Ìròyìn nípa Nàìjíríà

Bí orílẹ̀-èdè Nàìjíríà ṣe kojú ìdábẹ́ Ọmọbìnrin èyí tí ó ń ṣe lemọ́lemọ́: Ìfọ̀rọ̀wánilẹ́nuwò kan pẹ̀lú Dókítà Chris Ugwu

  28 Ọ̀wẹwẹ̀ 2022

Abẹ́dídá máa ń yọrí sí ìrora tó lágbára, ṣíṣe àgbákò àrùn àìfojú rí, ẹ̀jẹ̀ yíya lọ́pọ̀lọpọ̀, àìle kápá ojú ilé ìtọ̀, làásìgbò ní ìgbà ìbímọ, ìpayà, àti ní ìgbà mìíràn, ikú pàápàá. Ní orílẹ̀-èdè Nàìjíríà, ẹkùn tí ìdábẹ́ fún ọmọbìnrin ti gbilẹ̀ jùlọ ni apá gúúsù-ìwọ̀ oòrùn àti gúúsù-ìlà oòrùn.

Súyà Orílẹ̀-èdè Nàìjíríà!

  2 Agẹmọ 2022

Mọ́là kan ni a rí níbí tí ó jókòó sídìí Àtẹ Súyà rẹ̀ Súyà (tí wọ́n ń pè é báyìí pé Sú-yá-à) Ìyẹn ni orúkọ ìjànjá-ẹran kan tí a ń yan lórí ayanran tó fẹjú, pẹ̀lú òróró, àlùbọ́sà àti iyọ̀. Súyà jẹ́ gbajúgbajà ohun jíjẹ láàárín àwọn ọlọ́rọ̀ àti bọ̀rọ̀kìní...

Sọ̀rọ̀sọ̀rọ̀ ní Nàìjíríà darapọ̀ mọ́ àwọn akẹgbẹ́-ẹ wọn láti sààmì ayẹyẹ Ọjọ́ Ẹ̀rọ-ìgbóhùnsáfẹ́fẹ́ Àgbáyé ọdún-un 2020

Àwọn sọ̀rọ̀sọ̀rọ̀-ọ orílẹ̀-èdèe Nàìjíríà darapọ̀ mọ́ àwọn sọ̀rọ̀sọ̀rọ̀ orí ẹ̀rọ-ìgbóhùnsáfẹ́fẹ́ lágbàáyé láti sààmì Àyájọ́ Ọjọ́ Ẹ̀rọ-ìgbóhùnsáfẹ́fẹ́ Àgbáyé lọ́jọ́ 13 oṣù Èrèlé ọdún-un 2020 àti láti fọn rere iṣẹ́ ìdàgbàsókè àgbà-ńlá ayé tí ẹ̀rọ-ìgbóhùnsáfẹ́fẹ́ ń ṣe.