
Àwòrán-ojú-ìwò-ẹ̀rọ ti Ìkòròdú bois láti CNN spotlight.
Àwọn “Ìkòròdú bois” bẹ̀rẹ̀ ìrìnàjò ìyàwòráneré ìtàgé nígbà tí wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í pín àwòrán-olóhùn sí YouTube. Wọ́n di olókìkí fún ìsínjẹ àwọn eré bíi “Money Heist”, “Squid Game “ àti àwọn mìíràn.
Nínú oṣù kẹ́rin, Tyler Perry ti Hollywood dá wọn mọ̀, ó sì yìn wọ́n fún àtúndá àwọn erée rẹ̀ kan.
Yàtọ̀ sí fífi èdìdì ìrànwọ́ kan tí ó ní àwọn irinṣẹ́ ìyàwòráneré tí ó dọ́ṣọ̀ nínú ránṣẹ́ sí àwọn Ìkòròdú bois ní oṣù Ògún tó kọjá, Netflix fi iṣẹ́ ọpọlọ wọn hàn ní ìgbà ayẹyẹ Oscar oṣù kẹ́rin ọdún 2021, tí ó jẹ́ ètò ìfi-àmì-ẹ̀yẹ-dáni-lọ́lá ọlọ́dọọdún ti ẹ̀ka eré-àgbéléwò orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà.
Àṣeyọrí Ìkòròdú bois ti fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn tí ó ṣẹ̀ṣẹ̀ ń dìde àti àwọn ayàwòrán eré-ìtàgé tí ó ń tiraka ní orílẹ̀-èdè Nàìjíríà ní ìrètí. Lẹ́yìn náà, bí àwọn ọmọdé wọ̀nyí bá lè ya eré-àgbéléwò tí gbogbo ayé sì mọ̀ wọ́n pẹ̀lú irinṣẹ́ olówó pọ́ọ́kú tí wọ́n lò àti ìmọ̀ọ́ ṣe ìbẹ̀rẹ̀ síso-àwòrán-àti-ohùn-papọ̀, a jẹ́ wí pé dájúdájú àwọn ayàwòrán eré-ìtàgé yòókù náà ní àǹfààní bákan náà.
Nollywood tuntun àti àwọn gbàgede orí ẹ̀rọ-ayélujára ìgbàlódé
Nollywood ayé àtijọ́ tí a tún mọ̀ sí Asaba movies (èdè-ìperí Asaba jẹ yọ láti ara ìlú kan ní orílẹ̀-èdè Nàìjíríà) jẹ́ àwọn eré-àgbéléwò tí ó wà ní ìgbẹ̀yìn àwọn ọdún 1990. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn fíìmù Nollywood náà jẹ́ àgbéléwò, gẹ́gẹ́ bíi Living in Bondage láti ọwọ́ Chris Obi Rapu tí ó gbajúmọ̀ bí ìṣáná ẹlẹ́ta.
Ní 2020, Netflix ṣe ìfilọ́lẹ̀ ní orílẹ̀-èdè Nàìjíríà tí ó sì ṣe ìgbélárugẹ ogunlọ́gọ̀ iṣẹ́ àwọn èèyàn ilẹ̀ Áfíríkà. Láti ìgbà náà, ó ti fi àṣẹ fún onírurú ojúlówó àwọn ètò orí amóhùnmáwòrán àti fíìmù, ti lọ́wọ́lọ́wọ́ ni èyí tí ó jẹ́ eré oníṣísẹ̀ntẹ̀lé abala méje ti Kẹ́mi Adétiba “King of Boys”: The Return of the King”. Síwájú ìfilọ́lẹ̀ rẹ̀, gbàgede ìwòran orí ẹ̀rọ-ayélujára ẹ̀rìmọ̀ náà sanwó kí àwọn eré ilẹ̀ Áfíríkà ó ba di wíwò lórí ìkànnì rẹ̀.
Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ẹ̀ka fíìmù Nàìjíríà ti gòkè àgbà, àwọn abala kan ṣì wà bákan náà. Fún àpẹẹrẹ, ọjọ́ ti pẹ́ tí àwọn eléré ìtàgé orílẹ̀-èdè Nàìjíríà ti n tiraka láti já gbangba di ẹni àgbénáwò lágbàáyé látàrí àtúnntúnsọ àwọn ìtàn . Àwọn fíìmù méjì wọ̀nyí “Osuofia in London”(láti ọwọ́ Nollywood àtijọ́) àti “10 days in Sun City”(láti ọwọ́ Nollywood tuntun) ní ìlànà ìsọ̀tàn tí ó jọra wọn. Nínú àwọn eré méjèèjì, àwọn ẹ̀dá-ìtàn tí eré náà dá lórí wọn jẹ́ bóyá àwọn ará ìgbèríko tàbí òṣìṣẹ́ tí kò kàwé tí ó ti fi gbogbo ọjọ́ ayé wọn fi orílẹ̀-èdè Nàìjíríà ṣe ibùgbé tí wọ́n rí àǹfààní lójijì láti lọ sí òkè òkun. Síbẹ̀, tí wọ́n bá ti ṣe ìrìn-àjò, yóò di aáyan fún wọn láti gbé ayé mìíràn tí ó yàtọ̀ sí ìlú tí wọ́n ti wá. Pàtàkì, àwọn eré méjèèjì ń sọ ìkọlù ajẹmáṣà tí ó n wáyé látàrí ìbáṣepọ̀ àgbáyé àti ìṣínípò láti ìlú kan sí òmíràn.
Ohun kan tí ó yàtọ̀ gedegbe nígbà tí a bá ń ṣe àfiwé Nollywood tuntun àti ti àtijọ́ ni ti lílọsíwájú àgbéjáde tí ó dọ́ṣọ̀ àti iye àwọn fíìmù tí a ṣe ní orílẹ̀-èdè Nàìjíríà lásìkò yìí. Àwọn Ìlànà ìsọtàn àwọn fíìmù orílẹ̀-èdè Nàìjíríà ti ń ṣe bẹ́ẹ̀ yí padà. Àwọn eré Nollywood òde-òní bíi “Omo Ghetto”, “King Of Boys”, “Wedding Party”, “Oloture”, “October 1st” tí àwọn igi nla bíi Fúnkẹ́ Akíndélé àti Kúnlé Afọláyan ṣe ti di ìtẹ́wọ́gbà kárí àgbáyé. Ìwé ìròyìn The Premium Times, tó jẹ́ ìwé ìròyìn ojoojúmọ́ orí ẹ̀rọ-ayélujára orílẹ̀-èdè Nàìjíríà, sọ wí pé “Omọ Ghetto” pa owó tí ó tó mílíọ̀nù 468 owó náírà ìyẹn bílíọ̀nù kan lé díẹ̀ owó dọ́là (USD 1.1 million) owó tí ó wọlé láti àwọn sinimá àti mílíọ̀nù 636 owó náírà; ìyẹn mílíọ̀nù kan àti àbọ̀ owó dọ́là (USD 1.5 million) ní ibi tí wọ́n ti n ta tíkẹ́ẹ̀tì. Film One, ọ̀kan lára iléeṣẹ́ apín-eré ká, sọ wí pé “Wedding Party” pa mílíọ̀nù 452 owó náírà tí ó tó bílíọ̀nù kan ó lé díẹ̀ owó dọ́là (USD 1.1 million) ní àwọn sinimá Nàìjíríà. Láì sí àníàní, ìbáṣepọ̀ àgbáyé àti ìdìde gbàgede ìwòran orí ẹ̀rọ-ayélujára yóò tẹ̀síwájú láti lapa lára ẹ̀ka eré-ìtàgé, kò sì yọ Nollywood sílẹ̀.
Bí a ṣe ń lo àwọn eré Nollywood

Àwọn àwo eré Nollywood lórí àtẹ ní ìsọ̀ kan ní Kwakoe Festival ní Amsterdam Bijlmer. Àwòrán láti ọwọ́ Paul Keller, ọjọ́ 9, oṣù Keje 2006 (CC BY 2.0)
Àṣeyọrí Nollywood ti mú kí ìbárà àwọn ọjà ajẹmáṣà orílẹ̀-èdè Nàìjíríà ó lékan sí i, papàá jù lọ bí àwọn ibùdó-ìtakùn àgbáyé ìwòrán ṣe ń mú àwọn iṣẹ́ àtijọ́ padà wá sójú ìran. Ọpẹ́ lọ́wọ́ ẹ̀rọ ìbánidọ́rẹ̀ẹ́ àwùjọ, àwọn àfàyọ láti ara eré bíi àwàdà Tchidi Chikere ọdún 2014, “Pretty Liars,” ti rá pálá wọ inú àṣà òde òní. Láì sọ ti àwọn ọ̀kẹ́ àìmọye àwòrán-olóhùn àti àwòrán àwọn ẹ̀dá ìtàn eré ọlọ́jọ́ pípẹ́ bíi Aki (tí àbísọ rẹ̀ jẹ́ Chinedu Ikezie) àti Pawpaw (tí àbísọ rẹ̀ jẹ́ Osita Iheme) tí ó gba gbogbo orí ayélujára kan, tí àwọn ará òkè òkun ti jẹ dòdò wọn.
@mroyiborebel Ọ̀nà Ọjà Alábà ♬ orin àtilẹ̀bá – OYIBO REBEL
Bákan náà ni Nollywood ti tẹsẹ̀ bọnú ọjà àgbáyé nípasẹ̀ fífi àwọn òǹṣèré òkè òkun sí iṣẹ́ rẹ̀ láti rìn jìnà dáadáa. “Half of a Yellow Sun,” tí Bíyìí Bándélé darí, ní Thandie Newton, Anika Noni Rose, Chiwetel Ejiofor, àti Ini Dima Okojie, àti àwọn òṣeré ilẹ̀ òkèèrè gẹ́gẹ́ bíi Eric Anderson, Paul Hampshir, àti Roberto Davide nínú. Namaste Wahala ti Ruslaan Mumtaz èyí tí lààmìlaaka òǹṣèré Bollywood Ruslaan Mumtaz kópa nínú rẹ̀ jẹ́ àpẹẹrẹ mìíràn tí ó gbajúmọ̀.
Àwọn àjọ̀dún eré ìtàgé náà tún ti kópa tí ó pọ̀ láti mú Nollywood wá sí ojú ìwòran àwọn olùwòran tuntun. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ eré ni ó wọ́n ti ṣe àfihàn wọn ní onírúurú àjọ̀dún káàkiri àgbáyé, tí wọ́n sì ṣe bẹ́ẹ̀ gba àwọn àmì ẹ̀yẹ. Ní oṣù kẹsàn-án ọdún 2019, eré Joel Kachi Benson “Daughters of Chibok” gba ìtàn tí ó dára jù lọ Best Virtual Reality Story ní àjọ̀dún oníyì nì Venice International Film Festival. Bákan náà, ní Locarno Film Festival, “Juju Stories” ti Surreal16 Collective gba àmì ẹyẹ eré tí ó dára jù lọ Boccalino d’Oro Award for Best Film. Láti ìgbà tí ó kọ́kọ́ jáde, eré “Eyimofe,” láti ọwọ́ Guardian Digital Studios (GDN), ti gba onírúurú àmì ẹ̀yẹ, àti àmì the Achille Valdata Award ní Torino International Film Festival ọdún 2020. Àwọn àjọ̀dún kan ti fi àwọn abala kan fún àwọn eré Nàìjíríà, tí ó ń ṣe àfihàn àwọn ètò, àwọn èròjà, àti àwọn ènìyàn tí ó ṣe kókó tó wà lẹ́yìn orò tórò fi ń ké ní orílẹ̀-èdè náà
Iṣẹ́ eré-ìtàgé ṣíṣe Nàìjíríà ti gòkè àgbà ó sì ti di igi àràbà tí ìji rẹ̀ ti kọjá orílẹ̀-èdè náà, ó sì ti ń ṣe bẹbẹ lórí bẹbẹ lágbàáyé. Ìkòròdù Bois àti àwọn ayàwòrán eré ìran tuntun ti mú kí àlàfo tí ó wà láàárín Nollywood, gbàgede ìbánidọ́rẹ̀ẹ́, àti àwọn ẹ̀ka eré ìtàgé kárí ayé ó rí tóóró.