Àwọn ọmọ ìbílẹ̀ Brazili ra ìpín ìdókòòwò ní iléeṣẹ́ reluwé láti bá a wí fún ìkùnà ojúṣe àyíkáa rẹ̀

Àwọn ọmọ ìbílẹ̀ sọ wípé iṣẹ́ tuntun fífẹ reluwé ń kóbá àwọn ẹranko agbègbè náà àti ààbòo wọn.  Àwòrán: Pedro Biava, tí a fi àṣẹ lò.

Ní ọjọ́ 24 oṣù Igbe, ìpàdé akópìnín Rumo Logística, ìgbìmọ̀ reluwé orílẹ̀ èdèe Brazili, gba àwọn àlejò àìròtẹ́lẹ̀ tuntun: ẹgbẹ́ ẹlẹ́ni márùn-ún ìbílẹ̀ kan tí ó wá láti ẹ̀yà Guarani àti Tupi tí ó ṣẹ̀ṣẹ̀ ra ìpín ìdókòwò mẹ́fà iléeṣẹ́ náà.

Ọ̀kọ̀ọ̀kan wọ́n jẹ́ aṣojú Ilẹ̀ Ìbílẹ̀ tí ìjọba fọwọ́ sí ní gúúsù ìlà oòrùn ìpínlẹ̀ São Paulo tí reluwé akẹ́rù aláàdọ́run ọdún iléeṣẹ́ Rumo ń kó bá, ní ọdún-un 2014, bẹ̀rẹ̀ sí í fẹ̀ sí i. Láti san owóo gbà máà bínú fún ìbàjẹ́ tí ìmúgbòòrò sí i ilé iṣẹ́ náà kó bá agbègbèe náà, ìpínlẹ̀ ti fi ẹ̀tọ́ fún iiléeṣẹ́ reluwé náà láti “kọ́ ilé tuntun, ibùdó ìwúre, afárá, ọgbà àti ra ẹ̀rọ ìṣánko kékeré” fún àwọn agbègbè náà. Ó tó bíi ẹgbẹ̀rún márùn-ún ènìyàn tí ó ń gbé jákèjádò Ilẹ̀ Ìbílẹ̀ tí fífẹ̀ reluwé kó bá.

Ṣùgbọ́n àwọn aṣojú ìbílẹ̀ sọ wípé iléeṣẹ́ náà ti kùnà láti ṣe irú ẹ̀tọ́ náà, gẹ́gẹ́ bíi ìròyìn láti ọwọ́ Folha de São Paulo. Ọ̀fíìsì Abánirojọ̀ Ìjọba Àpapọ̀ jẹ́rìí sí i èyí: 63 nínúu iṣẹ́ àtúnṣe 97 ìwé àdéhùn ìfìmọ̀ṣọ̀kan ti di àpatì. Ní ọjọ́ 19 oṣù Igbe, àwọn afẹ̀sùnkanni pa á láṣẹ fún Ibama, àjọ ètò àyíká orílẹ̀ èdè Brazili, láti ṣíra dá iṣẹ́ reluwé tuntun náà dúró, wọ́n sì gba ìwé àṣẹ Rumo. Bákan náà ni wọ́n tún gba àjọ náà níyànjú láti mú kí Rumo ó san owó ìtanràn mílíọ̀nù 10 owóo reais (ìyẹn mílíọ̀nù 2,5 owóo dọ́là orílẹ̀ èdèe US).

Nínúu lẹ́tà tí a kà níbi àpèjọ ọjọ́ 24 oṣù Igbe, àwọn aràpín-ìdókòòwò ìbílẹ̀ náà ṣàlàyé ẹ̀dùn-un ọkàn-an wọn. Wọ́n ti ṣe àlàyé ìjàmbá tí àwọn ọkọ̀ ojú irin náà ti fà fún ẹranko inú ìgbẹ́ tí ó wà ní agbègbè náà, àti dín àwọn ọmọ ènìyàn lọ́wọ́ láti fọ́n ká sí agbègbè. Ní àfikún, wọ́n ti jábọ̀ akitiyan ìtàkùrọ̀sọ wọn pẹ̀lú Rumo, tí wọ́n sì bu ẹnu àtẹ́ lu Àtẹ̀jáde Ìgbéró Ọlọ́dọọdún-un iléeṣẹ́ náà, tí ó sọ pé Rumo “ń ṣe ojúṣe rẹ̀ bí ó ti tọ́ àti bí ó ti ṣe yẹ, ní ọ̀nà tí ó fa àwọn ọmọ ìbílẹ̀ wọ inú iṣẹ́.”

Nígbà tí ó ń bá Pedro Biava ajábọ̀-ìròyìn ìwé ìròyìn  Brasil de Fato fọ̀rọ̀jomitoro, Adriano Karai, tí ó wà láti agbègbè Guarani, sọ wípé ìlépa àwọn alájọpín ìdókòòwò ìbílẹ̀ náà ni láti mú kí ohùn-un wọn ó dé etí ìgbọ́ àwọn olùdókòòwò iléeṣẹ́ náà dípòo kí wọn ó jèrè láti ara ìdókòòwò náà (èyí tí wọ́n ra ọ̀kọ̀ọ̀kan-an ní 17 owó reais, tí ó tó bíi 4,30 owóo dọ́là US).

Karai tún ṣe àpèjúwe bí iṣẹ́ẹ fífẹ reluwé tuntun náà ti ṣe kóbá agbègbèe rẹ̀ Tenondé, tí ó wà ní ìlúu Paralheiros:

Tem o barulho do trem, que é a noite toda. Os animais não frequentam mais os locais de caça. A gente não tem mais uma noite calma. Eles também transportam muitos grãos que acabam se espalhando pelo território, e a gente sabe que aquele alimento não é de qualidade, é transgênico. (…) E a gente acaba convivendo com o perigo: o trem passa pelos nossos territórios, onde costumamos visitar as aldeias, nas trilhas. A gente corre o perigo de ser atropelado pelo trem, porque agora o trem passa a cada dez minutos.

Ariwo ọkọ̀ ojú irin náà, tí ó máa ń gbalẹ̀ kan títí lálẹ́. Àwọn ọmọ ẹranko kì í jẹ́ sí ibi ìdẹ mọ́ bíi tẹ́lẹ̀. A kò ní alẹ́ àìláriwo. Bákan náà ni wọ́n máa ń gbé ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọkàn tí ó máa ń dànù káàkiri ilẹ̀, a sì mọ́ wípé oúnjẹ yẹn kì í ṣe ojúlówó, tí àtọwọ́dá ni. (…) Ẹ̀mí àwa gan-an alára ń bẹ nínú ewu: ọkọ̀ ojú irin náà ń gba ilẹ̀ àjogúnbáa wa kọjá, níbi tí àwọn àpá ẹsẹ̀ àwọn àlejò afẹsẹ̀ rìn tọ́. A wà nínú ewu ńlá ìjàmbá ikú ọkọ̀ ojú irin, nítorí ọkọ̀ ojú-irin ń pa ènìyàn nínúu ìṣẹ́jú mẹ́wàá mẹ́wàá báyìí.”

Gẹ́gẹ́ bíi ìròyìn Folha, ní àkọ́kọ́, àwọn agbègbè ìbílẹ̀ ti gbèrò pẹ̀lú Rumo wípé kí ó gbé iṣẹ́ àtúnṣe náà fún ìgbìmọ̀ tí ó jẹ́ ọmọ ìbílẹ̀. Ní ti Ọ́fíìsì Abánirojọ̀, iléeṣẹ́ náà ti kọ́kọ́ gba àbá náà wọlé, ṣùgbọ́n ní kété tí ó di ẹ̀yìn-in ìbò oṣù Ọ̀wẹwẹ̀ ọdún-un 2018 tí ó gbé Ààrẹ Jair Bolsonaro tí kò fi bò wípé òun kórìíra ti ìbílẹ̀ sí orí àlèèfà, àyípadà dé bá ìpinnu ìgbésè ti ó wà nílẹ̀ tẹ́lẹ̀tẹ́lẹ́rí. Ní ọjọ́ 20 oṣù Belu, Rumo ṣàì dédé fagi lé ìkópa pẹ̀lú àwọn agbègbè ìbílẹ̀, tí kò ì tíì tún yọjú níbi ìpàdé láti ìgbà náà.

Nínú ìtàkùrọ̀sọ pẹ̀lú Folha, iléeṣẹ́ náà sọ wípé òun kò fi ìgbà kan t'ọwọ́ bọ ìwé àdéhùn pẹ̀lú àwọn agbègbè ìbílẹ̀ náà láti gbé iṣẹ́ àtúnṣe náà fún wọn ṣe.

Àpéjọ àwọn alájọpín ìdókòòwò tí ó wáyé lọ́jọ́ 24 oṣù Igbe wá sí òpin láì sí ìpinnu tí ó lórí, àmọ́ àwọn aṣojú Rumo sọ wípé ọ̀rọ̀ ti ìbílẹ̀ náà yóò jẹ́ sísọ nínú ìpàdé ti abẹ́nú tí yóò wáyé nínú oṣù Èbìbì.

Iṣẹ́ àtúnṣe bẹ̀rẹ̀ ní 2014. Àwọn ọmọ ìbílẹ̀ tí ó ń gbé ní agbègbè náà tó bíi 5,000. Àwòrán: Pedro Biava, pẹ̀lú àṣẹ ni a fi lò ó.

Ìjàgbara Alájọpín-ìdókòòwò 

Àwọn ọmọ ìbílẹ̀ Guarani àti Tupi nìkan kọ́ ni ó ṣe ohun tí a pè ní “ ìjàgbara alájọpín- ìdókòòwò,” tí ó jẹ́ ohun tuntun ní Brazil.

Ní ọdún-un 2010, ẹgbẹ́ Ìmọ́rọ̀-yéni-yékéyéké àwọn tí ọ̀ràn-an Vale náà kàn (Articulação dos Atingidos e Atingidas pela Vale) ra ìpín ìdókòòwò iléeṣẹ́ náà láti lè bá wọn jókòó ní àjọ wọn.

Vale ni ọkàn lára iléeṣẹ́ awakùsà ní àgbáyé, òun sì ni ó ṣe àkóso ìdídò  tí ó ba ìlúu Brumadinho jẹ́ nínú oṣùu Ṣẹẹrẹ ọdún-un 2019, tí ó mú ẹ̀mí èèyàn-an 236 lọ (tí 34 ṣì ti di ẹni àwátì).

Ní ọjọ́ 30 oṣù Igbe, ọjọ́ ìpàdé alájọpín ìdókòòwò, àwọn ọmọ ẹgbẹ́ Ìmọ́rọ̀-yéni-yékéyéké lẹ ìwé-àlẹ̀mógiri tí a tẹ orúkọ àwọn tí ó ti re ọ̀run àrìnmabọ̀ mọ́ ara ògiri olú-ilé-iṣẹ́ẹ Vale, gẹ́gẹ́ bí ìwé ìròyìn O Globo ti rò ó.

Nítorí àìdéènà-pa-ẹnu ọ̀ràn tí ó kàn wọ́n gbọ̀ngbọ̀n nínú àwọn ìpàdé wọ̀nyẹn, ó di dandan kí àwọn iléeṣẹ́ náà ó kọ ohun tí àwọn ajìjàgbara náà ń fẹ́ sílẹ̀ nínú ìpàdée wọn. Obìnrin kan lára àwọn ọmọ ẹgbẹ́ Ìmọ́rọ̀-yéni-yékéyéké, Carolina de Moura, tí òun náà ní ìpín nínú ìdókòòwò Vale, sọ fún O Globo:

Não vamos nos calar. A empresa tem que investir tudo o que ganha na melhoria dos rios e se preocupar com vidas humanas.

A kò ní dẹ́kun láti máa sọ ohun tí ó ń gbé wa lọ́kàn síta fún aráyé gbọ́. Iléeṣẹ́ náà gbọdọ̀ lo èrè tí wọ́n bá rí fi tún àwọn odòo wa ṣe àti ṣíṣe àbójútó ẹ̀mí ọmọ ènìyàn.

Bẹ̀rẹ̀ ìtàkùrọ̀sọ náà

Òǹkọ̀wé, jọ̀wọ́ àkọsílẹ̀ ìwọlé »

Ìlànà

  • Atukọ̀ yóò ṣ'àtúnwò gbogbo ìsọsí . Máà fi ìsọsíì rẹ sílẹ̀ ju ẹ̀rìnmejì lọ tàbí kí a kà á sí iṣẹ́-ìjẹ́-tí-a-o-fẹ́.
  • Jọ̀wọ́ fi ọ̀wọ̀ fún ẹlòmíràn . A ò ní fi àṣẹ sí ìsọsí ìkórìíra, ìṣekúṣe, àti ìdojú-ìjà-kọ ẹnikẹ́ni k.