Fún ìgbà àkọ́kọ́ ní orílẹ̀-èdèe Brazil, ọmọ ìbílẹ̀ lóbìnrin di ọmọ ìgbìmọ̀ ìjọba

UN/Screenshot

Joenia ni ọmọ ìbílẹ̀ lóbìnrin àkọ́kọ́ tí ó kẹ́kọ̀ọ́ gboyè nínú ẹ̀kọ́ ìmọ̀ òfin ní Brazil. Àwòrán: Àwòrán tí wọ́n yà nínú fídíò kan láti ọwọ́ọ United Nations Web TV.

Ní ọdún-un 1997, Joenia Wapichana di obìnrin àkọ́kọ́ tí yóò gboyè nínú ẹ̀kọ́ ìmọ̀ òfin ní Brazil. Lẹ́yìn ọdún kọ́kànlá, òun ni ọmọ ìbílẹ̀ àkọ́kọ́ tí ó gbẹjọ́rò ní ilé-ẹjọ́ gíga jùlọ. Ní oṣù Ọ̀wàrà ọdún-un 2018, Joenia tún gbajúmọ̀ sí i nígbà tí ó di ọmọ ìbílẹ̀ lóbìnrin àkọ́kọ́ tí wọn yóò yàn sípò nínú ìgbìmọ̀ ìjọba.

Ìbòo 8,491 tí wọ́n dì fún un ni wọ́n fi yàn án sípò kan nínúu mẹ́jọ tí ó tọ́ sí ìpínlẹ̀ Roraima tí ó ti wá. Ìgbà kan ṣoṣo tí Brazil ní ọmọ ìbílẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ọkàn lára àwọn ìgbìmọ̀ ìjọba ni ọdún-un 1986 — Mario Juruna, tí ó wá láti ẹ̀yà Xavante, wọ́n yàn án sípò ní ọdún-un 1983.

A bí Joana sínú ẹ̀yà Wapichana, ó lọ sí Boa Vista tí ó jẹ́ olú-ìlú Roraima nígbà tí ó wà ní ọmọ ọdún mẹ́jọ. Ó ń kọ́ ẹ̀kọ́ọ rẹ̀ nínú ìmọ̀ òfin bí ó ṣe ń ṣiṣẹ́ ní ọ́fíìsì àwọn oníṣirò kan, ó sì sọ ọ́ nínú  ìfọ̀rọ̀wánilẹ́nuwò kan láìpẹ́, pé òun ṣetán ní ilé-ẹ̀kọ́ ní ọdún kan ṣáájú ìgbà tí ó yẹ kí òun ṣetán tí òun sì gbé ipò karùn-ún nínúu kíláàsìi rẹ̀ àti láàárín-in àwọn ọmọ ọlọ́lá ní Roraima.

Ní oṣù Ọ̀pẹ ọdún-un 2018, gẹ́gẹ́ bí ọmọ ẹgbẹ́ ìgbìmọ̀ tí wọ́n dìbò yàn, Joenia gba àmì ẹ̀yẹ ìdánimọ̀ UN fún ìjàfẹ́tọ̀ọ́ ẹ̀dá lórí àṣeyọrí tí ó ṣe nínú ìpolongo ẹ̀tọ́ àwọn ọmọ ìbílẹ̀. Wọ́n ti fi àmì-ẹ̀yẹ ìdánimọ̀ yìí kan náà fún Nelson Mandela àti Malala rí.

Joenia Wapichana níbi tí ó ti ń gbè lẹ́yìn ọ̀rọ̀ ìbílẹ̀ kan ní ilé-ẹjọ́ gíga jùlọ. Àwòrán: Àwòrán tí wọ́n yà nínú fídíò YouTube ilé-ẹjọ́ gíga jùlọ ti Brazil.

Ibi tí àyípadà ti bẹ̀rẹ̀

Joênia ṣe àfikún ìtàn ní ọdún-un 2008 nígbà tí ó gba ẹjọ́ ẹgbẹ́ ìbílẹ̀ márùn-ún kan rò, pé kí wọn ya ilẹ̀ẹ wọn sọ́tọ̀ gẹ́gẹ́ bí ilẹ̀ abínibí, irú òfin tí yóò fún àwọn abínibí ilẹ̀ náà ní ẹ̀tọ́ láti pàṣẹ lórí àwọn ilẹ̀ ìlúu wọn.

Ilé ẹjọ́ dá ẹjọ́ tí ó gbè lẹ́yìn àwọn ẹgbẹ́ ìbílẹ̀ náà tí wọ́n ti wá di òǹnilẹ̀ kánrin-kése fún àwọn ilẹ̀ abínibí tí ó tóbi jù ní Brazil — ilẹ̀ẹ Raposa Terra do Sol, tí ó wà ní ìpínlẹ̀ Roraima.

Bẹ́ẹ̀, Jair Bolsonaro tí ó jẹ́ ọmọ ẹgbẹ́ ìgbìmọ̀ ní àkókò náà ti fi ìwọ̀sí lọ ajàfẹ́tọ̀ọ́ ìbílẹ̀ kan tí ó wá sí ibi gbígbọ́ ìdájọ́ nípa ìyàsọ́tọ̀ Raposa Terra do Sol ní ìyẹ̀wù àwọn igbá-kejì. Bolsonaro sọ̀rọ̀ báyìí ní ọjọ́ náà pé “ó yẹ kí o jáde síta láti lọ jẹ koríko pẹ̀lú àwọn alálẹ̀ẹ yín”.

Kò pẹ́ lẹ́yìn tí ó jáwé olúborí nínú ìdìbò 2018, Bolsonaro tún mú ọ̀rọ̀ Raposa Terra do Sol bọnu gẹ́gẹ́ bí àpẹẹrẹ agbègbè ìbílẹ̀ tí ó yẹ kí àwọn jẹ àǹfààní ètò ọrọ̀-ajée rẹ̀. Ó sọ fún àwọn akọ̀ròyìn pé:

É a área mais rica do mundo [em minerais]. Você tem como explorar de forma racional. E no lado do índio, dando royalty e integrando o índio à sociedade.

Ó jẹ́ agbègbè kan tí ó lọ́rọ̀ jù ní àgbáyé. Èèyàn lè jẹ àǹfààní rẹ̀ lọ́nà tó mọ́gbọ́n dání. Nípa ti àwọn ọmọ bíbí ibẹ̀, à á fún wọn ní ohun tí ó tọ́ sí wọn, à á sì dà wọ́n pọ̀ mọ́ àwùjọ.

Lọ́dún mẹ́wàá sẹ́yìn, pẹ̀lú ọ̀dà pupa lójúu rẹ̀, ní ìbámu pẹ̀lú àṣà ẹ̀yàa rẹ̀ ni Joenia lo èdè Portuguese àti ẹ̀ka-èdèe rẹ̀ láti rán àwọn adájọ́ létí pé bíi mílíọ̀nù dọ́là US lọ́nà mẹ́ta ni ó ń kárí àwọn ilẹ̀ wọ̀nyí láìsí pé wọ́n kópa nínú ètò ọrọ̀-ajée Brazil. Ó ní “wọ́n ń sọ̀rọ̀ bà wá lórúkọ jẹ́, bẹ́ẹ̀ ni wọ́n ń ṣe ìyàtọ̀ọ̀tọ̀ ẹ̀yà pẹ̀lúu wa ní ilẹ̀ẹ wa”.

Àwòrán: Àjọ tí ó ń rí sí ààbò gbogboògbò, CC 2.0

Alátakò tí kò ṣe é borí

Bí ó ṣe ń gbaradì láti gba ìjókòó rẹ̀ nínú ìgbìmọ̀ ìjọba gẹ́gẹ́ bí alátakò fún ìjọba Bolsonaro, ó sọ fún àwọn akọ̀ròyìn Folha de São Paulo, tí ó jẹ́ ilé iṣẹ́ oníwèé ìròyìn tó gbajúgbajà ní orílẹ̀-èdè pé:

Por que ele persegue tanto os povos indígenas? Qual é a razão de todo esse ódio e de querer retroceder tanto?

Temos turismo, medicinas tradicionais, uma vasta biodiversidade na Amazônia. A gente tem de mudar esse discurso de que somos empecilho ao desenvolvimento, que estamos prejudicando A ou B. Temos de fazer com que sejamos nós os protagonistas também.

Kí ló dé tí ó [Bolsonaro] ṣe ń ṣe inúnibíni sí àwọn ọmọ ìbílẹ̀ tó báyìí? Kí ni ìdí fún ìkórìíra àti òǹgbẹ fún ìṣubúu wa?

A ní ètò ìrìnàjò ìgbafẹ́, òògùn ìbílẹ̀ àti àwọn ohun mèremère tí ó pín yẹ́lẹyẹ̀lẹ káàkiri ilẹ̀ẹ wa. A nílò láti ṣe àyípadà ìgbàgbọ́ pé à ń ṣe ìdíwọ́ fún ìdàgbàsókè tàbí pé à ń ṣe ìpalára fún ẹnikẹ́ni. Àwa náà ní láti di aṣíwájú fún ara wa…

Ìfẹsẹ̀múlẹ̀ tí ó ń lọ

Ìgbìmọ̀ Brazil gba ipò ní oṣù Èrèlé 2019, Joênia sì bẹ̀rẹ̀ sáà rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí olùdarí ẹgbẹ́ òṣèlú rẹ̀, Rede Sustentabilidade (tí ó túmọ̀ sí Ẹgbẹ́ Alágbèéró lédè Portuguese) ní ìyẹ̀wù àwọn igbá-kejì ti ilé ìgbìmọ̀ aṣòfin kékeré. Olùṣàkóso fún ètò àyíká tẹ́lẹ̀ rí Marina Silva, tí orúkọ rẹ̀ gbajúmọ̀ nínú ìjàfẹ́tọ̀ọ́ agbègbè ni ó dá Rede sílẹ̀ pẹ̀lú bí ó ti ṣe fìdírẹmi tó nínú ètò ìdìbò ààrẹ lẹ́ẹ̀mẹ́ta léraléra.

Lẹ́yìn àjálù ìdídò ní Brumadinho, tí ó pa àwọn èèyàn tí ó lé ní 160, tí ó sì mú ìbàjẹ́ bá gbogbo ayé tí ó wà ní odò Paraopeba, Joenia ṣe àgbékalẹ̀ àkọsílẹ̀ àbá òfin rẹ̀ àkọ́kọ́, tí ó ń ka àwọn ọ̀ràn tí ó ń ṣe ìpalára fún agbègbè àti ìlera pẹ̀lú ẹ̀mí àwọn èèyàn gẹ́gẹ́ bí “ọ̀ràn ńlá” tí ó ní ìjìyà tí ó pọ̀ nínú.

Ní ó-ku-ọ̀la tí yóò gba ipò, arábìnrin inú ìgbìmọ̀ náà sọ fún Folha de Boa Vista, ilé-iṣẹ́ ìròyìn ìbílẹ̀ kan tí ó ti ìpínlẹ̀ẹ rẹ̀ wá pé àbá òfin náà ń dojúkọ ìwà àìbìkítà àwọn iléeṣẹ́ àdáni sí agbègbè:

Nos preocupa a política governamental de enfraquecer ainda mais os mecanismos criados para defender o meio ambiente saudável, previsto em nossa Constituição, e os impactos sociais, como, por exemplo, o licenciamento ambiental, diante da falta de responsabilidade das empresas e do baixo poder de fiscalização do Estado.

Ohun tí ó kàn wá ni ètò ìmúlò tí ìjọba fi ń ṣe àdínkù agbára àwọn àtòpọ̀ ẹ̀rọ tí a ṣẹ̀dá láti dáàbò bo àyíká tó ní ìlera, gẹ́gẹ́ bí a ti rí i nínú ìwé òfin àti àwọn ipa tí ó ń kó láwùjọ. Fún àpẹẹrẹ [lára àwọn àtòpọ̀ ẹ̀rọ yìí], a ní ètòo gbígba ìwé àṣẹ ní àwọn agbègbè yìí [tí ó ń bá wa dènà] àìlègbẹ̀rí àwọn iléeṣẹ́ jẹ́ àti àìtó agbára ìjọba láti kápáa wọn nínú ìpínlẹ̀ náà.
.

Nínú ọ̀rọ̀ọ rẹ̀ pẹ̀lú BBC, Joenia sọ pé ohun tí ó ṣe pàtàkì sí òun jùlọ nínú ìgbìmọ̀ náà ni ìyàsọ́tọ̀ àwọn ilẹ̀ abínibí:

Se por um lado há meia dúzia de ruralistas, por outro há uma população de minorias que se sente representada por mim ali. É uma população que precisa de representação. A política velha é formada por pessoas que só pensam em benefícios individuais. Eu vou levar valores coletivos.

Tí o bá ní èèyàn ńláńlá mẹ́fà ní ọwọ́ kan, tí ọwọ́ kejì sì ní àìmọye àwọn èèyàn tí wọn ò jámọ́ nǹkan tí wọ́n ń rí mi gẹ́gẹ́ bí aṣojú wọn níbẹ̀. Wọ́n jẹ́ ọ̀wọ́ àwọn tí ó nílò aṣojú. Ètò ìṣèlú àtẹ̀yìnwá wáyé nípasẹ̀ àwọn èèyàn tí wọ́n ń ro ohun tí ó máa jẹ́ èrèe tiwọn níbẹ̀, èmi máa mú iyì tí ó kárí wá.

Bẹ̀rẹ̀ ìtàkùrọ̀sọ náà

Òǹkọ̀wé, jọ̀wọ́ àkọsílẹ̀ ìwọlé »

Ìlànà

  • Atukọ̀ yóò ṣ'àtúnwò gbogbo ìsọsí . Máà fi ìsọsíì rẹ sílẹ̀ ju ẹ̀rìnmejì lọ tàbí kí a kà á sí iṣẹ́-ìjẹ́-tí-a-o-fẹ́.
  • Jọ̀wọ́ fi ọ̀wọ̀ fún ẹlòmíràn . A ò ní fi àṣẹ sí ìsọsí ìkórìíra, ìṣekúṣe, àti ìdojú-ìjà-kọ ẹnikẹ́ni k.