Ìgbàgbọ́ ọba kan nínú ewé àtegbó fún ìwòsàn COVID-19 f'ara gbún ìmọ̀-ìjìnlẹ̀ l'órílẹ̀-èdè Nàìjíríà

Ọọ̀ni Adéyẹyẹ̀ Ẹniìtàn Ògúnwùsì, Ọ̀jájá II ṣe àgbéjáde àwòrán-àtohùn kan tó ń ṣe ìpolongo àgbo ìbílẹ̀ t'ó lè kápá kòkòrò àìfojúrí corona lórí Twitter lọ́jọ́ 30, oṣù Kẹta, ọdún 2020.

Yẹ àkànṣe ìròyìn Ohùn Àgbáyé lórí arapa COVID-19 lágbàáyé wò. 

Àrùn kòkòrò corona àkọ́kọ́ tí a mọ̀ sí COVID-19 ń mi ilé ayé bí ìṣẹ́lẹ̀ títóbi.

Gẹ́gẹ́ bí Fásítì John Hopkins ti ṣe sọ, ènìyàn 900,000 lágbàáyé l'ó ti lùgbàdì àrùn náà; ní ọjọ́ 1, oṣù kẹrin, ọdún 2020, ènìyàn 174 ló ti kó àrùn náà ní orílẹ̀-èdè Nàìjíríà.

Bí àwọn oníwàádìí àti onímọ̀ ìjìnlẹ̀ ṣe ń ṣiṣẹ́ láìsùn láìwo láti pèsè egbògi ìbupá tí yóò dúró gẹ́gẹ́ bí oògùn tí yóò kápá àjàkáyé àrùn náà, àwọn oníṣègùn ìbílẹ̀ náà ti ṣe ìpolongo ohun tí yóò wo àrùn náà.

Ní orílẹ̀-èdè Nàìjíríà, Àdìmúlà Ifẹ̀, ọba ìran Yorùbá káàfàtà, Ọọ̀ni Adéyẹyẹ̀ Ẹniìtàn Ògúnwùsì, Ọ̀jájá II, nígbàgbọ́ wí pé ewé àti egbò lè kápá àrùn COVID-19.

Ní àjọṣepọ̀ pẹ̀lú iléeṣẹ́ oníṣègùn ìbílẹ̀, YemKem International, Ọọ̀ni ti ń to àgbo tí yóò jẹ́ títa.

Àgbo náà ní àkójọpọ̀ ewé ewúro, ewé àti èso igi dógóyárò, imí-ọjọ́, ẹ̀ẹ̀rù, òkìrìṣákọ́, ewé akòko, àti àrìdan tí ó ti jẹ́ oògùn ìbílẹ̀ tí ó kájú òṣùwọ̀n fún ìfọ-èérí-ara àti kòkòrò àìfojúrí dànù nílẹ̀ Yorùbá.

Ọọ̀ni, ẹni t'ó jẹ́ alága Ìgbìmọ̀ Ọba Ìbílẹ̀ Orílẹ̀-èdè Nàìjíríà (NCTRN), ṣe ìkéde lórí ẹ̀rọ agbọ́rọ̀káyé Twitter pẹ̀lú ọ̀kan-ò-jọ̀kan túwíìtì tí ó ṣe ìfilọ àwárí rẹ̀, èyí tí ó sọ pé àgbo náà ti la àyẹ̀wò kọjá tí àtòun àtàwọn tó kó àrùn kòkòrò àìfojúrí corona náà sì ti lò ó. Nínú àwọn túwíìtì ọjọ́ 30 Oṣù Kẹta náà, Ọọ̀ni pe àwọn oníwàádìí sí àkíyèsí láti ṣe ìṣàmúlò àwọn ewé àtegbó fún ṣíṣe egbògi ìbupá.

Àwọn túwíìtì náà ní àwòrán-àtohùn méjì tí ó ní ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ àlàyé lórí àwọn àgbo ìbílẹ̀, pẹ̀lú bí a ṣe ń lo àlùbọ́sà fi fa àrùn tó ń ràn ká yọ lágọ̀ọ́ ara àti bí a ti ṣe ń fi òórùn àkójọpọ̀ ewé àtegbó lé “àwọn ẹ̀mí ajogún jìnà.”

Ìgbàgbọ́ ìbílẹ̀ wàákò pẹ̀lú ìlànà ìmọ̀-ìjìnlẹ̀

Ihà kékeré kọ́ ni egbògi ìbílẹ̀ ń kó nínú àṣà ìbílẹ̀ Yorùbá.

Ní gbogbo Oṣù Kẹfà — èyí tó jẹ́ ìbẹ̀rẹ̀ ọdún tuntun nílẹ̀ Yorùbá — àwọn oníṣẹ̀ṣe Bàbá Akéréfinúṣọgbọ́n (Ifá) yóò péjọ fún àjọ̀dùn lórí Òkè Ìtasẹ̀ níbi tí Ifá yóò ti fọ̀ tí yóò sì sọ bí ọ̀la yóò ti rí.

Lọ́jọ́ 6, Oṣù Kẹfà, 2019, níbi Àjọ̀dún Ifá Àgbáyé, odù Òtúrá Méjì ló yọ lójú ọpọ́n, tí Ifá sì ṣe “ìkílọ̀ ìbínú àjàkálẹ̀ ogun àìfojúrí kan.” Àsọtẹ́lẹ̀ yìí ni a gbàgbọ́ wí pé ó jẹ́ COVID-19.

Àjọ Ètò Ìlara Lágbàáyé (WHO) ti ṣe àtìlẹ́yìn tó gogò fún Ìsẹ́gun Ìbílẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ọ̀kan gbòógì lára àwọn ètò ìlera alábọ́dé, tí wọ́n sì sé ìkéde lórí ajẹ́mọ́wà-ọmọlúàbí ìtúpalẹ̀ ewé àtegbó fún ìlera àgbáyé.

Bákan náà ẹ̀wẹ̀, WHO ti fi lé'de pé, lọ́wọ́lọ́wọ́ yìí, kò tíì sí ìwòsàn tàbí oògùn ìbupá fún kòkòrò àìfojúrí COVID-19 àkọ́kọ́.

Fífi ọwọ́ sọ̀yà lórí oògùn ìbílẹ̀ láì ṣe àyẹ̀wò tó múná dóko lé e lórí leè dá họ́hùhọ́hù sílẹ̀ láwùjọ.

Dókítà Olúwatómidé Adéoyè, tí ó jẹ́ onímọ̀ nípa àgbékalẹ̀ òògùn tí ó fi Lisbon, Orílẹ̀-Èdè Portugal ṣebùgbé, bu ẹnu àtẹ́ lu ọ̀rọ̀ tí ọba sọ nípa òògùn ìbílẹ̀ fún ìkápá kòkòrò àìfojúrí corona.

Nínú iṣẹ́-ìjẹ́ àpò ìwé orí ayélujára rẹ̀ sí Ohùn Àgbáyé, Dókítà Adéoyè kọ pé:

There is no way that [the Ọọ̀ni] could know for certain that his ‘medicine’ (concoction) can cure the coronavirus. The proper protocol to test such medicine will be to (i) isolate the virus and test the medicine in ‘petri dishes,’ if effective, (ii) test in animals (models) and eventually in (iii) Humans (safety and efficacy).

Kò sí ọ̀nà tí (Ọọ̀ni) fi lè fi ọwọ́ sọ̀yà pé ‘oògùn’ (àgbò) òun leè ṣe àwòtán kòkòrò àìfojúrí corona.  Ọ̀nà kan gbòógì láti lè fi ìdí bẹ́ẹ̀ múlẹ̀ ni ṣíṣe àyẹ̀wò (i) yíya kòkòrò tó ń fa àrùn yìí sọ̀tọ́ sínú ‘àwo-àyẹ̀wò’, bí ó bá jẹ́ bí idán, (ii) ṣíṣe àyẹ̀wò rẹ̀ lára àwọn ẹranko, kí ó tó kan (iii) ṣíṣe àyẹ̀wò rẹ̀ lára ènìyàn (ló fi ẹsẹ̀ àìléwu àti ìmúnádóko rẹ̀ múlẹ̀).

Onímọ̀ nípa ìpògùnpọ̀ náà tẹnumọ́rọ̀:

Even if we assume they jumped straight to human trials, there is no evidence that Ọọ̀ni has test kits with which he diagnosed people for COVID-19 in order to evaluate the clinical efficacy of the purported medicine.

Kódà bí a bá ti ẹ̀ ní wí pé wọ́n bẹ̀rẹ̀ àyẹ̀wò láti orí ènìyàn, láì tí ì ṣe àyẹ̀wò rẹ̀ lára ẹranko kankan, kò sí ẹ̀rí tó dájú wí pé Ọọ̀ni ní ohun èlò aṣàyẹ̀wọ̀ tí ó fi ṣe ìwádìí àrùn kòkòrò àìfojúrí COVID-19 lára ẹni tí ó bá ní, àti láti leè fi ìmúnádóko oògùn náà rinlẹ̀.

Nínú iṣẹ́-ìjẹ́ rẹ̀, Dókítà Adéoyè tún tako ìgbàgbọ́ tí ó rọ̀mọ ìṣègùn ìbílẹ̀ tí Ọọ̀ni ṣe ìgbélárugẹ rẹ̀ nínú àwọn àwòrán-àtohùn rẹ̀.

Bí àpẹẹrẹ, ọba náà fi yé wí pé àlùbọ́sà leè pa ẹ̀mí tí ò dára lára, tí yóò sì fi ẹ̀mí dídára ọ̀tun  rọ́pò. Àti pé, fífi àlùbọ́sà tí a rẹ́ sí àtẹ́lẹ́-ẹsẹ̀ leè pa, àti rẹ agbára kòkòrò yìí lágọ̀ọ́ ara sílẹ̀, tí yóò sì mú kí ètò ìlera àgọ́ ara ó di ọ̀tun.

Dókítà Adéoyè sọ pé, ìwé ìwádìí ìmọ̀ tó ṣe àtìlẹ́yìn fún agbára àlùbọ́sà wọ̀nyí “sábà máa ń mẹ́hẹ nínú ìwádìí tó jinlẹ̀” ní ti àwọn ète ìsèdánwó, àkóso àti ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ ọ̀rọ̀ alálàyé. Àti pé “ó ju ìdá 90 àwọn àyẹ̀wò bẹ́ẹ̀ lọ tí a ṣe lára ènìyàn t'ó kùnà ìmúnádóko àti àìléwu.”

Even if we assume that onions are effective viral neutralizers — if they can’t get into the body or get into the lungs (in the right dose/concentration), there's no way for them to act and be effective.

K'á tiẹ̀ sọ pé àlùbọ́sà leè ṣiṣẹ́ ìpafinínfinfín àwọn kòkòrò àgọ́ ara — bí wọn kò bá leè wọ inú ara tàbí wọ inú ẹ̀dọ̀ fóró (ní ìwọ̀n oògùn àlòlẹ́ẹ̀kan/bí ó ṣe tó), kò sí bí wọn ó tí ṣe jẹ́ bí mọna wáà lágọ̀ọ́ ara.

Dókítà Adéoyè tún fi ẹ̀yìnkùnlé ọwọ́ da ọ̀rọ̀ tí ọba sọ nù pé, jíjó àti fífa òórùn èéfín àwọn ewé àgbo ìwòsàn símú’ ń ṣiṣẹ́ ìwòsàn.

Considering the breathing difficulties observed in COVID-19 patients, it will be an extremely stupid thing to reduce the air quality (oxygen) of someone whose lungs are under-performing.

Bí a bá fi ojú wo ìṣòro àìleèmí sókè-sódò dáadáa tí àwọn tó ti lu gúdẹ àrùn kòkòrò àìfojúrí kòrónà máa ń kojú, kò mọ́gbọ́n dání láti mú àdínkù bá afẹ́fẹ́ (òyì-iná) ẹni tí ẹ̀dọ̀fóró rẹ kò ṣiṣẹ́ bí ó ti yẹ.

Bí jíjó àti fífa òórùn èéfín ewé ṣe jẹ́ ọ̀kan gbòógì lára ọ̀nà ìṣèwòsàn àdáyébá tí ó gbajúmò láwùjọ ní Orílẹ̀-Èdè Nàìjíríà, èéfín náà “kò jẹ́ gẹ́gẹ́ bí egbògi orìràn,” Dókítà Adéoyè sọ fún Ohùn Àgbáyé.

Ní ti arapa lílo àwọn egbògi tí Ọọ̀ni polongo fún ìlera àwọn ènìyàn, Dókítà Adéoyè ṣe àlàyé pé, àwọn tí wọ́n ń ta ọjà irọ́ “gbogbonìṣe gẹ́gẹ́ bí oògùn apakòkòrò àìfojúrí kòrónà… Yóò túnbọ̀ jẹ́ kí àwọn ènìyàn ó máa ríkú he láwùjọ ni.”

Dókítà Adéoyè ṣe ìkìlọ̀ pé lílo àwọn àgbo  wọ̀nyí “lóró, ó sì leè ṣe okùnfà ìjàmbá àrùn pípẹ́ títí síni lágọ̀ọ́ ara”. 

Bẹ̀rẹ̀ ìtàkùrọ̀sọ náà

Òǹkọ̀wé, jọ̀wọ́ àkọsílẹ̀ ìwọlé »

Ìlànà

  • Atukọ̀ yóò ṣ'àtúnwò gbogbo ìsọsí . Máà fi ìsọsíì rẹ sílẹ̀ ju ẹ̀rìnmejì lọ tàbí kí a kà á sí iṣẹ́-ìjẹ́-tí-a-o-fẹ́.
  • Jọ̀wọ́ fi ọ̀wọ̀ fún ẹlòmíràn . A ò ní fi àṣẹ sí ìsọsí ìkórìíra, ìṣekúṣe, àti ìdojú-ìjà-kọ ẹnikẹ́ni k.