Ìròyìn tó ṣẹ̀ṣẹ̀ jáde

Fún Ayẹyẹ Àìsùn Ọdún Tuntun àwọn Ilé-Ìwé ní Moscow, àwọn orin kan ò bójúmu

Ìkùrìrì RuNet  31 Ọ̀pẹ 2022

Ní àpapọ̀, àtòjọ náà ní àwọn olórin àti ẹgbẹ́ eléré 29. Díẹ̀ nínú wọn, bíi Little Big àti Manizha, ti ṣojú orílẹ̀-èdè Russia rí ní ìdíje Eurovision fún ọdún púpọ̀ látẹ̀yìnwá. Gbogbo wọn pata ni wọ́n bu ẹnu àtẹ́ lu ìkọlù orílẹ̀-èdè Russia sí Ukraine ní gbangba

Bí orílẹ̀-èdè Nàìjíríà ṣe kojú ìdábẹ́ Ọmọbìnrin èyí tí ó ń ṣe lemọ́lemọ́: Ìfọ̀rọ̀wánilẹ́nuwò kan pẹ̀lú Dókítà Chris Ugwu

  28 Ọ̀wẹwẹ̀ 2022

Abẹ́dídá máa ń yọrí sí ìrora tó lágbára, ṣíṣe àgbákò àrùn àìfojú rí, ẹ̀jẹ̀ yíya lọ́pọ̀lọpọ̀, àìle kápá ojú ilé ìtọ̀, làásìgbò ní ìgbà ìbímọ, ìpayà, àti ní ìgbà mìíràn, ikú pàápàá. Ní orílẹ̀-èdè Nàìjíríà, ẹkùn tí ìdábẹ́ fún ọmọbìnrin ti gbilẹ̀ jùlọ ni apá gúúsù-ìwọ̀ oòrùn àti gúúsù-ìlà oòrùn.

Àwọn Jàndùkú Èkó orílẹ̀-èdè Nàìjíríà ń Dá Ìpayà bá àwọn aráàlú, ń lọ́ àwọn awakọ̀ èrò lọ́wọ́gbà, wọ́n sì ń ba nǹkan jẹ́

Àwọn ọmọ ìta (agbèrò) ń fayé ni àwọn olùgbé Èkó lára. Wọ́n ń gbowó lọ́wọ́ awakọ̀, ta egbòogi olóró, pàdíàpòpọ̀ pẹ̀lú àwọn olóṣèlú gẹ́gẹ́ bí jàgídíjàgan tí wọ́n sì ń dá ẹ̀mi légbodò pẹ̀lú àwọn ìjà wọn.

Ọlọ́pàá Orílẹ̀-èdè Indonesia mú akẹ́kọ̀ọ́ mẹ́fà tí ó na àsíá ‘Àyájọ́ òmìnira orílẹ̀-èdè Papua’ tí a gbẹ́sẹ̀lé sókè

  7 Ọ̀pẹ 2021

Ọjọ́ kìnínní, oṣù Kejìlá, ọdún 2021 ni àwọn ènìyán kà sí Ọjọ́ Òmìnira orílẹ̀-èdè Ìwọ̀ Oòrùn Papua, sàmì àyájọ́ ọgọ́ta ọdún tí a kọ́kọ́ ta àsíá Ìràwọ̀ Òwúrọ̀ ní ìgbésẹ̀ láti gba òmìnira lọ́wọ́ ìjọba àmúnisìn Dutch

Di atúmọ̀ tàbí òǹkọ̀wé

Ẹ káàbọ̀ sí ibùdó Ohùn Àgbáyé ní èdè Yorùbá. Ìwọ náà lè darapọ̀ mọ́ wa, báwo? Kọ nípa araà rẹ sílẹ̀ níbí >>> "https://globalvoices.org/lingua/translator-application-form/"

Ìṣúra oṣooṣù

Aládàásí