COVID-19 ṣe àgbéǹde ìṣẹ̀lẹ̀-àtẹ̀yìnwá tó burú jáì nípa ìdánwò egbògi ní Ilẹ̀-Adúláwọ̀

Olóyè ọmọ-ogun. 1st Class Marites Cabreza, olùtọ́jú ọmọ tí ó ń ṣiṣẹ́ pẹ̀lú 354th Civil Affairs Brigade, Special Functioning Team, Combined Joint Task Force-Ìho Ilẹ̀-Adúláwọ̀, ń tọ́jú aláìsàn lọ́jọ́ 29, oṣù kẹta, ọdún-un 2008, lásìkò àkànṣe iṣẹ́ ìwòsàn ìlú ní Goubetto, Djibouti. Àwòrán láti àkàtà Ọmọ-ogún Òfuurufú US Ẹ̀ka ìmọ̀ ẹ̀rọ , Jeremy T. Lock. Ìlò gbogboògbò.

Yẹ àkànṣe ìròyìn-in ‘Ohùn Àgbáyé’  lórí ipa tí COVID-19 ń kó lágbàáyé.

Arée pànpàlà bí o ò lọ ó yàgò tí ń ṣẹlẹ̀ láàárín àwọn onímọ̀ ìjìnlẹ̀ àti oníṣẹ́ ìwádìí kò ṣẹ̀yìn ìgbésẹ̀ láti ṣe àyẹ̀wò àwọn oògùn tí wọ́n rò pé ó lè wo àrùn COVID-19 sàn lára ọmọ ènìyàn ti ń dá gbọ́nmisíi-omi-ò-tóo sílẹ̀ ní Ilẹ̀-Adúláwọ̀.

Lọ́jọ́ 1, oṣù kẹrin, àwọn oníṣẹ́ ìwádìí ọmọ ilẹ̀ Faransé méjì, Oníṣègùn Jean-Paul Mira, àti Camille Locht, dá a lábàá lórí ètò kan ní orí ẹ̀rọ-amóhùnmáwòrán wí pé Ilẹ̀-Adúláwọ̀ ni ó yẹ kí wọn ó ti kókó dán egbògi àjẹsára tí yóò ká apá àrùn kòkòrò àìfojúrí kòrónà sàn wò, gẹ́gẹ́ bí Al-Jazeera ti ṣe jíyìn ìròyìn náà. Oníṣègùn Mira, olórí ẹ̀ka ìtọ́jú àfẹ́jù ti Cochin Hospital tí ó wà ní Paris, fi ọ̀rọ̀ náà wé “àwọn ìwádìí àyẹ̀wò fún Àrùn Kògbóògùn ÉÈDÌ, tí ó jẹ́ wí pé lára àwọn olówòo nàbì ni a ti kọ́kọ́ dán an wò, a gbìyànjú àwọn nǹkan kan nítorí a mọ̀ dájú wí pé wọn kì í dá ààbò bo ara wọn, àti pé ó rọrùn fún àrùn ìbálòpọ̀ láti lúgọ sí ara wọn.”

Àwọn oníṣẹ́ ìwádìí méjèèjì mẹ́nu lọ́rọ́ nígbà tí àsọgbà ọ̀rọ̀ kan wáyé lórí ìṣàyẹ̀wò egbògi àjẹsára BCG fún ikọ́-àwúpẹ̀jẹ̀ ní Yúróòpù àti Australia láti mọ̀ bóyá yóò ṣiṣẹ́ ìwòsàn fún kòkòrò àìfojúrí kòrónà àkọ́kọ́ irú ẹ̀. Ní Australia, àyẹ̀wò ti ń lọ lórí àwọn oníṣẹ́ ìlera ẹgbẹ̀rún 4.

Ìṣesí àwọn oníṣẹ́ ìwádìí wọ̀nyí jẹ́ gbohùngbohùn ìṣẹ̀lẹ̀-àtẹ̀yìnwá ọlọ́jọ́ pípẹ́ tí ó ní ṣe pẹ̀lú ìdánwò àti fífọwọ́ọlá gbá ọmọ Adúláwọ̀ ní ojú, tí ó ṣe wí pé àwọn adarí Ilẹ̀-Adúláwọ̀ ti pàdí-àpò-pọ̀ pẹ̀lú àwọn iléeṣẹ́ apooògùntà — tí ó fi Yúróòpù tàbí ilẹ̀ Amẹ́ríkà ṣe ibùgbé — láti wá ṣe àyẹ̀wò ní ara àwọn tí kò rí já jẹ láwùjọ.

Lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀ ni ìṣọ̀rọ̀sí àwọn oníṣẹ́ ìwádìí wọ̀nyí rí ìdálẹ́bi àti ìbínú àwọn ènìyàn, tí ó mú àpólà ọ̀rọ̀ kan, “Ọmọ ilẹ̀-Adúláwọ̀ kì í ṣe eku ẹmọ́.” gbajúmọ̀ lórí ẹ̀rọ-agbọ́rọ̀káyé.

Ìràwọ̀ agbábọ́ọ̀lù ọmọ orílẹ̀-èdè Ivory Coast Didier Drogba túwíìtì:

Nígbà tí ó di ọjọ́ 3, Oṣù Kẹrin, Oníṣègùn Mira ti ṣe ìtọrọ àforíjì fún àwọn ọ̀rọ̀ tí ó sọ, àmọ́ lẹ́yìn tí àwọn ẹgbẹ́ SOS Racisme kọ ẹ̀yìn sí i ni ó ṣe èyí. Òṣìṣẹ́ẹ oníṣègùn Locht, bákan náà, da àwọn ẹ̀hónú orí Twitter dànù gẹ́gẹ́ bí i “ìròyìn ẹlẹ́jẹ́,” nítorí wí pé àwọn ọ̀rọ̀ náà kò rí bí wọ́n ti ṣe ń sọ ọ́.

Ní àárín ọ̀sẹ̀ yẹn kan náà, onímọ̀ nípa àrùn àìfojúrí ọmọ orílẹ̀-èdè Congo Jean-Jacque Muyembe, tí ó ń léwájú nínú ìgbógunti àjàkálẹ̀ àrùn ibà ìdà ẹ̀jẹ̀ Ebola ní orílẹ̀-èdè Ìlú Ìjọba Àwaarawa Olómìnira Congo, filọ̀ wí pé DR Congo “ti ṣe tán láti kópa nínú irúfẹ́ ìdánwò egbògi tí yóò pa kòkòrò àìfojúrí kòrónà tí kò bá à wáyé lọ́jọ́ iwájú,” bí News 24 ti jábọ̀.

Muyembe, olórí ìgbìmọ̀ amúṣẹ́ṣe lórí àjàkáyé àrùn náà àti Iléeṣẹ́ ètò ìlera orílẹ̀-èdè náà, sọ níbi àpérò àwọn oníròyìn kan:

Wọ́n ti yàn wá láti ṣe àwọn àyẹ̀wò wọ̀nyí … Ìlú Ìṣọ̀kan Amẹ́ríkà tàbí Canada tàbí ní China ni a ó ti ṣe egbògi àjẹsára náà. Àwa ni ẹni ayàn fún iṣẹ́ àyẹ̀wò náà níbí.

Lẹ́ẹ̀kan sí i, àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí fa ìrúnú àwọn ọmọ Congo àti àwọn ọmọ orí ayélujára jákèjádò ilé ayé tí wọ́n dá Oníṣègùn Muyembe ní ẹ̀bí nítorí ó faramọ́ ìṣàyẹ̀wò egbògi ní DR Congo, níbi tí iye àwọn tí ó ti kó àrùn COVID-19 kò tí ì fi bẹ́ẹ̀ pọ̀.

Láàárín wákàtí díẹ̀, Oníṣègùn Muyembe yànnàná ọ̀rọ̀ọ rẹ̀ nínú àwòrán-àtohùn kan, tí ó fi ìdíi rẹ̀ múlẹ̀ wí pé ó di ìgbà tí wọ́n bá ti kọ́kọ́ yẹ iṣẹ́ egbògi náà wò ní US àti China ni yóò tó jẹ́ lílò ní DR Congo:

Ìṣẹ̀lẹ̀-àtẹ̀yìnwá tó burú jáì nípa ìdánwò egbògi ní Ilẹ̀-Adúláwọ̀

Ìdánwò egbògi ní Ilẹ̀-Adúláwọ̀ — tí ó sábà máa ń wáyé lábẹ́ ẹ̀tàn “ìfẹ́ẹ gbogboògbò” tí ó pọn dandan ní ojúnà àti wá ìwòsàn fún àrùn aṣekúpani bí i àrùn yírùnyírùn àti àrùn kògbóògùn HIV/AIDS — ti lu agogo ìtanijí ìwà-ọmọlúwàbí fún àìníye ọdún — pàápàá jù lọ lórí ìgbàṣẹ lọ́wọ́ àwọn ènìyàn kí wọn ó tó ṣe ìdánwò àti ìlànà ìṣètò ìlera onítúláàsì.

Àwọn iléeṣẹ́ tí ó jẹ́ asíwájú nínú ètò ìlera lágbàáyé bí i Àjọ Elétò Ìlera Àgbáyé, Àjọ Aṣàkóso Àrùn ti orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà àti Iléeṣẹ́ Ètò Ìlera Ìjọba Àpapọ̀ ni ó máa ń kó owó sílẹ̀ fún irú àwọn iṣẹ́ báyìí.

Ní orílẹ̀-èdè Zimbabwe, ní àárín àwọn ọdún tí ó ré kọjá kí a tó wọ Ẹgbàá ọdún, ó lé ní 17,000 àwọn obìnrin tí ó ní àrùn kògbóògùn ni ó ṣe ìdánwò láì fi àṣẹ fún àwọn elétò ìdánwò wí pé àwọn fi ọwọ́ si í kí wọn ó lo àwọn fún iṣẹ́ ìwádìí àyẹ̀wò egbògi-agbógunti ìtànká àrùn kògbóògùn AZT lágọ̀ọ́ ara tí CDC, WHO àti NIH kó owó lé lórí.

Bákan náà ẹ̀wẹ̀, àgbà ọ̀jẹ̀ iléeṣẹ́ apooògùntà Pfizer dán oògùn kan wò tí a pè ní Trovan ní ara àwọn èwe 200 ní Ìpínlẹ̀ Kano, orílẹ̀-èdè Nàìjíríà, nígbà tí àjàkálẹ̀ àrùn yírùnyírùn ṣẹ́ yọ. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìdílé ni ó pe Pfizer ní ẹjọ́ lórí àìgbàṣẹ lọ́wọ́ àwọn kí wọn ó tó lo àwọn ọmọ àwọn fún ìdánwò.

Ìdánwò egbògi kì í ṣe èyí tí ó dá lórí ìṣẹ̀lẹ̀-àtẹ̀yìnwá nípa ti ẹlẹ́yàmẹyà àti ìfipámúnisìn nìkan — bákan náà ni ó ń ṣe okùnfàa ìṣòro àìfọkàn tán láàárín àwọn aṣojú ètò ìlera àti ará ìlú.

Patrick Malloy kọ sí inú àpilẹ̀kọ ajẹmákadá tí a pe àkọ́lée rẹ̀ ní, “Èròjà Iṣẹ́-ìwádìí àti Ìbókùúsọ̀rọ̀: Ìgbéyẹ̀wò ìrònú nípa ètò Ìṣèlú-tòun Ọrọ̀-ajé tí ó ní ṣe pẹ̀lú ìṣoògùn ìgbàlódé ní ayé ìfipámúnisìn ní Tanganyika” pé “Àti ìfipámúnisìn àti ìṣoògùn ìgbàlódé ní í jọ ń parapọ̀ ṣe, tí ìk-ín-ní ń kín ìlọsíwájú ìkejì lẹ́yìn.”

Láti ayée àmòdi sí ayé irú àwọn “àjàkálẹ̀-àrùn báwọ̀n-ọnnì”, àwọn aṣojú ìjọba ìfipámúnisìn sábà máa ń fi àwọn Ọmọ Adúláwọ̀ ṣe ohun èlò fún ìdánwò láì gba àṣẹ, Malloy kọ pé “…ẹ̀jẹ̀ Ọmọ Adúláwọ̀ ni ó dára jù lọ láti fi bọ́ iṣẹ́ ìwádìí egbògi ayé ìjọba amúnisìn.” Ó tẹ̀síwájú nínú ọ̀rọ̀ọ rẹ̀: 

Ní Tanganyika àti ní apá ibòmíràn ní Ilẹ̀-Adúláwọ̀, èyí túmọ̀ sí wí pé ní ìgbàkúùgbà ni àwọn amúnisìn leè ké sí àwọn tí wọ́n ń jẹ gàba lé lórí láti yànda àwọn pádi ẹ̀jẹ̀, tí ó dúró fún ẹ̀yà àbùdá ara wọn fún aṣojú ètò ìlera tí yóò jẹ́ lílò fún ìdánwò.

Àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ báwọ̀nyí kò yàtọ̀ sí gbọ́yìí-sọ̀yìí ọ̀rọ̀ tí àwọn ènìyàn ń jẹ ní ẹnu ní Ìlà-oòrùn Ilẹ̀-Adúláwọ̀ nípa “àwọn ẹgbẹ́” tí ó ń ṣiṣẹ́ fún àwọn Òyìnbó tí iṣẹ́ẹ ti wọn kò ju kí wọn ó máa jí Ọmọ Adúláwọ̀ gbé lọ láti gba ẹ̀jẹ̀ tí wọn yóò fi ṣe oògùn kan bí òjíá tí a pè ní mumiani. Ọ̀rọ̀ ìperí ní èdèe Swahili àkàwé oògùn náà ni “amùjẹ̀” tàbí “agbẹ̀jẹ̀-fún-ìwòsàn” — tí ó ti di “ìmórí-ẹni-sábẹ̀” báyìí.

Ìṣẹ̀lẹ̀-àtẹ̀yìnwá tí ó burú jáì yìí ti gbin èso àìfọkàn tán nínú àwọn egbògi àjẹsára, ìṣàyẹ̀wò àti ìdán oògùn wò ní Ilẹ̀-Adúláwọ̀, tí ó sì ń farahàn nínú iṣẹ́ àwọn aṣojú ètò ìlera tí ó ń ṣiṣẹ́ papọ̀ pẹ̀lú ìjọba àti àwọn iléeṣẹ́ alooògùntà ní àgbáyé.

Ìdánwò oògùn àrùn yírùnyírùn ìgbàa nnì ní Kano, orílẹ̀-èdèe Nàìjíríà, gbin ọ̀pọ̀lọpọ̀ àìnígbágbọ̀ tí kò mú kí ìpolongo ìdánwò oògùn àrùn rọmọlápárọmọlẹ́sẹ̀ ó rinlẹ̀.  Àhesọ nípa egbògi àjẹsára agbógunti àrùn rọmọlápárọmọlẹ́sẹ̀ fọ́n ká sí ìgboro. Àwọn àhesọ ọ̀rọ̀ náà di pínpín ká bí ìròyìn tí ó ṣe atọ́nà ètò ìmúlò ìjọba agbègbè tí ó f'òfin de ìlòo egbògi àrùn rọmọlápárọmọlẹ́sẹ̀ ní orílẹ̀-èdèe Nàìjíríà ní ọdún-un 2003.

Ìmúláradá lẹ́yìn ‘orí fífọ́’ ìfipámúnisìn

Pẹ̀lú ohun tí a ti sọ, kí ni gbogbo ìwọ̀nyí yóò fà fún ìdánwò egbògi àrùn COVID-19 ní Ilẹ̀-Adúláwọ̀? Àwọn ènìyàn ní orí ayélujára àti ajìjàngbara gbogbo ló ti pẹnupọ̀ wí pé “àwọn Ọmọ Adúláwọ̀ kì í ṣe eku ẹmọ́ òyìnbó.”

Ọ̀gá àgbà Àjọ Ètò Ìlera Àgbáyé (WHO) Tedros Adhanom Ghebreyesus ti pe ìhùwàsí àwọn oníṣègùn méjèèjì náà sí “orí fífọ́” tí ó dá lórí “làákàyè ìfipámunisìn”, ó sì fi léde:

Kò leè jẹ́ Ilẹ̀ Adúláwọ̀ àti pé kì í ṣe Ilẹ̀ Adúláwọ̀ ni yóò jẹ́ ibi ìdánwò fún èyíkéyìí irúfẹ́ egbògi.

Síbẹ̀, ìbẹ̀rùbojo àti àìfọkàn tán ìdánwò egbògi ti mú kí dídá àwọn ẹni tí ó ti lùgbàdè àrùn àfòmọ́ kòkòrò àìfojúrí kòrónà mọ́ láwùjọ àti ìṣàyẹ̀wò ó nira fún àwọn òṣìṣẹ́ elétò ìlera.

Ní orílẹ̀-èdèe Côte d'Ivoire ní ọjọ́ 6, Oṣù kẹrin, àwọn afẹ̀hónúhàn ti iná bọ ibi àyẹ̀wò àrùn COVID-19 kan, ìdí tí wọ́n fi ṣe bẹ́ẹ̀ ni wí pé agbègbè tí èró pọ̀ sí ni wọ́n sọrí ibi àyẹ̀wò náà sí tí kò sì bójúmu. Iléeṣẹ́ BBC jábọ̀ wí pé, ìkọlù náà “mú ‘ni rántí ìhùwàsí àwọn ènìyàn ní àsìkò tí àrùn ibà Ebola ń jà rọ̀ìnrọ̀ìn ní Ìwọ̀-oòrùn àti Àárín gbùngbùn Ilẹ̀ Adúláwọ̀ níbí tí àwọn kan ti ya bo àwọn oníṣẹ́ ètò ìlera, pẹ̀lú ìmúfuradání wí pé wọn ń kó àrùn náà wọ àdúgbòo àwọn, bókànràn-an kí wọ́n fún àwọn ní ìtọ́jú tí ó lẹ́tikẹ.”

Jù bẹ́ẹ̀ lọ, nínú rògbòdìyàn àjàkálẹ̀-àrùn ibà Ebola ọdún-un 2018 ní DR Congo, àwọn àyẹ̀wòkan àyẹ̀wòkàn tí a ṣe ní ara àwọn ẹni tí ó ti lu gúdẹ àrùn Ebola “tí ó tẹ̀lé àlàkalẹ̀ ìwà-ọmọlúwàbí kan” — lábẹ́ ìtọ́nàa Oníṣègùn Muyembe àti ìjọba orílẹ̀-èdèe DR Congo — dóòlà ẹ̀mí àwọn ènìyàn níkẹyìn. Nígbà tí ó máa fi di Oṣù Kọkànlá ọdún-un 2019, tí a ti ṣe àyẹ̀wò fún ọmọ orílẹ̀ èdèe Congo tí ó ju ẹgbẹ̀rún lọ, a fi òǹtẹ̀ lu egbògi àjẹsára kan.

Ó yẹ kí WHO ó ṣe ìkéde wí pé àrùn ibà ìdà ẹ̀jẹ̀ Ebola kò sí ní DR Congo mọ́ ní ọjọ́ 12 Oṣù Kẹrin, ṣùgbọ́n lẹ́yìn 50 ọjọ́ tí kò sí ẹni tí ó lùgbàdìi àrùn yìí, ọmọkùnrin tí ọjọ́ oríi rẹ̀ jẹ́ ọdún 26 kó àrùn ibà ìdà ẹ̀jẹ̀ Ebola ó sì filẹ̀ ṣ'aṣọ bora ní ọjọ́ 10 Oṣù Kẹrin.

Ní báyìí, ní àfikún Ebola àti awuyewuye ọ̀rọ̀ ẹ̀tọ́ ọmọnìyàn tí ó ń m'ìgboro tìtì lọ́wọ́lọ́wọ́, orílẹ̀-èdèe DR Congo ní láti kọ ojú sí dídẹ́kun ìgbodikan àjàkálẹ̀-àrùn kòkòrò àìfojúrí kòrónà tí ó ń gbilẹ̀ bí ọ̀gẹ̀dẹ̀.

Àwọn ìgbésẹ̀ 62 tí ó ń gbèrò láti wá egbògi àjẹsára fún àrùn COVID-19 ló ń lọ lọ́wọ́. Àyẹ̀wò àti ìdánwò egbògi àjẹsára tí yóò ṣiṣẹ́ dé góńgó tí a gbé ṣe lọ́nà tí ó bá ìwà-ọmọlúwàbí mu máa ń gba àsìkò. Ǹjẹ́ àwọn iléeṣẹ́ apooògùntà ńlá yóò dìrọ̀ mọ́ àwọn òfin ìwà-ọmọlúwàbí ní Ilẹ̀-Adúláwọ̀ bí wọ́n ti ṣe ń ṣe bí wọ́n bá ń ṣe ìdánwò ní Ilẹ̀ òyìnbó?

Bẹ̀rẹ̀ ìtàkùrọ̀sọ náà

Òǹkọ̀wé, jọ̀wọ́ àkọsílẹ̀ ìwọlé »

Ìlànà

  • Atukọ̀ yóò ṣ'àtúnwò gbogbo ìsọsí . Máà fi ìsọsíì rẹ sílẹ̀ ju ẹ̀rìnmejì lọ tàbí kí a kà á sí iṣẹ́-ìjẹ́-tí-a-o-fẹ́.
  • Jọ̀wọ́ fi ọ̀wọ̀ fún ẹlòmíràn . A ò ní fi àṣẹ sí ìsọsí ìkórìíra, ìṣekúṣe, àti ìdojú-ìjà-kọ ẹnikẹ́ni k.