Bí orílẹ̀-èdè Nàìjíríà ṣe kojú ìdábẹ́ Ọmọbìnrin èyí tí ó ń ṣe lemọ́lemọ́: Ìfọ̀rọ̀wánilẹ́nuwò kan pẹ̀lú Dókítà Chris Ugwu

Ìdánilẹ́kọ̀ọ́ kan nípa dídábẹ́ ọmọbìnrin (FGM) fún àwọn ọ̀dọ́ orílẹ̀-èdè Nàìjíríà. Àwòrán láti ọwọ́ SIRP Nigeria, a sì gba àṣẹ ká tó lò ó.

Ní orílẹ̀-èdè Nàìjíríà, ogún mílíọ̀nù ọmọdébìnrin àti àwọn obìnrin ni a ti dábẹ́ (FGM) fún. Ní ìbámu pẹ̀lú àjọ tó ń mójú tó ètò ìlera àgbáyé (WHO), dídábẹ́ ọmọbìnrin ní í ṣe pẹ̀lú yíyọ lára ẹ̀yà ojú-ara tàbí yíyọ nnkan ojú-ara ọmọbìnrin ti ìta ara kúrò pátápátá tàbí ìpalára mìíràn sí ojú-ara fún ìdí tí kò rọ̀ mọ́ ètò ìlera.”

Jákèjádò àgbáyé, ọ̀kan nínú àwọn ọmọdébìnrin àti obìnrin 10 tó ní ìrírí abẹ́ dídá wà ní Nàìjíríà. Orílẹ̀-èdè náà ní ìyàtọ̀ lákọlábo tó fojú hàn gbangba nínú ètò òṣèlú, ọrọ̀-ajé àti ètò-ẹ̀kọ́. Ìṣe ẹ̀yàmẹ̀yà, ìwà ipá sí àwọn obìnrin, àti ìdójúlé àbùdá ìbí ìṣakọṣabo ní í ṣe ìdíwọ́ fún ìṣọdoogba ìṣakọṣabo.

Dídábẹ́ fún ọmọbìnrin àti àwọn oríṣìiríṣìi àwọn ìwà ipá ìṣakọṣabo mìíràn di ẹsẹ̀ tó ní ìjìyà lábẹ́ òfin pẹ̀lú àkọsílẹ̀ òfin Orílẹ̀ Èdè Nàìjíríà tó ọdún 2015 tí ó lòdì sí ìwà ipá sí Ènìyàn. Síbẹ̀, ìṣe yìí tẹ̀síwájú fún oríṣìiríṣìi ìdí.

Ní oṣù kẹfà, Sangita Swechcha fi ọ̀rọ̀ wá dókítà Chris Ugwu, ẹni tí í ṣe Adarí Àgbà ti Àwùjọ fún Ètò Ìdàgbàsókè Àwọn Ará Ìgbèríko (SIRP) lẹ́nu wò, ẹgbẹ́ tó ní í ṣe pẹ̀lú ẹ̀tọ́ àwọn ará agbègbè, tó ń ṣiṣẹ́ láti fòpin sí dídábẹ́ fún àwọn ọmọbìnrin nípa ètò ìbánidọ́rẹ̀ẹ́ àti àyípadà ìwà ní Nàìjíríà.

Ohùn Àgbáyé: Kí ni ìdí tí a fi ń dá abẹ́ fún ọmọbìnrin àti pé báwo ni ó ti ń mú akùdé bá ìlera àti àlàáfíà àwọn ọmọbìnrin lọ́mọdélágbà?

Dókítà Chris Ugwu: Ní orílẹ̀-èdè Nàìjíríà, ẹkùn tí ìdábẹ́ fún ọmọbìnrin ti gbilẹ̀ jùlọ ni apá gúúsù-ìwọ̀ oòrùn àti gúúsù-ìlà oòrùn. Oríṣìiríṣìi ìdí ni wọ́n fi ń ṣe ìdábẹ́ fún ọmọbìnrin ní Nàìjíríà. Bẹ̀rẹ̀ láti orí ohun tí ó rọ̀ mọ́ àṣà dé  lílòó láti fi dẹ́kun ìpòhùngbẹ ìbálòpọ̀ ọmọbìnrin lọ́mọdé lágbà ní orílẹ̀-èdè náà. Àmọ́ ní àtàrí ìbéèrè yìí, a ó dójú lé díẹ̀ lára àwọn ìdí tí ó fi jẹ́ pé wọ́n ń ṣe é ní Enugu ní apá gúúsù-ìlà oòrùn Nàìjíríà. Ní ìpínlẹ̀ Enugu, wọ́n ń ṣe abẹ́ dídá fún ọmọbìnrin nítorí ti ètò ìṣẹ̀nbáyé ìṣolórí àwọn ọkùnrin, èyí tó ń fìdí ìjẹgàba ọkùnrin lórí obìnrin múlẹ̀. Ó jẹ́ ọ̀nà tí àwọn ọkùnrin ń gbà tẹ àwọn obìnrin lórí ba tí wọ́n sì ń gbé ara wọn lékè obìnrin tipátipá.

Ìdí mìíràn ni pé ìdábẹ́ fún ọmọbìnrin ni wí pé wọ́n máa ń rí i gẹ́gẹ́ bí ohun tó bá ẹ̀sìn àti ojúṣe àṣà mu, fún àpẹẹrẹ, ètò ìṣísẹ̀ wọ ìpele ẹni tó tójú-bọ́, ìdábẹ́ fún ọmọbìnrin gẹ́gẹ́ bí ọ̀kan lára ayẹyẹ ìsọmọlórúkọ, àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ. Ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ agbègbè ní Ìpínlẹ̀ Enugu ìdábẹ́ fún ọmọbìnrin máa ń wáyé ní ọjọ́ kẹjọ tí a bí ọmọ, láti ṣe pẹ̀kí-ǹ-rẹ̀kí pẹ̀lú ìsọmọlórúkọ, tí ó jẹ́ ayẹyẹ alájọ̀dún ńlá pẹ̀lú ọ̀pọ̀lọpọ̀ ẹ̀bùn àti àwẹ̀jẹwẹ̀mu. Ìsọmọlórúkọ àti ìdábẹ́ náà wọnú ara wọn. Ìwádìí tún fi hàn pé àwọn ìyá tí kò lọ́wọ́ sí i kò lè sọ ní gbangba pé kí wọ́n má dábẹ́ fún ọmọbìnrin wọn nítorí èyí túmọ̀ sí wípé kò sí ìsọmọlórúkọ nìyẹn. Gbogbo èyí ti mú kí àṣà yìí gbilẹ̀ sí i ní ìpínlẹ̀ Enugu.

Dókítà Chris Ugwu, ń kópa nínú ọ̀kan nínú àwọn ìpolongo SIRP tí ó wáyé ní Nàìjíríà.

Ohùn Àgbáyé: Kí ni ipa ìdábẹ́ fún ọmọbìnrin lórí ètò-ẹ̀kọ́ àwọn obìnrin lọ́mọdé àti lágbà ní Nàìjíríà?

Dókítà Ugwu: Ipa ìdábẹ́ fún ọmọbìnrin lórí ètò ìlera kò ṣe é fẹnu sọ. Ìdí ni pé ó má a ń yọrí sí ìrora tó lágbára, ṣíṣe àgbákò àrùn àìfojú rí, ẹ̀jẹ̀ yíya lọ́pọ̀lọpọ̀, àìle kápá ojú ilé ìtọ̀, làásìgbò ní ìgbà ìbímọ, ìpayà, àti ní ìgbà mìíràn, ikú pàápàá. Bákan náà, ó ń ní ipa lórí ètò-ẹ̀kọ́ ọmọbìnrin. Ìdábẹ́ fún ọmọbìnrin dúró gẹ́gẹ́ bí ohun tó ṣíde ìgbéyàwó ní kùtùkùtù ayé ọmọdébìnrin. Èyí túmọ̀ sí wípé yóò ní láti fi ilé-ìwé sílẹ̀ láti bójú tó ẹbí rẹ̀. Èyí tí yóò yọrí sí àìní àǹfààní sí rírí iṣẹ́ tó dára tó ń mówó wọlé dáadáa ní ọjọ́ iwájú.

Ohùn Àgbáyé: Àyẹ̀wò ìwádìí Àwùjọ fún Ètò Ìdàgbàsókè Àwọn Ará Ìgbèríko (SIRP) fi hàn pé ìdá àádọ́rùn-ún nínú ọgọ́rùn-ún (95%) àwọn olùdáhùn ni kò tí ì gbọ́ wí pé ìdábẹ́ fún ọmọbìnrin ti di ẹsẹ̀ tó ní ìjìyà lábẹ́ òfin ní Nàìjíríà. Kí ni ẹ lè sọ nípa èyí?

Dókítà Ugwu: Èyí jẹ́ ohun tí kò wúni lórí rárá ni ní Nàìjíríà nítorí láìsí ìmọ̀ yìí, a ti rí àwọn ẹbí àti agbègbè tó gbójúgbóyà láti tẹ̀síwájú nínú ìṣe yìí. Ó bá ni lọ́kàn jẹ́ púpọ̀. Torí náà, ohun tí a ń ṣe ni pé kí a gbé ìmọ̀ yìí lọ sí agbègbè lóríṣiríṣi níbí ní Nàìjíríà. A ti ń ṣe èyí fún ọdún mẹ́ta sẹ́yìn báyìí a ó sì tẹ̀síwájú láti máa ṣe é. Ní báyìí, à ń fi ṣe iṣẹ́ àkànṣe ifòpin sí ìdábẹ́ fún ọmọbìnrin ní Akwuke pẹ̀lú ìrànlọ́wọ́ Feed the Minds (UK). Nínú iṣẹ́ àkànṣe yìí, a rí i dájú pé àwọn ará agbègbè náà ni a fún ní ìtanijí nípa Ìlòdì òfin sí ìwà ipá sí ènìyàn (VAPP Law) ti Ìpínlẹ̀ Enugu, tí ó lòdì sí dídábẹ́ fún ọmọbìnrin ní Nàìjíríà.

Ohùn Àgbáyé: Ẹ ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìrírí nínú ṣíṣiṣẹ́ pẹ̀lú àwọn agbègbè ní ìgbèríko. Báwo ni àyípadà ṣe ń dé bá àwùjọ ènìyàn ní ìgbèríko ní ti dídábẹ́ fún ọmọbìnrin?

Dókítà Ugwu: Ó lẹ́wà púpọ̀ láti rí àyípadà àwùjọ. Èyí rí bẹ́ẹ̀ nítorí a ti ń rí àwọn ẹbí àti agbègbè tó ń yí èrò àti ìkọrasí wọn padà nípa ìṣe yìí. Wọ́n ti wá kọ̀yìn sí i tí wọ́n sì ń lòdì sí ìṣe yìí ní gbangba lójútáyé. A ti rí èyí ní àwọn agbègbè kan bí i Awgu, Okpanku, àti Oduma níbí ní Ìpínlẹ̀ Enugu. Ohun kan tó ti ràn wá lọ́wọ́ nínú gbogbo èyí ni ìlànà à-á-tẹ̀lé wá, tí ó ní í ṣe pẹ̀lú ṣíṣe àmúlò àìṣèdájọ́, ìtàkuròsọ ìta gbangba. Tí ó je pé a ní ètò ìtàkuròsọ tí kò ní ìdájọ́ nínú pẹ̀lú onírúurú ọmọ àdúgbò.

Ohùn Àgbáyé: Kí ni ìlànà àátẹ̀lé fún fífòpin sí dídábẹ́ fún ọmọbìnrin ní Nàìjíríà àti kí ni àwọn ètò ìdènà rẹ̀ tí ẹ ti fi lélẹ̀?

Dókítà Ugwu: Ìlànà àátẹ̀lé wa fìdí sọlẹ̀ sínú àwọn ẹ̀yà 6 ti Ìkòsílẹ̀ Ìdábẹ́ fún ọmọbìnrin ti àjọ UNICEF. Ìlànà àátẹ̀lé yìí ní ojú púpọ̀ èyí tó ní ṣe pẹ̀lú ṣíṣe àmúlò ìtàkuròsọ gbangba tí kò ní ìdálẹ́jọ nínú, ìgbanimọ́ra àwọn ará agbègbè, ìgbóhùn sáfẹ́fẹ́, òfin, àti bákan náà ìran tó ń bọ̀.

Lọ́wọ́lọ́wọ́ à ń fi ṣiṣẹ́ àkànṣe Fòpin sí dídábẹ́ fún ọmọbìnrin olóṣù méjìlá ní agbègbè Akwuwe ti Ìpínlẹ̀ Enugu, Nàìjíríà. A ti ṣe ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìkọ́ni, ìdánilẹ́kọ̀ọ́ àti ètò orí ẹ̀rọ asọ̀rọ̀mágbèsì tí a sì ti ń rí àbájáde rere. A lérò pé a ó ṣe àyípadà tí yóò lapa fún ìgbà pípẹ́.

Bẹ̀rẹ̀ ìtàkùrọ̀sọ náà

Òǹkọ̀wé, jọ̀wọ́ àkọsílẹ̀ ìwọlé »

Ìlànà

  • Atukọ̀ yóò ṣ'àtúnwò gbogbo ìsọsí . Máà fi ìsọsíì rẹ sílẹ̀ ju ẹ̀rìnmejì lọ tàbí kí a kà á sí iṣẹ́-ìjẹ́-tí-a-o-fẹ́.
  • Jọ̀wọ́ fi ọ̀wọ̀ fún ẹlòmíràn . A ò ní fi àṣẹ sí ìsọsí ìkórìíra, ìṣekúṣe, àti ìdojú-ìjà-kọ ẹnikẹ́ni k.