Wọ́n máa ń sọ pé tí àgbàlagbà bá kú, yóó dà bí ẹni pé ilé-ìkàwé kan ti jó lulẹ̀ ráúráú. Ìpàdánù náà gbòòrò tí àgbàlagbà tí à ń mẹ́nu bà bá jẹ́ òǹsọ̀tàn nílànà ewì, ògbóǹtarìgì òǹpìtàn tí ó jẹ́ ibi-ìṣura àṣà àti àgbà ọ̀jẹ̀ nínú ìtàn àtẹnudẹ́nu. Ní ọjọ́ 28 oṣù Ọ̀pẹ, orílẹ̀-èdè Trinidad àti Tobago rí àdánù nígbà tí ògbólògbó òǹkọrin Leroy Calliste, tí orúkọ ìnagijẹ rẹ̀ ń jẹ́ “Black Stalin,” jáde láyé ní ẹni ọdún 81.
Ó jẹ́ gbajúgbajà fún orin kíkọ́ àti eré ṣíṣe lọ́nà tí yóò ṣe àgbéyẹ̀wò àwọn ohun tí ó jẹ mọ́ ìmúnisìn àti ìrẹ́jẹ, ìrínisí àti ìhùwàsí rẹ̀ dídára lórí ìtàgé, ní ìdàpọ̀ pẹ̀lú ẹ̀bùn àwọn ọ̀rọ̀ orin apanilẹ́rìn-ín tí ó ń gúnni lára àti orin àlùjó, sọ ọ́ di ààyò láàárín àwọn ẹgbẹ́ olórin calypso àti àwọn ẹgbẹ̀lẹ́gbẹ̀ olùwòran tí yóò tú yáyá tú yàyà láti wò ó.
A bíi ní gúúsù Trinidad ní ọjọ́ 24, oṣù Ọ̀wẹwẹ̀ ọdún 1941, Calliste kópa nínú ijó limbo àti lílu irin fẹ́lẹ́fẹ́lẹ́ (steelpan) nígbà ọ̀dọ́-ọ rẹ̀, ó bẹ̀rẹ̀ orin calypso kíkọ́ lẹ́ni ọdún 17. Ó darapò mọ́ àgọ́ orin calypso àkọ́kọ́, Southern Brigade, lẹ́yìn ọdún mẹ́ta, kò sì wẹ̀yìn wò. Nínú àwọn ọdún tí ó tẹ̀lé 1960, nígbà tí àgbà ọ̀jẹ̀ olórin calypso kan — nínú bàtà ti Stalin, Lord Blake fún un ní orúkọ ìnagijẹ (gẹ́gẹ́ bí ìṣe), ìràwọ̀ Stalin bẹ̀rẹ̀ síí kàn. Ó darapọ̀ mọ́ àgọ́ olókìkí olórin calypso nì Lord Kitchener Calypso Revue ní 1967 ó sì kógo já dé ìparí ìdíje Ọba Calypso ọdún yẹn.
Ó tẹ̀síwájú láti gba àmì ẹ̀yẹ Ọba Calypso tí ọ̀pọ̀ ń wá fún ìgbà àkọ́kọ́ ní 1979 pẹ̀lú àkójọpọ̀ orin àgbọ́ṣífìlàa rẹ̀ “Caribbean Man” àti “Play One,” ewì kúkúrú tó wà fún wíwárìrì ìlu steelpan àti àwọn tí ó dá calypso sílẹ̀. Stalin tún gba àmì ẹ̀yẹ náà ní ìgbà mẹ́rin ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀: ní 1985 (“Ism Schism” àti “Wait Dorothy Wait”), 1987 (“Mr. Panmaker” àti “Bun ‘Dem”), 1991 (“Look on the Bright Side” àti “Black Man Feelin’ to Party”) àti 1995 (“In Times” àti “Tribute To Sundar Popo”).
Ó tún gba àmì ẹ̀yẹ Ọba orin Calypso ti Àgbáyé ní 1999, ayẹyẹ àgbáyé níbi tí ó jẹ́ pé, nígbà ìfílọ́lẹ̀ ìdíje àkọ́kọ́ irú ẹ̀ ní 1985, ipò kejì ni Stalin wà sí The Mighty Sparrow, Ọba orin Calypso Àgbáyé tí gbogbo aráyé ń wárí fún. Ní àárín ọ̀rúndún 1990, Stalin tọwọ́bọ̀wé pẹ̀lú ilé-iṣẹ́ agbórinjáde Grant Ice Records ti Barbadian Eddy, tí ó ṣe àgbéjáde àwo rẹ “Rebellion” ní 1994 àti “Message to Sundar” ní ọdún tí ó tẹ̀lé e.
Ní ọjọ́ 31 oṣù Kẹwàá, 2008, Stalin di dókítà Leroy Calliste nígbà tí St. Augustine, ọgbà ọmọléèwé Yunifásitì West Indies ti Trinidad dá a lọ́lá pẹ̀lú àmì akẹ́kọ̀ọ́ gboyè fún àwọn ipa ribiribi tí ó kó láwùjọ àwọn orin Calypso, tí ó tẹ̀lé àmì ẹ̀yẹ orílẹ̀-èdè, the Hummingbird Medal rẹ̀ (fàdákà), ìjọba fi dá a lọ́lá ní 1987 fún àwọn akitiyan rẹ̀ níbi ìgbáṣà lárugẹ.
Ọjọ́ méjì sí àyájọ́ ọjọ́ ìbíi rẹ̀ 73, ní oṣù Kẹsàn-án ọdún 2014, Black Stalin lùgbàdì àrùn rọpárọsẹ̀ kan lẹ́yìn tí ó kọ́rin ní ibi ètò ìkówójọ inú-rere ní gúúsù Trinidad. Bí ó ti lẹ̀ jẹ́ pé ó ń tẹ̀síwájú, kò ní padà sí orí ìtàgé mọ́ pẹ̀lú ara tí ó jí pépé.
Ní gbogbo ìgbà tí ó fi ń ṣiṣẹ́ orin kíkọ rẹ̀ pẹ̀lú ara líle, Stalin máa ń tiraka láti fi ojúlówó, ọgbọ́n inú àìlẹ́lẹ́gbẹ́ sọ̀rọ̀ nípa àwọn ọ̀rọ̀ náà tó ń lọ lọ́wọ́. Ó jẹ́ aládàánìkàn ronú tó gbóná àti olùpilẹ̀sẹ̀ ọ̀rọ̀ orin tí yóò pè é gẹ́gẹ́ bí ó ti hàn sí i. “Wait Dorothy Wait,” bí àpẹẹrẹ, jẹ́ ìró ohùn tó dùn-ún gbọ́ tí ó sì ṣe ìlérí fún àwọn olólùfẹ́ẹ rẹ̀ pé òun yóò kọ orin atunilára, calypso arínilára — ṣùgbọ́n lẹ́yìn àwọn kùdìẹ̀kudiẹ àwùjọ bíi ìwà ìbàjẹ́, àìdọ́gba àti ìṣẹ́ bá dópin nìkan. Orin náà, tí ó ṣe é jó sí, tí ó sì jinlẹ̀, ṣe àfihàn bí ojú-ọnà rẹ̀ ṣe lọ́ọ̀rìn sí, tí ó sì gbèjà ẹ̀tọ́ rẹ láti kọ orin nípa àwọn kókó ohun tí ó kan àwùjọ.
Orin rẹ̀ tí ó kọ ní 1979 tó mìgboro tìtì “Caribbean Man” (tí a tún mọ̀ sí “Ìṣọ̀kan Caribbean”), dá rúgúdù sílẹ̀ káàkiri ẹkùn, bí ó ṣe ṣe àfihàn ìrò ìsọdọ̀kan Caribbean tó ṣòro. Ilé-iṣẹ́ Ìfi-nnkan-pamọ́-sí Ìjọba Trinidad àti Tobago sọ ọ́ báyìí:
Pàápàá ní òní, orin náà ṣì n fa àríyànjiyàn káàkiri ìsọdọ̀kan Caribbean látàrí àwọn ìdojúkọ ìṣọ̀kan ẹkùn kò jẹ́ tuntun. Wòye pàtàkì àwọn ọ̀rọ̀ orin […]: ‘Wò ó ọkùnrin tí kò mọ ìtàn-an ara rẹ̀/kò le jẹ́ kí ìsọ̀kan wáyé. Báwo ni ọkùnrin kan tí kò mọ orísun rẹ̀/lè gbé èrò tirẹ̀ kalẹ̀?’
Olóògbé akọ̀rọ̀yìn ará Trinidad Terry Joseph ṣe àkọsílẹ̀ ní ọdún 2001 pé Stalin jẹ́ “olórin calypso tí ó yàrà ọ̀tọ̀”, pẹ̀lú àwọn àseyege tí ó sábà máa ń wá “ní ọ̀nà àrà” dípò àwọn ọ̀gá ńlá olórin calypso tí ó jinlẹ̀. Ó kọ́ àpadé-àludé ohun gbogbo láti orí orin ayẹyẹ dé orí orin alálàyé, orin ìfẹ́ dé orí orin òṣèlú:
Stalin fòpin sí wàhálà ṣíṣojú èrò àwọn tí ìnilára ń bá. Àsọyé rẹ lórí àwùjọ àti òṣèlú kò fi ìgbà kan máà kún ojú òṣùwọ̀n, ṣùgbọ́n ó ṣe àfihàn òye bí àtúnṣe ṣe lè wáyé, tàbí kí ó dábàá àwọn ọ̀nà láti kápá ségesège ìdíyelé.
Ẹ̀rín àfanimọ́ra àti ìwà pẹ̀lẹ́ bo àgbọ́nṣáṣáà rẹ̀ mọ́lẹ̀, èyí tí ó ti fìmọ̀ṣọ̀kan pẹ̀lú àkójọpọ̀ ogunlọ́gọ̀ orin mánigbàgbé àti àwọn orin àjọkọpọ̀, láti ràn án lọ́wọ́ láti ní àwọn olólùfẹ́ kárí àgbáyé.
Lóòótó, Stalin rin òkun ó rọ̀sà, ó ń kọrin ní Yúróòpù, Àríwá Amẹ́ríkà àti jákèjádò Caribbean — pẹ̀lú àìdilẹ̀ rẹ̀, ó jẹ́ baálé ilé tí ó ń ṣe ojúṣe rẹ sí aya rẹ Patsy àti àwọn ọmọ wọn mẹ́tẹ̀ẹ̀ta. Nígbà tí wọ́n gbọ́ ìròyìn ikú u rẹ̀, àwọn ará-orí-ẹ̀rọ-ayélujára bẹ̀rẹ̀ sí ní fi ìbánikẹ́dùn wọn hàn lórí àwọn onírúurú gbàgede àwùjọ orí ẹ̀rọ-ayélujára, tí wọ́n ń fi ìdúpẹ́ wọn hàn fún “orin àti àwọn ìrántí.”
Òǹṣàmúlò Facebook àti akọ̀ròyìn nígbà kan rí Neil Giuseppi sọ pé “Àgbà ọ̀jẹ̀ ti fi wá sílẹ̀,” nígbà tí deejay Jus Jase ṣe ìdágbére sí “òòṣà Calypso tòótọ́.”
Akọrin calypso akẹgbẹ́ rẹ̀ Austin Lyons, tí àwọn ènìyàn mọ̀ sí Superblue, ṣe àtẹ̀jádé:
Ọba ni ọkùnrin yìí, ó máa ń kọrin ó máa ń ṣeré, ó sì máa ń fi gbogbo ara ṣe é.
Ọmọ Superblue, ìràwọ̀ olórin soca Fay-Ann Lyons, ṣọ:
Máa rìn nínú ògo. Fò lókè lálá. […] Àgbà ọ̀jẹ̀ mìíràn tún ti fi wá sílẹ̀ pẹ̀lú orin aládùn àti àwọn ìrántí. #BlackStalin
Bákan náà ni ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ọ̀rọ̀ ìjúba lórí Twitter:
“Black Stalin ti kọ orin níwájú àwọn èrò lágbàáyé ó sì yọ ohun tí kò yẹ lọ́kàn ogunlọ́gọ̀ àwọn olùwòran tí ó pé jọ sí ibi orin ìdánilárayá rẹ̀ tó lààmìlaaka .”
Trinbago Unified Calypsonians Organisation lórí ikú àgbà ọ̀jẹ̀ olórin Calypso Black Stalin
— Anselm Gibbs (@AnselmGibbs) December 28 2022
Sùn un re #BlackStalin, Akọrin orílẹ̀-èdè Trinidad Akínkan tó kọ orin aládùn tí àwọn ará West Indians fẹ́rán jú https://t.co/eqfdsVnbIo
— Natasha Lightfoot 🇦🇬 (@njlightfoot) December 28, 2022
Ìràwọ̀ olórin Soca Bunji Garlin náà twíìtì:
Sùn un re àgbà ọ̀jẹ̀ Ògbó Leroy Calliste Black Stalin. Ìbánikẹ́dùn sí àwọn olólùfẹ́ àti ẹ̀bí rẹ̀. Kí iṣẹ́ rẹ máa tẹ̀síwájú fún àwọn ọmọ tí ó ń bọ̀ lẹ́yìn àti fún ìgbéga rẹ. pic.twitter.com/SW8ZJ3M5kd
— Bunji Garlin (@BUNJIGARLIN) December 28, 2022
Orin Stalin jẹ́ aláìlákòókò ó sì ń fa àwọn ọ̀dọ́ mọ́ra, gẹ́gẹ́ bí ó ti rí ní ọjọ́ 21 oṣù kọkànlá tí ó kọjá, nígbà tí orin àgbọ́ṣífìlà rẹ “We Can Make It” di kíkọ nígbà ètò ìṣíde Ìpàdé Ọ̀dọ́ Commonwealth Youth Parliament ìkọkànlá irú ẹ̀ tí ó wáyé ní Red House ní Port ti Spain, ibùjókòó ìgbìmọ̀-ìjọba Trinidad àti Tobago.
Fún àyájọ́ ọjọ́ ìbí 80 òǹkọrin náà ní 2021, Stalin di ẹni tí ó kọ́kọ́ gba àmì ẹ̀yẹ Legacy láti Presentation College tí ó wà ní ihà gúúsù, ọ̀kan lára ilé-ẹ̀kọ́ ìwé mẹ́wàá tí ó níyì ní Trinidad. Ní ibi ayẹyẹ náà, àwọn akọ́ṣẹ́mọṣẹ́ olórin calypso akẹgbẹ́ rẹ̀ sọ̀rọ̀ nípa bí wọ́n ṣe mọ iyì ìtọ́sọ́nà àti ìbánirẹ́pọ̀ rẹ̀, nígbà tí Alákòóso fún ọ̀rọ̀ Àṣà Randall Mitchell mọ rírì ìkópa Stalin nínú ìgbáṣà lárugẹ ní orílẹ̀-èdè náà.
Wọ́n mọ ìwúlò Stalin gan-an fún ènìyàn iyì tí ó jẹ́ àti fún orin náà tí ó kọ, àpapọ̀ tí ó ṣọ̀wọ́n èyí tí ó fi hàn pé lóòótọ́ ni oyè “àgbà ọ̀jẹ̀” tọ́ sí i.