Akẹ́kọ̀ọ́bìrin kan tí ó jẹ́ ọmọ Tibet-Canada rí ìkọlu lórí ayélujára lẹ́yìn tí ó já ewé olú borí nínú ìdìbò àjọ-ìgbìmọ̀ akẹ́kọ̀ọ́. Ó rò pé, Beijing ló yẹ á bá wí.

Àwòrán wá láti ọwọ́ọ Chemi Lhamo láti ìbáwọlé The Stand News.

Leung Hoi Ching ni ó kọ́kọ́ kọ ìròyìn yìí tí a sì tẹ̀jáde ní èdèe Chinese lórí ilé ìgbéròyìn jáde ará ìlú Hong Kong, The Stand News ní ọjọ́ karùn-ún-dínlógún, Oṣù Èrèlé, ọdún-un 2019. Zhao Yunlin ni ó tú ìmọ̀ọ rẹ̀ sí èdèe Gẹ̀ẹ́sì.

Ní ọjọ́ kẹsàn-án Oṣù Èrélé, àwọn akẹ́kọ̀ọ́ ti Ifáfitì Toronto, ọgbà Scarborough dìbò yan ọmọ ọdún méjìlél'ógún kan tí ìlú abínibíi rẹ̀ jẹ́ Tibet, gẹ́gẹ́ bí ààrẹ ìgbìmọ̀ àwọn akẹ́kọ̀ọ́.

Lẹ́yìn ọjọ́ mélòó kan tí a kéde èsì ìdìbò ọ̀hún, ogunlọ́gọ̀ àwọn ọmọ China tí wọ́n ń kẹ́kọ̀ọ́ l'ókè òkun fi òǹtẹ̀ lu àpilẹ̀kọ ìfi-èhónú kan ní orí ẹ̀rọ-ayélujára, tí wọ́n sì ń t'ọ́ka àbùkù sí Lhamo pé ó ń l'ẹ̀díàpòpọ̀ pẹ̀lú àwọn àjọ tó ń jà fún òmìnira Tibet. Wọn rọ àwọn aláṣẹ ilé-ìwé ọ̀hún láti yọ ọ́ kúrò l'órí òye náà.

Kòbákùngbé ìfèsì ọ̀rọ̀ láti ẹnu àwọn akẹ́kọ̀ọ́ tí ó ń gbé ní òkè òkun gbùngbùn òkè-odò China.

Ìṣàmúlò ẹ̀rọ-alátagbàa ti Lhamo kún fún àwọn kòbákùngbé ìjábọ̀-ọ̀rọ̀ àti èyí tí ó ń pè fún ìwàa jàgídíjàgan, èyí tí kò ṣẹ̀yìn àwọn akẹ́kọ̀ọ́ òkè-òkun tí ó ń gbé gbùngbùn China. Bí àwọn ilé ìgbéròyìn sáfẹ́fẹ́ àgbàńlá-ayé gbogbo ṣe tán ìròyìn-in rẹ̀ ká, àwọn akẹ́kọ̀ọ́ tí ó wà láti Hong Kong àti Taiwan gbìnnàyá láti gbéjàa Lhamo.

Nínú ìfọ̀rọ̀wáni-lẹ́nuwo orí ẹ̀rọ ìbánisọ̀rọ̀ pẹ̀lú Stand News, Chemi Lhamo sọ pé òun nígbàgbọ́ pé ohun tí ó ṣẹlẹ̀ kò sẹ́yìn àwọn àjọ tí wọ́n ń bá Ìjọba China ṣe, ẹ̀sùn èyí tí àwọn òṣìṣẹ́ àgbà àjọ ọba China ti sẹ́ lé lórí.

Kí a tó dìbò yìí, a ti yàn mí gẹ́gẹ́ bí igbá-kejì ààrẹ ìgbìmọ̀ akẹ́kọ̀ọ́ fún oṣù mẹ́jọ gbáko, kò sì sí ohun kan tí ó ṣẹlẹ̀. Ní ìdakèjì, lẹ́yìn gbogbo ìṣẹ̀lẹ̀ẹ pàjáwìrì wọ̀nyìí, kò sí àní-àní pé àjọ kan ń gbìyànjú láti tìka bọ ìṣẹ̀lẹ̀ wọ̀nwọ̀nyí ní bírípó. Ó pani lẹ́rìn-ín pé láti ìgbà yìí wá tí mo ti ń ṣiṣẹ́ gẹ́gẹ́ bí igbá-kejì ààrẹ, bí mo ti ṣe ń ṣe ètò oríṣiríṣi tí n ò sì yé fi àwọn àṣàyàn ìhùwàsí mi l'éde, ṣùgbọ́n kò sí ẹni tí ó ti wádìí nípa àwọn ọ̀nà òṣèlú tí mo yàn ní ààyò.

Ó tẹ̀ síwájú sí i pé ìwà àwọn akẹ́kọ̀ọ́ akẹgbẹ́ òun láti gbùngbùn China tí ń yí padà. Ọ̀kàn nínú àwọn akẹgbẹ́ẹ rẹ̀ tí ó wá láti gbùngbùn China fi ìwàǹwara pè é níjà láti fi èrò rẹ s'óde lórí gbígba òmìnira Tibet. Ó tún gba àwọn ìpè kan, èyí tí ó ń kọ “orin pupa” (orin ọ̀tẹ̀ tí ó ń yín Ẹgbẹ́ Òṣèlú Chinese Communist Party). Àwọn orin wọ̀nyìí kò yé Lhamo, bó ṣe jẹ́ pé kò mọ èdèe Mandarin Ilẹ̀ China sọ.

Bí àkànlù àtakò àti ìjàbọ̀ ṣe ń lọ lọ́wọ́ lórí ayélujára, àpapọ̀ àwọn akẹ́kọ̀ọ́ kan tí gbógun lọ sí ọ́fíìsì ìgbìmọ̀ akẹ́kọ̀ọ́ láti lọ pè fún gbígbé èsì ìdìbò ọ̀hún yẹ̀wò. Ìgbìmọ̀ akẹ́kọ̀ọ́ sì ti ti ìyàrá ìpàdée wọn pa fún ìgbà díẹ̀, nítorí ọ̀rọ̀ àbò.

Chemi Lhamo ti jẹ́ ajàjàǹgbara akẹ́kọ̀ọ́ fún ọdún mélòó kan. Ó jẹ́ ọmọ ẹgbẹ́ tó ní áápọn ní ìlú àjọgbé àwọn Tibet tí ó wà ní Toronto àti pé ó ti kópa nínú ìjàfẹ́tọ̀ọ́ kan tí ó wáyé níta Akànkọ́ Ilé Ẹ̀kọ́ Confucius tí fáfitì ọ̀hún, ẹ̀ka ìbílẹ̀ àjọ ìsọdọ̀kan àṣà Ilẹ̀ China tí ìjọba China ń ṣe agbátẹrù fún lọ́nà tí ó fi ń mú kí China lágbára sí i ní ilẹ̀ òkèèrè. Ní ìgbà yìí wá, ó ti fi èrò ọkàn-an rẹ̀ hàn pẹ̀lú àwọn ajàfẹ́tọ̀ọ́ ìlú láti Hong Kong àti Taiwan lórí kókó ọ̀rọ̀ tó jẹ mọ̀, òmìnira ọ̀rọ̀ sísọ, ìdá-gbé nǹkan ṣe, ìjọba àwarawa àti àwọn kókó tó jọ mọ́ ọ ní ìpàdé ìta gbangba.

Lhamo ò fi ìgbà kan bẹ̀rù láti sọ èrò ọkàn-an rẹ̀ jáde rí tàbí fi ara rẹ̀ hàn gẹ́gẹ́ bí ọmọ Tibet- ó má ń wọ Chuba, aṣọ ìbílẹ̀ àwọn ọmọ Tibet, ní gbogbo ọjọ́ Ọjọ́rú. Títí di ìgbà ìdìbò, kò gbó-òórùn inúnibíni kán rí láti ọ̀dọ àwọn akẹgbẹ́ẹ rẹ̀ tí wọ́n jẹ́ ọmọ China. Èyí ni ó mú u fura pé ìkoni síta bíi ọmọ ọjọ́ mẹ́jọ yìí kò sẹ́yìn àwọn aláṣẹ China.

Láti èèyàn ogúnléndé aláìníbùgbé sí olórí ìgbìmọ̀ akẹ́kọ̀ọ́

Kí ó tó rin ìrìnàjò lọ sí Canada ní ọmọ ọdún mọ́kànlá , Chemi Lhamo jẹ́ ẹni ogúnléndé tí kò rí ibùgbé kan gbé ní India. Àwọn òbíi rẹ̀ àgbà sá kúrò ní ilẹ̀ẹ wọn pẹ̀lú Dalai Lama ní ọdún-un 1959. Nínú hàhámọ́ ìnira tí wọ́n wà yìí, kò sí ibi tí òun àti mọ̀lẹ́bí rẹ̀ lọ, tí wọ́n kà wọ́n kún.

Nígbàkúùgbà tí wọ́n bá bí mí léèrè pé : ‘Ibo lo ti wá?’ Ara mi máa ń kótì láti dáhùn – Ìgbà mìíràn mà á pé India ni mo ti wá, ṣùgbọ́n wọn kò fún mi ní ìwé ìgbèlùú; nígbà mìíràn ẹ̀wẹ̀ mà á dáhùn pé Tibet ni mo ti wá, ṣùgbọ́n tí wọ́n bá béèrè pé báwo ni Tibet ṣe rí, n ò mọ bí n ó ṣe dáhùn-un rẹ̀, ìdí ni pé China ò fún mi ní ìwé ìgbèlùú lọ sí Tibet. Ṣùgbọ́n ìrírí mi bí wọ́n ṣe ń rí mi bíi atọ̀húnrìnwá ti jẹ́ kí n ní ìmọ̀ nípa àṣà àwọn èèyàn mi: àṣà Tibet.

Llamo sọ̀rọ̀ nípa ìrìnàjòo rẹ̀ lọ sí Canada, ọmọ kékeré akẹ́kọ̀ọ́ tuntun kan tí ó wá láti Tibet tí ó bá wá sí ìyàrá ìkẹ́ẹ̀kọ̀ọ́. Ara rẹ̀ yá gágá, inú rẹ̀ dùn láti ṣe alábàpàdé àwọn ọ̀rẹ́ tí ó wá láti ilẹ̀ẹ rẹ̀, bẹ́ẹ̀ ló mọ̀ pé ó lé sọ èdè Tibet. Síbẹ̀síbẹ̀, nínú ìfún-ojúpọ̀, ó sọ fún un pé: “Tí a kò bá sọ èdè Tibet ńkọ́? Mo lè sọ Gẹ̀ẹ́sì.”

N ò mọ̀ bóyá ojú ń tì í ni tàbí ẹ̀rí ọkàn ń jẹ́ ẹ. N ò mọ̀. Ṣùgbọ́n ìgbà náà ni mo tó mọ̀ pé àwọn ọ̀dọ́ Tibet kan ò fẹ́ sọ èdè wọn bí ẹni pé wọn kàn-án nípa fún wọn láti sọ èdè elédè.

Ní ìgbà yẹn, Lhamo jẹ́ ọmọ ọdún 12. Ẹ̀míi rẹ̀ ò lé ‘lẹ̀ nípa ìdánimọ̀ọ rẹ̀, ó yìí ọkàn àwọn òbí rẹ̀ padà láti kó lọ sí àdúgbò tí àwọn ọmọ Tibet ń gbé. Láti ìgbà náà wá, ó kọ́ nípa èdè, àṣà àti ìṣẹ̀ṣe Buddha ti Tibet, ó sì di àjà-fún-ẹ̀tọ́ ọmọ ènìyàn.

Àwọn àdáyanrí ìwà Tibet bíi ìní elẹgbẹ́ ẹni lọ́kàn, ìbọ̀wọ̀ fún àgbà, àìmọ̀kan ní ìpilẹ̀ ìbàjẹ́, ti fún mi ní ìgboyà. Bí ìmọ̀ mi ṣe ń lé kún sí i nínú àṣà ìbílẹ̀ẹ mi, ní ìgboyà mi ṣe ń pọ̀ sí i.

Agbára àti ìgboyà yìí, bí ó ṣe sọ, tí mú u láti lè sọ̀rọ̀ akin gẹ́gẹ́ bí atọ̀hùn-rìnwá àti ọmọ Tibet:

Ó le láti jẹ́ atọ̀hùn-rìnwá, ṣùgbọ́n ìjàjàǹgbara yìí ní ó sọ mí di bí mo ṣe wà. Lónìí, mò ń sọ̀rọ̀ ní ohùn ìrara nípa àwọn ará Tibet ní kíkankíkan àti ìwúrí ọlọ́pẹ́ tí ìdánimọ̀ọ mi gẹ́gẹ́ bí ọmọ Tibet fún mi.

Nígbà tí à ń dìbò ìgbìmọ̀ akẹ́kọ̀ọ́, mo máa ń tẹnu mọ ọn pé ó yẹ kí àwọn tí wọ́n ayàsọ́tọ̀ ní aṣojú nígbà ìdìbò. À ń fẹ́ aṣojú tí yóò rí i wípé à ń rí ẹtọ wa gbà lóòrèkóòrè.

Ìjìyà yóò wá sópin 

Fún Lhamo, ayé tí ó pé pérépéré ni èyí tí kò sí ìdálọ́wọ́kọ́ tàbí ìyàsọ́tọ̀ — Òmìnira Tibet àti ìdádúróo rẹ̀ kọ́ ni ohun tí ó hún jẹ wá lẹ́sẹ̀.

Ìmísí ọjọ́ ọ̀la mi sí Tibet kan náà ni mo ní sì gbogbo àgbá-ńlá-ayé: Mo fẹ́ jẹ́ kí ẹ̀tọ́ tí àwọn ará Tibet ń jẹ gbádùn máà yàtọ̀ sí ti àwọn Canada, àwọn ni òmìnira láti lè sọ èrò ọkàn ẹni, òmìnira láti ní ìgbàgbọ́, òmìnira láti máà fi òṣèlú pá ẹniẹlẹ́ni lẹ́kún.
N ò ṣe ojúṣàájú fún àwọn ará Tibet láti ní àwọn ẹ̀tọ́ wọn yìí nìkan, ó wù mí kí àwọn tí wọ́n wá láti Hong Kong àti Taiwan, ìwọ̀-oòrùn Turkey, àwọn ẹgbẹẹgbẹ̀rún lọ́nà ẹgbẹ̀rún ní ìlọ́po méjì 60 ẹni ogúnléndé tí ó wà ní kárí ayé àti fún gbogbo àwọn ènìyàn láti jàǹfààní ẹ̀tọ̀ wọ̀nyí.

Ọ̀pọ̀ àwọn èèyàn láti Hong Kong ní ìgbàgbọ́ pé China tí ń lo agbára tìkúùkú, wọ́n sì ń lo ètò ìlú láti ṣẹ́ àwọn ọ̀tá àti àwọn ẹ̀yà tí kò pọ̀ lẹ́yìn. Kódà ni Hong Kong, àyè láti sọ ọ̀rọ̀ ẹnu ẹni jáde àti láti bá èèyàn ṣe pọ̀ ti jákulẹ̀.

Àwọn ìpèníjà òṣèlú tí ó ń kojú wọn ní Hong Kong lẹ́yìn Àkójọpọ̀ Ẹgbẹ́ Alábùradà; 2014 Umbrella Movement kò ṣe àjòjì sí Chemi Lhamo, ṣùgbọ́n ó bá àwọn ará Hong Kong kẹ́dùn, ó pẹ̀tù sí wọn lọ́kàn pé kò kí wọ́n máà ṣe juwọ́ sílẹ̀:

Mo kọ́ ẹ̀kọ́ kan nínú àṣà àwọn Tibet nípa àìwàfúnìgbàpípẹ́: gbogbo nǹkan ni òpin yóò dé bá. Mo ní ìgbàgbọ́ pé ìjìyà gbogbo ń bọ̀ wá dópin…Mo ní ìrètí pé ọjọ́ kan ń bọ̀ tí mo máa wọ aṣọ Chuba mi lọ sí Tibet.

Bẹ̀rẹ̀ ìtàkùrọ̀sọ náà

Òǹkọ̀wé, jọ̀wọ́ àkọsílẹ̀ ìwọlé »

Ìlànà

  • Atukọ̀ yóò ṣ'àtúnwò gbogbo ìsọsí . Máà fi ìsọsíì rẹ sílẹ̀ ju ẹ̀rìnmejì lọ tàbí kí a kà á sí iṣẹ́-ìjẹ́-tí-a-o-fẹ́.
  • Jọ̀wọ́ fi ọ̀wọ̀ fún ẹlòmíràn . A ò ní fi àṣẹ sí ìsọsí ìkórìíra, ìṣekúṣe, àti ìdojú-ìjà-kọ ẹnikẹ́ni k.