Ọ̀rọ̀ àyálò nínú èdè Yorùbá: Bí èdè ṣe yí padà

Àkàrà tàbí beans cake ní Nàìjíríà jẹ́ oúnjẹ àárọ̀ ní Nàìjíríà, ọjọ́ 11, oṣù kéje, ọdún 2013. Àwòrán láti ọwọ́ Atimukoh láti orí i Wikimedia Commons, àṣẹ CC BY 2.0.

Àjọṣepọ̀ láàárín onírúurú èdè ti wà láti ayébáyé. Fún àkàwé, kí á wo gbólóhùn bí i “restaurant,” tí ó jẹ́ ọ̀rọ̀ tí a yá láti inú èdè Faransé wá sínú èdè Gẹ̀ẹ́sì. Lóde òní, ọ̀rọ̀-àyálò yìí —  ìyẹn gbólóhùn tí a gbà lò láti inú èdè kan sí inú èdè mìíràn láì tú ìmọ̀ rẹ̀ — kò l'óǹkà nínú èdè Gẹ̀ẹ́sì àfi bí ẹni pé kì í ṣe ọ̀rọ̀ tí a yá lò.

Àwọn èdè àyálò wọ̀nyí wáyé látàrí àbápàdé onírúurú ènìyàn kárí ayé, bí wọ́n ṣe ń ṣíkiri, ṣe ọrọ̀ Ajé, àti káràkátà. Látàrí ìtàkùrọ̀sọ tí ó wáyé láàárín àwọn onírúurú ènìyàn wọ̀nyí, èdè wọnú èdè, gbólóhùn àti àpólà ọ̀rọ̀ di àyálò.

Ìṣẹ̀lẹ̀ yìí kò yọ ìran Yorùbá sílẹ̀. Ó tó ẹgbẹẹgbẹ̀rún ènìyàn 40 tíó ń fọ èdè Yorùbá ní orílẹ̀ èdè Nàìjíríà, irú èdè Yorùbá ti dàpọ̀ mọ́ ṣapala èdè Gẹ̀ẹ́sì, tí í ṣe èdè ìjọba amúnisìn àná láti ọdún 1914 sí 1960.

Ó tó ìdajì gbólóhùn èdè Gẹ̀ẹ́sì tí a yà lò nínú èdè Yorùbá. Kí a wo ọ̀rọ̀ bí i “cup.” Ó di kó̩ò̩pù. A pe “phone” ní fóònù, “ball” di bó̩ò̩lù, “television” ni te̩lifís̩ó̩ò̩nù, àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ.

Àwọn gbólóhùn “àyálò” wọ̀nyí mú èdè Yorùbá fẹjú sí i. Bákan náà ni àwọn ọ̀rọ̀ àyálò inú èdè Hausa tí àwọn ẹgbẹẹgbẹ̀rún 44 ènìyàn ní Àríwá ilẹ̀ Nàìjíríà ń sọ lọ sua. Èdè yìí yá ọ̀kẹ́ àìmọye ọ̀rọ̀ lò láti inú èdè Lárúbáwá, àwọn ọ̀rọ̀ bí i àlùbáríkà (“ìbùkún”), àlbásà (“àlùbọ́sà”) àti wàhálà (“ìyọnu”).

Ohun tí ó jẹ́ ìwúrí ní ti àwọn ọ̀rọ̀ àyálò nínú èdè Yorùbá ni bí àwọn ènìyàn ṣe ń lò wọ́n nínú ìtàkùrọ̀sọ lójoojúmọ́ bí wọ́n ṣe ń ṣàn wọ inú èdè náà. Wà á gbọ́ gbólóhùn bí i, m yn mú bó̩ò̩lu è̩  tàbí “Help the child take the ball” lédè Gẹ̀ẹ́sì. Adi, ọmọ-ọ̀rọ̀ tí a falà sí lábẹ́ bó̩ò̩lu jẹ́ tiwantiwa nínú èdè Yorùbá, àwọn aṣàfọ̀ mọ bí wọ́n ṣe ń lò ó.

Ìpèníjà kan tí èdè Yorùbá ní nípa ti ọ̀rọ̀ àyálò ò ju ti ògbufọ̀ ọ̀rọ̀ wuuru tí àwọn aṣàfọ̀ èdè Yorùbá máa ń ṣe láti túmọ̀ àwọn gbólóhùn èdè Yorùbá sí ti Gẹ̀ẹ́sì tí wọ́n máa ń lò nínú ìpèdè dípò ojúlówó èdè Yorùbá. Fún àpẹẹrẹ, àkàrà  — tí àwọn ọmọ Yorùbá ti túmọ̀ sí bean cake — pàápàá nínú ìfọ̀rọ̀jomitoro-ọ̀rọ̀ pẹ̀lú àlejò.

Lílo ọ̀rọ̀ ní èdè pọ́nbélé máa ń mú kí àṣà — ó gbòòrò — tí yóò sí máa jẹ́ kí èdè ó di ìtẹ́wọ́gbà. Bí a bá wò ó báyìí, kò s'ẹ́ni jẹ́ pe sushi Japan lórúkọ mìíràn — sushi ni sushi ń jẹ́.

Bí èyí bá rí bẹ́ẹ̀ fún àwọn ọ̀rọ̀ Yorùbá náà, èdè àti àṣà rẹ̀, yóò gbilẹ̀ kọjá orílẹ̀-èdè Nàìjíríà àti ibi tí wọ́n ti ń fọ èdè Yorùbá kárí ayé. Fún àpẹẹrẹ, àmàlà jẹ́ oúnjẹ tí ó ilẹ̀ Yorùbá lókìkí, pàápàá ní òkè òkun. Gbólóhùn yìí ti rá pálá wọnú ìlò ọ̀rọ̀ èdè mìíràn bí àwọn aṣàfọ̀ Yorùbá bá tẹnu mọ́ ọn. Títúmọ̀ rẹ̀ sí “yam flour” dín agbára ìpèdè náà kù — yóò sọ “ipò Yorùbá nù.”

Bí a bá wo gbólóhùn èdè Gẹ̀ẹ́sì tí a yí padà sí èdè Yorùbá “fanimorious,” tí ó ti ń lókìkí tí ó sì ti wà nínú Ìwé Ìtumọ̀ Ìgbàlódé. Ó túmọ̀ sí “bójúmu,” tàbí “rẹwà,” tí ó súyọ láti fanimó̩ra tí í ṣe gbólóhùn Yorùbá.

Èyí f'ara pẹ́ ìbáṣepọ̀ fonọ́lọ́jì àti mọfọ́lọ́jì: èdè Yorùbá kì í fàyè gba ìhunpọ̀ kọ̀nsónántì àti kí ọ̀rọ̀ parí pẹ̀lú kọ̀nsónántì. Torí ìdí èyí, a fi àfòmọ́ ìparí -ious èdè Gẹ̀ẹ́sì kún ọ̀rọ̀ ìpìlẹ̀ Yorùbá. Síbẹ̀, òtítọ́ farahàn wípé láti ara èdè Yorùbá ni ó ti sú yọ. Ìgbéga ni èyí jẹ́ fún Yor Yorùbá.

Ní kò pẹ́ kò pẹ́ yìí, ọ̀gọ̀rọ̀ èdè Gẹ̀ẹ́sì bí a ti ṣe ń lò ó ní Nàìjíríà di àfikún nínú ìwé ìtúmọ̀ èdè Gẹ̀ẹ́sì ti Oxford.

Ọpọ́n èdè Yorùbá yóò sún síwájú bí àwọn tó ń fọ èdè náà bá lọ́wọ́ sí ìdàgbàsókè rẹ̀; ìlò rẹ̀ nínú iṣẹ́ ìkọ̀ròyìn pọn dandan ní ìbámu pẹ̀lú bí ayé ṣe ń lu jára wọn bí ajere lóde òní.

Ní ìparí, èyí yóò túbọ̀ mú kí iṣẹ́ ìwádìí èdè Niger-Congo ó rinlẹ̀.

Bẹ̀rẹ̀ ìtàkùrọ̀sọ náà

Òǹkọ̀wé, jọ̀wọ́ àkọsílẹ̀ ìwọlé »

Ìlànà

  • Atukọ̀ yóò ṣ'àtúnwò gbogbo ìsọsí . Máà fi ìsọsíì rẹ sílẹ̀ ju ẹ̀rìnmejì lọ tàbí kí a kà á sí iṣẹ́-ìjẹ́-tí-a-o-fẹ́.
  • Jọ̀wọ́ fi ọ̀wọ̀ fún ẹlòmíràn . A ò ní fi àṣẹ sí ìsọsí ìkórìíra, ìṣekúṣe, àti ìdojú-ìjà-kọ ẹnikẹ́ni k.