Oníròyìn Orí ẹ̀rọ-alátagbà Luis Carlos Diaz di àwátì ní Venezuela

“Níbo ni Luis Carlos wà?” Àwòrán ìpolongo orí ayélujára tí Provea taari síta. Wọ́n sọ ìgbà tí a pè é kẹ́yìn àti túwíìtì tí ó tẹ̀ kẹ́yìn nínú àwòrán náà.

Ní ìrọ̀lẹ́ ọjọ́ 11, oṣù Ẹrẹ́nà olùfèsì sí ọ̀rọ̀ ìṣèlú Naky Soto tí ó tún jẹ́ aya akọ̀ròyìn àti ajììjàǹgbara iṣẹ́ ìròyìn tí ó jẹ́ ọmọ orílẹ̀ Venezuela, Luis Carlos Díaz túwíìtì pé òun ti ń wá ọkọ òun fún wákàtí márùn-ún.

[Ìròyìn tí ó tẹ̀ wá lọ́wọ́] Àjọ àwọn Òṣìṣẹ́ Ìròyìn (SNTP lédè Spanish) jábọ̀ pé àwọn Agbófinró Ọ̀tẹlẹ̀múyẹ́ Bolivaria (SEBIN) ti fi Luis Carlos sí àtìmọ́lé.

PÀJÁWÌRÌ Àjọ Sebin kan fìdíi rẹ̀ múlẹ̀ pé akọ̀ròyìn Luis Carlos Diaz ti wà ní àhámọ́ àwọn ọlọ́pàá yẹn. Wọ́n yọ àwọn ohun ìjà ti akọ̀ròyìn Marco Ruiz, Luz Mely Rehes àti Federico Black [pẹ̀lú àwọn ọmọ ẹgbẹ́ òṣìṣẹ́ ìròyìn.

Wákàtí díẹ̀ sẹ́yìn, Soto túwíìtì pé àwọn ti ń wá Luis Carlos Díaz fún wákàtí márùn-ún:

Ẹ̀yin èèyàn àtàtà: Mi ò rí @LuisCarlos bá sọ̀rọ̀ láti aago 5:30 lọ́sàn-án yìí, ó sì sọ fún mi pé òun ń bọ̀ nílé láti sinmi nítorí pé òun ní ìkéde pàtàkì kan láti se lórí @Unionradionet láti aago 10:00 alẹ́ sí 5:00 ìdájí #DóndeEstáLuisCarlos

@LuisCarlos wà ní orí kẹ̀kẹ́ẹ rẹ̀, ṣùgbọ́n láti aago 5:30 ni mi kò ti gbúròó rẹ̀ mọ́, bẹ́ẹ̀:
– Kò sí ní ilé iṣẹ́ ìgbóhùnsáfẹ́fẹ́ náà
– Kò sí nílé
– Kò tíì túwíìtì
– Kò gbé ìpèe rẹ̀
– Kò fèsì sí àtẹ̀jíṣẹ́ tàbí iṣẹ́-ìjẹ́ oríi WhatsApp
#DóndeEstáLuisCarlos

[Ìròyìn tó tẹ̀wá lọ́wọ́] Luz Mely Reyes tí ìṣẹ̀lẹ̀ náà ṣe ojúu rẹ̀, fi tó wa létí nípa bí àwọn Agbófinró SEBIN ṣe yẹ ilée Díaz pẹ̀lú ilée Soto náà wò. Ìsọ̀kan àwọn Oníròyìn náà fẹ ọ̀rọ̀ náà lójú:

NÍ KÍÁKÍÁ Ní dédé àsìkò yìí, ní dédé agogo 3:00 òwúrọ̀ kùtùkùtù, ìgbìmọ̀  láti àjọ Amúninípá dé ilé oníròyìn àti ajà-fún- ẹ̀tọ́ọ ọmọ ènìyàn Luis Carlos Díaz, tí ó ti di ẹni àwátì láti agogo 5:30 ìrọ̀lẹ́ #NiboNiLuisCarlosWa.

Àwọn ajàfúnẹ̀tọ́ ọmọnìyàn àti àjọ òmìnira ọ̀rọ̀ sísọ náà darapọ̀ mọ ìpolongo yìí pẹ̀lú #DondeEstaLuisCarlos (Níbo ni Luis Carlos wà?), tí ó jẹ́ pé, ní báyìí, ni àkọlé tí ó gbajúmọ̀  ní orí ìkànnì ayélujára Twitter ti Orílẹ̀ Èdè Venezuela.

Díaz jẹ́ ajábọ̀ ìròyìn àti a-jà-fún-ẹ̀tọ́-ọmọ ènìyàn tí ó jẹ́ ògbólógbòó ajàfúnẹ̀tọ́ òmìnira ọ̀rọ̀ sísọ tí wọ́n sì mọ ìṣe rẹ̀ fún un l'órílẹ̀ èdè Venezuela àti òkè òkun fún ìdásọ́rọ̀ àti ìtakò ìjọba Nicholas Maduro. Ó ti tó ìgbà díẹ̀ kan tí ó ti ń ṣiṣẹ́ pẹ̀lú ìyàwó rẹ̀ àti olùdásọ́rọ̀ òṣèlú tí ó gbajúmọ̀ n nì, Naky Soto, tí wọn sì ń ṣe ìgbéjáde àwọn fídíò àti ètò Ìgbóhùnsáfẹ́fẹ́ lórí ayélujára èyí tí ó dá lórí ìṣèlú àti ẹ̀tọ́ ọmọ ènìyàn ní Venezuela. Ó ti ṣiṣẹ́ gẹ́gẹ́ bí akọ́ni àti olùgbé-lárúgẹ ìdásílẹ̀ àyè ọ̀tọ̀ fún àwọn ará ìlú àti àwọn àkànṣe eto ìgbóhùn sáfẹ́fẹ́ tí kò lọ́wọ́ ìjọ̀ba nínú. Díaz tún jẹ́ olùkópa nínú ẹgbẹ́ Ohùn Àgbáyé fún ọdún mẹ́wàá.

Lọ́dọ̀ tèmi, Luis Carlos jẹ́ onílàákàyè ẹ̀dá kan, ó gbọ́njú nínú ìròyìn gbígbà àti ìkànsì-ara-ẹni nínú Venezuela ti wa yìí tí kò fara rọ. Ó ti ṣe àwárí ìjápọ̀ nínú ìlú (láti ìtakò sí ibi ìṣẹ̀ṣe) #NiboniLuisCarlosWa.

Láàrin ọjọ́ péréte tó ṣíwájú ìpòóráa rẹ̀, ètò ìkàn-sára- ẹni ti ìjọba Con el Mazo Dando ṣàfihàn fídíò tí Díaz sọ̀rọ̀ nínúu rẹ̀. Atọ́kùn ètò ọ̀hún, olóṣèlú Diosdado Cabello, rò kàn pé Díaz lọ́wọ́ sí ìfẹ̀hónú hàn àìsí ináa mọ̀nàmọ̀nà tí ò lọ jákèjádò orílẹ̀ èdè èyí tí ó mú kí àwọn ọmọ Venezuela máa gbé nínú òkùnkùn fún ó lé ní wákàtí mẹ́rin lé lógún lọ́jọ́ 7 àti 8 Oṣù Ẹrẹ́nà

Kò sí ẹ̀rí tí ó fi ẹsẹ̀ rinlẹ̀.

#DenounceEP Láti 5:30 ìrọ̀lẹ́ ni a kò ti mọ ibi tí oníṣẹ́ ìròyìn Luis Carlos Díaz wà. A fi ẹ̀sùn “ìlọ́wọ́sí- ìgbé ayé ìfipamúni” ní oríi ìṣàmúlò Twitter ti “Con el mazo dando”.

Bí ọjọ́ ṣe ń lọ láì rí ẹ̀rí tí ó yanrantí dì mú, SNTP darapọ̀ tí ó bẹ̀rẹ̀ àbẹ̀wò sí olú ilé iṣẹ́ẹ Ọ̀tẹlẹ̀múyẹ́ (SEBIN):

Wákàtí méje ti ré kọjá lọ tí Luis Carlos Díaz ti di àwátì. [Díaz] jẹ́ oníròyìn fún ilé iṣẹ́ ìgbóhùnsáfẹ́fẹ́ Unión Radio Noticias , ó sì tún jẹ́ ajàfúnẹ̀tọ́ ọmọnìyàn.

Àwa ní olú ilé iṣẹ́ẹ SEBIN headquarters àti pé wọ́n ní àwọn kò ní í [ní àhámọ́ àwọn] #NiboNiLuisCarlosWa.

[Ìròyìn tí ó tẹ̀ wá lọ́wọ́: they wọ́n pàpà jẹ́wọ́ wípé [Diaz wà ní akolóo wọn]

Akọ̀ròyìn Vladimir Villegas sọ wípé kò rí bẹ́ẹ̀ mọ́ wípé ìjọba ni ó fi ọwọ́ agbára mú u:

Olóbó ti ta wá wípé oníròyìn fún @Unionradionet Luis Carlos Díaz, ti wà nínú àtìmọ́lé agbófinró Ìlú. A bá a kẹ́dùn ipò tí ó wà. A béèrè fún ìtọ́sọ́nà nípa mímọ ibi tí ó wà, àti ìbọ̀wọ̀ fún ẹ̀tọ́ ọmọnìyàn-an rẹ̀.

Ẹgbẹ́ Ohùn Àgbáyé dúró ṣinṣin pẹ̀lú Luis Carlos, ẹbíi rẹ̀, àti oníròyìn aládàáṣiṣẹ́ gbogbo  àwọn tí ó ń mú ìjọba ṣe bí ó ti yẹ ní Venezuela. À ń retíi rẹ̀ kí ó dé kíákíá ní àlàáfíà ara àti ẹ̀mí, a ó máa gbé àwọn ìròyìn síta nípa ìròyìn yìí bí ó ba ṣe ń tẹ̀ wá lọ́wọ́.

Bẹ̀rẹ̀ ìtàkùrọ̀sọ náà

Òǹkọ̀wé, jọ̀wọ́ àkọsílẹ̀ ìwọlé »

Ìlànà

  • Atukọ̀ yóò ṣ'àtúnwò gbogbo ìsọsí . Máà fi ìsọsíì rẹ sílẹ̀ ju ẹ̀rìnmejì lọ tàbí kí a kà á sí iṣẹ́-ìjẹ́-tí-a-o-fẹ́.
  • Jọ̀wọ́ fi ọ̀wọ̀ fún ẹlòmíràn . A ò ní fi àṣẹ sí ìsọsí ìkórìíra, ìṣekúṣe, àti ìdojú-ìjà-kọ ẹnikẹ́ni k.