Èdè Ohùn Àgbáyé

A group of people smile at the camera.

Àwọn akópa Èdè ní ibi ìpàdé àwọn akọ̀ròyìn ará ìlú Ohùn Àgbáyé ní Colombo, Sri Lanka. 2017. Jer Clarke ni olùyàwòrán.

“A mú un ní ojúṣe láti kọ́ afárá gba orí àwọn omi òkun tí ó pín àwọn ènìyàn níyà, kí òye ara wọn ó ba yé ara wọn yéké. […] A ní ìgbàgbọ́ pé ìròyìn ìlú sí ìlú ṣe pàtàkì fún ọjọ́ ọ̀la olómìnira, olódodo, tí ó gbèrú, tí ó sì dúró ṣánṣán fún gbogbo àwọn ọmọ ìlú tí ó wà ní orí ilẹ̀ ayé.” —Àfàyọ láti inú ìkéde ní gbangba èrò Ohùn Àgbáyé

Àjọ àgbáyé àwọn àfínnúfíndọ̀ṣe ṣiṣẹ́ tí ó ti ń ṣe àmúlò ipá ẹ̀rọ-ayélujára fi gbé ìròyìn nípa àwọn ènìyàn tí a kì í sábà gbọ́ ìròyìn wọn àti ìrírí wọn lórí àwọn iléèṣẹ́ ìròyìn ńláńlá láti ọdún 2005 ni Ohùn Àgbáyé.

Fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọdún, àkànṣe-iṣẹ́ títúmọ̀ Èdè ti ṣiṣẹ́ gidi láti jẹ́ kí àwọn ìròyìn Ohùn Àgbáyé ó wà fún kíkà ní onírúurú èdè. Ní ọdún 2006, àkójọpọ̀ àwọn aládàásí ọmọ elédè Faransé kan mú àbá wá láti ṣe àfilọ́lẹ̀ ibùdó-ìtakùn Ohùn Àgbáyé ní èdè Faransé, apákan ìmísí tí ó wá láti ọ̀dọ̀ aládàásí ọmọ elédè Taiwanese ẹni tí ó ti bẹ̀rẹ̀ sí í tú ìmọ̀ èdè àwọn ìròyìn Ohùn Àgbáyé sí èdè Chinese fún àkọọ́lẹ̀ oríìtakùn àgbáyé tirẹ̀. Àwọn ọmọ ẹgbẹ́ tí ó jẹ́ elédè mìíràn náà fi ìfẹ́ ọkàn wọn hàn láti máa ṣe ògbufọ̀ àwọn ìròyìn Ohùn Àgbáyé, báyìí ni Èdè ṣe wáyé.

A group of people smile at the camera.

Àwọn akópa ní ibi ìpàdé Ohùn Àgbáyé ní Delhi, India. 2006. Kiran Jonnalagadda ni olùyàwòrán. CC BY-NC-SA 2.0

Láti ìgbà náà, àwọn àfínnúfíndọ̀ ti ṣe ògbufọ̀ àkànṣe-iṣẹ́ Èdè títúmọ̀ àwọn ìròyìn Ohùn Àgbáyé sí onírúurú èdè, bẹ̀rẹ̀ láti orí àwọn èdè tí wọ́n ń sọ jù ní àgbáyé bí i Arabic, Bangla, French, Russian àti Spanish títí dé orí àwọn èdè ńlá àti kékeré mìíràn bí i Aymara, Albanian, Malagasy, Odia, Swahili, àti Yorùbá. Àwọn Alákòóso Ìtúmọ̀ tí àwọn náà jẹ́ àfínnúfíndọ̀, ló ń tukọ̀ àwọn ibùdó-ìtakùn àwọn èdè gbogbo.

Kí ni ìdí tí ó fi yẹ kí o di òǹgbifọ̀ àfínnúfíndọ̀ṣe? “Nítorí láì sí àní-àní, ìrírí ọlọ́pọ̀-àṣà ni. Àwọn onímìísí ènìyàn máa ń kọ àwọn ìròyìn káàkiri ilé-ayé. Mo fẹ́ ṣe ìrànlọ́wọ́ láti mú kí ohùn-un wọn ó ró gooro sí i!”  —Kasia Odrozek, ẹni tí ó ń ṣe ògbufọ̀ fún Ohùn Àgbáyé ní èdè Polish

Ní nǹkan bí i ọdún 2010, Ohùn Àgbáyé pọ̀ sókè rajà, ó sì bẹ̀rẹ̀ láti máa gba iṣẹ́ títúmọ̀ èdè lọ́wọ́ àwọn oníbàárà àti àwọn ilé-iṣẹ́ tí ó bá nílò ògbufọ̀. Ọ̀pọ̀ àwọn òǹgbifọ̀ tí ó gba àwọn iṣẹ́ wọ̀nyí ṣe ni ó wá láti inú àwọn ikọ̀ Èdè.

Káàkiri àgbá-ńlá ayé ni àwọn ọmọ ẹgbẹ́ wa wà tí olúkúlùkù wọn sì ní ìrírí tí ó yàtọ̀ọ̀tọ̀. Ara wọn ni àwọn akọ́ṣẹ́mọṣẹ́ òǹgbifọ̀, àwọn akẹ́kọ̀ọ́, àwọn akọ̀ròyìn, àwọn amòye, ajàfẹ́tọ̀ọ́-ọmọ-ènìyàn, àwọn onítara ohun ajẹ́mọ́-èdè, onímọ̀-ẹ̀rọ àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ.

Láì fi ti ìrírí ìṣáájú wọn pè, àwọn àfínnúfíndọ̀ ṣe ògbufọ̀ máa ń ṣàkíyèsí wí pé kíkópa nínú àkànṣe-iṣẹ́ Èdè mú kí ìmọ̀ọ́ṣe títúmọ̀, àrògún àti àwọn nǹkan mìíràn nípa wọn ó dára sí i. Ó sì tún fún wọn ní àyè láti fi ìmọ̀ kún ìmọ̀ nípa ilé-ayé, ṣe ìbáṣepọ̀ àti ìbánidọ́rẹ̀ẹ́ pẹ̀lú àwọn ènìyàn tí wọn ò bá ti má pàdé láyé. Ìdí tí ó fi yẹ kí o darapọ̀ mọ́ wa.

Kí ni ìdí tí ó fi yẹ kí o di àfinúfẹ́dọ̀ ṣe ògbufọ̀? “Nítorí o lè ṣe ìrànlọ́wọ́ fún ìròyìn láti dé ọ̀dọ̀ àwọn ènìyàn.” Aygun Janmammadova, ẹni tí ó ń ṣe ògbufọ̀ fún Ohùn Àgbáyé ní èdè Russian  

A group of people jump for joy with balloons.

Àwọn akópa ní ibi ìpàdé Ohùn Àgbáyé ní Santiago, Chile, ní ọdún 2010. David Sasaki ni olùyàwòrán. CC BY-NC-SA 2.0

Bóyá ṣíṣe ìtumọ̀ ìròyìn kan tàbí ṣíṣe àkóso ibùdó-ìtakùn èdè, àwọn iṣẹ́ ìfarajìn wọ̀nyí tí àwọn àfínnúfíndọ̀ ń ṣe ni ó ń mú kí àkànṣe-iṣẹ́ Èdè ó ṣì máa di àsìkò yìí. Nítorí wí pé àwọn òǹgbifọ̀ máa ń yan ohun tí ó bá hùn wọ́n láti ṣiṣẹ́ lé lórí nígbà tí wọ́n bá ráyè, ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn ibùdó-ìtakùn èdè Ohùn Àgbáyé ni ó ní bí wọ́n ṣe ń ṣiṣẹ́, ó sì ní irú ìròyìn Ohùn Àgbáyé tí wọ́n sábà máa ń gbé jáde.

Àwọn àfínnúfíndọ̀ Ohùn Àgbáyé lè máa wá kí wọn ó máa lọ, ṣùgbọ́n iṣẹ́ tí wọ́n ti ṣe sílẹ̀ ṣì wà nígbà tí wọ́n lọ. Níwọ̀n bí àwọn ibùdó-ìtakùn Èdè kan tí wọ́n fi ìgbà kan rí gbé ìròyìn jáde ṣùgbọ́n tí ìparọ́rọ́ ti bá, bí ó ti lẹ̀ rí bẹ́ẹ̀ wọ́n ṣì ń ṣe àfihàn àwọn ìròyìn láti ibi gbogbo nílé ayé ní ojú ìwòye èdè kan àti àkókò kan lọ́wọ́lọ́wọ́ yìí nínú ìwé ìtàn, a sì dúpẹ́ lọ́wọ́ àwọn àfínnúfíndọ̀ wa àtijọ́ fún iṣẹ́ tí wọ́n ṣe sílẹ̀.

Fún àtòjọ àwọn èdè tí ó wà, bojú wo àtẹ èdè ní orí òkè ojú ewé ibùdó-ìtakùn yìí.

Bí o bá hùn ọ́ láti di àfinúfẹ́dọ̀ ṣe ògbufọ̀ ìròyìn fún Ohùn Àgbáyé sí èdè Yorùbá, jọ̀wọ́ fi ìwé ìfẹ́ ọkàn láti bá wa ṣiṣẹ́ ṣọwọ́.

Bí o bá hùn ọ́ láti finúfẹ́dọ̀ ṣe òǹgbifọ̀ fún èdè mìíràn tàbí ó hùn ọ́ láti ṣe ìgbédìde àwọn ibùdó-ìtakùn tí kò jẹ́ lílò fún ọjọ́ pípẹ́, jọ̀wọ́ lọ sí ibùdó-ìtakùn Èdè fún ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ àlàyé.