Twitter di pápá ìròyìn ayédèrú lásìkò Ìdìbò ọdún-un 2019 ní Nàìjíríà

Àtòpọ̀ àwòrán láti ọwọ́ Nwachukwu Egbunike

Èyí ni apá kejì ìròyìn nínú àkọsílẹ̀ ẹlẹ́ka méjì lórí ọ̀rọ̀ ìkórìíra ẹ̀yà lórí ayélujára, ìròyìn ayédèrú àti ìsọkiri lásìkò ìdìbò ọdún-un 2019 lórílẹ̀-èdèe Nàìjíríà. O lè ka apá kìíní níbí.

Ní orílẹ̀-èdèe Nàìjíríà, àwùjọ ìbánisọ̀rọ̀ orí ayélujára jẹ́ ibi tí ìròyìn ìtakora-ẹ̀yà tẹ̀gbintẹ̀gbin àti ìsọkiri ti máa ń gbilẹ̀ bíi ṣẹ́lẹ̀rú lásìkò ìdìbò. Ní àsìkò ìdìbò ọdún-un 2015, Twitter Nàìjíríà kó sí ìjà àti ìsọ̀rọ̀-takora láàárín àwọn alátilẹyìn olùdíje-dupò méjèèjì tí ó lérò lẹ́yìn jù lọ lásìkò náà, ìyẹn Goodluck Jonathan (ọmọ ẹgbẹ́ẹ PDP tí ó jẹ́ kìrìsìtẹ́nì àti ọmọ Ijaw) àti Muhammadu Buhari (ọmọ ẹgbẹ́ APC tí ó jẹ́ Mùsùlùmí àti ọmọ Hausa-Fulani). Túwítà di ohun èlò fún ìsọkiri ọ̀rọ̀ ìkórìíra ẹ̀yà àti ọ̀rọ̀ ẹgbẹ́ òṣèlú.

“Àsìkò ìdìbò ọdún 2019 ò yàtọ̀ rárá. Ní ọjọ́ 15, oṣù Èrèlé ẹgbẹ́ Ajábọ̀ Ìròyìn Láìsí Àlà (RSF) ṣe àkọsílẹ̀ kan tí ó ń ṣe àfihàn èròo wọn lórí ìpolongo ìdìbò tí “ìròyìn ayédèrú ti mú bàjẹ́.”

Àwọn ọmọ orílẹ̀-èdèe Nàìjíríà náà fi èròo wọn hàn. Akọ̀ròyìn Abdulbaqi Jari túwíìtì pé:

Ìròyìn ayédèrú àti ìṣèlú ní àwọn orílẹ̀-èdè ilẹ̀ Adúláwọ̀

Ìwádìí ọdún-un 2019 kan láti ọwọ́ Dani Madrid-Morales ní Ilé-ẹ̀kọ́ gíga Huston àti Herman Wasserman ní ilé-ẹ̀kọ́ gíga Cape Town fẹnukò pé “ìròyìn irọ́ àti ìròyìn ayédèrú ni wọ́n ti máa ń lò láti fi mú ìfẹ́-inú àwọn olóṣèlú ṣẹ” ní orílẹ̀-èdèe Nàìjíríà, Kenya àti South Africa. Ọ̀pọ̀ Ìròyìn ayédèrú lórí àwọn àwùjọ ìbánisọ̀rọ̀ orí ayélujára pàápàá lásìkò ìpolongo ìbò máa ń fa “àìgbara-eni-gbọ́” láàárín àwọn tí wọ́n ń lo àwùjọ ìbánisọ̀rọ̀ orí ayélujára “nítorí pé ibẹ̀ ni wọ́n ti ń rí ‘ìròyìn ayédèrú’ lọ́pọ̀ ìgbà,” Madrid-Morales sọ̀rọ̀.

Ìwádìí mi lórí onírúurú ẹ̀yà láàárín ọjọ́ 28, oṣù Ọ̀wàrà ọdún-un 2018 àti ọjọ́ 29 oṣù Èbìbí, ọdún-un 2019 lórí ìdìbò ọdún-un 2019 lórílẹ̀-èdèe Nàìjíríà tó wáyé ní ọjọ́ 23, oṣù Èrèlé (láti dìbò yan ààrẹ àti aṣòfin sí ilé ìgbìmọ̀ aṣòfin ti orílẹ̀-èdè) àti ọjọ́ 9, oṣù Erénà (láti yan gómìnà àti aṣòfin sí ilé-ìgbìmọ̀ aṣòfin ti ìjọba ìpínlẹ̀) ṣe àfihàn ìṣẹ̀lẹ̀ ìròyìn ayédèrú méjì pàtàkì kan: ìròyìn ayédèrú tó tako ẹ̀yà kan àti ìsọkiri láti mú èrò inú àwọn olóṣèlú ṣẹ.

Ìròyìn Ayédèrú tó tako ẹ̀yà

Peter Obi, igbá kejì Atiku Abubakar tí ó jẹ́ òǹdíje-dupò ẹgbẹ́ òṣèlú (PDP) jẹ́ ẹni tí ó dojú kọ ìpalára ìròyìn ayédèrú tó tako ẹ̀yà lásìkò ìdìbò tó kọjá. Obi jẹ́ gómìnà ìgbà kan rí ní ìpínlẹ̀ Anambra ní gúúsù-ìlà oòrùn Nàìjíríà. Ìkànni Túwítà kan tí ó ń ṣe àtìlẹyìn ìpolongo fún Buhari-Osinbajo, Coalition of Buhari-Osinbajo Movement pín Túwíìtì kan (Atọ́ka 1) tí ó ń fẹ̀sùn kan Obi pé ó “lé àwọn ará àríwá orílẹ̀-èdèe Nàìjíríà kúrò ní ìpínlẹ̀ Anambra nígbà tí ó jẹ́ gómìnà.

Àwòrán 1: Àwòrán Túwíìtì kan láti ọwọ́ Coalition of Buhari-Osibanjo Movement tí ó ń fẹ̀sùn kan òbí pé ó ṣe ‘ìdápadà’ àwọn ará àríwá sí ìlúu wọn.

Atọ́ka 2: Àwòrán Túwíìtì kan láti ọwọ́ Nasir El-Rufia

Gómìnà ìpínlẹ̀-ẹ Kaduna àti ọmọ ẹgbẹ́ òṣèlú tí ó ń ṣè ìjọba lọ́wọ́, Nasir El-Rufai, mú ẹ̀sùn yìí rinlẹ̀ sí i, ó túwíìtì (Atọ́ka 2) pé Obi jẹ́ “ẹni tí ó ń ṣe ìyàtọ̀ọ̀tọ̀ ẹ̀yà”. Ohun tí El-Rufai sọ yìí ò mú kí ipò igbákejì ààrẹ tọ́ fún Obi.

Kí ni ohun tí ó ṣẹlẹ̀ gan-an?

Ilé-iṣẹ́ ìwé ìròyìn Vanguard jábọ̀ wípé ní oṣù Agẹmọ ọdún-un 2013, ọmọ Nàìjíríà 67 tí ọ̀pọ̀lọpọ̀ wọn wá láti ilẹ̀-ẹ Igbo ni “wọ́n dá padà láti Èkó tí wọ́n sì pa wọ́n tì sí ibi kan náà ní agbègbè Upper Iweka” tí ó gbajúmọ̀ ní Onitsha, Ìpínlẹ̀ Anambra.

Obi, tí ó jẹ́ gómìnà ìpínlẹ̀ Anambra ní ìgbà náà, ṣàpèjúwe ìhùwàsí yìí tí akẹgbẹ́-ẹ ‘ẹ̀ Túndé Fáṣọlá ní ìpínlẹ̀ Èkó hù gẹ́gẹ́ bí “ohun tí kò bá òfin mu àti ìrúfin ẹ̀tọ́ ọmọnìyàn àwọn ẹni tí ó di èrò ìlúu wọn.”

Lẹ́yìn ìbínúu gbogboògbò tí ọ̀rọ̀ yìí fà, Premium Times jábọ̀ pé Obi náà jẹ̀bi irú ọ̀rọ̀ bẹ́ẹ̀: Ní 2011, ó lé àwọn atọrọbárà tó jẹ́ ọmọdé padà sí ìpínlẹ̀ Ebonyi àti Akwa Ibom, ní apá gúúsù orílẹ̀-èdèe Nàìjíríà.

Atọ́ka 3: Àwòrán Túwíìtì kan láti ọwọ́ Jubril A. Gawat

Nígbà tí Obi dá àwọn oníbárà padà sí àwọn ìpínlẹ̀ ní Gúúsù Nàìjíríà lóòótọ́, kò lé àwọn ará Àríwá, ẹ̀sùn tí ìṣàmúlò-o Twitter ẹgbẹ́ alátìlẹ́yìn-in Coalition of Buhari-Osinbajo Movement túwíìtì (Atọ́ka 1) kò gún régé. Kódà Túndé Fáṣọlá ti ẹgbẹ́ APC ni ó “ṣe ìdápadà àwọn ará Àríwá 70 sí ìpínlẹ̀-ẹ Kano nítorí wọ́n tọrọ bárà” gẹ́gẹ́ bí ìwé ìròyìn aṣèwádìí lórí ayélujára Sahara Reporters ṣẹ jábọ̀.

Bẹ́ẹ̀ àwọn agbèsẹ́yìn egbẹ́ òṣèlú APC ni wọ́n ṣàmúlò ìròyìn ayédèrú tó tako ẹ̀yà kan yìí láti fi bu ẹnu àtẹ́ lu òǹdíje-dupò lábẹ́ àsíá ẹgbẹ́ tó tako ẹ̀gbẹ́ẹ wọn. Fún àpẹẹrẹ, Jubril Gawat tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ yàn sípò aṣèrànwọ́ Gómìnà pàtàkì lórí ẹ̀rọ ìgbéròyìnjáde ìgbàlódé tuntun túwíìtì pé (Atọ́ka 3) ìbò kan fún òǹdíje-dupò ẹgbẹ́ atako Atiku Abubakar “jẹ́ ìbò fún ẹ̀yà Igbo.”

Nàìjíríà jẹ́ orílẹ̀-èdè kan tí ọ̀rọ̀ ẹ̀yà ti rinlẹ̀ gan-an. Àwọn olóṣèlú sì máa ń sa ẹ̀yàmẹyà yìí bí oògùn ní àsìkò ìdìbò nítorí wọ́n máa ń nílò láti pín àwọn ènìyàn sí ẹgbẹ́ “àwa” pẹ̀lú “wọn”.

Nítorí náà, wọ́n ní í lọ́kàn láti fi ẹ̀sùn tí wọ́n fi kan Obi pé ó lé àwọn ará Àríwá padà sí ìlú wọn rú inúnibíni tí ó ti wà tẹ́lẹ̀ láàárín ẹ̀yà Igbo àti Hausa tí ó fa Ogun Abẹ́lée Nàìjíríà.

Èròǹgbà wọn pẹ̀lú ìpolongo àwọn ìròyìn ayédèrú yìí ni láti ṣe àfihàn Obi gẹ́gẹ́ bí ajìjàǹgbara fún ẹ̀yà Biafra. Ẹ̀yà tó wà ní Gúúsù-ìwọ̀ oòrùn Nàìjíríà, tí ọ̀pọ̀lọpọ̀ wọn jẹ́ ọmọ Igbo gbìyànjú láti ya kúrò lára orílẹ̀-èdè nípasẹ̀ ogun abẹ́lé tí ó wáyé fún ọdún mẹ́ta láàárín ọdún 1967 sí 1970.

Fún ìdí èyí, wọ́n ní í lọ́kàn láti lo àkọsílẹ̀ inú atọ́ka 3 tí ó sọ pé “Ìbò kan fún Atiku jẹ́ ibo fún ẹ̀yà Igbo…” fi jí òkú ìkórìíra ẹ̀yà tẹ̀gbintẹ̀gbin tí ó ti wà láàárín ẹ̀yà Hausa àti Igbo. Ní àsìkò ìdìbò ọdún-un 2019, èyí túmọ̀ sí pé Atiku jẹ́ agbèsẹ́yìn ẹ̀yà Igbo tí wọ́n ti fìgbà kan gbìyànjú láti pínyà kúrò nínú orílẹ̀-èdèe Nàìjíríà.

Àkọsílẹ̀ inú atọ́ka 1 dé 3 ń ṣe àfihàn àwọn èrò tí ó lágbára láti jí ìṣẹ̀lẹ̀ àtijọ́ tí ó ti relẹ̀, tí kòì tí ì tán nínú àwọn ẹ̀yà méjèèjì. Àjọ UNESCO sọ pé ìròyìn ayédèrú báyìí máa ń lapa lára àwọn “tí ó mọ̀ díẹ̀ káàtó tí ìpalára lè bá tí ó ń gbà á” yóó sì sọ wọ́n di “aláriwo àti alápìínká ìròyìn náà.” Ìpolongo ìbò tí ó bá ti ń tako ẹ̀yà kan máa ń fi ẹ̀tanú tó rinlẹ̀ sínú ọkàn àwọn tí ó ń gbọ́ ọ, ó sì máa ń sọ àwọn olùgbọ́ yìí di alápìínká ìròyìn ayédèrú.

Irọ́ tí wọ́n pa pé àwọn Yorùbá ń tiná bọ ìsọ̀ àwọn ọmọ Igbo nílùú Èkó

Atọ́ka 4: Àwòrán Túwíìtì kan [ti Twitter lòdì sí tí wọ́n sì yọ kúrò] láti ọwọ́ Chioma tí ó ń ṣe ìtànká ìròyìn ayédèrú pé àwọn Yorùbá ń dáná sun ìsọ̀ àwọn Igbo nílùú Èkó.

Bákan náà, àwọn agbèsẹ́yìn ẹgbẹ́ẹ PDP náà lo ọ̀rọ̀ ìdójúkọ ẹ̀yà yìí láti kó ìbò ju ẹgbẹ́ẹ APC lọ ní ìpínlẹ̀ Èkó. Atọ́ka 4 àti 5 ń ṣàfihàn àwòrán Túwíìtì láti ọwọ́ abánikẹ́dùn PDP kan tí ó ń sọ pé àwọn Yorùbá ti ń ti iná bọ ìsọ̀ àwọn ọmọ Igbo nílùú Èkó.

Irọ́ ni àwọn ìròyìn náà, Àjọ Ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Èkó sì tètè fi òtítọ́ hàn láti pa á rẹ́.

Àkọsílẹ̀ orí Facebook kan tí ó fẹ́rẹ̀ẹ́ ṣàmúlò gbogbo ọ̀rọ̀ inú àwòrán atọ́ka 4, pẹ̀lú àwòrán ibi tí wọ́n ti fi táyà tó ń jó dí ọ̀nà náà ṣe àpínká ìròyìn irọ́ náà. African Check jábọ̀ pé àwòrán tí wọ́n lò yìí jẹ́ àwòrán kan lati ibi ìfẹ̀hónúhàn kan ni ọjọ́ 24 oṣù Èrèlé ọdún 2017 tí ó wáyé ní agbègbè kan nítòsí Pretoria ní orílẹ̀ èdè South Africa.

Atọ́ka 5: Àwòrán Túwíìtì kan tí ó ń ṣe ìtànká ìròyìn ayédèrú kan pé àwọn Yorùbá ń tiná bọ ìsọ̀ àwọn ọmọ Igbo nílùú Èkó II

Ìsọkiri láti mú èrò inú àwọn olóṣèlú ṣẹ 

Ní ọjọ́ 13 oṣù Èrèlé, olùṣàmúlò Túwítà kan Souljah túwíìtì (Atọ́ka 6) pé Ballard Partners, tí ó jẹ́ iléeṣẹ́ Alukoro kan tí wọ́n gbà síṣẹ́ tí ó kalẹ̀ sí Washington DC, láti ṣe ìpolongo fún Abubakar gẹ́gẹ́ bí Ààrẹ, ṣe ìwádìí àyẹ̀wò lábẹ́lẹ̀ kan tí ó ti ṣàpẹẹrẹ ìfìdírẹmi òǹdíje-dupò lábẹ́ àsiá ẹgbẹ́ alátakò, ìyẹn PDP.

Ní ọjọ́ 5, oṣù Èrèlé, ìwé àbájáde ìwádìí náà tí Brian Ballard, adaríiléeṣẹ́ Ballard Partners buwọ́lù tẹ Olúṣọlá Saraki, tí ó jẹ́ adarí pátápátá fún ìpolongo ìbò Abubakar lọ́wọ́.

Túwíìtì Souljah tàn káàkiri tí ènìyàn ẹgbẹẹgbẹ̀rún kan fẹ́ràn-an rẹ̀, tí ẹgbẹẹgbẹ̀rún ènìyàn-án sì ṣe àtúnpín-in rẹ̀ fún ìdí tí ò f'ara sin. Wọ́n gbé ọjọ́ ìdìbò láti yan ààrẹ sí ọjọ́ 16 oṣù Èrèlé (tí wọ́n padà sún un síwájú sí ọjọ́ 23 oṣù Èrèlé), nǹkan ò bá bàjẹ́ fún ẹgbẹ́ asàtakò PDP pẹ̀lú àbájáde ìwádìí tí ó ń fara hàn ní ọjọ́ mẹ́ta kí ìdìbò ó tó wáyé yìí..

Atọ́ka 6: Àwòrán Túwíìtì kan láti ọwọ́ Souljah

Sùgbọ́n ní ìrólẹ́ ọjọ́ 13 oṣù Èrèlé, Ballard Partners ní àbájáde ìwádìí náà kò rí bẹ́ẹ̀ (Atọ́ka 7) tí wọ́n ṣe àpèjúwe rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí i “jìbìtì”, wọ́n sì fi ìdíi rẹ̀ múlẹ̀ pé àwọn kò “ṣe ìwádìí kankan fún ẹgbẹ́ òṣèlú PDP.”

Ose Anenih, tí ó jẹ́ agbèsẹ́yìn ẹgbẹ́ PDP ṣe ìfisùn lára àwọn ará APC orí Túwítà tí wọ́n ṣe ìtànká àbájáde ìwádìí náà sí ìkànni àwọn ọlọ́pàá orílẹ̀-èdèe Nàìjíríà àti àjọ tí ó ń ṣe àmójútó ọ̀rọ̀ ìdìbò, INEC fún “ìwà ọ̀daràn àti ohun tí ó lòdì sófin” tí ó ń gbìyànjú “láti dí ìdìbò tí ó yẹ kí ó lọ nírọ̀rùn lọ́wọ́.”

Ṣùgbọ́n èyí kì í ṣe ìgbà àkọ́kọ́ tí wọ́n máa fi ìròyìn ayédèrú mú èrò inú àwọn olóṣèlú ṣẹ lórí ayélujára ní àsìkò ìdìbò.

Atọ́ka 7: Àwòrán Túwíìtì kan láti ọwọ́ iléeṣẹ́ Ballard and Partners tí í sẹ́ ayédèrú ìwádìí tí wọ́n purọ́ mọ́ wọn pé wọ́n ṣe.

Ọ̀pọ̀lọpọ̀ irọ́ olùrànlọ́wọ́ ààrẹ

Atọ́ka 8: Àwòrán Túwíìtì kan by Lauretta Onochie, láti ọwọ́ Lauretta Onochie, tí ó jẹ́ olùrànlọ́wọ́ fún ààrẹ

Ní ọjọ́ 4, oṣù Ọ̀pẹ, ọdún-un 2018 Lauretta Onochie, tí ó jẹ́ olùrànlọ́wọ́ fún Buhari [tí ó jẹ́ òǹdíje-dupò ààrẹ lásìkò náà] túwíìtì (Atọ́ka 8) àwòrán kan pẹ̀lú oúnjẹ àti owóo náírà 500 tí wọ́n ní wọ́n pín fún àwọn èrò lọ́jọ́ kejì ìrìnde ìpolongo ìdìbò fún Abubakar gẹ́gẹ́ bí ààrẹ ní Sokoto, apá àríwá-ìlà oòrùn orílẹ̀-èdèe Nàìjíríà ní àná ọjọ́ náà.

Irọ́ pátápátá ni àwọn ẹ̀sùn Onochie. Kódà, níbi òde kan tí kò tan mọ́ “ọ̀rọ̀ ìdìbò” ni a ti ya àwòrán náà nínú “oṣù Èrèlé ọdún-un 2017″, Chuba Ugwu tan ìmọ́lẹ̀ sí èyí nínú èsì sí túwíìtì rẹ̀ kan.

Onochie jẹ́ ògbóǹtarìgì níbi ká máa ṣe àpínká ìròyìn ayédèrú. Iléeṣẹ́ agbéròyìnjáde orí ayélujára kan tí ó ń ṣe ìwádìí ìjábọ̀ ìròyìn (ICIR), ti ṣe àgbéyẹ̀wò àwòrán tó ju 1,000 lọ tí Onochie ti pín sórí Twitter láàárín ọjọ́ 1, oṣù Ògún ọdún-un 2018 àti ọjọ́ 31, oṣù Agẹmọ ọdún-un 2019. Àgbéyẹ̀wò náà fi hàn pé ó kéré tán “ìgbà méjìlá” ni Onochie “ti lo àwòrán tí kò yẹ.”

Ọ̀rọ̀ Àtakò lórí Ayélujára: ọ̀ràn ní Nàìjíríà

Abala 26 òfin Nàìjíríà nípa ọ̀ràn orí ayélujára kọ “lílérí ìjà àti lílo ọ̀rọ̀ èébú sí àwọn èèyàn nítorí ẹ̀yàa wọn, ẹ̀sìn-in wọn, àwọ̀-ọ wọn, ìràn-an wọn tàbí orílẹ̀-èdèe wọn.” Àwọn ẹni tí adé ìwà náà bá ṣí mọ́ lórí á fi ẹ̀wọ̀n ọlọ́dún-márùn-ún gbára tàbí kí wọ́n san owó ìtanràn tí kò dín ní ẹgbẹẹgbẹ̀rún 10 owóo naira [tí ó ń lọ bí i $28,000] tàbí méjèèjì.

Ní oṣù Ẹrẹ́nà ọdún yìí, Enough is Enough Nigeria (EIE), tí ó jẹ́ àkójọpọ̀ àwọn ọ̀dọ́ kan àti Paradigm Initiative (PI), tí ó jẹ́ ẹgbẹ́ aṣòfin àti ajàfẹ́tọ̀ọ́ ẹni lórí ẹ̀rọ-ayárabíàṣá, ṣe ìfilọ́lẹ̀ ìpèlẹ́jọ́ Onochie àti Gbénga Ọlọ́runpomi tí ó jẹ́ olùrànlọ́wọ́ gómìnà ìpínlẹ̀-ẹ Kogi lẹ́jọ́ ní Ilé-ẹjọ́ kan ní Abuja.

Àjọ méjèèjì yìí “ṣe àkópọ̀ àwọn ọ̀rọ̀ àtakò tí ó jẹ́ ọ̀rọ̀ Onochie àti Ọlọ́runpomi lórí ayélujára” tí wọ́n rí i pé ó rú òfin orílẹ̀-èdèe Nàìjíríà nípa ọ̀ràn orí ayélujára ti 2015.

Àkójọpọ̀ àwọn ajagun orí Twitter tí wọ́n ń ṣe àpínká irọ́

Púpọ̀ nínú àwọn àpẹẹrẹ tí a ṣe lókè yìí kì í ṣe ohun tí wọn kò mọ̀-ọ́n-mọ̀ ṣe. Wọ́n dìídì gbìyànjú láti ṣe àpínká irọ́ bí i pé òótọ́ ni.

Èyí kò yani lẹ́nu rárá nítorí a rí i pé APC àti PDP ni wọ́n di ajagun orí ayélujára láti lè ṣe “ìmúwálẹ̀ ìjábọ̀ búburú” lórí ayélujára nípa wọn tàbí láti “gbèjà” níbi ìdojúkọ lásìkò ìpolongo ìbò. Ẹgbẹ́ méjèèjì ni ó ṣe àmúlò “ajagun orí ayélujára” — “àwọn akópa nínú ìjọba tàbí ẹgbẹ́ òṣèlú tí wọ́n fún ní iṣẹ́ láti tọwọ́bọ ọpọlọ àwọn ará ìlú láti yí èròo wọn padà lórí ayélujára.”

Ìdìbò ọdún yìí jẹ́ àṣẹtúnṣe ti 2015, níbi tí APC àti PDP ti kópa nínú ìtànká ìròyìn ayédèrú àti irọ́ pẹ̀lú ìsọkiri láti mú èrò àwọn olóṣèlú ṣẹ “nínú àwọn ìpolongo wọn lórí àwùjọ ayélujára tí wọ́n “fara balẹ̀ ṣètò láti fi tan  àwọn olùdìbò tí kò fura, “báyìí ni Eshemokha Austin Maho, tí ó jẹ́ ọ̀mọ̀wé Nàìjíríà kan nípa ìkéde àti ìgbéròyìnjáde ṣe sọ. Wọ́n rí èyí ṣe nípasẹ̀ “ìdásílẹ̀ àwọn ìkànnì irọ́ lórí ayélujára “níbi tí wọ́n ti ń pín “ọ̀rọ̀ ibanilórúkọjẹ́” àti “ìròyìn tí kò ṣe é fọkàn tán pẹ̀lú ìsọkiri láti mú èrò àwọn olóṣèlú ṣẹ”.

Àbájáde tí ipa wọn kó ni pé Twitter di pápá ìròyìn ayédèrú tí ó ń ṣe ẹlẹ́yàmẹyà àti ìsọkiri láti mú èrò àwọn olóṣèlú ṣẹ ṣáájú àsìkò ìdìbò, ní àsìkò ìdìbò àti lẹ́yìn ìdìbò ọdún-un 2019 lórílẹ̀-èdèe Nàìjíríà.

Àròkọ yìí jẹ́ apá kan nínú ọ̀wọ̀ọ́ àwọn àkọsílẹ̀ tí ó ń ṣe àgbéyẹ̀wò ìkọlura pẹ̀lú ẹ̀tọ́ ẹni lórí ayélujára nípasẹ̀ àwọn ìlànà bí i pípa òpó ìbánisọ̀rọ̀ àti ìròyìn ayédèrú ní àsìkò tí ọ̀rọ̀ ìṣèlú pàtàkì bá ń wáyé ní orílẹ̀-èdè ilẹ̀ Adúláwọ̀ méje: Algeria, Ethiopia, Mozambique, Nigeria, Tunisia, Uganda, and Zimbabwe. Àjọ tí ó ń ṣàmójútó ẹ̀tọ́ ẹni lórí ẹ̀rọ Africa Digital Rights Fund ti The Collaboration on International ICT Policy for East and Southern Africa (CIPESA) ni ó ṣe agbátẹrù iṣẹ́ yìí.

Bẹ̀rẹ̀ ìtàkùrọ̀sọ náà

Òǹkọ̀wé, jọ̀wọ́ àkọsílẹ̀ ìwọlé »

Ìlànà

  • Atukọ̀ yóò ṣ'àtúnwò gbogbo ìsọsí . Máà fi ìsọsíì rẹ sílẹ̀ ju ẹ̀rìnmejì lọ tàbí kí a kà á sí iṣẹ́-ìjẹ́-tí-a-o-fẹ́.
  • Jọ̀wọ́ fi ọ̀wọ̀ fún ẹlòmíràn . A ò ní fi àṣẹ sí ìsọsí ìkórìíra, ìṣekúṣe, àti ìdojú-ìjà-kọ ẹnikẹ́ni k.