Ìròyìn nípa Amẹ́ríkà
Àwọn ọmọ ìbílẹ̀ Brazili ra ìpín ìdókòòwò ní iléeṣẹ́ reluwé láti bá a wí fún ìkùnà ojúṣe àyíkáa rẹ̀
Ìlépa alájọpín-ìdókòòwòo wọn kì í ṣe fún ti èrè ìdókòòwò, àmọ́ láti mú kí ohùn-un wọn ó dé etí ìgbọ́ àwọn olùdókòòwòo iléeṣẹ́ náà.
Fún ìgbà àkọ́kọ́ ní orílẹ̀-èdèe Brazil, ọmọ ìbílẹ̀ lóbìnrin di ọmọ ìgbìmọ̀ ìjọba
Joenia ni ọmọ ìbílẹ̀ lóbìnrin àkọ́kọ́ tí ó kẹ́kọ̀ọ́ gboyè nínú ẹ̀kọ́ ìmọ̀ òfin ní Brazil, òun sì ni agbẹjọ́rò tí ó jẹ́ ọmọ ìbílẹ̀ àkọ́kọ́ tí yóò gbejọ́rò ní Ilé-ẹjọ́ Gíga jùlọ.
Oníròyìn Orí ẹ̀rọ-alátagbà Luis Carlos Diaz di àwátì ní Venezuela

Luis Carlos "jẹ́ ọ̀kan lára àwọn tí ó síwájú nínú akọ̀ròyìn tako ìgbésẹ̀ ìjọba ní Venezuela".
Akẹ́kọ̀ọ́bìrin kan tí ó jẹ́ ọmọ Tibet-Canada rí ìkọlu lórí ayélujára lẹ́yìn tí ó já ewé olú borí nínú ìdìbò àjọ-ìgbìmọ̀ akẹ́kọ̀ọ́. Ó rò pé, Beijing ló yẹ á bá wí.

Chemi Lhamo dojú kọ onírúurú èsì ìdáyàjáni ní orí ẹ̀rọ-alátagbà láti ẹnu àwọn akẹ́kọ̀ọ́ òkè-òkun tí ó ń gbé ní gbùngbùn orílẹ̀-èdè China.