A lé òǹṣàmúlò TikTok Nekoglai láti Moscow padà sí Moldova pẹ̀lú àmì lúlù

Nekoglai, kí ó tó di wí pé wọ́n rán an lọ sí ibi ìdánipadàsílùúẹni ní Moscow àti lẹ́yìn ìgbà tí ó dé. Èyí ni àpapọ̀ awòrán láti ọwọ́ Daria Dergacheva láti ara àwọn àwòrán tí a yọ láti àwọn àwòránolóhùn Nekoglai, àti àtẹ̀jáde ti RIA Novosti lórí Telegram.

Gbajúgbajà òǹṣàmúlò TikTok Nekoglai ní àwọn olólùfẹ́ tí ó lé ní mílíọ̀nù 9.6 àti pé ó jẹ́ àwòkóṣe láàárín àwọn ọ̀jẹ̀-wẹ́wẹ́. Ó ń gbé ní ìlú Moscow, àwọn àwòránolóhùn rẹ̀ sábà máa ń jẹnu wúyẹ́ láti bá orin tí ó ń lọ lábẹ́lẹ̀ dọ́gba. Èdè Russia ni ó máa fi ń ṣàgbéjáde TikTok rẹ̀. Ní ọjọ́ 8 oṣù kọkànlá, ọdún 2022, Nekoglai ṣe àká-ṣílè àwòránhùn ẹ̀fẹ̀ ti ọmọ ogun Russia kan. Àwòrán-olóhùn náà tí ó jẹ́ àtilẹ̀bá gangan ni ẹnìkan tí ń ṣe alátìlẹ́yìn fún ogun gbé jáde lórí ìkànnì Telegram tí ó sì ṣàfihàn ọmọ-ogun kan tí ó ba mọ́lẹ̀ lóun nìkan nínú kòtò kan, kí wọn ó tó rọ́ àdó olóró alákàrà méjì (tí a gbọ́ wí pé ó jábọ́) láti ara ẹ̀rọ òfuurufú aládàáṣiṣẹ́ ọmọ-ogun Ukraine bò ó, tí ó sì fi ọwọ́ jù wọ́n nù.  Nínú àwòránhùn àgbélẹ̀rọ ẹlẹ́fẹ̀ẹ rẹ̀, akọbúlọ́ọ̀gù àwọn ọ̀gọ̀ṣọ́ náà nì Nekoglai dùbúlẹ̀ sórí kápẹ́ẹ́tì ó sì sọ “àdó olóró alákàrà náà” nù.

Ekaterina Mizulina, olórí “Ajọ fún Ààbò orí ẹ̀rọ-ayélujára” (ìdásílẹ̀ orílẹ̀-èdè Russia kan) tí ó ti kọ ọ̀pọ̀ àpilẹ̀kọ̀ àwọn ìhámọ́ lórí ìlò ẹ̀rọ-ayélujára orílẹ̀-èdè Russia ni ẹni tí ó fi ẹjọ́ rẹ̀ sùn látàrí yíya àwòránolóhùn yìí. Ó jẹ́ ọmọbìnrin ògbólógbòó oníwà ìbàjẹ́ ọmọ ìgbìmọ̀ Russia Elena Mizulina (tí ó jẹ́ òǹkọ̀wé ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn òfin ìpanilára lórí LGBTQ+ àti ‘àwọn ohun àmúyangàn ẹbí’). Ọ̀dọ́ Mizulina náà sọ lórí òpó ìkànnì Telegram rẹ̀ pé òun yóò rọ àwọn agbófinró àti ilé-iṣẹ́ Aṣèdájọ́ Gbogboogbò láti bójú wo àwòránolóhùn Nekoglai nítorí ó “yẹpẹrẹ àwọn ọmọ-ogun Russia.”

Kà sí i: ‘Pè wọ́n lórúkọ tí wọ́n ń jẹ́': Àwọn ìròyìn àwọn ẹlẹ́wọ̀n òṣèlú àtako-ogun ti orílẹ̀ èdè Russia

ọmọ orílẹ̀-èdè Moldova ni Nekoglai. Nítorí ẹ̀sùn Mizulina, wọ́n fi sí àhámọ́ ní ọjọ́ 9 oṣù kọkànlá fún “rírú ofin ìṣípò,” wọ́n sì fi sí àhàmọ́ fún àwọn aṣípò, wéré lẹ́yìn náà ni ilé-ẹjọ́ Presnya ti Moscow ti dájọ́ láti dá a padà sí Moldova. Àwọn agbejọ́rò akọbúlọ́ọ̀gù náà bẹ̀bẹ̀ lórí ìpinnu náà ṣùgbọ́n ilé ẹjọ́ ìlú Moscow náà fọwọ́ sí ìjẹ́jọ́ náà ni ọjọ́ 11 oṣù Kọkànlá. Lẹ́yìn ìpinnu ilé ẹjọ́ náà, àwọn àjọ tí ó ń bójú tó ìròyìn orílẹ̀-èdè Russia RIA Novosti ṣàgbéjáde àwòránolóhùn ti Nekoglai kan pẹ̀lú irun orí àti irun ìpéǹpé ojú rẹ̀ tí ó máa ń gé lọlẹ̀ tí ó jẹ́ àmì ìdánimọ̀ rẹ̀, tí ojú rẹ̀ sì ní àpẹẹrẹ ẹni tí wọ́n lù. Lórí àwòránhùn náà, akọbúlọ́ọ̀gù náà sọ wí pé: “Wàyìí ni ó ṣẹ̀ṣẹ̀ yé mi irú àṣìṣe tí mo ṣe. Mo kábàámọ̀, ojú tì mí gidigidi. Mo wòye wí pé bí mo bá wà ní irú ipò tí ọmọ-ogun náà wà nínú kòtò náà, mi ò bá má ti yè é. Ó ṣe mí bíi ẹranko. Ẹ dárí jì mi, bí ó bá ṣe é ṣe.”

Èyí kọ́ ni ìgbà àkọ́kọ́ tí àwọn agbófinró àti ẹ̀rọ àwíkiri tí orílẹ̀-èdè Russia ti lo àwọn àwòránhùn ìdójútara-ẹni láti fi dá sẹ̀ríà ìtakò àti láti fi ẹ̀rù bojo sí ọkàn àwọn yòókù. Gẹ́gẹ́ bí BBC ṣe kọ, “orò ìjẹ̀bi àti ìtìjú” yìí ni àwọn agbófinró ti pọwọ́lé lílò rẹ̀, alákọ̀ọ́kọ́ rẹ̀ ní Gúúsù Caucasus, bẹ́ẹ̀ ó tàn ká gbogbo ilẹ̀ Russia, láti fi àbámọ̀” náà hàn ní gbangba àti ìpayà àwọn afẹ̀hónúhàn. Ọgbọ́n kan náà ni wọ́n lò nígbà ìṣèjọba Lukashenka ní Belarus lẹ́yìn tí ìfẹ̀hónúhàn àwọn ènìyàn bíi erùpẹ̀ tako màgòmágó ìbò ọdún 2020 bẹ́ sílẹ̀ lójijì.

Gẹ́gẹ́ bí àwọn ìjábọ̀ Meduza, àwọn olùgbèjà Nekoglai dá àbá pé wọn ń ṣe akọbúlọ́ọ̀gù náà ṣìbáláṣìbo ní àtìmọ̀lẹ̀. Agbẹjọ́ro náà béèrè bóyá wọ́n lọ ìyà ipá lórí rẹ̀, ní èyí tí Nekoglai, gẹ́gẹ́ bí àjọ aṣagbátẹrù ìròyìn orílẹ̀-èdè Russia TASS, “pẹ̀lú omijé lójú rẹ̀” dáhùn pé “rárá” ó sì sọ wí pé: “mo fẹ́ kí wọ́n lé mi ní kíákíá, mi ò fẹ́ dúró mọ́, mo fẹ́ lọ ilé. Ojú ń tì mí, mo kábàámọ̀ ohun gbogbo.”

Ọ̀kan lára àwọn èsì lábẹ́ àwòránhùn-un Nekoglai lórí TikTok sọ pé, ní Romania: “Brat noi te așteptăm mai repede la Moldova ca aici contentul tau va fi mult mai interesant, tot va fi bine!” [Arákùnrin wa, à ń dúró dè ọ́ ní Moldova láìpẹ́, nítorí níbí àwọn àgbéjáde rẹ yóò wunni jọjọ, yóò sì tún dára!].

Bẹ̀rẹ̀ ìtàkùrọ̀sọ náà

Òǹkọ̀wé, jọ̀wọ́ àkọsílẹ̀ ìwọlé »

Ìlànà

  • Atukọ̀ yóò ṣ'àtúnwò gbogbo ìsọsí . Máà fi ìsọsíì rẹ sílẹ̀ ju ẹ̀rìnmejì lọ tàbí kí a kà á sí iṣẹ́-ìjẹ́-tí-a-o-fẹ́.
  • Jọ̀wọ́ fi ọ̀wọ̀ fún ẹlòmíràn . A ò ní fi àṣẹ sí ìsọsí ìkórìíra, ìṣekúṣe, àti ìdojú-ìjà-kọ ẹnikẹ́ni k.