Súyà Orílẹ̀-èdè Nàìjíríà!

Súyà Orílẹ̀-èdè NàìjíríàMọ́là kan ni a rí níbí tí ó jókòó sídìí Àtẹ Súyà rẹ̀

Súyà (tí wọ́n ń pè é báyìí pé Sú-yá-à)
Ìyẹn ni orúkọ ìjànjá-ẹran kan tí a ń yan lórí ayanran tó fẹjú, pẹ̀lú òróró, àlùbọ́sà àti iyọ̀.
Súyà jẹ́ gbajúgbajà ohun jíjẹ láàárín àwọn ọlọ́rọ̀ àti bọ̀rọ̀kìní ní orílẹ̀-èdè Nàìjíríà. Ìrọ̀lẹ́ ni a máa ń ṣe súyà ní ojú pópó, ní àwọn ilé-ijó, àwọn ilé ìtura tàbí àwọn ibi àríyá. Súyà jẹ́ ohun-àṣe-lákànṣe ti àwọn ẹ̀yà Hausa láti orílẹ̀-èdè Nàìjíríà.
Ekìrí súyà kan lè yí èrò rẹ nípa ẹran màlúù padà. Láti jẹ súyà ní ìdí ‘Àtẹ Súyà’ yòówù, ‘Mọ́là’ náà yóò kọ́kọ́ fún ọ ní ìtọ́wọ́ amọ́fundátòló. Yóò rẹ́ ìjànjá kínkín fún ọ láti mọ adùn ohun tí ó ń tà. Pẹ̀lú ìtọ́wò àkọ́kọ́ yìí, ó lè tanni láti kó gbogbo owó àpò ẹni fi ra ẹran amọ́nà-ọ̀fun-dá-tòló yìí.
Súyà jẹ́ ògidì amáradàgbà nítorí pé kò ní gbogbo àwọn èròjà àtọwọ́dá kẹ́míkà tí à ń pè ní amóúnjẹ́dùn ní ayé òde òní. Àwọn ọmọ orílẹ̀-èdè Nàìjíríà fẹ́ràn fàájì, kò sì sí ohun tí ó dà bíi kí o fi súyà gbígbóná rẹ jẹ pẹ̀lú Ẹmu tàbí Ọtí bíà orílẹ̀-èdè Nàìjíríà.

Bẹ̀rẹ̀ ìtàkùrọ̀sọ náà

Òǹkọ̀wé, jọ̀wọ́ àkọsílẹ̀ ìwọlé »

Ìlànà

  • Atukọ̀ yóò ṣ'àtúnwò gbogbo ìsọsí . Máà fi ìsọsíì rẹ sílẹ̀ ju ẹ̀rìnmejì lọ tàbí kí a kà á sí iṣẹ́-ìjẹ́-tí-a-o-fẹ́.
  • Jọ̀wọ́ fi ọ̀wọ̀ fún ẹlòmíràn . A ò ní fi àṣẹ sí ìsọsí ìkórìíra, ìṣekúṣe, àti ìdojú-ìjà-kọ ẹnikẹ́ni k.