rọ-ayélujára látàrí ohun tí à ń gbé sórí ẹ̀rọ-ayélukára.”

Gẹ́gẹ́ bí ìwádìí náà ti fi hàn, àwọn ọmọYorùbá mẹ́rẹ̀ẹ̀rin tí ó ń ṣàmúlò ẹ̀rọ-ayélujára wọ̀nyí ni ó ṣẹ̀dá ìlànà ààbò tiwọn, kíkọ́gbọ́n láti ara àwọn òǹṣàmúlò mìíràn, àti láti ara àwọn àbájáde ìrírí òdì bíi ìṣàmúlò jíjágbà tàbí fíṣíìnì tí wọ́n fi ń takóró wọnú ìṣàmúlò oníṣàmúlò. Síbẹ̀síbẹ̀, bí Ọmọ Yoòbá ṣe sọ, “àìsílárọ̀ọ́wọ́tó àwọn ohun-àmúlò ààbò orí ẹ̀rọ-ayárabíàṣá àti ẹ̀kọ́ ààbò orí ẹ̀rọ-ayárabíàṣá ní ipa ribiribi lórí lílo àwọn ohun-èlò ẹ̀rọ-ayárabíàṣá fún ìdáààbòbò àti àtiṣe láti dáàbò bo ara ẹni lórí ẹ̀rọ-ayélukára-bíi-ajere.” Ọ̀nà wo ni ìkóraẹniníjánu ṣe ń dín ìkópa òǹṣàmúlò kù lórí ẹ̀rọ-ayélukára? Ǹjẹ́ rírí àǹfààní sí ìwífún lórí ààbò ẹ̀rọ-ayárabíàṣá yóò mú kí ìpolongo nípa ààbò orí ẹ̀rọ-ayárabíàṣá àti ìkóraẹniníjánu ó gbèrò sí i, nígbàtí wọ́n ń ṣe ìmúdárasíi gbígbé nǹkan sórí ẹ̀rọ-ayárabíàṣá ní èdè wọn?

Ẹ̀rọ-ayélujára fún gbogbo ènìyàn, ní àwọn èdè wa

Gbogbo àwọn akópa pátá ló sọ wí pé àwọn rí àǹfààní sí ìwífún nípa ààbò orí ẹ̀rọ-ayárabíàṣá ṣùgbọ́n èdè Gẹ̀ẹ́sì ni wọ́n fi kọ́ ọ, wọn ò sì lè sọ pàtó bóyá àwọn ohun-èlò wọ̀nyí wà ní àrọ́wọ́tó lédè Yorùbá. Àìtó àyè sí ìwífún nípa ohun gbogbo tí ó ní í ṣe pẹ̀lú ẹ̀rọ-ayárabíàṣá ní èdè Yorùbá fi ààbò orí ẹ̀rọ-ayárabíàṣá fún àwọn òǹṣàmúlò rẹ̀ sínú ewu. Gẹ́gẹ́ bí àlàyé Ọmọ Yoòbá:

“Ààbò orí ẹ̀rọ-ayárabíàṣá jẹ́ ẹ̀tọ́ ọmọ ènìyàn tí a gbọdọ̀ dáàbò bò ní gbogbo ọ̀nà. Àwọn ohun-àmúlò nípa ààbò orí ẹ̀rọ-ayárabíàṣá wà ní èdè Gẹ̀ẹ́sì jàntìrẹrẹ, àti èyí tí ó ní í ṣe pẹ̀lú ìdáààbòbò orí ẹ̀rọ-ayélujára àti ibi-ìkọ̀kọ̀. Síbẹ̀, kò fi bẹ́ẹ̀ sí àyè fún àwọn tí ó ń sọ èdè Yorùbá nítorí àìsílárọ̀wọ́tó àwọn ohun-àmúlò ẹ̀kọ́ ẹ̀rọ-ayárabíàṣá wọ̀nyí ní èdè Ìbílẹ̀ wọn, èyí tí ó ti dá kún àìní àṣà ààbò ẹ̀rọ-ayárabíàṣá ní àárín àwọn ọmọ Yorùbá náà.”

Tayọ ìmòye-taraẹni àti àbójútó ẹnìkọ̀ọ̀kan tí àwọn olùsọ ìbílẹ̀ Yorùbá ń gbàmọ́ra, ó ṣì nílò ìsọ-ketekete àti ìgbésẹ̀ ní ṣísẹ̀ntẹ̀lé tí yóò mú kí ẹ̀rọ-ayélujára ó di agbo fún gbogbo ènìyàn. Fún àpẹẹrẹ, ìhu àwọn ojúiṣẹ́ ẹ̀rọ-ayárabíàṣá, gbàgede, àti ìwífún ní àwọn èdè bí i Yorùbá jẹ́ kànránǹgídá fún àwọn òǹṣàmúlò láti lọ́wọ́ nínú àwọn ìpinnu àti àgbékalẹ̀ àwọn ohun-èlò tí ó wà ní onírúurú èdè àgbáyé.

Látàrí àwọn àbájáde tí ó jẹ yọ yìí, Ọmọ Yoòbá dá àwọn àbá tí a tó jọ wọ̀nyìí:

  • Àwọn nǹkan orí ẹ̀rọ-ayélujára àti ohun-àmúlò lórí ìlànà ààbò orí ẹ̀rọ-ayárabíàṣá, ibi ìkọ̀kọ̀ pípamọ́ lórí ẹ̀rọ-ayélukára-bíi-ajere, mímọ̀ọ́lò ẹ̀rọ-ayárabíàṣá àti ètò-ẹ̀kọ́ ní èdè Ìbílẹ̀ Yorùbá fún àwọn ènìyàn àwùjọ tí ó ń sọ èdè náà gbọdọ̀ pọ̀ bẹẹrẹ.
  • Àwọn akọ́ṣẹ́mọṣẹ́ atúmọ̀-èdè àti aṣọ-èdè-ditìbílẹ̀ ní láti ṣiṣẹ́ kí wọn ó túmọ̀ ohun-àmúlò ààbò orí ẹ̀rọ-ayárabíàṣá, mímọ̀ọ́lò ẹ̀rọ-ayárabíàṣá àti ibi-ìkọ̀kọ̀ pípamọ́ sí èdè Yorùbá kí àwọn èdè-ìperí kàǹkà tí ó le lè baà yéni yékéyéké.
  • Kí àwùjọ àwọn onímọ̀ ẹ̀rọ ṣe àgbékalẹ̀ ọ̀nà ẹ̀rọ tí yóò fi àyè sílẹ̀ fún àwọn ìlànà wọ̀nyí nípa ṣíṣẹ̀dá àwọn irinṣẹ́ tí yóò ṣe àfikún èdè Yorùbá àti àwọn èdè Ilẹ̀ Adúláwọ̀ mìíràn.
  • Kí àwọn Ẹgbẹ́ Àwùjọ ó tẹramọ́ ìpolongo láàárín gbogbo ènìyàn àwùjọ, kí wọ́n ṣètò ìdánilẹ́kọ̀ọ́, kí wọ́n sì gbárùkù ti mímọ̀ọ́lò ẹ̀rọ-ayárabíàṣá tí yóò mú wọn lóye kíkún nípa ọ̀rọ̀ ààbò orí ẹ̀rọ-ayárabíàṣá.

Gẹ́gẹ́ bí Ọmọ Yoòbá ṣe ṣàròyé, “bí ó bá jẹ́ pé gbogbo ènìyàn ni ẹ̀rọ-ayélujára yẹ kí ó wà fún, a jẹ́ pé ó yẹ kí ó wà ní èdè gbogbo ènìyàn,” èyí tí ó pè fún akitiyan tí ó pọ̀ àti ìkáràmásìkí. Àwọn Yorùbá bọ̀, “igi kan ò lè dágbó ṣe,” ó yẹ kí a gbáríjọpọ̀ láti mú ìlépa tí ó káríayé yìí wá sí ìmúṣẹ.

Fún ìròyìn síwájú sí i àti ìwífúnni lórí àwọn àwùjọ èdè tí ó kópa, jọ̀wọ́ lọ sí ojú ewé “Ààbò Orí ẹ̀rọ-ayárabíàṣá + Èdè”

 

Bẹ̀rẹ̀ ìtàkùrọ̀sọ náà

Òǹkọ̀wé, jọ̀wọ́ àkọsílẹ̀ ìwọlé »

Ìlànà

  • Atukọ̀ yóò ṣ'àtúnwò gbogbo ìsọsí . Máà fi ìsọsíì rẹ sílẹ̀ ju ẹ̀rìnmejì lọ tàbí kí a kà á sí iṣẹ́-ìjẹ́-tí-a-o-fẹ́.
  • Jọ̀wọ́ fi ọ̀wọ̀ fún ẹlòmíràn . A ò ní fi àṣẹ sí ìsọsí ìkórìíra, ìṣekúṣe, àti ìdojú-ìjà-kọ ẹnikẹ́ni k.