Kín ni Global Voices?

Photo taken on January 25, 2015 in Cebu, Philippines, to commemorate GV's 10th anniversary.CC BY-NC 2.0.

Àwòrán ìsààmì ayẹyẹ ọdún mẹ́wàá tí a dá GV ní Cebu, Philippines. CC BY-NC 2.0

Ohùn Àgbáyé jẹ́ àjọṣe àwọn agbédègbẹyọ̀ oníròyìn, akọbúlọ́ọ̀gù, atúmọ̀-èdè, olùkọ́, àti ajàfún-ẹ̀tó ọmọnìyàn káríayé. Pẹ̀lú inú kan, à ń lo agbára ẹ̀rọ ayélujára fún ìbáṣepọ̀ t'ó ní láárí. Báwo ni a ṣe ń ṣe é?

  • Ìròyìn:  ikọ̀ agbédègbẹyọ̀ láti yàrá ìròyìn wa máa ń rò nípa àwọn ènìyàn tí ohùn tàbí ìrírí wọn ò wọ inú ìròyìn ilé-iṣẹ́ oníròyìn ńlá.
  • Túmọ̀ èdè: àwọn atúmọ̀ èdè Lingua l'ọ́fẹ̀ẹ́ wa ní í ṣiṣẹ́ takuntakun láti ṣe ògbufọ̀ ìròyìn sí èdè àgbáyé kí ìròyìn ba yé òǹkàròyìn yékéyéké níbikíbi lágbàáyé.
  • Ìgbèjà: ikọ̀ Advox wa máa ń jà fún òmìnira ọ̀rọ̀ sísọ lórí ayélujára, pàápàá jù lọ ọ̀ràn òfin, ìdẹ́rùbà tàbí ìhàlẹ̀ ojúkorojú mọ́ àwọn t'ó ń fi ẹ̀rọ-ayélujára fọhùn ọ̀ràn t'ó kan ènìyàn gbogbo.
  • Ìrólágbára: Rising Voices – Ohùn Tó-ń-dìde ń dá àwọn ìlú àti agbègbè tí ilé iṣẹ́ akọ̀ròyìn ò kọ nípa wọn l'ẹ́kọ̀ọ́ bí wọn ṣe lè lo irinṣẹ́ ìròyìn alákòópa.

Ohùn Àgbáyé gẹ́gẹ́ bí àṣà, ní àkànṣe iṣẹ́ kan tàbí méjì l'ẹ́ẹ̀kan náà. Àkànṣe iṣẹ́ ọdún 2018 ni Ìṣọwọ̀Kọ̀ròyìn – NewsFrames t'ó jẹ́ àjọṣepọ̀ àlàyé pẹrẹhu àti iṣẹ́ ìtúmọ̀ wa t'ó ń lọ lọ́wọ́,
Translation Services project, tí ó ń ṣe iṣẹ́ ìtúmọ̀ fún ilé-iṣẹ́ t'ó nílòo rẹ̀ fún owó bíntín.

Ẹgbẹ́

Àwọn aládàásí iṣẹ́ ọ̀fẹ́ ni ẹ̀rọ t'ó ń mú Ohùn Àgbáyé ṣiṣẹ́. Láfikún ìròyìn kíkọ àti títúmọ̀ ìròyìn, aládàásí ń fi ìmọ̀ ìbílẹ̀ lélẹ̀ àti ìsopọ̀ àwọn Ohùn Àgbáyé tí ó ń ṣe iṣẹ́ kan náà káríayé. Àwọn aládàásí wa.

Àjọṣepọ̀ pẹ̀lú ilé-iṣẹ́ akọ̀ròyìn àti ilé-iṣẹ́ tí-kìí-ṣe-ti-ìjọba jẹ́ ọ̀kan pàtàkì nínú iṣẹ́ Ohùn Àgbáyé gẹ́gẹ́ bí ẹgbẹ́, ilé-iṣẹ́ akọ̀ròyìn, àti ajàfún-ẹ̀tó òmìnira ọ̀rọ̀ sísọ. Kọ́ nípa àjọṣepọ̀ wa.

Aṣáájú àti Ìdarí

Ọ̀pọ̀lọpọ̀ alákòóso, akọ̀ròyìn àti olùdarí lóríṣiríṣi ni òpó tí Ohùn Àgbáyé dúró lé lórí. Agbáṣẹ́ṣe àti òṣìṣẹ́ ń ṣiṣẹ́ lábẹ́ òfin tó dé òṣìṣẹ́. Àwọn aṣáájú wa.

Ìgbìmọ̀, àwọn olùdásílẹ̀, aṣiṣẹ́ l'ọ́fẹ̀ẹ́ àti òṣìṣẹ́, pẹ̀lú àwọn àgbà ọ̀jẹ̀ alátinúdá nípa ẹ̀rọ-ayélujára ní í tukọ̀ Ohùn Àgbáyé. Kò sí ẹni tó ń gba owó nínú ọmọ ìgbìmọ̀. Àwọn ìgbìmọ̀ wa.

Kọ́ sí i lẹ́kùnúnrẹ́rẹ́ nípa iṣẹ́ẹ wa àti àgbékalẹ̀ òṣìṣẹ́ lójúewé Ojúṣẹ ti Atọ́nà Ẹgbẹ́ Ohùn Àgbáyé

Ipò lábẹ́ òfin àti Ìkówólélórí

Ìlú Netherlands ni a ti ṣe ìdàpọ̀ Ohùn Àgbáyé mọ́n Ohùn Àgbáyé Stichting, ilé-iṣẹ́ ìpìlẹ̀ tí-ò-lérè-lórí. A gbọ́kàn lé owó ìrànwọ́ láti ọ̀dọ̀ onígbọ̀wọ́ wa, àjọ ìjọba tí ó ń rí sí ìròyìn, àti ìkówójọ àwọn èèyàn onínúure. Kà sí i nípa iṣẹ́ẹ wa àti bí a ṣe ń kówó jọ nínú àkọsílẹ̀ ọdọọdún wa.

O fẹ́ ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ àlàyé? Ka ìbéèrè Tó-wọ́pọ̀.

STICHTING GLOBAL VOICES
151 Kingsfordweg
1043GR Amsterdam
Netherlands
RISN No: 818855605