Láti ọ̀sẹ̀ tó kọjá, àwọn ọ̀dọ́ ọmọ orílẹ̀-èdè Nàìjííríà ti gbéra sọ lọ́pọ̀ yanturu láti gbógun ti ẹ̀ka kan lábẹ Ilé Iṣẹ́ Ọlọ́pàá Orílẹ̀-èdè Nàìjííríà tí a mọ̀ sí Ikọ̀ Agbógunti Ìdigunjalè (SARS), èyí tí ìṣekúpani wọn, ìlọ́nilọ́wọ́gbà, ìjínigbé, ìfipábánilòpọ̀ wọn burú jáì láti ọdún 1992 tí wọ́n ti dá ẹ̀ka ọ̀hún sílẹ̀.
Ó lé ní 100 ènìyàn tí Ikọ̀ SARS ti ṣekú pa láti bí ọdún mẹ́rin sí márùn-ún sẹ́yìn gẹ́gẹ́ bí Amnesty International ṣe jábọ̀.
Àwọn ọ̀dọ́ ọmọ orílẹ̀-èdè Nàìjííríà — tí ó máa ń jẹ́ àfojúsùn ikọ̀ SARS lọ́pọ̀ ìgbà — ti figbe ta láìmọye ìgbà pé kí wọn ó pa ẹ̀ka náà rẹ́ pátápátá ṣùgbọ́n tí kò ṣẹnuure. Ṣùgbọ́n ní báyìí, ìfipáńpẹ́-ọba-gbé àti ìṣekúpani tó ń peléke sí i lẹ́nu lọ́ọ́lọ́ yìí ní ìpínlẹ̀ Èkó ni ó tún ta àwọn ènìyàn jí láti rí i pé ó wá sí ìmúṣẹ — èyí fa oríṣìiríṣìi ní àárín ìgboro — lẹ́yìn tí Ikọ̀ SARS ti kọ́kọ́ di tíkúkà ní ẹ̀ẹ̀mẹrin ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ láàárín ọdún mẹ́rin — ti ti ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn síta.
Ìgbógunti ìwà òkúrorò àwọn ọlọ́pàá yìí tún di ohun tí gbogbo ènìyàn ń gbà bí ẹni gba igbá ọtí, ó sì tún di kókó ọ̀rọ̀ ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìtàkùrọsọ lórí gbàgede ẹ̀rọ alátagbà
Ìfẹ̀hónúhàn ti gbéra sọ ní ó kéré tán ìpínlẹ̀ 12 nínú ìpínlẹ̀ 36 orílẹ̀-èdè Nàìjííríà tí ó fi mọ́ Abuja, olú ìlú orílẹ̀-èdè náà àti Èkọ́, níbi tí àwọn afẹ̀hónúhàn ti dí àwọn ẹnu ibodè asanwó kí a tó kọjá, àwọn pápákọ̀ òfuurufú ní ìpínlẹ̀ náà, pẹ̀lú ìrètí àtimú kí ó fa ètò ọrọ̀ ajé sẹ́yìn kí àwọn adarí tí a yàn lè gbọ́ sí àwọn àfẹ̀hónúhàn lẹ́nu láifi àkókò ṣòfò.
Èyí ni àwọn ohun tí àwọn afẹ̀hónúhàn fẹ́:
Àwọn ìbéèrè #EndSARS #EndSarsNow pic.twitter.com/SHEYENsTZR
— Asa (@Asa_official) Ọjọ́ 11, Oṣù Òwàrà, Ọdún 2020
Àwọn ọmọ orílẹ̀-èdè Nàìjííríà lẹ́yìn odi náà ti fọ́n sígboro láti fi àìdùnnú wọn hàn sí ikọ̀ ògbólógbo SARS yìí, tí ó ti ń hu oríṣiríṣi ìwa láabi láti àìmọye ọdún sẹ́yìn. Àwọn afẹ̀hónúhàn kóra jọ ní London, England, Dublin, Ireland, Ottawa, àti Toronto, Canada, Cologne, Germany, Moscow, Russia, Pretoria, South Africa tí ó fi mọ́ Texas àti Washington, DC ní ilẹ̀ Amẹ́ríkà láti bu ẹnu àtẹ́ lu ikọ̀ SARS.
Ààrẹ Buhari, a ní iṣẹ́-ìjẹ́ fún un ọ. FI ÒPIN SÍ SARS BÁYÌÍ-BÁYÌÍ.
Àwọn ọmọ orílẹ̀-èdè Nàìjííríà àti ẹ̀yin olùfẹ́ orílẹ̀-èdè Nàìjííríà, ẹ jọ̀wọ́ ẹ tú yáyáyá jáde sí ìfẹ̀hónúhàn #EndSARS (Fòpin sí ikọ̀ SARS) ní London (Àjọ Aṣojú orílẹ̀-èdè Nàìjííríà)
•#EndPoliceBrutality(Fi òpin sí ìwà òkúrorò àwọn Ọlọ́pàá) #EndSarsNow(fi òpin sí SARS báyìíbáyìí) #EndSARSProtest(Ìfẹ̀hónúhàn fi òpin sí SARS)pic.twitter.com/1RN7fe1p6q
— DrKelechi Anyikude (@KelechiAFC) October 11, 2020•
•#EndPoliceBrutality #EndSarsNow #EndSARSProtest pic.twitter.com/1RN7fe1p6q
— Dr. Kelechi Anyikude (@KelechiAFC) Ọjọ́ 11, Oṣù Òwàrà, Ọdún 2020
Ó kéré tan àwọn afẹ̀hónúhàn 10 ni wọ́n ti ṣekú pa ní àsìkò ìfẹ̀hónúhàn, gẹ́gẹ́ bí Amnesty International ṣe sọ. Lára àwọn tí wọ́n rán s'ọ́run àpàpàǹdodo ni Jimoh Isiaq, tí wọ́n pa ní ìlú Ogbomosho, Ìpínlẹ̀ Oyo, àti Ikechukwu Ilohamauzo tí wọn pa ní àsìkò ìfẹ̀hónúhàn Sùúrùlérè ní Èkó, àwọn wọ̀nyìí tí orúkọ wọn gba orí àwọn ìkànnì ìbánidọ́rẹ̀ẹ́ orí ẹ̀rọ alátagbà kan.
Ní báyìí, àwọn oníṣègùn òyìnbó tí ń kọ́wọ̀ọ́ rìn pẹ̀lú àwọn afẹ̀hónúhàn tórí bí ìṣẹ̀lẹ̀ pàjáwìrì bá wáyé.
Ọ̀gá àgbà ilé iṣẹ́ Ọlọ́pàá ilẹ̀ Nàìjííríà Muhammad Adamu tú ikọ̀ náà ká ní bí ọjọ́ mélòó kan sẹ́yìn, ṣùgbọ́n ìgbésẹ̀ yìí kò tẹ́ àwọn ọmọ orílẹ̀-èdè Nàìjííríà lọ́rùn nítorí pé àwọn ìgbésẹ̀ tí wọ́n ti gbé ṣáájú nípa ikọ̀ náà kò so èso rere.
Ní ọjọ́ Ajé, Ààrẹ orílẹ̀-èdè President Nàìjííríà Muhammad Buhari fi ọkàn àwọn ọmọ orílẹ̀-èdè náà balẹ̀ pé ìgbésẹ̀ ìtú ikọ̀ náà ká yóò fẹsẹ̀ múlẹ̀ ní kíá, bẹ́ẹ̀ sì ni ìgbìmọ̀ àtúndá ilé iṣẹ́ ààrẹ yóò rí sí ìgbáyégbádùn àwọn ọlọ́pàá àti àwọn nǹkan mìíràn tí ó tun ṣe pàtàkì, ó ń fi àrídájú hàn pé àwọn ìbéèrè àwọn ará ìlú yóò di mímú ṣe.
Àwọn amòfin tí wọ́n tún jẹ́ ajàfẹ́tọ̀ọ́ ọmọnìyàn àti àwọn ọ̀dọ́ ajàfẹ́tọ̀ọ́ tí ń ṣiṣẹ́ kára láti rí i pé wọ́n dá àwọn afẹ̀hónúhàn tí wọ́n tì mólé sílẹ̀.
Àwọn afẹ̀hónúhàn ti sọ ọ́ yanya pé ìjàfitafita láti fi òpin sí ikọ̀ SARS kò lọ́wọ́ òṣèlú nínú, bẹ́ẹ̀ ni wọ́n ṣe ìkìlọ̀ fún àwọn olóṣèlú tí ó fi mọ́ àwọn alátìlẹ́yìn ẹgbẹ́ òṣèlú alátakò láti má ṣe gbé ìfẹ̀hónúhàn ọ̀hún karí nítorí àtirí èrè nínú ẹgbẹ́ òṣèlú tàbí ti òṣèlú gan pàá.
Àwọn afẹ̀hónúhàn tá kú pé kò sí adarí nínú ìfẹ̀hónúhàn wọn, wí pé ẹnikẹ́ni tí ó bá jáde láti wá fẹ̀hónú hàn jẹ́ adarí àti ọmọ ẹ̀yìn pèlú. Wọ́n takú pé kí ààrẹ àti/tàbí Ọ̀gá Àgbà Ilé iṣẹ́ Ọlọ́pàá dojú ọ̀rọ̀ kọ gbogbo àwọn tí inú ń bí ní ẹ̀ẹ̀kan ṣoṣo ni kì í ṣe pé kí wọn ó ṣa àwọn kan bá sọ̀rọ̀.
Ìbéèrè lórí ẹni tí ó ń darí àwọn ọlọ́pàá àti ikọ̀ SARS kò tíì fi gbogbo ara rí ìdáhùn. Ìwé òfin ilẹ̀ náà gbé agbára ìdárí ọlọ́pàá lé ààrẹ lọ́wọ́ lábẹ́ ìbòjútó ọ̀gá àgbà ilé iṣẹ́ ọlọ́pàá.
Àmọ́ ẹ̀wọ̀n-àṣe àti ìdarí yẹn ti já.
Bí àpẹẹrẹ, láti jọ̀wọ́ àwọn afẹ̀hónúhàn ní Sùúrùlérè, ní ìpínlẹ̀ Èkó, èyí gba ìpè láti ọ̀dọ̀ Gómìnà ìpínlẹ̀ Èkó Babájídé Sanwó-Olú, Abẹnugan ilẹ́ Ìgbìmọ̀ Aṣojúṣòfin Fẹ́mi Gbàjàbíàmílà, ọmọ ilé ìgbìmọ̀ aṣòfin ìpínlẹ̀ Èkó tí ó ń ṣojú ẹkùn Sùúrùlérè Desmond Elliot àti àwọn agbẹjórò díẹ̀.
Ní Ọjọ́ 12, Oṣù Òwàrà, Gómìnà Ìpínlẹ̀ Rivers Nyesom Wike, kéde láti orí túwíìtì kan pé kò sí ààyè fún ìfẹ̀hónúhàn kankan — pàápàpá jùlọ ti #EndSARS protest — ní ìpínlẹ̀ òhun.
Èyí kò dùn mọ́ ọ̀pọ̀ àwọn ọmọ ìlú nínú. Ọ̀pọ̀ àwọn ènìyàn ni wọ́n dá èsì padà lórí àwọn ìkànnì ẹ̀rọ àwùjọ pé ìwé òfin tí ó gbé gómínà dé orí ipò náà ni ó fún àwọn ọmọ ìlú ní ẹ̀tọ́ láti fi ẹ̀hónú hàn.
Ta nìwọ láti dí àwọn ènìyàn lọ́wọ́ láti gùnlé lo ẹ̀tọ́ wọn lábẹ́ òfin láti tò lọ́wọ̀ọ̀wọ́ fún ìfèhónúhàn aláìléwu? https://t.co/94TdNAxv0g
— Bop Daddy (@falzthebahdguy) Ọjọ́ 12, Oṣù Òwàrà, Ọdún 2020
Síbẹ̀, Wike yíjú padà ó sì padà bá àwọn afẹ̀hónúhàn sọ̀rọ̀, níbi tí ó ti fi àtìlẹ́yìn rẹ̀ hàn sí ìpè wọn
Ìfẹ̀hónúhàn yìí tẹ̀síwájú ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìlú ní orílẹ̀-èdè náà tí ó fi mọ́ ìpínlẹ̀ Rivers. Àwọn afẹ̀hónúhàn ti ṣèlérí pé àwọn ò ní tẹ̀tì àyàfi bí àwọn bá rí ààmì ìyípadà ní ọ̀dọ̀ àwọn ọlọ́pàá àti ọ̀dọ̀ ìjọba àpapọ̀.
Ní ọjọ́ Ìṣẹ́gun, Ọjọ́ 13, Oṣù Òwàrà, àwọn afẹ̀hónúhàn fi léde lórí Twitter pé ní Ojúnà Ìwó, Ìbàdàn, àwọn ọmọ ológun orí ilẹ̀ ń kọ́wọ̀ọ́rìn pẹ̀lú àwọn afẹ̀hónúhàn pẹ̀lú ìsọ̀kan.
Mo gbọ́ pé àwọn ọmọ ogun orí ilẹ̀ ń kọ́wọ̀ọ́rìn pẹ̀lú àwọn Afẹ̀hónúhàn lọ́wọ́lọ́wọ́ #ENDSARS(fi òpin sí ikọ̀ SARS) ní ìlú Ibadan pic.twitter.com/pm5XxB5xUR
— //|) ? (@MDee_01) Ọjọ́ 13 Oṣù Òwàrà, Ọdún 2020
Bákan náà ní Ọjọ́ 14, Oṣù Owara, Gómìnà Ìpínlẹ̀ Èkó Babàjídé Sanwó-Olú kọ́wọ̀ọ́rìn pẹ̀lú àwọn afẹ̀hónúhàn, níbi tí ó tún ti fi ìdánilójú àtìlẹyìn ìjọba títí dé òpin hàn.
Gómìnà @jidesanwoolu (pẹ̀lú fìlà bọ́ọ̀lù béèsì aláwọ̀ àyìnrín) tí gbà láti rìn tòhun ti ìfẹ̀hónúhàn ní Aláùsá. #SARSMUSTEND(IKỌ̀ SARS GBỌ́DỌ̀ DÓPIN)pic.twitter.com/lcv30Mo0xG
— Tola Badekale (@BadekaleTola) Ọjọ́ 13, Oṣù Owara Ọdún 2020