Gbólóhùn asọ̀ láàárín ẹni méjì ní ọ̀nà àrà tí ó gbà di ìjà ìgboro — papàá nínú iṣẹ́ orin kíkọ. Ìjà mo jù rẹ́ lọ láàárín àwọn ọ̀jẹ̀ bíi ti Kanye West àti Taylor Swift àti ọmọ Jamaica Mavado àti Vybz Kartel, títí kan ìjà ìbílẹ̀ ọdún 2004 ní àárín-in akọrin soca ìlú Trinidad méjì Destra àti Denise Belfon, ìjà mo jù ọ́ lọ àwọn gbajúgbajà sábà máa ń já sí ìpolongo fún akọrin àti orin wọn.
Wàyí, ọpẹ́ fún asọ̀ tí ó wà ní àárín-in akọrin adìde Trinidad àti Tobago méjì Machel Montano àti Neil “Iwer” George, orin soca wọ ìròyìn fún ìgbà àkọ́kọ́ ní ọdún 2019.
Ayẹyẹ ijó ìta-gbangba ọlọ́dọọdún Trinidad àti Tobago tí ọdún yìí wáyé ní ọjọ́ 4 àti 5 oṣù Ẹrẹ́nà, tí ó sì jẹ́ àkókò fún orin soca. Ọ̀jẹ̀ olórée soca bíi Montano àti George ti gba ìpè láti ṣeré níbi ètò ijó ìta-gbangba kí ọjọ́ ó tó kò rárá. Wọn yóò gbé orin tuntun jáde ní ìpalẹ̀mọ́ fún ẹni tí yóò gbégbáorókè nínú ìdíje Ìwọ́de Ojúná, tí ó ń gbé ẹ̀bùn owó sílẹ̀ fún akọrin tí a bá kọ orin rẹ̀ jù lọ nínú Ijó ìta-gbangba.
Àwọn olólùfẹ́ẹ orin Soca ṣe àkíyèsí àròyé ọ̀tẹ̀ láàárín-in akọrin méjèèjì nígbà tí George gbé orin àkọ́ṣe ọdún 2019 jáde, “Ìwọ́de Ojúná Bacchanal 2″. Orin náà kò fi igbákanbọ̀kan nínú nípa ìkùnsínú tí ó wà nílẹ̀ látàrí ìpàdánù ìfigagbága ọdún 2018 tí Montana jáwé olúborí. Orin rẹ̀ tí a pè ní “Savannah”, bá ti ẹnìkejì figagbága, ṣùgbọ́n Montana tí pàdí-àpò-pọ̀ pẹ̀lú ògbóǹtarigi akọrin soca Superblue wọ́n sì ṣe àgbéjáde “Soca Kingdom”, tí ó gba oyè orin Ìwọ́de Ojúná ọdún 2018 . Iye ìgbà 336 ni a kọ orin “Soca Kingdom”, a sì kọ “Savannah” fún iye ìgbà 140.
Ìpàdánù oyè yìí ni ó fa ìbínú ní ìta-gbangba, George fi orin fẹ̀sùn kan “jàndùkú soca” – ìyẹn àkójọpọ̀ òṣìṣẹ́ ilé iṣẹ́ agbóhùnsáfẹ́fẹ́ àti olùdaríI wọn – fún ìpàdíàpòpọ̀ tí ó mú wọn kọ orin “Soca Kingdom” ní àsìkò ìdájọ́ láti yan ẹni tí ó jáwé olúborí. Ó kọrin:
On the stage was a next set of drama, the DJs and them playing ‘Savannah’
But when the mafia come, they switching from ‘Savannah’ to ‘Kingdom’
They join forces to win the big fight … this year you have to team up with Jesus Christ
Lórí ìtàgé ni eré tí ó kàn-án wà, àwọn DJ àti wọn ń kọ ‘Savannah’
Ṣùgbọ́n nígbà tí àwọn jàndùkú dé, wọ́n sún láti ‘Savannah’ sí ‘Kingdom’
Wọ́n pawọ́pọ̀ láti borí ìjà ńlá náà… lọ́dún yìí ẹ ní láti pawọ́pọ̀ pẹ̀lú Jésù Kristì ọmọ Màríà
Nínú ẹ̀dà orin náà mìíràn , George fi ẹ̀sùn kan Montana pé ó ń “sọ ọ̀rọ̀ àlùfànṣá” sí òun, ó sì fi ẹnu tẹ́ oyè ọ̀mọ̀wé tí Montano ṣẹ̀ṣẹ̀ gbà ní Ifásitì Trinidad àti Tobago látàrí ipa tí ó kó ní ti ìgbélárugẹ orin soca.
Kò pẹ́ tí a gbé orin George jáde, Montano fèsì pẹ̀lú orin tí a pe àkọlée rẹ̀ ní “Dr. Mashup”, nínúu rẹ̀ ni ó ti sọ màdàrú tí wọ́n ṣe níbi ìdíje Ìwọ́de Ojúná:
We doh plan for no road march, We doh sing bout man for no road march
We doh beg no one for no road march, everybody show me yuh hand for de road march …
A kì í gbáradì fún ìwọ́de ojúnàkankan, A kì í kọrin nípa èèyàn fún Ìwọ́de Ojúnà kankan A kì í bẹ ẹnikẹ́ni fún Ìwọ́de Ojúnà kankan, gbogbo yín ẹ fi ọwọ́ọ yín hàn mí…
Kò tán síbẹ̀: níbi ayẹyẹ Ijó ìta-gbangba tuntun, “Hydrate”, ní ọjọ́ 13 oṣù Ṣẹrẹ, àwọn akọrin méjèèjì ṣeré. George lé orin rẹ̀ tuntun Montano náà sọ ọ̀rọ̀ ìkẹyìn:
Lẹ́yìn eré, alábòójútó Montano, Anthony Chow Lin On, tari àwòrán kan sí orí Instagram tí ó fi ara jọ ẹ̀fẹ̀ ìtúká ẹni méjì tí ó ń jà:
Àtẹ̀jáde náà mú ìfura dání bóyá ìjà tòótọ́ ni tàbí ète lásán-làsàn:
Not sure if this Iwer vs Machel clash fabricated but I am here for all of it. ALL. pic.twitter.com/XZ9xpUzZb8
— Dominic Angelo (@RayBanzs) January 18, 2019
Mi kò rò wípé ìjà Iwer àti Machel yìí jẹ́ tòótọ́ ṣùgbọ́n mo wà níbi fún gbogbo rẹ̀. PÁTÁ. pic.twitter.com/XZ9xpUzZb8
Machel vs Iwer >>>> Drake vs Meek
— Carnival Horse (@brian_savage14) January 18, 2019
Machel àti Iwer >>>> Drake àti Meek
Orírun Calypso
Ète tàbí bẹ́ẹ̀ kọ́, ọ̀pọ̀lọpọ̀ òǹlo ẹ̀rọ-alátagbà tó ń tẹ̀lé awuyewuye náà ti tọ́ka sí irúfẹ́ àríyànjiyàn orin báyìí (tí a mọ̀ sí “orin ìjà”) kò jẹ́ tuntun; àti pé, ó bá orísun orin calypso mu, ó sì jẹ́ àmúlùmálà, soca.
Nínú ìfọ̀rọ̀wánilẹ́nuwò kan, George fúnra rẹ̀ sọ òtítọ́ ibẹ̀ wípé òun kàn ń “ṣe àkópamọ́ ìṣẹ̀lẹ̀ àtijọ́” gẹ́gẹ́ “bí ó ṣe máa ń ṣe”, títọpa àwọn ènìyàn jàǹkàn-jàǹkàn tí ó ti kọ orin calypso sẹ́yìn.
Orin calypso jẹ́ ìlúmọ̀nánká tí ó máa ń sọ nípa àwùjọ àti ìṣèlú, ní ìbẹ̀rẹ̀ pẹ̀pẹ̀ orin náà ni ìsọ̀rọ̀ síra ẹni méjì tí ó fi ara pẹ́ ogun ọ̀rọ̀ tí ó ń lọ ní àárín-in George àti Montano. Abẹ́ àtíbàbà orin Calypso, níbi tí àwọn eléré calipso ti máa ń ṣeré ní àsìkò Ijó ìta-gbangba, gbajúmọ̀ fún “ogun àìròtẹ́lẹ̀”, ìdíje tí àwọn akọrin yóò kọrin èébú sí ara wọn láì rò tẹ́lẹ̀ lójú ẹsẹ̀, tàbí lórí àkọ́lé kan. Ìfigagbága àwọn akọrin wọ̀nyí ni a mọ̀ sí “picong”.
Irúfẹ́ eré wọ̀nyí máa ń fi àyè gba ìdásí, tí àwọn olùwòràn yóò máa gbe orin, ọ̀kan tí ó wọ́pọ̀ jù lọ ni “Santimanitay!”, tí ó jẹ́ ẹ̀dà àbọ̀-ọ̀rọ̀ Faransé “sans humanité”, tàbí “àìláàánú”.
Àmọ́ àwọn òǹwòrán kò ì tíì rí irú èyí rí nínú orin soca tí a ti ká sílẹ̀. Ó jẹ́ òtítọ́ tàbí kò jẹ́ òtítọ́, àwọn olólùfẹ́ẹ George/Montano dá sí ogun àìròtẹ́lẹ̀ wọn gẹ́gẹ́ bí olùwòràn, ní Ijó ìta-gbangba àti lórí ayélujára.
George àti Montano yô, láì sí àní-àní, nínú ìdíje Ìwọ́de Ojúná ọdún 2019 àti èyí tí ó kéré jù lọ, awuyewuye ìjà gẹ́gẹ́ bí ìdárayá gidi àti orin.
Àwọn olólùfẹ́ẹ Soca kò le è béèrè ju bẹ́hẹ̀ lọ.