Láti ọwọ́ Vaneisa Baksh
Orí Wired868 ni wọ́n ti kọ́kọ́ ṣe àtẹ̀jáde ìròyìn yìí, tí a sì ṣe àtúntẹ̀jáde rẹ̀ lórí Global Voices pẹ̀lú àṣẹ ìyọ̀ǹda láti ọwọ́ òǹkọ̀wé náà.
Nínú gbogbo àwọn àjọ̀dún inú ọdún wa— a sì ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ — ọ̀kan ṣoṣo tí ó ní àmì jùlọ fún mi ni Ọjọ́ Àìsùn Ọdún Tuntun.
Kò ní ohun kan ṣe ju ìfojúsọ́nà àti ìrètí tí ó máa ń dé pẹ̀lú ìkéde ọdún tuntun lọ. Ìgbàgbọ́ tèmi ni pé wákàtí mẹ́rìnlélógún (24) ló wà láàárín àwọn ọjọ́ kọ̀ọ̀kan, bí a bá ṣe lò ó kù sí wa lọ́wọ́: bóyá kí a mú u bárajọ àti bu ẹwà kún un tàbí kí a fi àìdunnú ṣe ọdún náà.
Ilé-ayé ní ọ̀nà kan tí ó máa ń fi mú ìdàrúdàpọ̀ wá àti ohun àìròtẹ́lẹ̀, bí ojúmọ́ ti ń mọ́, tí alẹ́ sì ń lẹ́. Mo máa ń ní láti kó ara mi ní ìjánu níbi kí n máa ki àwọn màjèsí nílọ̀ pé ìsàmì àwọn àyájọ́ ọjọ́ ìbí tí ó jẹ́ ìṣẹ̀lẹ̀ pàtàkì — ọjọ́ orí ìbẹ̀rẹ̀ ọ̀gọ̀ṣọ́ 16, ọjọ́ ori ìbẹ̀rẹ̀ géndé 18, ọjọ́ orí ìnígboyà 21 — ò ní mú ìyípadà àràmàǹdà tí a ti ń rètí ti wà. Yóò kàn jẹ́ ohun ìbànújẹ́ ni.
Rárá, ohun tí mo ní pẹ̀lú Ọjọ́ Àìsùn Ọdún Tuntun wá láti ara ohun tí ọkàn mi máa ń fà sí ní ìgbà èwe mi, ìhùwà kan tí ó rọrùn tí ó fi yé mi pé àwọn idán àràmàndà lè ṣẹlẹ̀. Pẹ̀lú irú ẹ̀dá tí mo jẹ́, èrò méjì ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ tí ó tako ara wọn ni, ṣùgbọ́n ó wà bẹ́ẹ̀.
Nígbà tí a wà ní èwe — pẹ̀lú àwọn ọmọ ìbátan mi a jẹ́ ìdílé ńlá kan — tí à ń gbé ní ojú pópónà tí mo ṣì ń pè ní ilé, ó jẹ́ àṣà láti kí ọ̀gànjọ́ òru ní ìkóríta kan. Mi o tilẹ̀ rántí ohun tí a máa ń ṣe ṣáájú, ṣùgbọ́n mo ṣì ń ní ìmọ̀lára ìdùnnú náà káàkiri bí àkókò náà ṣe ń súnmọ́.
Ní bí ìṣẹ́jú mẹ́wàá (10) sí mẹ́ẹ̀ẹ́dógún (15) bíi nnkan sí àkókò náà, ìrúsókè ariwo yóò ti máa bẹ̀rẹ̀ ní gbogbo àyíká. Àwọn ẹbí bàbá mi lóbìnrin àti àwọn ọmọ wọn yóò kọjá (n ò rántí bóyá àwọn ẹbí bàbá mi lọ́kùnrin gẹ́gẹ́ bí akópa) tí gbogbo wa yóò sì jọ kọ́wọ̀ọ́ rìn lọ sí ìkangun òpópónà náà.
Ní òdodo, ó lè máà jẹ́ ìkóríta, torí pé ilé-iṣẹ́ bisikí Bermudez ló la òpópónà Hollis, tí ilé-iṣẹ́ rẹ̀ wà ní ìtòsí òpin òpópónà náà, tí ó já papọ̀ sí i — tí ó mú u di oríta mẹ́ta ju ti ọ̀nà tí ó pàdé lọ.
Ó wúlò fún wa lóòótọ́, fún gbogbo ènìyàn àdúgbò wa. Ní èyí tí ó fojú hàn gedegbe, dídúró sí irúfẹ́ ibi olóore bẹ́ẹ̀ ní ọjọ́ tó kẹ́yìn ọdún ní ọ̀gànjọ́, túmọ̀ sí wí pé àwọn ìfẹ́ ọ̀kan yóò wá sí ìmúṣẹ. Ni a bá rìn gba àyíká Bermudez lọ, a sì darapọ̀ mọ́ àwọn aládùúgbò wa tayọ̀tayọ̀ bí ìgbà tí onitẹ́tẹ́ bá rí tẹ́tẹ́ jẹ. A óò sì dúró síbẹ̀, pẹ̀lú inú dídùn àti ìtàkùrọ̀sọ dídùn, tí a sì ń retí kí ago méjìlá òru ó lù.
Ẹnìkan yóò bẹ̀rẹ̀ kíkà-sẹ́yìn ọwọ́ ago, àwa yòókù á sì parapọ̀. Kò sí orin, kò sí iná ajóbùlàbùlà ìsààmì ayẹyẹ, kò sí nǹkankan bí kò ṣe àwọn ènìyàn àdúgbò tí ó kórajọ pẹ̀lú inú kan.
Ní àkókò náà, mà á di ojú mi pa tí n ó sì tọrọ àwọn ohun tí mo bá fẹ́, lẹ́yìn náà, ìṣẹ́jú bíi mẹ́wàá (10) yóò wà fún ìtàkùrọ̀sọ, títí di ìgbà tí ọ̀rọ̀ lórí afẹ́fẹ́ tútù Kérésìmesì yóò fi bẹ̀rẹ̀— òtútù rẹ̀ — ni yóò rán àwọn òbí létí wí pé àwọn ọmọdé níl áti kúrò nínú ìrì náà.
Ní a óò bá kọrí sílé, ìrìn inú dídùn yóò wá di ìrìn-in fífà-kùnnù. Ìrìn kan náà tí ó máa ń gúnni tí ó sì máa ń jó wa ní àtẹ́lẹ́ ẹsẹ̀ ní àwọn ìgbà iṣẹ́ jíjẹ́ àti àwọn ìgbà eré, ni ó wá di ohun tí ń gbé díẹ̀díẹ̀ lábẹ́ ìmọ́lẹ̀ òṣùpá àti àwọn ìràwọ̀ tí ó ń kọ mọ̀nàmọ̀nà tí ó ń mú òjìji ọlọ́lá hàn.
Ǹjẹ́ ẹsẹ̀ lásán láì wọ bàtà ni a máa ń wà ní àkókò yìí? N kò lè rántí. Ìrántí mi ò kọjá èrò wíwà ohun ìyanu kan láàárín àbọ̀ wákàtí kan yẹn: Ọgbọ́n (30) ìṣẹ́jú idán gbankọgbì.
A lè jẹun, a sì lè máà jẹun ní irú àkókò náà, ṣùgbọ́n mo kíyèsí pé ní ohun tí kò mọ́ni lára bíi àìwò títí di òru, a ò bá ti lọ sùn. Bí ti tèmi, oúnjẹ náà tilẹ̀ lè jẹ́ ẹ̀wà funfun àti irẹsì, kò sí lára àwọn oúnjẹ ààyò mi, oúnjẹ alẹ́ àtètèjẹ ò bá jẹ́ adìẹ yíyan tí a kó àwọn oríṣiríṣi nǹkan sínú rẹ̀ àti búrẹ́dì tí mo fẹ́ràn jù.
Gbogbo rẹ̀ pin bí a tí a kó kúrò nígbà tí mo ṣì wà ní ọmọdé, ṣùgbọ́n ìrántí àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ náà ò fi ìgbà kan kúrò.
Títí di ìsinsìyí, N kò tíì ṣe wádìí ìjìnlẹ̀ nípa ìdí tí mo fi fẹ́ràn alẹ́ Ọjọ́ Àìsùn Ọdún Tuntun, bí mo bá tún wò ó, mo lérò wí pé èyí ni ó ba gbogbo ìrírí àgbà mi nípa àjọyọ̀ náà jẹ́. Èrò aṣiwèrè ni láti gbé òṣùwọ̀n pàtàkì lórí àsìkò kan. Kì í ṣe ohun tí ó ṣe é gbéró.
Kì í ṣe pé gbogbo àwọn àjọyọ̀ yòókù náà ò ní àmì, ọ̀kan àbí méjì nínú wọn ti jẹ́ mánigbàgbé, ṣùgbọ́n kì í ṣe nítorí àjọyọ̀ náà. Bákan náà ni wọn yóò ṣe rí bí ó bá jẹ́ alẹ́ ọjọ́ mìíràn. Síbẹ̀, kò sí ohun tí ó ṣe é fi wé ìdùnnú àìmọ̀kan ìgbà èwe àti òmìnira ojú inú.
Àti wí pé kí ni pàtàkì rẹ̀? Àwọn ará àdúgbò ni wọ́n parapọ̀ nínú ìfẹ́ àti ìrẹ́pọ̀. Ní irú agbègbè oníṣẹ́ bí-o-jí-o-jí-mi bẹ́ẹ̀, kò sí àpéjọ ní ilé ẹnìkankan. A ò wọ àwọn ilé. Wọn á rán mi láti lọ pín erè-oko láti inú ọgbà bàbá baba mi, n ó dúró ní ẹnu ọ̀nà ìta pẹ̀lú àwo tó kún fún èyíkéyìí ohun ọ̀gbìn tí ó bá wà níta lásìkò náà, tí n ó sì máa dúró kí wọ́n wá kó gbogbo tí ń bẹ nínú rẹ̀ tán, tí n ó sì dá agbada padà.
Èrò nípa ọtí líle funfun dídan (ṣànpéénì), iná iná ajóbùlàbùlà ìsààmì ayẹyẹ Kérésì, fìlà ayẹyẹ àti àwọn aṣọ títàn winiwini ò sí ní àdúgbò wa rí.
Ṣùgbọ́n fún èmi, ó dúró fún àkókò kan tí ó jẹ́ ìgbà, ojúlówó, tí ó rọrùn, Mo lérò pé kò rí bákan náà fún ọ̀pọ̀. Mi ò mọ̀ pé tálákà ni wá — kódà di àsìkò yìí, mi ò rí i bí àsìkò ìdènà-ohun. Gbogbo wa wọ ṣòkòtò kakí kan náà. Ṣùgbọ́n mo ti gbọ́ tí àwọn ènìyàn ti sọ rí wí pé bí àwọn ti ń dàgbà àwọn fẹ́ gbé àwọn ìrántí wọ̀nyẹn tì, kí àwọn fi gbogbo ìlekoko tí àwọn kojú sí oko-ìgbàgbé.
Bóyá ìyẹn ló bí àwọn ayẹyẹ afẹfẹyẹ̀yẹ̀ àti ariwo láti ri ìdákẹ́jẹ́jẹ́ àwọn alẹ́ tálákà bomi, tí àìdára sì kọjá ojú mi tí mo là kalẹ̀.
A kú ọdún tuntun!