Ìròyìn asọ̀tàn nípa Caribbean
Ìròyìn nípa Caribbean
Olórin Calypso Trinidad àti Tobago, Black Stalin, àwòkọ́ṣe ‘ọkùnrin Caribbean,’ jáde láyé ní ẹni Ọdún 81
Ògbó aládàánìkàn ronú tó gbóná àti olùpilẹ̀sẹ̀ ọ̀rọ̀ orin, ní gbogbo ìlàkàkà rẹ Stalin gbìyànjú láti jẹ́ kí ohun gbogbo lọ déédé.
Iyùn Tobago tí ó ti ń pàwọ̀dà fi hàn gbàgàdàgbagada pé kò sí ọ̀nà mìíràn ju kíkojú àyípadà ojú-ọjọ́
Ìgbóná òkun ń kóbá àwọn òkúta iyùn-un Tobago àti àwọn erékùṣù Ọ̀sàa Caribbean, a bá onímọ̀ ìṣẹ̀dá kan tí ọjọ́ iwájúu wọn jẹ́ lógún sọ̀rọ̀.
Àyájọ́ Ọjọ́ Òmìnira ní Trinidad àti Tobago — àmọ́ ǹjẹ́ orílẹ̀-èdè náà ní òmìnira bí?
"Òmìnira yìí faramọ́ ẹni tí o jẹ́, ibi tí o ti ṣẹ̀ wá, ẹ̀jẹ̀ àti ìṣẹ̀lẹ̀-àtẹ̀yìwá tí ó wà nínú iṣan-ẹ̀jẹ̀ rẹ"
‘Ohùn-un Jamaica fún Àyípadà Ojú-ọjọ́’ fi orin jíṣẹ́ẹ wọn
Iléeṣẹ́ tí kì í ṣe ti ìjọba ń ṣe ìgbélárugẹ àwọn ọ̀nà tí a lè gba jẹ́ iṣẹ́ yìí nípa lílo iṣẹ́ ọpọlọ orin láti kéde nípa àyípadà ojú-ọjọ́.
Ta ni yóò jáwé olúborí nínú Ayẹyẹ ijó ìta-gbangba orílẹ̀-èdè Trinidad àti Tobago ọdún-un 2019?
Orin tí ó dùn ún gbọ́ létí, ègbè tí ó ṣòro láti gbàgbé ... jẹ́ díẹ̀ lára àwọn ohun idán tí ó mú orin Ijó ìta-gbangba Ìwọ́de Ojúnà Trinidad àti Tobago yàrà ọ̀tọ̀.