Orin ẹ̀hónú: àwọn ọ̀dọ́mọdé òǹkọrin ní orílẹ̀-èdè Nàìjíríà ń kọrin tako ìwà ìrẹ́jẹ láwùjọ

Àwọn ònìlú ń ṣeré fún àwọn akópa níbi ẹ̀hónú #EndSARS. Àwòrán láti ọwọ́ Sàlàkọ́ Ayọ̀ọlá, CC0 lórí Wikimedia Commons, Oṣù Ọ̀wàrà 2020.

Ka Apá Kìíní ìròyìn atẹ̀léra yìí níhìn-ín

Orílẹ̀-èdè Nàìjíríà ní ìtàn àtìgbàdégbà nípa orin ẹ̀hónú, àti pé òpin kò bá ìtara láti kọrin tako àwọn ìwà ìbàjẹ́ ní orílẹ̀-èdè Nàìjíríà lẹ́yìn ọdún 1970.   

Wọ́n ń tọpaṣẹ̀ àwọn àgbà olórin tí ó sáájú wọn — tí wọ́n kọ orin tako ìjẹgàba ìjọba ológun, wọ́n sì béèrè fún òmìnira Nelson Mandela láti ọwọ́ ìjọba ẹlẹ́yàmẹyà orílẹ̀-èdè South Africa — àwọn ọ̀dọ́mọdé olórin orílẹ̀-èdè Nàìjíríà ti tẹ̀síwájú nínú àṣà kíkọ orin tako ìrẹ́jẹ láwùjọ.

Bí àwọn ènìyàn tilẹ̀ ń sọ̀rọ̀ pé ìgbàgbé ti bá àwọn orin ẹ̀hónú orílẹ̀-èdè Nàìjíríà, láti àwọn ọdún 1990 sí 2000, àwọn olórin orílẹ̀-èdè Nàìjíríà tẹ̀síwájú láti máa bu ẹnu àtẹ́ lu ìwà ìkà àwọn ọlọ́pàá àti àwọn ìṣòro àwùjọ. Lẹ́yìn náà ni ẹ̀hónú #ENDSARS, ẹ̀hónú àgbáríjọpọ̀ àwọn ọ̀dọ́ tí ó ṣe àtúntàn iná orin ìdájọ́ àwùjọ.

Síwájú ẹ̀hónú #EndSARS

Àwòrán àwo orin Àṣá

Bùkọ́lá Elemide, ẹni tí orúkọ rẹ̀ tún ń jẹ́ Àṣá, olórin orílẹ̀-èdè Nàìjíríà àti Farancé, akọrin, àti òṣèré tí ó ń gbé orin jáde, jẹ́ èèkàn pàtàkì láàárín àwọn ohùn ọ̀dọ́ fún orin ẹ̀hónú. Orin rẹ “Jailer“, tí ó gbé jáde ní ọdún 2007, sọ̀rọ̀ láti tako ìwà oró ọlọ́pàá orílẹ̀-èdè Nàìjíríà: “nítorí náà o ń ṣe mí bí ẹrú ìgbàlódé, Ọ̀gbẹ́ni Onítúbú”

Orin rẹ̀, “There is fire on the Mountain,” (Iná wà lórí Òkè) eléyìí tí ó gbé jáde ní ọdún kan náà, sọ̀rọ̀ nípa wàhálà tí yóò tàn kálẹ̀ bí ohunkóhun kò bá di ṣíṣe nípa ìwà ìkà àwọn ọlọ́pàá: “Mo jí ní àárọ̀’/Ṣé kí n sọ ohun tí mo rí lójú àtẹ ẹ̀rọ tẹlifíṣàn mi/Mo rí ẹ̀jẹ̀ ọmọ aláìṣẹ̀ kan/Gbogbo ènìyàn sì ń wò ó.” Àwọn orin méjèèjì lè jẹ́ àsọtẹ́lẹ̀ nípa ẹ̀hónú #EndSARS.

Orin Àṣá jẹ́ àmúlùmọ́là “díẹ̀ nínú orin Bob Marley, díẹ̀ nínú orin Fẹlá Aníkúlápò Kútì, àfikún orin India Arie díẹ̀ pẹ̀lú àdàlù Miriam Makeba àti Anhelique Kidjo àti àwọn orin ìgbaanì Yorùbá,” ni ọ̀rọ̀ Marc Amigone, akọ̀ròyìn pẹ̀lú Huffington Post.

Ní ọjọ́ 8 oṣù Òkúdù, 2018, “This is Nigeria” (Nàìjíríà nìyí), orin kan láti ọwọ́ òǹkọrin mìíràn Fọlárìn Fálànà ẹni tí orúkọ ìṣeré rẹ ń jẹ́ Flaz, ni wọ́n ní “kò dára lórí rédíò”. Àjọ tí ó ń rí sí ìgbóhùnsáfẹ́fẹ́, ìyẹn Nigerian Broadcasting Commission (BBC) ni inú wọn kò dùn sí àwọn ọ̀rọ̀ inú orin Falz: “Nàìjíríà nìyí, wo bí a ṣe ń gbáyé báyìí, ọ̀daràn ni gbogbo ènìyàn,” èyí tí wọ́n ṣàpèjúwe bí “ìsọkúsọ”, nítorí náà ni wọ́n ṣe fi òfin dè é lórí afẹ́fẹ́. Àwọn àjọ náà ṣe ìkìlọ̀ pé ilé-iṣẹ́ ìgbóhùnsáfẹ́fẹ́ èyíkéyìí tí ó bá kọ̀ láti tẹ̀lé òfin yìí yóò san owó ìtanràn NGN 100, 000 (USD 276).

Orin Falz “This is Nigeria”, tí ó gbé jáde ní ọjọ́ 25, oṣù Karùn-ún, 2018 ṣe ìsínjẹ orin “This is America” ti òǹkọrin ilẹ̀ America Childish Gambino. Orin náà jẹ́ àwòrán ìfẹ̀dáṣẹ̀fẹ̀ ìwà àjẹbánu, ìwà ìkà àwọn ọlọ́pàá àti ìpànìyàn tí kò tọ́ lábẹ́ òfin, jìbìtì orí íímeèlì, ìlòkulò egbò0gi, àti jágídíjàgan ẹ̀sìn. Orin náà bẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú ohun agbẹjọ́rò Fẹ́mi Fálànà, bàbá Falz ẹni tí ó tún jẹ́ ajìjàǹgbara.

Orin ẹ̀hónú #EndSARS

Ní oṣù Kẹwàá 2020, àwọn ọ̀dọ́ orílẹ̀-èdè Nàìjíríà léwájú àwọn ìfẹ̀hónúhàn #EndSARS káàkiri orílẹ̀-èdè yìí àti gbogbo àgbáyé, èyí tí wọ́n ti ń pè fún fífi òpin sí ìwà ìkà àwọn ọlọ́pàá. Wọ́n mú ìfẹ̀hónúhàn náà wá sí òpin pẹ̀lú ipá ní alẹ́ ọjọ́ 20 oṣù Kẹwàá, 2020, èyí tí “àwọn ènìyàn 48 ti fara pa yánnayannà, nínú àwọn tí ènìyàn 11 ti gbẹ́mìí mì, tí àwọn ènìyàn mẹ́rin sì di àwátì, ” nínú àbọ̀ ìwádìí tí àjọ aṣèwádìí ṣe àpèjúwe bí “ìpakúpa” Lekki, orúkọ ẹnu-ibodè tí ó ti wáyé.

Ìfẹ̀hónúhàn #EndSARS náà jẹ́ ìtako Ikọ̀ Agbógunti Oṣà; Special Anti-Robbery Squad (SARS), ẹ̀ka ọlọ́pàá orílẹ̀-èdè Nàìjíríà tí ó lókìkì fún fífi-ṣìkún-òfin mú, dẹ́rùbà, àti pípa àwọn ará-ìlú nípakúpa lọ́nà tí kò bá òfin mu. Láàárín oṣù kìíní ọdún 2017 àti oṣù karùn-ún ọdún 2018, Amnesty International ṣàkọsílẹ̀ ìsẹ̀lẹ̀ ìfìyàjẹni àti ìpànìyàn 82 tí kò tọ́ lábẹ́ òfin láti ọwọ́ SARS.

Ní àsìkò ẹ̀hónú #EndSARS náà, “Mr. President,” orin ọdún 2006 láti ọwọ́ Chinagorom Onuoha, ẹni tí orúkọ ìṣeré rẹ̀ ń jẹ́ African China di orin tí òkìkíi rẹ̀ kàn lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀:

Ọlọ́run-ùn mi, ọlọ́pàá yóò rí funfun/ Yóò sọ fún ọ, mo ní pé pupa ni / Sọ ohun kan tí mi ò mọ̀ fún mi.

Bákan náà, orin Timaya ọdún 2007 “Dem mama” náà jẹ́ lílò dáadáa ní àsìkò àwọn ẹ̀hónú náà, látàrí wí pé gbogbo wọn ń tẹnumọ́ ìwà ìkà àwọn Àjọ ẹ̀sọ́ aláàbò orílẹ̀-èdè Nàìjíríà tí ó ń ṣẹnu gọngọ sí àwọn ará ìlú.

Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé, ọkàn lára àwọn orin tí ó gbajúmọ̀ jùlọ nípa ẹ̀hónú #EndSARS ni “20.10.20” láti ọwọ́ òǹkọrin ráàpù orílẹ̀-èdè Nàìjíríà Damini Ebùnolúwa Ogulu, ẹni tí gbogbo ayé mọ̀ pẹ̀lú orúkọ ìṣeré rẹ, Burna Boy. Àwọn ọ̀rọ̀ orin amárabùmáṣọ náà, èyí tí ó parí pẹ̀lú ohùn àwọn ọ̀dọ́ tí ó ń fi ẹ̀hónú hàn nígbà tí ìbọn yínyìn náà ń lọ lọ́wọ́ ní ẹnu-ibodè Lekki, jẹ́ èyí tí ó báni lọ́kàn jẹ́ jáì: “Lógúnjọ́ oṣù kẹwàá 2020/ o kó àwọn ológun lọ pa àwọn ọ̀dọ́ púpọ̀ ní Lekki/ Bẹ́ẹ̀ ni omijé o, omijé dà lójú mi/ Kò sí ohun tí o máa sọ tí yóò mú ọ jàre ìṣẹ̀lẹ̀ ikú wọn [….]. Lógúnjọ́ oṣù kẹwàá 2020/ o kó àwọn ológun lọ pa àwọn ọ̀dọ́ púpọ̀ ní Lekki/ Bẹ́ẹ̀ ni omijé o, omijé dà lójú mi/ Kò sí ohun tí o máa sọ tí yóò mú ọ jàre ìṣẹ̀lẹ̀ ikú wọn.”

Ṣé orin ẹ̀hónú ti di ohun ìgbàgbé ní orílẹ̀-èdè Nàìjíríà?

Àwọn kan ti sọ wí pé orin ẹ̀hónú àwọn ọ̀dọ́mọdé ti kú regbè lẹ́yìn ikú Fẹlá Aníkúlápò Kútì ní 1997.

Florence Nweke, onímọ̀ nípa orin ní Yunifásítì Èkó, sọ pé “àlàfo kan ti wà nínú àwujọ orin ẹ̀hónú Nàìjíríà” láti ìgbà tí Fẹlá ti darapọ̀ mọ́ àwọn alálẹ̀. Nweke fìdíi rẹ̀ múlẹ̀ pé ìdí tí èyí fi rí bẹ́ẹ̀ kò ṣẹ̀yìn-in “owó yanturu tí ó wà nínú ẹ̀ka náà”. Nítorí náà, àwọn ọ̀dọ́ olórin Nàìjíríà “ń kàndí láti gbé ẹ̀hónú wọn jáde nígbà tí àǹfààní wà fún àwọn olórin láti bù lá nínú òṣèlú tí wọ́n sì ń ṣàjọṣepọ̀ pẹ̀lú ìjọba,” Nweke ṣàkíyèsí.

Ṣùgbọ́n ọ̀nà mìíràn láti wo èyí ni pé àwọn orin ẹ̀hónú kò roko ìgbàgbé, ṣùgbọ́n wọ́n ti bá àwùjọ Nàìjíríà yípadà.

Iṣẹ́-ọnà ṣì ń kó “ipa tí ó ṣe pàtàkì nínú ìtẹ̀síwájú ìtiraka àwọn ọ̀rọ̀ ajẹ́máwùjọ àti òṣèlú”, akọ̀ròyìn Nàìjíríà Adékúnlé Fáladé sọ. Àwọn orin ẹ̀hónú orílẹ̀-èdè Nàìjíríà ti máa ń sọ àti ṣe àgbéjáde ìhùwàsí àwọn ènìyàn, ohun kan tí ó jọ wí pé àwọn ọ̀dọ́ olórin Nàìjíríà jogún láti ọwọ́ àwọn ará ìṣáájú wọn.

Bí ó ti wù kí ọ̀rọ̀ náà rí, láti ìgbà ẹ̀hónú #EndSARS, iye àwọn ọ̀dọ́ olórin tí ó ń fi ẹ̀hónú hàn lórí ìjọba burúkú ti pọ̀ sí i. Pàápàá jùlọ, àwọn orin wọn ń rí i dájú pé àwọn ènìyàn ò gbàgbé àwọn ọ̀dọ́ tí ó kú ní àsìkò ẹ̀hónú yẹn.

Ṣàwárí àwọn àkójọpọ̀ orin Spotify ti Global Voice tí ó ń tọ́ka sí ọ̀ràn wọ̀nyí àti àwọn orin mìíràn tí àjọ bá gbẹ́sẹ̀ lé jákèjádò ilé-ayé níbí. Fún ìwífún siwajú síi nípa àwọn orin tí a fi òfin dè, bojú wo àkànṣe ìròyìn wa, Títẹ àwọn Kọ́kọ́rọ́ orin tí kò tọ́.

Àkójọpọ̀ orin ẹ̀hónú láti ọwọ́ àwọn ọ̀dọ́mọdé òǹkọrin ní orílẹ̀-èdè Nàìjíríà: 

Bẹ̀rẹ̀ ìtàkùrọ̀sọ náà

Òǹkọ̀wé, jọ̀wọ́ àkọsílẹ̀ ìwọlé »

Ìlànà

  • Atukọ̀ yóò ṣ'àtúnwò gbogbo ìsọsí . Máà fi ìsọsíì rẹ sílẹ̀ ju ẹ̀rìnmejì lọ tàbí kí a kà á sí iṣẹ́-ìjẹ́-tí-a-o-fẹ́.
  • Jọ̀wọ́ fi ọ̀wọ̀ fún ẹlòmíràn . A ò ní fi àṣẹ sí ìsọsí ìkórìíra, ìṣekúṣe, àti ìdojú-ìjà-kọ ẹnikẹ́ni k.