Kò sí irọ́ kan níbẹ̀ wípé Ẹ̀rọ-ìgbóhùnsáfẹ́fẹ́ jẹ́ ohun èlò ìgbéròyìn ká tí ó ti ṣiṣẹ́ ribiribi fún ìdàgbàsókè àgbà-ńlá ayé. Àwọn Yorùbá ní, “kí a gbé oyè fún olóyè, kí á gbádé fún ẹni tí ó ni adé”, èyí ló mú Àjọ Ìṣọ̀kan Àgbáyé tí ó ń rí sí Ètò Ẹ̀kọ́, Ìmọ̀ Ìjìnlẹ̀ àti Àṣà (UNESCO) ya ọjọ́ 13 oṣù Èrèlé sọ́tọ̀ gẹ́gẹ́ bíi Ọjọ́ Ẹ̀rọ-ìgbóhùnsáfẹ́fẹ́ Àgbáyé.
UNESCO yà ọjọ́ yìí sọ́tọ̀ láti ṣí ojú àwọn ènìyàn sí ipa tí ẹ̀rọ-ìgbóhùnsáfẹ́fẹ́ ń kó ní ìgbésí ayé — tí ó jẹ́ ọ̀nà ìgbéròyìnká tí kò hàn, tí ó sì ṣe é gbé kiri.
Àwọn sọ̀rọ̀sọ̀rọ̀-ọ orílẹ̀-èdèe Nàìjíríà darapọ̀ mọ́ àwọn sọ̀rọ̀sọ̀rọ̀ orí ẹ̀rọ-ìgbóhùnsáfẹ́fẹ́ lágbàáyé láti sààmì ọjọ́ náà àti láti fọn rere iṣẹ́ ìdàgbàsókè àgbà-ńlá ayé tí ẹ̀rọ-ìgbóhùnsáfẹ́fẹ́ ń ṣe.
“Ẹ̀rọ ìgbéròyìnjáde ń yí bí a ti ṣe ń ṣe nǹkan padà, síbẹ̀síbẹ̀ ẹ̀rọ-ìgbóhùnsáfẹ́fẹ́ ṣì ni ó ṣì wúlò jù lọ fún ọ̀gọ̀rọ̀ ènìyàn láti gbọ́ ìròyìn ohun tí ó ń lọ lọ́wọ́, òhun ṣì ni ohun èlò tí ó máa ń lapa tí ó pọ̀ jù nínúu gbogbo ọ̀nà tí àwọn oníròyìn máa ń lò nítorí ó lágbára láti dé ibi jínjìn àti ìgbèríko tí ó jẹ́ ibi kọ́lọ́fín… ” Àlùfáà George Bako sọ̀rọ̀, nígbà tí ó ń ṣíde ètò níbi Àpérò Ọjọ́ Ẹ̀rọ-ìgbóhùnsáfẹ́fẹ́ Àgbáyé. Bako ti fi ìgbà kan rí jẹ́ Ọ̀gá-Àgbà pátápátá fún Iléeṣẹ́ Alájọṣepọ̀ Ìgbóhùnsáfẹ́fẹ́ Ìjọba Àpapọ̀ Orílẹ̀-èdèe Nàìjíríà (FRCN).
FRCN — tí a tún ń pè ní Radio Nigeria — ni ó léwájú nínúu iṣẹ́ẹ ẹ̀rọ-ìgbóhùnsáfẹ́fẹ́ ní orílẹ̀-èdèe Nàìjíríà, pẹ̀lú ẹgbẹlẹmùkù àwọn olólùfẹ́ tí ó ń gbọ́ ọ jákèjádò Ìpínlẹ̀ Èkó th oríi ìkànnì mẹ́ta ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀, tí orúkọ wọ́n jẹ́: Radio One 103.5 FM, Metro 97.7 FM àti aláràa gbàyídá inúu wọn Bond 92.9 FM.
Ọ̀kọ̀ọ̀kan ìkànnì yìí — ní àwọn olólùfẹ́ẹ rẹ̀ àti àwọn tí ó ń gbọ́ ọ — tí ó ń fi èdèe Gẹ̀ẹ́sì, Àdàlùmọ́-Gẹ̀ẹ́sì, Hausa, Igbo àti èdèe Yorùbá.
Ẹ̀rọ-ìgbóhùnsáfẹ́fẹ́ ṣì ni ọ̀nà tí ó dára jù lọ fún ìfọ́nká ìròyìn ní Nàìjíríà. FM (Ìgbóhùnsáfẹ́fẹ́ Aláṣeéyípadà) ni ó wọ́pọ̀ jù lọ, AM (Ìgbóhùnsáfẹ́fẹ́ Títóbi) tẹ̀lé e gbọ̀ngbọ̀ngbọn, gẹ́gẹ́ bí iléeṣẹ́ Media Landscape ti European Journalism Centre ní i lákọsílẹ̀ — tí ìgbóhùnsáfẹ́fẹ́ orí ẹ̀rọ ayélujára sì ti di gbajúmọ̀.
Ní ọdún-un 2019, Nigeria Diary Radio Stations Ratings ti oṣù Ògún fi hàn wípé Bond FM ló di ipò kìíní mú ní Ìpínlẹ̀ Èkó gẹ́gẹ́ bí ìkànnì tí ó ní olùgbọ́ jù lọ.
Látàrí ayẹyẹ náà, àwọn sọ̀rọ̀sọ̀rọ̀ jákèjádò orílẹ̀-èdèe Nàìjíríà fi gbàgede Twitter kéde ìfẹ́ ẹ wọn fún rédíò:
Àwọn òṣìṣẹ́ẹ Spider Radio (102.7) tí ó jẹ́ Rédíò Ọgbà Ilé Ìwé Gbogbonìṣe Kaduna, Ìpínlẹ̀ Kaduna, orílẹ̀-èdèe Nàìjíríà fún pọ̀pọ̀ṣìnṣìn Àyájọ́ Ọjọ́ Ẹ̀rọ-ìgbóhùnsáfẹ́fẹ́ Àgbáyé ọdún-un 2020 pic.twitter.com/nPP7HDpMY6
— Auwal (@Kauwal23) February ọjọ́ 13, Oṣù Èrèlé ọdún-un 2020
Àwọn òṣìṣẹ́ẹ Spider Radio (102.7) tí ó jẹ́ Rédíò Ọgbà Ilé Ìwé Gbogbonìṣe Kaduna, Ìpínlẹ̀ Kaduna, orílẹ̀-èdèe Nàìjíríà fún pọ̀pọ̀ṣìnṣìn Àyájọ́ Ọjọ́ Ẹ̀rọ-ìgbóhùnsáfẹ́fẹ́ Àgbáyé ọdún-un 2020 pic.twitter.com/nPP7HDpMY6
— Auwal (@Kauwal23) February ọjọ́ 13, Oṣù Èrèlé ọdún-un 2020
Dan Manjang, alákòóso fún oọ̀rọ̀ ìgbóhùnsáfẹ́fẹ́ àti ìkéde ti Ìpínlẹ̀ Plateau, kí àwọn sọ̀rọ̀sọ̀rọ̀ níbi gbogbo fún “gbogbo akitiyan, ìgbìyànjú àti àsìkò” tí wọ́n fi ń kéde ìròyìn àti onírúurú ètò akọ́nilọ́gbọ́n:
Mo kí gbogbo iléeṣẹ́ ẹ̀rọ-ìgbóhùnsáfẹ́fẹ́ tí ó wà ní ìpínlẹ̀ Plateau, orílẹ̀-èdèe Nàìjíríà àti kárí ayé, iṣẹ́ ribiribi ni rédíò ń ṣe níbí ìdàgbàsókè orílẹ̀-èdè, ẹ ṣeun fún akitiyan, ìgbìyànjú àti àsìkò tí ẹ̀ ń fi sílẹ̀ fún ìkéde ìròyìn àti onírúurú ètò akọ́nilọ́gbọ́n. #WorldRadioDay #HappyWorldRadioDay
— Dan Manjang (@DanManjang1) Ọjọ́ 13, oṣù Èrèlé ọdún-un 2020
Mo kí gbogbo iléeṣẹ́ ẹ̀rọ-ìgbóhùnsáfẹ́fẹ́ tí ó wà ní ìpínlẹ̀ Plateau, orílẹ̀-èdèe Nàìjíríà àti kárí ayé, iṣẹ́ ribiribi ni rédíò ń ṣe níbí ìdàgbàsókè orílẹ̀-èdè, ẹ ṣeun fún akitiyan, ìyànjú àti àsìkò tí ẹ̀ ń fi sílẹ̀ fún ìkéde ìròyìn àti onírúurú ètò akọ́nilọ́gbọ́n. #WorldRadioDay #HappyWorldRadioDay
— Dan Manjang (@DanManjang1) Ọjọ́ 13, oṣù Èrèlé ọdún-un 2020
Ìtàn-àkọsílẹ̀ ẹ̀rọ-ìgbóhùnsáfẹ́fẹ́ ní Nàìjíríá
Ìgbóhùnsáfẹ́fẹ́ ní Nàìjíríà bẹ̀rẹ̀ ní ọdún-un 1933 pẹ̀lú Ìtàn káàkiri Rédíò Ìjọba Amúnisìn (RDS), tí ó jẹ́ wípé gbé àwọn ẹ̀rọ-gbohùngbohùn sí ìta gbangba níbi tí àwọn ènìyàn yóò ti tẹ́tí sí ìròyìn òkèèrè ti Iléeṣẹ́ Ìgbóhùnsáfẹ́fẹ́ Ìjọba Gẹ̀ẹ́sì.
Ní ọdún-un 1950, RDS gbé aṣọ tuntun wọ̀ — ó di Iléeṣẹ́ Ìgbóhùnsáfẹ́fẹ́ Orílẹ̀-èdèe Nàìjíríà (NBS) — nígbà tí ó ṣe, ó di Iléeṣẹ́ Alájọṣepọ̀ Ìgbóhùnsáfẹ́fẹ́ Orílẹ̀-èdèe Nàìjíríà (NBC), pẹ̀lú ìkànnì ìgbóhùnsáfẹ́fẹ́ ní àwọn ẹ̀ka tí Nàìjíríà pín sí. NBC pàpà paradà di Iléeṣẹ́ Alájọṣepọ̀ Ìgbóhùnsáfẹ́fẹ́ Ìjọba Àpapọ̀ Orílẹ̀-èdèe Nàìjíríà (FRCN) lọ́dún-un 1978.
“Iléeṣẹ́ Rédíò àkọ́kọ́ ní Nàìjíríà tí a dá sílẹ̀ ní Ìbàdàn ní ọdún-un 1939. Ìkànnì-i Kano ló tẹ̀lée ní 1944,” gẹ́gẹ́ bí iléeṣẹ́ ìròyìn oríaayélujára Legit ti ṣe ṣàlàyé. Legit ṣàlàyé wípé RayPower FM, ni rédíò aládàáni àkọ́kọ́ ní orílẹ̀-èdèe Nàìjíríà, ọdún-un 1994 ni a dá a sílẹ̀, nígbàtí ó mmáa fi di ọdún-un 2007, àwọn olùgbọ́ ti ń gbọ́ ìròyìn kárí ayé.
Rédíò ti ṣiṣẹ́ gẹ́gẹ́ bíi ohun èlò àyẹ̀wò fún àwọn tí ó wà nípò àṣẹ, ìfìdírinlẹ̀ òfin àti ìpèsè ìkéde tí yóò lapa dáadáa lára àwọn ènìyàn.
Ní ọdún-un 2019, Ìgbìmọ̀ Ètò Ìgbóhùnsáfẹ́fẹ́ Orílẹ̀-èdèe Nàìjíríà (NBC) ṣán African Independent Television àti RayPower FM pa nítorí wípé ó ṣe àgbéjáde ètò tí ó tako ìjọba. Bákan náà ní ọdún- 2019, Jay FM tíó wà ní Port Harcourt di ṣíṣánpa lẹ́yìn tí a fi ẹ̀sùn ìtako ìjọba kàn án.
Rédíò tí ó ń mú ìsọdọ̀kan àti ìgbéga wáyé
UNESCO rọ ìlú gbogbo láti sààmì ayẹyẹ Ọjọ́ Ẹ̀rọ-ìgbóhùnsáfẹ́fẹ́ Àgbáyé nípasẹ̀ ṣíṣe àwọn ètò àjọṣe pẹ̀lú iléeṣẹ́ ìgbóhùnsáfẹ́fẹ́, iléeṣẹ́ ìjọba, iléeṣẹ́ aládàáni àti iléeṣẹ́ tí kì í ṣe ti ìjọba kárí ayé.
Àkórí Àyájọ́ Ọjọ́ Ẹ̀rọ-ìgbóhùnsáfẹ́fẹ́ Àgbáyé ti ọdún yìí, tí í ṣe ìkẹrìnlá irú ẹ̀ ni “Ẹ̀rọ-ìgbóhùnsáfẹ́fẹ́ àti Onírúurú.”
Rédíò ẹlẹ́rọ-amìtìtì orílẹ̀-èdèe Nàìjíríà ń jí gìrì sí ọ̀rọ̀ àṣàròo rẹ̀ tí ó ní “ìgbésókè àwọn ènìyàn àti ṣíṣe ìsọdọ̀kan ètò afúnilóye, akọ́nilẹ́kọ̀ọ́ àti aṣínilétí tó ń ró àwọn ọmọ orílẹ̀-èdèe Nàìjíríà lágbára láti ní ìfẹ́ ìlú ẹni.
Èyí wúlò ní àsìkò tí ìpínyà àti ìyapa ẹ̀yà, àìbalẹ̀-ọkàn látàrí ọ̀rọ̀ òṣèlú tó ń kojúu orílẹ̀-èdèe Nàìjíríà. Ìpín ipò Ìlú tí ó rọrùn láti fọ́ ọdún-un 2019 fi Nàìjíríà sí ipò kẹrìnlá lágbàáyé, ìkẹsàn-án ní Ilẹ̀-Adúláwọ̀. Láti ọdún-un 2011, Boko Haram, ajìjàǹgbara ẹ̀sìn Ìmàle ní Ìlà-oòrùn àréwá orílẹ̀-èdèe Nàìjíríà, ti fi ẹ̀rù sí ọkàn àwọn ènìyàn àti bí àwọn ìkọlù tó rorò wọ́n ti ṣe fa ikú láì rò tẹ́lẹ̀ ìpí àwọn ènìyàn, tí ọ̀pọ̀ọ́ sì ti di àwátì.
Kà síwájú sí i: Nàìjíríà: Ìlú tí ó kùnà — òótọ́ tàbí ìwòye?
Ní ìtẹ̀síwájú ìgbésókè orílẹ̀-èdèe Nàìjíríà, àwọn aláṣẹ FRCN Ẹ̀ka ti Èkó ṣe àgbékalẹ̀ ọkànòjọ̀kan ètò láti sààmì Àyájọ́ Ọjọ́ Ẹ̀rọ-ìgbóhùnsáfẹ́fẹ́ Àgbáyé ọdún-un 2020.
Eré gbogboó bẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú ìdíje àròkọ ọlọ́rọ̀ 1,200 tí ó dá lóríi “ìdí tí mo fi nífẹ̀ẹ́ sí láti máa gbọ́ rédíò” fún àwọn akẹ́kọ̀ọ́ iléèwé gíga. Àwọn akẹ́kọ̀ọ́ ìmọ̀ iṣẹ́ ìròyìn náà ṣe ètò alálàyé oníṣẹ̀ẹ́jú 5 tí ó dá fìrìgbagbòó lóríi pàtàkìi ẹ̀rọ-ìgbóhùnsáfẹ́fẹ́ fún ìmúṣẹ àwọn ìlépa ìmúdúró ìdàgbàsókè. Àwọn àkópa méjì ló jáwé olúborí.
Olúborí ìdíje àròkọ Ìlọ̀rí Olúwatóbi ti iléèwé Mater Christi Catholic Girls’ High School, Ìgede Èkìtì, Ìpínlẹ̀ Èkìtì, mú u wá sí ìrántí ìgbà àkọ́kọ́ tí òùn-ún ṣalábàápàdée rédíò nígbà tí òùn-ún wà ní ọmọ ọdún 5:
Ó dà bí ẹni pé ọmọ ọdún 5 ni mí nígbà tí mo kọ́kọ́ ní ẹ̀rọ-ìgbóhùnsáfẹ́fẹ́ẹ̀ mi. … Mo tẹ àwọn ohun-àtẹ̀-àṣẹ ara rẹ̀, ó sì tàn. Ìyàlẹ́nu ló jẹ́ fún mi bí mo ṣe ń gbọ́ ohùn tí ó ń ti inúu “àpótí” yìí jáde tí mo sì rò wípé àwọn èèyàn ló wà nínúu rẹ̀. Ẹ̀rú bá mi mo sì béèrè lọ́wọ́ọ bàbáà mi ohun tí ó jẹ́, ó sì ṣàlàyé ohun tí rédíò jẹ́ fún mi…”
Ní ọjọ́ 12 oṣù Èrèlé, àwọn akẹ́kọ̀ọ́ ilé ẹ̀kọ́ gíga, akẹ́kọ̀ọ́ ìmọ̀ iṣẹ́ ìròyìn, ọ̀jẹ̀ sọ̀rọ̀sọ̀rọ̀ àti àwọn alẹ́nulọ́rọ̀ nínú iṣẹ́ ìròyìn àti àwọn olólùfẹ́ẹ̀ rédíò péjúpésẹ̀ sí Lekki Coliseum ní Èkó fún àpérò láti jíròrò nípa pàtàkìi ẹ̀rọ-ìgbóhùnsáfẹ́fẹ́ fún ìdàgbàsókè.
Ní ìgbàtí ọjọ́ rọ̀, àwọn ògbóǹtarìgì sọ̀rọ̀sọ̀rọ̀, àwọn aṣojú the Ọba Èkó, Ọ̀túnba Gani Adams, Ààrẹ Ọ̀nà Kakanfò ilẹ̀ẹ Yorùbá àti àwọn àlejò mìíràn péjọ sí Lekki Coliseum fún àpèjẹ alẹ́ àti ìfàmìẹ̀yẹ dánilọ́lá Àyájọ́ Ọjọ́ Ẹ̀rọ-ìgbóhùnsáfẹ́fẹ́ Àgbáyé.
Àwọn àgbà ọ̀jẹ̀ẹ sọ̀rọ̀sọ̀rọ̀ bíi Cordelia Okpei àti àwọn tó kù wá sí ayẹyẹ náà. Àmì-ẹ̀yẹ̀ẹ̀ fún akíkanjú lẹ́nu iṣẹ́ àti ìṣiṣẹ́sìnlú lọ sí ọ̀dọ̀ àwọn ẹni tí ó tọ́ sí.
Ọ̀kan-ò-jọ̀kan ètò náà wá sópin pẹ̀lú ìṣójú òpó sílẹ̀ láti gba ìpè àwọn olùgbọ́ wọlé sórí afẹ́fẹ́, níbi tí wọ́n ti ní kí àwọn ènìyàn ó sọ wípé “ẹ kú Àyájọ́ Ọjọ́ Ẹ̀rọ-ìgbóhùnsáfẹ́fẹ́ Àgbáyé” ní àwọn onírúurú ọ̀kan-ò-jọ̀kan èdè àti ahọ́n:
Kò sẹ́ni tí kò kópa nínú ayẹyẹ náà. Ohùn àwọn ikọ̀ Ohùn Àgbáyé náà bọ́ sórí afẹ́fẹ́ ní orí ìkànnì Metro 97.7FM. Àwọn sọ̀rọ̀sọ̀rọ̀ tí ó ti fẹ̀yìntì ló ka ìròyìn tí wọ́n sì tọ́kùn ètò.
Àkọ́kọ́ irú ‘ẹ̀ ni Àyájọ́ Ọjọ́ Ẹ̀rọ-ìgbóhùnsáfẹ́fẹ́ Rédíò Orílẹ̀-èdèe Nàìjíríà ọdún-un 2020 àmọ́ àwọn òṣìṣẹ́ àti olólùfẹ́ẹ̀ rédíò lérò wípé ayẹyẹ náà yóò máa wáyé lọ́dọọdún.