Ìròyìn nípa Ètò-ẹ̀kọ́

Sọ̀rọ̀sọ̀rọ̀ ní Nàìjíríà darapọ̀ mọ́ àwọn akẹgbẹ́-ẹ wọn láti sààmì ayẹyẹ Ọjọ́ Ẹ̀rọ-ìgbóhùnsáfẹ́fẹ́ Àgbáyé ọdún-un 2020

Àwọn sọ̀rọ̀sọ̀rọ̀-ọ orílẹ̀-èdèe Nàìjíríà darapọ̀ mọ́ àwọn sọ̀rọ̀sọ̀rọ̀ orí ẹ̀rọ-ìgbóhùnsáfẹ́fẹ́ lágbàáyé láti sààmì Àyájọ́ Ọjọ́ Ẹ̀rọ-ìgbóhùnsáfẹ́fẹ́ Àgbáyé lọ́jọ́ 13 oṣù Èrèlé ọdún-un 2020 àti láti fọn rere iṣẹ́ ìdàgbàsókè àgbà-ńlá ayé tí ẹ̀rọ-ìgbóhùnsáfẹ́fẹ́ ń ṣe.

Ilé ẹjọ́ gíga Tanzania pa á láṣẹ fún ìfòpinsí ìsoyìgì láàárín àgbàlagbà àti ọmọdé láì wo ti ìgbésẹ̀ ìmúpadàa rẹ̀

Nínú oṣù Ọ̀wàrà 2019, Ilé-ẹjọ́ Gíga Tanzania ṣe ìdímú ṣinṣin ìdájọ́ láti fòpin sí ìgbéyàwó ọmọdé. Ìdájọ́ ilé ẹjọ́ náà jẹ́ atọ́ka sí ìfòpinsí àwọn àṣà tí ó ń mú ìpalára bá àwọn ọmọdébìnrin àti onírúurú ẹlẹ́yàmẹyà tòun ìfọwọ́rọ́sẹ́yìn àwọn ọmọdébìnrin.