Ìròyìn nípa Àyíká
Ìtọ́jú àwọn erin aláìlóbìíi Myanmar
Erin ẹgàn-an Myanmar ń bẹ ń'nú ewu, àwọn adẹ́mìí légbodò kò jẹ́ kí wọn ó gbáyé, erin kan lọ́sẹ̀ kan ni wọ́n ń pa.
Iyùn Tobago tí ó ti ń pàwọ̀dà fi hàn gbàgàdàgbagada pé kò sí ọ̀nà mìíràn ju kíkojú àyípadà ojú-ọjọ́
Ìgbóná òkun ń kóbá àwọn òkúta iyùn-un Tobago àti àwọn erékùṣù Ọ̀sàa Caribbean, a bá onímọ̀ ìṣẹ̀dá kan tí ọjọ́ iwájúu wọn jẹ́ lógún sọ̀rọ̀.
‘Ohùn-un Jamaica fún Àyípadà Ojú-ọjọ́’ fi orin jíṣẹ́ẹ wọn
Iléeṣẹ́ tí kì í ṣe ti ìjọba ń ṣe ìgbélárugẹ àwọn ọ̀nà tí a lè gba jẹ́ iṣẹ́ yìí nípa lílo iṣẹ́ ọpọlọ orin láti kéde nípa àyípadà ojú-ọjọ́.
Àwọn ọmọ ìbílẹ̀ Brazili ra ìpín ìdókòòwò ní iléeṣẹ́ reluwé láti bá a wí fún ìkùnà ojúṣe àyíkáa rẹ̀
Ìlépa alájọpín-ìdókòòwòo wọn kì í ṣe fún ti èrè ìdókòòwò, àmọ́ láti mú kí ohùn-un wọn ó dé etí ìgbọ́ àwọn olùdókòòwòo iléeṣẹ́ náà.
Fún ìgbà àkọ́kọ́ ní orílẹ̀-èdèe Brazil, ọmọ ìbílẹ̀ lóbìnrin di ọmọ ìgbìmọ̀ ìjọba
Joenia ni ọmọ ìbílẹ̀ lóbìnrin àkọ́kọ́ tí ó kẹ́kọ̀ọ́ gboyè nínú ẹ̀kọ́ ìmọ̀ òfin ní Brazil, òun sì ni agbẹjọ́rò tí ó jẹ́ ọmọ ìbílẹ̀ àkọ́kọ́ tí yóò gbejọ́rò ní Ilé-ẹjọ́ Gíga jùlọ.
Spiny Babbler, ẹyẹ orílẹ̀-èdè Nepal, fa àwọn onímọ̀-nípa-ẹyẹ àti olólùfẹ́ ẹyẹ mọ́ra
Ẹyẹ Spiny Babbler, tí ó wà ní Nepal nìkan, ti fa àwọn onímọ̀-nípa-ẹyẹ àti olólùfẹ́ ẹyẹ káríayé mọ́ra. Oko ríro fún iṣẹ́ ọ̀gbìn àti ìsọ̀gbẹ́dìgboro ti ń dá ẹ̀míi rẹ̀ ní ègbodò.
Bí àpamọ́ àlọ́ àti ìtàn àtọwọ́dọ́wọ́ ṣe mú ọ̀rọ̀ àyíká di mímọ̀ ní Mekong
"By means of stories, the communities search for ways to accommodate and/or resist changes that are taking place in the Mekong river basin."