Ọjọ́ 7 oṣù Ọ̀pẹ, ọjọ́ àbẹ́là ní Colombia, ti dé. Ó jẹ́ ìsinmi pàtàkì tí ìtan ìmọ́lẹ̀ àbẹ́là yóò gba àwọn ilé àti pópónà kan láti ṣe àjọyọ̀ wúńdíá Màríà náà ṣáájú Kérésìmesì. Gbogbo ìdílé ní ó ń tẹ̀lé ìṣe yìí pẹ̀lú oúnjẹ́ àkànṣe kan, novena, tàbí gbígbàdúrà pẹ̀lú rosary. Wọ́n sọ fún ìyá mi pé à ń tan àwọn àbẹ́là náà láti tan iná sí ipa ọ̀nà Wúńdíá náà. Àwọn iná náà jẹ́ ìdánilójú, ìtọ́ni nínú òkùnkùn. A ti sọ fún ọmọkùnrin mi pé à ń tan àbẹ́là fún ìmoore àti fún ààbò ẹbí.
Mo jẹ́ ìyá tí ó ń tọ́ ọmọ rẹ̀. Kò sí pé ọlẹ̀ sọ nínú mi, ṣùgbọ́n fún èmi, ìyanu ni ó jẹ́ — nítorí ohun kan tí ó ṣe pàtàkì ni láti tọ́ ọmọ kì í ṣe kí á kàn pèsè ìwọ̀n àtọ̀.
Ní ọjọ́ 8 oṣù Ọ̀pẹ, mà á la iṣẹ́ abẹ kọjá, inú mi sì dùn púpọ̀ nípa èyí nítorí iṣẹ́ abẹ yìí yóò dín ìrora tí ó ti ara àwo ọ̀pá ẹ̀yìn mi kan tí ó yọ kù. Mo gbé ní Bogotá pẹ̀lú ìyá mi. Àti òhun àti èmi ni ó ní ìpèníjà ẹ̀yà ara gbígbé. A sọ̀rọ̀ bí ó ti ń ṣe àwọn àtùpà fún ọjọ́ àbẹ́là pàtàkì yẹn, tí à ń dúró kí àwọn olùtọ́jú aláìsàn wá sí ilé láti fún wọn ní òògùn kan. Bákan náà, mò ń rán àwọn ọmọ pẹ́pẹ́yẹ tí a kó òwú bọ̀ nínú, ọ̀kan fún ọmọkùnrin mi àti ọ̀kan fún mi.
Kódà láìsí àbẹ̀wò láti ọ̀dọ̀ ẹbí, à ń ní ìbàlẹ̀ ọkàn. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé, mo ní ìbàjẹ́ ọkàn nígbà tí ẹni tí ó yẹ kí ó tẹ̀lé mi lọ ní ọjọ́ kejì fagilé ètò ní ìdákúrékú. Mo ní ìbàjẹ́-ọkàn láti ní àwọn mọ̀lẹ́bí tí mi ò lè pè láti darapọ̀ mọ́ mi, yálà nítorí pé wọn yóò bú mi ni o tàbí nítorí pé wọn ò kàn ní yọjú nítorí ìṣòwò tiwọn.
Ìyáàfin wa dá wà. Báwo ni yóò ṣe gbèrò àti jẹ́ ìyá láìsí ọkùnrin lẹ́gbẹ̀ẹ́ rẹ̀? Báwo ni yóò ti gbèrò ohun tí kò leè jẹ́? Kódà kí ó ní Ọmọ Ọlọ́run nínú ilé-ọmọ rẹ̀, kò leè jẹ́ ìyá.
Mo di ẹni àpatì. Báwo ni ó ṣe ṣẹlẹ̀ sí mi láti jẹ́ obìnrin? Àti pé bí mo bá jẹ́ obìnrin, báwo ni mo ṣe lè fi tọ́ ọmọ mi láìsí bàbá? Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé obìnrin ni mí mo sì ní ọmọ tèmi, mi ò jẹ́ nǹkankan.
Sí ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn, mi ò le jẹ́ obìnrin n ò sì lè jẹ́ ìyá. Ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọdún sẹ́yìn, mo kí gbogbo àgbáyé, mo ṣàfihàn ara mi mo sì sọ wí pé, “Ẹ ǹlẹ́ ó, èmi ni Lucia.” Àwọn ìbátan àti àwọn ọ̀rẹ́ tí o lè fọkàn tán dẹ́kun láti má a bá mi sọ̀rọ̀. Mi ò gbàdúrà, ṣùgbọ́n inú bí mi púpọ̀; mo sọ ọkàn mi nípa sísọ ìyẹn jáde. Nígbà tí mo ṣì lè gbé ara mi dáadáa, mà á tẹ̀lé ẹnikẹ́ni tí ó bá béèrè lọ́wọ́ mi láti ṣe bẹ́ẹ̀. Ó nira fún mi láti rò ó pé mo ti fìgbà kan jẹ́ olùtọ́jú ìyá mi; ní báyìí mo nílò ìtọ́jú, bákan náà. Wáyìí o, n ò le gbọ́kànlé àwọn ẹbí mi tí ẹ̀jẹ̀ so wá pọ̀ láti bá mi lọ.
Wẹ́rẹ́ wẹ́rẹ́, mò ń gba ara mi sílẹ̀ lọ́wọ́ àwọn ìmọ̀lára wọ̀nyí, kí n lè gbájú mọ́ ohun tí ó ṣe pàtàkì: láti lè lọ fún iṣẹ́ abẹ tí mo ti ń dúró láti ṣe fún oṣù mẹ́rin ó lé.
Ìṣẹ̀lẹ̀ náà ò bá burú jáì, gẹ́gẹ́ bí ó ti ṣe burú fún àwọn ọmọ ìyá mi obìnrin. Wọn kò ní àǹfààní sí ètò ìlera tàbí ètò ẹ̀kọ́, èyí tí ó mú ayé wọn túnbọ̀ kún fún ewu. Láì ní ẹ̀tọ́ sí àwọn ibi àwùjọ ní gbangba. Ó kéré tán 56 àwọn tí ìdánimọ̀ wọ́n jẹ́ ọkùnrin tàbí obìnrin ni wọ́n di pípa ní ọdún nìí ní Colombia, ní ojú pópó, pẹ̀lú ìwà ìkà, tí ẹnikẹ́ni kò sì bìkítà. Ní ìdàkejì, ètò eré ìdárayá àgbáyé kan wáyé ní orílẹ̀-èdè tí ó gbajúmọ̀ fún ìwà jàgídíjàgan sí àwọn ènìyàn tí ìdánimọ̀ wọn kò ṣe déédé pẹ̀lú àkọsílẹ̀ ti ìbí wọn.
Ìṣòrò mi kò le tó bẹ́ẹ̀, mo sì gbà pẹ̀lú ìyá mi láti kàn sí olùtọ́jú tí ó mọ̀. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé kò leè wà níbẹ̀ nígbà tí mo wọlé fún iṣẹ́-abẹ, yóò lè gbé mi nígbà tí mo bá ṣe tán. Àwọn òṣìṣẹ́ ètò ìlera ti wá fún-un ní òògùn, ṣùgbọ́n wọ́n gún ọwọ́ rẹ̀ lábẹ́rẹ́ wọn kò sì rí iṣan kan. A kò sùn, a sì wa lójúran títí di ọjọ́ kejì.
Aago lu 4 àárọ̀ mo sì nílò láti gba ilé ìwòsàn lọ. Mo jáde láti lọ wọ ọkọ̀ akérò. Mi ò ní láti bẹ̀bẹ̀ fún ìjókòó, nítorí èrò péréte ni ó ń rìnrìn-àjò ní àkókò náà, ní ọjọ́ 8 oṣù Kejìlá, ọjọ́ ìsinmi lẹ́nu iṣẹ́. Mo gbìyànjú láti yẹra fún ìbẹ̀rù ìfojúọkùnrinwoni ní ilé ìwòsàn, bákan náà, ti ìwà àìbìkítà àti ìkanra. Kò wọ́pọ̀ mọ́; ní ìgbà mìíràn ó má a ń ṣẹlẹ̀, ní ìgbà mìíràn kì í ṣẹlẹ̀. Rárá, ní àkókò yìí kò ṣẹlẹ̀.
Báwo ni ó ṣe dára tó kí a rí mi gẹ́gẹ́ bí ẹni tí mo jẹ́, kì í ṣe bí mo ti ṣe ṣe ìdámọ̀ ara mi nìkan, àmọ́ gẹ́gẹ́ bí mo ti jẹ́, obìnrin ní tòótọ́, ní ti àbùdá ìbí bí Sanín, gẹ́gẹ́ bíi Rowling, tàbí ti obìnrin kóbìnrin mìíràn tí ìdánimọ̀ pé wón jẹ́ obìnrin kò ṣe déédé pẹ̀lú àkọsílẹ̀ ti ìbí wọn. Gẹ́gẹ́ bí obìnrin tí ó pé bí i ti wúńdíá aláìlábàwọ́n. Kò sí ohunkóhun láti pamọ́ nínú ara mi. Bí ó tilè jẹ mọ́ àbùdá ìbí, bákan náà ni ó rí fún oníṣègùn egungun tí yóò siṣẹ́ abẹ lára mi, tí ó sì tún ti jẹ́ onígbọ̀nwọ́ ńlá láti ṣe ìdámọ̀ pé ìṣe ipá tí ó jẹ mọ́ àbùdá ìbí níbi iṣẹ́ mi fi àwọn àtúbọ̀tán sílẹ̀ nínú ìlera mi.
Wọ́n jí mi láti ojú oorun tí òògùn kùn mí. Olùtọ́jú kan wí pé “mo fẹ́ kí o wọ aṣọ”; mo fèsì, “Wọṣọ.” Ó fèsì, “mo fẹ́ kí o wọ aṣọ rẹ.” Mi ò wo ojú rẹ̀ tí kò fanimọ́ra, mo ní ìgbénúwòye pé nítorí pé ó ń siṣẹ́ ní ọjọ́ ìsinmi lẹ́nu iṣẹ́ ni. Kò kàn mí mo sì yàn láti pa ìrántí ìtọ́jú tí ó dára tí mo rí gbà lọ́wọ́ àwọn dókítà àti àwọn nọ́ọ́sì yòókù mọ́, àwọn tí mo dúpẹ́ púpọ̀ lọ́wọ́ wọn. Àwọn nǹkan kọ̀ọ̀kan ti yí padà láti ọdún tí ó kọjá.
A fi ibẹ̀ sílẹ̀ pẹ̀lú nọ́ọ́sì náà a kò sì pẹ́ délé. Mo ṣàkíyèsí wí pé fọ́nrán tí ó wà ní ọrùn ọwọ́ mi fihàn pé ọjọ́ 7, oṣù Kejìlá ni a gbà mí wọ ilé ìwòsàn, dípò ọjọ́ 8 oṣù Kejìlá, tí mo la iṣẹ́-abẹ kọjá. Mà á fi pamọ́ fún ìtàn, ṣùgbọ́n ju gbogbo rẹ̀ lọ, fún ìrántí wí pé a fi tọ̀wọ̀ tọ̀wọ̀ fún mi ní ìtọ́jú, àti pé ìrora tí mò ń ní ń dín kù.
Obìnrin ni wúńdíá náà jẹ́. Ó gòkè re ọ̀run níbi tí a ti ṣe ìdámọ̀ rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí i obìnrin àti ìyá. Èmi náà jẹ́ obìnrin gẹ́gẹ́ bíi Màríà wúńdíá náà.
Lórí tábìlì, ni àwọn àtùpà ìyá mi ti kò lò wà. Ní ọjọ́ 24 tàbí 31 oṣù Ọ̀pẹ, ó dájú pé a ó fi wọ́n fún àwọn tí ó bá wá bẹ̀ wá wò. Mà á tan àbẹ́là kan fún ìmoore ẹ̀mí àti fún ìtura àìlera mi àti ti ìyá mi.
Òmíràn, fún ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn ọmọbìnrin tí ìdánimọ̀ pé wọ́n jẹ́ obìnrin kò ṣe déédé pẹ̀lú àkọsílẹ̀ ti ìbí wọn tí ó ti pòórá ní ọdún nìí kí ayé nínú ìlú yìí àti orílẹ̀-èdè yìí o má ba à kún fún ìwà ipá sí wa.
Eyí tí ó kẹ́yìn, kí àwọn àbẹ́là wọ̀nyí ó ba tan ìmọ́lẹ̀ sí ipa ọ̀nà ọkàn àwọn tí ó kórira ìwàláàyè àwọn ọmọbìnrin tí ó ní ìrírí ìgbé-ayé tí ìdánimọ̀ pé wón jẹ́ obìnrin kò ṣe déédé pẹ̀lú àkọsílẹ̀ ti ìbí wọn, kì í ṣe ní ọjọ́ 7 oṣù Ọ̀pẹ nìkan o ṣùgbọ́n ní gbogbo ọjọ́ ìwàláàyè wa, nínú ètò ìlera àti níbi gbogbo.
Fún ọjọ́ tí, wúńdíá obìnrin tí ìdánimọ̀ pé ó jẹ́ obìnrin kò ṣe déédé pẹ̀lú àkọsílẹ̀ ti ìbí rẹ̀ àti ọmọkùnrin rẹ̀ yóò rìn láàárín àwọn àbẹ́là, láìsí ìbẹ̀rù ìkàn mọ́ àgbélébùú.