Ìròyìn nípa Ìmọ̀-ìjìnlẹ̀
COVID-19 ṣe àgbéǹde ìṣẹ̀lẹ̀-àtẹ̀yìnwá tó burú jáì nípa ìdánwò egbògi ní Ilẹ̀-Adúláwọ̀
Ilẹ̀-Adúláwọ̀ 'kì í ṣe yàrá ìṣàyẹ̀wò' fún egbògi àjẹsára COVID-19. Àríyànjiyàn tí ó dá lóríi ìṣẹ̀lẹ̀-àtẹ̀yìnwá tí ó burú jáì nípa fífi ọmọ ènìyàn ṣe ìdánwò àti fífọwọ́ọlá gbá ọmọ Ilẹ̀-Adúláwọ̀ lójú.
Ìgbàgbọ́ ọba kan nínú ewé àtegbó fún ìwòsàn COVID-19 f'ara gbún ìmọ̀-ìjìnlẹ̀ l'órílẹ̀-èdè Nàìjíríà
Ọba orílẹ̀-èdè Nàìjíríà yìí nígbàgbọ́ nínú ewé àtegbó fún àwòtán COVID-19. Àmọ́ fífi Ògún gbárí láìfẹ̀rìílàdìí lórí Twitter fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ olùbárìn lè ṣini lọ́kàn — ó sì léwu — fún àwọn ènìyàn.