Sísọnù sínú ògbufọ̀: Ìdí tí Atúmọ̀ Google ṣe ń kùnà — nínú títúmọ̀ èdè Yorùbá — àti àwọn èdè mìíràn

Aṣàmúlò Ẹgbẹ́ Wikimedia Orílẹ̀-èdè Nàìjíríà, oṣù Ọ̀wàrà ọdún 2018 láti orí Wikimedia Commons CC.BY.2.0.

Èdè Gẹ̀ẹ́sì ti jẹ gàba lórí ìbánisọ̀rọ̀ tí ó ń wáyé ní orí ẹ̀rọ ayélukára-bí-ajere gẹ́gẹ́ bí èdè “gbogbo àgbáyé” fún ìtàkùrọ̀sọ láti ìbẹ̀rẹ̀ pẹ̀pẹ̀ ẹ̀rọ ayélujára. Nínú oṣù Èrèlé ọdún 2020, gẹ́gẹ́ bí WebTech3 ti ṣe fi hàn, ìdajì ibùdó ìtakùn àgbáyé tó wà lórí ayélujára ni a kọ ní èdè Gẹ̀ẹ́sì.

Àmọ́ bí ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn tí ó ń sọ oríṣìíríṣìí èdè àgbáyé ṣe ń bọ́ sórí ayélukára-bí-ajere, ó ṣẹ́ ẹtà ìjà fún èdè ẹni — ìráàyè sí ìṣògbufọ̀ sí onírúurú èdè tí yóò ṣẹ̀ ní mọnawáà.

Ọ̀pọ̀lọpọ̀ iléeṣẹ́ onímọ̀ ẹ̀rọ ti ṣe iṣẹ́ ribiribi ní ti ìṣàkọsílẹ̀ àwọn ọ̀rọ̀ tí kì í ṣe èdè Gẹ̀ẹ́sì sórí ayélujára, tí ó ń ṣe olùlànà onírúurú èdè lórí ẹ̀rọ ayárabíàṣá lọ́nà ìgbàlódé. Google, Yoruba Names, Masakhane MT àti ALC jẹ́ àpẹẹrẹ àwọn iléeṣẹ́ ńlá àti àwọn iléeṣẹ́ kéréje tí ó ṣẹ̀ṣẹ̀ bẹ̀rẹ̀ tí ó ti mú ìmọ̀-ẹ̀rọ ṣiṣẹ́ pọ̀ pẹ̀lú àwọn èdè tí kì í ṣe èdè Gẹ̀ẹ́sì.

Kí oṣù Èrèlé ọdún 2020 ó tó tẹnu bepo, Google filọ̀ wípé òun yóò fi èdè tuntun márùn-ún kún iṣẹ́ Atúmọ̀ Google rẹ̀, àwọn èdè náà ni Kinyarwanda, Uighur, Tatar, Turkmen àti Odia, lẹ́yìn ìsinmi ọdún mẹ́rin tí wọ́n fi èdè tuntun kún un kẹ́yìn.

Ọkùnrin kan ń wò bí ẹni tí ó nídààmú nígbà tí ó ń ka gbólóhùn ọ̀rọ̀ lórí ayélujára. Àwòránlláti ọwọ́ Ọládiméjì Ajégbilẹ̀, àṣẹ-àtúnlò láti orí Pexels.

Àmọ́ ṣe o ti ṣíra tẹ àṣàyàn ìtumọ̀ rí tí ó ṣàkíyèsí wípé, bákan, ló dára jù lọ? Bákan náà, ló kù díẹ̀ káàtó, kò ṣe déédéé?

Orísìírísìí àríyànjiyàn àti ìṣòro ló máa ń wáyé bí ó bá kan irú ìtumọ̀ èdè báyìí àti rírí i lò.

Twitter máa ń ṣe ìtumọ̀ èdè Yorùbá sí èdè Gẹ̀ẹ́sì nípasẹ̀ lílo Atúmọ̀ Google bí ó ti ṣe fàyè gbà wọ́n, tí àbájáde rẹ̀ sì kù díẹ̀ káàtó nígbàgbogbo — tí àwọn ọ̀rọ̀ kọ̀ọ̀kan sì ṣe déédéé.

Ohun tí ó fa àwọn ìpeníjà wọ̀nyí ó ju pé orí ayélujára ni àwọn iléeṣẹ́ onímọ̀ ẹ̀rọ ti máa ń ṣe àkójọ èdè wọn for tí wọ́n ń fi ṣe ògbufọ̀ gbólóhùn ọ̀rọ̀. Àwọn àkójọ gbólóhùn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí lè ṣiṣẹ́ fún àwọn èdè kan, àmọ́ èdè bí i Yorùbá àti Ìgbò, jẹ́ èdè méjì ní orílẹ̀-èdè Nàìjíríà, tí ìpèníjà yìí bá, látàrí àìpọ̀tó gbólóhùn ọ̀rọ̀ àti gbólóhùn tí a ò yán lórílábẹ́ dáadáa tí yóò tọ́ka sí ìró ohùn.

Láti fèsì sí ohun tí ó fa sábàbí tí ó fi gba Google ní ọdún mẹ́rin kí ó tó ṣe àfikún èdè tuntun márùn-ún kún tilẹ̀, agbẹnusọ iléeṣẹ́ náà ṣe ìṣípayá:

Orí ìtakùn àgbáyé ni Atúmọ̀ Google ti máa ń ṣa gbólóhùn tí a ti túmọ̀ jọ, àmọ́ bí èdè kò bá ní gbólóhùn ọ̀rọ̀ tí ó pọ̀ tó lórí ayélujára, ó nira fún ẹ̀rọ wa láti ṣe àtìlẹ́yìn tí ó lákaakì fún irú àwọn èdè bẹ́ẹ̀… Síbẹ̀, látàrí ìlọsíwájú àbùdá kíkọ́ ẹ̀rọ lẹ́kọ̀ọ́ wa, àti àwọn aṣiṣẹ́ Ìtumọ̀ Google lọ́fẹ̀ẹ́, ecent advances in our machine a ti fi àtìlẹ́yìn fún àwọn èdè wọ̀nyí.

Bákan náà, ọ̀pọ̀ ènìyàn ni kò mọ bí a ṣe ń kọ ọ̀rọ̀ dájúdánu — tàbí pípe ọmọ-ọ̀rọ̀ — inú àwọn èdè wọ̀nyí. Torí náà, ògbufọ̀ tí ó kúnjú òṣùwọ̀n kò jẹ́ àkópọ̀ nítorí kò sí bí a ṣe lè dá àwọn àṣìṣe wọ̀nyí mọ̀.

Púpọ̀ nínú ògbufọ̀ tí ẹ̀rọ ṣe ni kò ní ìtumọ̀, pàápàá jù lọ àwọn gbólóhùn tí ó rọ̀ mọ́ àṣà tí ó ní ju ìtúmọ̀ kan ṣoṣo lọ. Fún àpẹẹrẹ, gbólóhùn Yorùbá bí i ayaba àti ọbabìnrin ní ìtumọ̀ tó yàtọ̀.  Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ẹ̀rọ ní í máa tú ìmọ̀ gbólóhùn méjèèjì sí “queen.” Síbẹ̀, tí a bá ti ọ̀nà ìṣe-àti-àsà wò ó, ó ṣe kókó láti sọ wí pé ìtúmọ̀ ayaba and ọbabìnrin yàtọ̀ síra wọn: Ọbabìnrin túmọ̀ sí “queen” lédè Gẹ̀ẹ́sì nígbà tí ayaba jẹ́ “wife of the king.”

Pẹ̀lú àwọn àìṣedéédéé wọ̀nyí, ìmọ̀-ẹ̀rọ ti ṣe ìrànwọ́ fún ìdàgbàsókè àwọn èdè Ilẹ̀-Adúláwọ̀ lórí àwọn gbàgede orí ayélujára, tí ó ti mú ìṣẹ̀dá ọ̀rọ̀ tuntun wáyé. Èdè Ilẹ̀-Adúláwọ̀ ti gòkè àgbà látàrí àwọn lílo àwọn ẹ̀rọ ìgbàlódé tuntun bí i ẹ̀rọ-ìléwọ́ àti ẹ̀rọ ọpọ́n ayárabíàṣá, tí ó sì ń bí àwọn gbólóhùn tuntun tí a fi ń pe àwọn irinṣẹ́ ìmọ̀-ẹ̀rọ tuntun wọ̀nyí. Èyí sì ti fẹ bí a ti ṣe ń lo àwọn èdè wọ̀nyí lójú.

Látàrí àwọn ẹ̀rọ tuntun wọ̀nyí, ìpèdè ọ̀pọ̀lọpọ̀ èdè Ilẹ̀-Adúláwọ̀ ti lé kún sí i. Fún àpẹẹrẹ, èdè Yorùbá ní àwọn gbólóhùn tí ó ní ṣe pẹ̀lú ìmọ̀-ẹ̀rọ bí i ẹ̀rọ-amúlétutù (“air conditioner”), erọ-ìbánisọ̀rọ̀ (“phone”) and ẹ̀rọ-ìlọta (“grinder”). Ẹ̀wẹ̀wẹ̀, èdè Igbo náà ní ọ̀rọ̀ bí i ekwè nti (“telephone”) àti ugbọ̀ àlà (“vehicle”). A ṣẹ̀dá àwọn orúkọ yìí ní ìbámu pẹ̀lú iṣẹ́ tí wọ́n ń ṣe.

Nínú ẹ̀kọ́ ìmọ̀ ìgbóhùnsáfẹ́fẹ́ àti ètò ìpolówó ọjà lédè Yorùbá, àwọn akẹ́kọ̀ọ́ ti kọ́ wí pé ẹ̀rọ-amóhùnmáwòrán ni oọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn ń pe TV. Ìṣẹ̀dá ọ̀rọ̀ yìí fa àwọn onírúurú ìbéèrè àti èrò — àwọn akẹ́kọ̀ọ́ kan jiyàn wí pé a lè pe ẹ̀rọ-ayàwòrán náà ní ẹ̀rọ-amóhùnmáwòrán nítorí iṣẹ́ tí wọ́n ń ṣe.

Àwọn ìpèníjà t'ó tara ìmọ̀-ẹ̀rọ wá yìí ni yóò mú ìdàgbàsókè bá èdè — ó máa ń fa àròjìnlẹ̀ fún ìgbéga èdè àti ìmọ̀-ẹ̀rọ.

Lọ́dún 2019, gẹ́gẹ́ bí CNN ti ṣe ròyìn, Google ṣí ibiṣẹ́ ìwádìí AI àkọ́kọ́ irú ẹ̀ sí Accra, Ghana, tí ó ń lépa láti mú kí “Atúmọ̀ Google ó gba àwọn èdè Ilẹ̀-Adúláwọ̀ jọ kí ó lọ geere”. Onímọ̀ ìjìnlẹ̀ nípa iṣẹ́ ìwádìí Moustapha Cisse, tó jẹ́ olórí iṣẹ́ Google AI ní Ilẹ̀-Adúláwọ̀, nígbàgbọ́ wí pé ó tọ́ sí “ilẹ̀ tí ó ní ju ẹ̀ka-èdè 2,000 lọ láti jẹ́ àǹfààní iṣẹ́,” — CNN jábọ̀.

Mozilla àti BMZ kéde àjùmọ̀ṣe wọn láti ṣe agbátẹrù iṣẹ́ àkànṣe tí ó dá fìrìgbagbòó lórí ìmọ̀-ẹ̀rọ alohùn fún thei èdè Ilẹ̀-Adúláwọ̀. Pẹ̀lú àwọn iṣẹ́ àtinudá bí eléyìí, ọjọ́ iwájú ìwádìí èdè Ilẹ̀-Adúláwọ̀ dára.

Bẹ̀rẹ̀ ìtàkùrọ̀sọ náà

Òǹkọ̀wé, jọ̀wọ́ àkọsílẹ̀ ìwọlé »

Ìlànà

  • Atukọ̀ yóò ṣ'àtúnwò gbogbo ìsọsí . Máà fi ìsọsíì rẹ sílẹ̀ ju ẹ̀rìnmejì lọ tàbí kí a kà á sí iṣẹ́-ìjẹ́-tí-a-o-fẹ́.
  • Jọ̀wọ́ fi ọ̀wọ̀ fún ẹlòmíràn . A ò ní fi àṣẹ sí ìsọsí ìkórìíra, ìṣekúṣe, àti ìdojú-ìjà-kọ ẹnikẹ́ni k.