Ìròyìn nípa Ìròyìn ayọ̀
Boji rè é, Ajá tí ó máa ń jayé orí i rẹ̀ kiri ìgboro Istanbul nínú ọkọ̀ èrò
Ẹ pàdé Boji, Ajá kan ni Istanbul tí ó máa ń wọ ọkọ̀ èrò kiri ìgboro lójoojúmọ́.
Sọ̀rọ̀sọ̀rọ̀ ní Nàìjíríà darapọ̀ mọ́ àwọn akẹgbẹ́-ẹ wọn láti sààmì ayẹyẹ Ọjọ́ Ẹ̀rọ-ìgbóhùnsáfẹ́fẹ́ Àgbáyé ọdún-un 2020
Àwọn sọ̀rọ̀sọ̀rọ̀-ọ orílẹ̀-èdèe Nàìjíríà darapọ̀ mọ́ àwọn sọ̀rọ̀sọ̀rọ̀ orí ẹ̀rọ-ìgbóhùnsáfẹ́fẹ́ lágbàáyé láti sààmì Àyájọ́ Ọjọ́ Ẹ̀rọ-ìgbóhùnsáfẹ́fẹ́ Àgbáyé lọ́jọ́ 13 oṣù Èrèlé ọdún-un 2020 àti láti fọn rere iṣẹ́ ìdàgbàsókè àgbà-ńlá ayé tí ẹ̀rọ-ìgbóhùnsáfẹ́fẹ́ ń ṣe.
Ilé ẹjọ́ gíga Tanzania pa á láṣẹ fún ìfòpinsí ìsoyìgì láàárín àgbàlagbà àti ọmọdé láì wo ti ìgbésẹ̀ ìmúpadàa rẹ̀
Nínú oṣù Ọ̀wàrà 2019, Ilé-ẹjọ́ Gíga Tanzania ṣe ìdímú ṣinṣin ìdájọ́ láti fòpin sí ìgbéyàwó ọmọdé. Ìdájọ́ ilé ẹjọ́ náà jẹ́ atọ́ka sí ìfòpinsí àwọn àṣà tí ó ń mú ìpalára bá àwọn ọmọdébìnrin àti onírúurú ẹlẹ́yàmẹyà tòun ìfọwọ́rọ́sẹ́yìn àwọn ọmọdébìnrin.
‘Ohùn-un Jamaica fún Àyípadà Ojú-ọjọ́’ fi orin jíṣẹ́ẹ wọn
Iléeṣẹ́ tí kì í ṣe ti ìjọba ń ṣe ìgbélárugẹ àwọn ọ̀nà tí a lè gba jẹ́ iṣẹ́ yìí nípa lílo iṣẹ́ ọpọlọ orin láti kéde nípa àyípadà ojú-ọjọ́.
Òṣìṣẹ́ inú ọkọ̀ òfuurufú olóbìrin nìkan wọ ìwé ìtàn ní Mozambique
For the first time in the country's civil aviation history, an airplane was operated entirely by women.