Ìròyìn nípa Ìdàgbàsókè

Sísọnù sínú ògbufọ̀: Ìdí tí Atúmọ̀ Google ṣe ń kùnà — nínú títúmọ̀ èdè Yorùbá — àti àwọn èdè mìíràn

Ohùn Tó-ń-dìde  11 Ẹrẹ́nà 2020

Bí àwọn iléeṣẹ́ onímọ̀ ẹ̀rọ ṣe ń gbìyànjú láti mú kí ògbufọ̀ èdè wà lárọ̀ọ́wọ́tó fún onírúurú èdè lórí ayélujára, ni àríyànjiyàn àti ìpèníjà ń gbérí — pàápàá jù lọ ti àṣe déédéé àti ìtumọ̀ ọ̀rọ̀ ọlọ́pọ̀ ìtumọ̀.

Ilẹ̀-Adúláwọ̀ rí àbọ̀ ẹgbẹẹgbẹ̀rún-lọ́nà-ẹgbẹ̀rún owóo dollar láti ọ̀dọ̀ Ilé-ìfowópamọ́sí ńláńlá fún ìgbéfúkẹ́ Iléeṣẹ́ ọgbọ́n àtinudá

  31 Ṣẹẹrẹ 2020

“Nítorí àìtó ìdókoòwò ń'nú iléeṣẹ́ ọgbọ́n àtinudá àti àṣà, Ilẹ̀-Adúláwọ̀ kò sí ń'nú ọjà iṣẹ́ ọpọlọ, àti ìdáraáwò ní àgbáyé," Benedict Oramah, ààrẹ Afreximbank ló sọ bẹ́ẹ̀.

Ilé ẹjọ́ gíga Tanzania pa á láṣẹ fún ìfòpinsí ìsoyìgì láàárín àgbàlagbà àti ọmọdé láì wo ti ìgbésẹ̀ ìmúpadàa rẹ̀

Nínú oṣù Ọ̀wàrà 2019, Ilé-ẹjọ́ Gíga Tanzania ṣe ìdímú ṣinṣin ìdájọ́ láti fòpin sí ìgbéyàwó ọmọdé. Ìdájọ́ ilé ẹjọ́ náà jẹ́ atọ́ka sí ìfòpinsí àwọn àṣà tí ó ń mú ìpalára bá àwọn ọmọdébìnrin àti onírúurú ẹlẹ́yàmẹyà tòun ìfọwọ́rọ́sẹ́yìn àwọn ọmọdébìnrin.