Àwọn Jàndùkú Èkó orílẹ̀-èdè Nàìjíríà ń Dá Ìpayà bá àwọn aráàlú, ń lọ́ àwọn awakọ̀ èrò lọ́wọ́gbà, wọ́n sì ń ba nǹkan jẹ́

Ibùdókọ̀ Berger, Èkó, Nàìjíríà. Àwὸrán láti ọwọ́ Kaizen Photography lórí Wikimedia Commons, ọjọ́ 27 Oṣù Kẹ́ta, 2016, (CC BY-SA 4.0). Ibùdókọ̀ ni a ti sábà máa ń rí àwọn agbèrò, níbi tí wọ́n ti ń ṣiṣẹ́ gẹ́gẹ́ bí ọmọ ẹgbẹ́ awakọ̀-èrò National Union of Road Transport Workers (NURTW).

Ní àárín àwọn ìlú tí ó wà ní ìgboro Nàìjíríà, Àwọn ọmọọ̀ta (tí a tún mọ̀ sí agbèrò ní èdè Yorùbá) jẹ́ ọ̀wọ́ tí ó ń wu ìwà ìbàjẹ́ àti ìwà arúfin ní òpópónà àti ibùdókò jákèjádò orílẹ̀ èdè. Wọ́n jẹ́ ikọ̀ tí ó léwu láti bá jìjàdù wọ́n sì ti di ìṣòro tí ó gbilẹ̀ bíi ṣẹ́lẹ̀rú ní àwùjọ Èkó. Wọ́n jẹ́ ẹ̀rù tí ọ̀pọ̀ olùgbé Èkó tí fi kọ́ra nípa dídíbọ́n bí ọ̀kan lára wọn nípa kíkọ́ àṣà ọ̀rọ̀-sísọ àti kíkẹ ohùn sọ̀rọ̀ wọn láti yẹra fún wàhálà. Ìwà àìlófin àwọn ọmọ ìpáǹle  yìí ti di ohun tí ó ń fẹ́ àmójútó gidi ní Èkó. Wọ́n ń yọnilẹ́nu, dúkokò àti fi agbára mú àwọn awakọ̀ èrò láti fi ó kéré tán ìdajì owó tó ń wọlé fún wọn sílẹ̀. Wọn ti gbòòrò jù ní ojú pópó Èkó èyí sì fa rúdurùdu, síbẹ̀, ìjọba kòì tíì ṣe òfin tó múlẹ̀ láti dá ohun gbogbo padà sípò.

Ó fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ gbogbo agbèrò ni onísẹ́ ọmọ ẹgbẹ́ onímòtò National Union of Road Transport Workers (NURTW), èyí tí ó fún wọn ní àyè láti di agbèrò tí ó ń já tíkẹ́ẹ̀tì. Orúkọ yìí wáyé látàrí ipa bíntín tí wọ́n kó lórí ètò ìrìnnà ọkọ̀ èrò ní ìlú náà.  Ìjábọ̀ ìwádìí láti ọwọ́ Odinaka Anudu, ti International Center for Investigative Reporting (ICIR), ṣe ìṣirò wí pé lápapọ̀ agbèrò ń rí ẹgbẹlẹmùkù owó tí ó tó ẹgbẹẹgbẹ̀rún-lọ́nà-ẹgbẹ̀rún lọ́nà 123 náírà lọ́dọọdún (bí i ẹgbẹẹgbẹ̀rún lọ́nà 296 owó dọ́là) láti ọwọ́ àwọn awakọ̀ èrò. Bí ICIR ṣe sọ, iye owó yìí jẹ́ gbogbo owó ọ̀yà, iye, owó ibodè àti àwọn oríṣi owó orí mìíràn tí wọ́n ń gbà jáde lọ́wọ́ awakọ̀ èrò, oníkẹ̀kẹ́ ẹlẹ́sẹ̀mẹ́ta àti alùpùpù. Awakọ̀ kan ń san NGN 3,000 (ó tó USD 7.23) fún àwọn agbèrò wọ̀nyí lójúmọ́. Àwọn ọkọ̀ èrò tí ó wà ní Ìpínlẹ̀ náà ń lọ bí i 75,000 (ICIR), èyí tí ó túmọ̀ sí pé 225,000,000 (bí i 542,000 USD) ni ó ń jẹ́ gbígbà lọ́joojúmọ́ láti ara irúfẹ́ ìrìnnà ojú pópó kan ṣoṣo yìí.

Àwọn oníkẹ̀kẹ́ Márúwá (kẹ̀kẹ́ ẹlẹ́sẹ̀mẹ́ta) ń san NGN 1,800 (ó tó USD 4) fún àwọn agbèrò, tí gbogbo owó ojúmọ́ sì ń kú sí NGN 90,000,000 (USD 217,000). Síwájú sí i, àwọn ọlọ́kadà ń san owó tí ó tó NGN 600 (USD 1.5) lójúmọ́, èyí tí ó parapọ̀ jẹ́ ẹgbẹẹgbẹ̀rún 22 owó náírà (ó tó USD 530,000). A lè kádìí rẹ̀ pé àwọn agbèrò ní Èkó ń pa owó tí kò dín ní ẹgbẹẹgbẹ̀rún 337 owó náírà (ó tó USD 812,000) lójúmọ́ tàbí owó tabua ẹgbẹẹgbẹ̀rún-lọ́nà-ẹgbẹ̀rún lọ́nà 123 owó náírà (ó tó ẹgbẹ̀rún 296 owó dọ́là) lọ́dọọdún.

ICIR sọ pé “iye owó tí wọ́n rí jẹ́ ìdá 29.4 owó tí ó ń wọlé sínu àpò àsùnwọ̀n Ìpínlẹ̀ Èkó tí í ṣe ẹgbẹẹgbẹ̀rún-lọ́nà-ẹgbẹ̀rún 418.99 owó náírà. Àwọn agbèrò máa ń sọ pé àwọn ń gba owó orí ojú ọ̀nà ni, ṣùgbọ́n kì í dé inú àpò ìjọba ìpínlẹ̀, wọn kì í sì í fi jíṣẹ́. Kò sí àní-àní pé owó yìí  ń bọ́ sínú àpò àwọn kan ni.

Ní ọ̀pọ̀ ìgbà ni àwọn ibùdókọ̀, àwọn agbèrò yìí má ń fòró ẹ̀mí àwọn òṣìṣẹ́ ojú pópó. Púpọ̀ nínú àwọn òṣìṣẹ́ yìí ni òwò náà ti sú nítorí àwọn ọmọ ìta tí ó ń jẹ́ eré iṣẹ́ òógùn wọn ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìgbà . Ìbànújẹ́ ohun ìdààmú tí ó ń ti ibi èyí jáde jẹ́ kí á ní àwùjọ tó gbóná janjan, kò sì jẹ́ tuntun pé wàhálà máa ń bẹ́ sílẹ̀ lọ́pọ̀ ìgbà láàárín awakọ̀, èrò, àti àwọn ará àdúgbò. Láfikún, láti lè dí àlàfo owó tí wọ́n pàdánù sí ọwọ́ àwọn ọmọ ìta wọ̀nyí, ọ̀pọ̀ awakọ̀ máa ń fikún owó ọkọ̀ náà ní ìlọ́po méjì láì wo ti àwọn èrò. Nítorí náà, àwọn agbèrò ń dààmú àwọn olùgbé Èkó, wọ́n sì ń sọ wọ́n di otòṣì.

“Ó ti sú wa o, ó ti sú wa,” ọlọ́kadà kan tí orúkọ rẹ ń jẹ́ Saliu sọ fún Ohun Àgbáyé. “Lọ́joojúmọ́, mò ń fún wọ́n lówó, tipátipá sì ni mo fi ń rówó tọ́jú ara mi àti ẹbí mi. Òmíràn sọ pé “ṣebí ìdá mẹ́wàá gan ni Ọlọ́run ń gbà.” “Ta ni àwọn agbèrò yìí gan-an tí wọ́n lérò pé àwọn ní ẹ̀tọ́ láti máa jà wá lólè owó òógùn wá?”

Owó Àwọn Ọmọ-ìgboro 

Yàtọ̀ sí iṣẹ́ wọn gẹ́gẹ́ bí agbèrò tó ń já tíkẹ́ẹ̀tì, àwọn agbèrò tún ń ta àwọn egbòogi tí kò bá òfin mú, wọ́n ń siṣẹ́ gẹ́gẹ́ bí ẹ̀ṣọ́ aláàbò, wọ́n sì má ń ṣe ìlọ́nilọ́wọ́gbà owó lọ́wọ́ àwọn olùgbé Èkó ní ọ̀nà mìíràn. “Owó àwọn ọmọ-ìgboro” jẹ́ ohun tí wọ́n máa ń sọ tí wọ́n bá ń bèèrè owó. Wọ́n má ń ṣe èyí nígbà mìíràn nípa dídí ọ̀nà láti dá ọkọ̀ àdáni dúró àti bíbéèrè fún owó láti kọjá.

Ìṣòro gbòógì kan pẹ̀lú àwọn ọmọ ìta ni pé wọ́n ń kó ewu bá ẹ̀mí àti ìpàdánù dúkìá. Gbogbo wọn ni wọ́n jẹ́ ọmọ-ẹgbẹ́ jàndùkú, tí ó sábà máa ń fìjàpẹ́ẹ́ta. Àwọn orogún yìí ti yọrí sí oríṣiríṣi ìjà tí kò bá ilégbèé tàbí ilé ìtajà nìkan jẹ́ ṣùgbọ́n tí ó dá ọ̀pọ̀lọpọ̀ ẹ̀mí aláìṣẹ̀ légbodò.

Ó ní ìṣẹ̀lẹ̀ ìbànújẹ́ búburú tí ó ṣẹ alága ẹkùn kan ní Sùúrùlérè. Wọ́n pa ọkùnrin náà nínú ìjà ìgboro kan tí ó wáyé láàárín àwọn ọmọ ẹgbẹ́ awakọ̀ ni ọdún 2019. Ó jẹ́ onídùúró ìjà láàárín àwọn ọmọ-ìta Àgùdà àti àwọn ti Muṣin, léyìí tí àwọn ọmọ Àgùdà ń jà láti gba àkóso lórí agbègbè tí wọ́n lérò pé àwọn ọmọ-ìta Muṣin ń gbógunsí. Díẹ̀ nínú àwọn ọmọkùnrin náà ni ọwọ́ tẹ̀ bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé kò sí ohunkóhun tí wọ́n lè ṣe láti dá ẹ̀mí ọkùnrin tí wọ́n pa náà padà.

Àwọn agbèrò a tún máa siṣẹ́ gẹ́gẹ́ bí oníjàádì fún àwọn olóṣèlú. Olùgbé agbègbè Òjòdú kan tí kò fẹ́ dárúkọ ara rẹ̀ nítorí ààbò ara rẹ̀ sọ pé ìdí tí ohunkóhun kò fi jẹ́ siṣẹ́ sí ọ̀rọ̀ àwọn ọmọ-ìta pẹ̀lú bí wọ́n ṣe ń ṣọṣé tó ni pé wọ́n ní àtìlẹ̀yìn àwọn olóṣèlú, tí wọ́n ń lò wọ́n fún ànfààní ara wọn.

ICIR sọ wí pé nígbà tí Musiliu Akínsànyà, tí a tún mọ̀ sí MC Olúọmọ, gba ipò gẹ́gẹ́ bí alága ẹgbẹ́ awakọ̀ àpapọ̀ NURTW, ó gbé ìbà fún Aṣíwájú Bọ́lá Ahmed Tinúubú, Gómìnà Èkó tẹ́lẹ̀ rí àti olùdíje sí ipò ààrẹ láti inú ẹgbẹ́ òṣèlú onígbàálẹ̀ (APC), fún “ìfẹ́ àti àtìlẹ́yìn” tí ó rí “kí ó tó di alága ẹgbẹ́ NURTW.” Njẹ́ a lè sọ pé ó ṣe é ṣe kí àwọn ìfọwọ́wẹwọ́ kan láàárín agbèrò sí olóṣèlú ti wáyé lẹ́yìn ìtàgé bí?

Ọ̀pọ̀ ti sọ pé ọ̀nà àbáyọ kan ṣoṣo ni láti fòpin sí ìwà ìjẹ gàba àwọn ọmọ-ìta àti láti tú ẹgbẹ́ NURTW ká pátápátá. ṣùgbọ́n ní oṣù Kẹsàn-án ọdún 2020, Igbá-kejì Gómìnà Ìpínlẹ̀ Èkó, Ọbáfẹ́mi Hamzat, sọ wí pé ẹgbẹ́ náà jẹ́ mímọ̀ lábẹ́ òfin. Nítorí náà, ìjọba ń ṣọ́ra ṣe kí wọ́n ba máà tẹ òfin lójú.

Ìwà jàgídíjàgan àwọn agbèrò, ìpànìyàn nípakúpa àti àwọn owó tíkẹ́ẹ̀tì tí kò tọ̀ ń fa àwùjọ Nàìjíríà sẹ́yín, síbẹ̀, ìjọba ń lọ́ra ní ti ìmójútó ọ̀rọ̀ náà. Bí àwọn aráàlú bá ní láti máa wẹ̀yinwò bí wọ́n bá ń rìn ní òpópónà tí àwọn awakọ̀ èrò kò sì lè rìnnà laì jẹ́ wí pé tipátipá ni wọ́n gba owó wọ́n, dájúdájú ètò náà ti fọ́ yángá. Wọ́n ń kó ìpayà àti ẹ̀rù bá àwọn aráàlú, ṣùgbọ́n ìbéèrè kù : ta ló lè ká wọn lápá kò?

Bẹ̀rẹ̀ ìtàkùrọ̀sọ náà

Òǹkọ̀wé, jọ̀wọ́ àkọsílẹ̀ ìwọlé »

Ìlànà

  • Atukọ̀ yóò ṣ'àtúnwò gbogbo ìsọsí . Máà fi ìsọsíì rẹ sílẹ̀ ju ẹ̀rìnmejì lọ tàbí kí a kà á sí iṣẹ́-ìjẹ́-tí-a-o-fẹ́.
  • Jọ̀wọ́ fi ọ̀wọ̀ fún ẹlòmíràn . A ò ní fi àṣẹ sí ìsọsí ìkórìíra, ìṣekúṣe, àti ìdojú-ìjà-kọ ẹnikẹ́ni k.