Iyùn Tobago tí ó ti ń pàwọ̀dà fi hàn gbàgàdàgbagada pé kò sí ọ̀nà mìíràn ju kíkojú àyípadà ojú-ọjọ́

Iyùn bí ìwo àgbọ̀nrín tí ó ti pàwọ̀dà. Àworán láti ọwọ́ọ Matt Kieffer, CC BY-SA 2.0.

Iyùn-un abẹ́ òkúta òkun jẹ́ ohun tí a ò leè fọwọ́ rọ́ sẹ́yìn nínú àwọn àmúṣọrọ̀ tí ó ń mú ọrọ̀ Ajé Tobago àti àwọn àyíká erékùṣù náà gbòòrò. Ibùgbé ọ̀kan-òjọ̀kan ẹ̀yà ẹ̀dá inú omi (àti ibi ẹja pípa fún àwọn apẹja ìbílẹ̀), tí ó sì tún ń dá ààbò bo èbúté, èyí tí kò mú kí àwọn ìjì líle etí omi ó pọ̀ kọjá àlà ni à ń sọ. Òkúta inú òkun Buccoo Reef tí o gbajúmọ̀ bí ìṣáná ẹlẹ́ta tí àwọn arìnrìn-àjò afẹ́ máa ń wọ́ tùùrùtù níbẹ̀ náà kò gbẹ́yìn.

Àmọ́ lẹ́yìn àtẹ̀jáde kan sí ilé ìròyìn tí Àjọ tí ó ń ṣàkóso Omi orílẹ̀ èdè náà (IMA) tẹ̀ jáde ní ọjọ́ 22, oṣù Ògún ọdún-un 2019, èyí tí ó kìlọ̀ wípé – ìwádìíi National Oceanic and Atmospheric Administration (NOAA) Coral Reef Watch sọ wípé — iyùn abẹ́ òkúta òkun Tobago ti bọ́ sì abẹ́ ìṣọ́ láti ṣe òfíntótó “Ìkéde Ìpàwọ̀dàa Ìpele Ìkíni”, gbogbo ojú ló ń wo erékùṣù náà. A ì í ṣe é mọ̀, ìpàwọ̀dà náà lè fò fẹ̀rẹ̀ sí ìpele kejì láàárín ọ̀sẹ̀ díẹ̀, tí yóò sì fa àkóbá fún ìwàláàyè àwọn iyùn wọ̀nyí, àwọn ẹ̀dá inú omi mìíràn àti àwọn olùgbé erékùṣù náà.

Kí ni ohun tí ń pàwọ̀dà ní pàtó?

Alábàágbé àti alájọṣe iyùn ni àwọn ewé inú omi tí ó máa ń bá a kó ohun aṣaralóore pamọ́ àti da èérí ara nù. Ewé wọ̀nyí yóò sì fún iyùn ní okun tí ó nílò fún ìdàgbàsókè, àmọ́ àyípadà ìgbóná inú omi ń dí àjọṣepọ̀ yìí lọ́wọ́.
Bí omi bá gbóná ju bí ó ṣe yẹ lọ (tàbí bí ó bá tutù jù) àwọn iyùn yóò lé ewé omi — tí yóò sì pàdánù ọwọ́ tí ó ń fi oúnjẹ nù ún. Àṣèyìnwá àṣẹ̀yìnbọ̀, ebi yóò pa iyùn kú; àwọ̀ ara tí yóò yí padà ni àmì tí a ó fi mọ̀, ìpàwọ̀dà láti àwọ̀ olómi-ọkà àti ewéko sí funfun egungun.
Ìkéde Ìpàwọ̀dà Ìpele Kìíní ń kéde wípé bí a kò bá wá nǹkan ṣe sí i, àwọn iyùn náà yóò bẹ̀rẹ̀ sí í pàwọ̀dà. IMA dábàá wípé kí àwọn onímọ̀ ìṣẹ̀dá àti ọmọ ìlú ó máa ṣọ́ àwọn ẹ̀dá inú omi náà fún àwọn àmì ìpàwọ̀dà ní àárín-in ọ̀sẹ̀ mẹ́sàn-án sí méjìlá tí ó ń bọ̀.
Ìpele ìpàwọ̀dà kejì yóò jẹ́ ìtọ́ka sí ìpàwọ̀dà iyùn kárí ayé àti ikú iyùn.

Kí ló fa sábàbí? What causes it?

Gẹ́gẹ́ bí onímọ̀ àyíká ìbílẹ̀ Anjani Ganase ti ṣe ṣàlàyé, ọ̀dádá tí ó dá ìpàwọ̀dà iyùn-un Tobago ni ìwọ̀n ìgbóná omi tí ó re òkè — tí í ṣe arapa àyípadà ojú-ọjọ́.
Nínú ímeèlì, Ganase ṣàlàyé wípé òkun máa ń fa èyí tí ó pọ̀ nínú ooru inú afẹ́fẹ́ mu, tí ó sì ń fa kí omi — pàápàá jù lọ àwọn ibú omi jínjìn gbungbunrungbun bíi Ọ̀sàa Caribbean — ó gbóná janjan.
Kódà, ìṣọ́ ọlọ́sẹ̀ méjìláa NOAA Tobago tan pinpin àyípadà yìí dé iyùn Lesser Antilles. Àwọn òkúta tí ó wà ní agbègbè náà, bíi Greater Antilles àti Cuba, ti wà ní Ìpele Kejì Ìkéde Ìpàwọ̀dà:

Kí ni arapa rẹ̀?

Ohun tí ó léwu ni ìpàwọ̀dàa iyùn. Nítorí wípé iyùn máa fún ẹja ní oúnjẹ, òun náà ni ó dúró gẹ́gẹ́ bí ilé fún àwọn ẹja àti fún àwọn ọmọ ẹja tí kòì tíì lè wẹ̀ nínú alagbalúgbú omi, nítorí ìdí èyí, bí a bá pàdánùu wọn, ẹja náà yóò bá wọn lọ. Bí ẹjá bá sì tán lómi, iṣẹ́ bọ́ lọ́wọ́ àwọn apẹja nìyẹn.
Tobago gbẹ́kẹ̀lé iléeṣẹ́ ìrìnàjò afẹ́ ìbílẹ̀; ìdá 40 àwọn arìnrìn-àjò afẹ́ erékùṣù yìí ni ó máa ń wá láti wo àwọn iyùn omi wọ̀nyí. Bí ìpàwọ̀dà bá tẹ̀síwájú, àwọn ènìyàn kò ní rí òkúta iyùn, owó dollar ìrìnàjò afẹ́ yóò fìdí jálẹ̀, tí yóò sì kó bá àwọn iléeṣẹ́ agbàlejò bíi: ilé ìtura, ilé ìjẹun, iṣẹ́ ìgbòkègbodò ọkọ̀ àti ilé iṣẹ́ aṣàkóso ìrìnàjò.
Bí ìjì líle bá ń pọ̀ sí i látàrí ségesège ojú-ọjọ́, òkúta iyùn-ún níṣẹ́ pàtàkì ní ṣíṣe láti fa agbára àwọn ìgbé omi àti ìdúró gẹ́gẹ́ bí alárinà láàárín òkun àti etí òkun — àmọ́ ìgbóná àgbáńlá ayé ń dí i lọ́wọ́ láti ṣiṣẹ́ẹ rẹ̀.
Ìwádìí ti fi ìdíi rẹ̀ múlẹ̀ wípé òkúta iyùn ní ń gba ìdá 90 etídò Tobago sílẹ̀-lọ́wọ́ ọ̀gbàrá tí ìgbé omi ń fà.
Ní ibi ètò Àyájọ́ Ọdún Òkúta iyùn ní Ifásitì West Indies ní ọdún-un 2018, Ọ̀jọ̀gbọ́n John Agard sọ wípé iṣẹ́ yìí yóò pọ̀ sí i bí ìjì ṣe ń pọ̀ sí i àti bí ọ̀sà ṣe ń kún sókè.

Kí ni a lè ṣe láti dẹ́kun rẹ̀?

Ganase ní pé àìmójútò omi wọ̀nyí bí ó ti tọ́ ló fa ẹja pípa kọjá àlà àti ìbàjẹ́ àyíká ni eku ẹdá tí ó fa ìpàwọ̀dà iyùn-un Tobago. Bí ó bá ń bá a lọ bẹ́ẹ̀, títẹmpẹlẹ mọ́ ìṣàkóso àti ààbò òkúta iyùn nìkan ló lè mú kí wọn ó padà bọ̀ sípò àti dàgbà:

Ó yẹ kí òkúta iyùn ó di ohun tí yóò pamọ́ fún àwọn èrò, kí iṣẹ́ ìràpadà ó fẹsẹ̀ múlẹ̀ kí ọ̀wọ́ ẹja onílera àti omi tí ó dára tí yóò mú kí iyùn ó dàgbà ó padà.

Ó sọ síwájú sí i:

Ojúṣe oníkálukú ni láti dín èéfín inú àyíká kù, bẹ́ẹ̀ náà ni ọmọ aráyé ní ẹ̀tọ́ láti béèrè fún iṣẹ́ ìlọsíwájú láti ọ̀dọ̀ àwọn ìjọba kí wọn ó pèsè ohun tí yóò mú nǹkan sún pẹ́lí, ohun èlò àti ìdánilẹ́kọ̀ọ́ nípa ìpamọ́ àti ìfikọ́ra. Ó pọn dandan kí a ṣàkóso àti ìpamọ́ ohun àlùmọ́ọ́nì wa, bóyá ìjọba ni o tàbí iléeṣẹ́ ńláńlá tí ó ń lo àwọn àlùmọ́ọ́nì wọ̀nyí. 

Ó ti di ṣíṣe fún ìjọba ti erékùṣù agbègbè kan náà láti kéde nípa ojúṣe àgbáyé ní ti ìgbógunti ìṣòro àyípadà ojú-ọjọ́. Ní ọjọ́ 11, oṣù Ọ̀wẹwẹ̀, ọdún-un 2019, Olùdarí Barbadia Mia Mottley mẹ́nu lé ìṣòro yìí ní olú iléeṣẹ́ Àjọ Àgbáyé ní Geneva, ó ń rọ àwọn orílẹ̀-èdè ńlá kí wọn ó gbé ìgbésẹ̀ akin láti kọjúu àyípadà ojú-ọjọ́. Ó sọ wípé, erékùṣù Caribbean, “kò ní àsìkò tí ó pọ̀ nítorí [à] ń ṣiṣẹ́ ìyè lọ́wọ́”.

Ganase gbà wípé ọ̀ràn náà gba àtúnṣe ní kíákíá. Ohun gbogbo tí ó bá gbà láti gba òròmọdìẹ ojú-ọjọ́ lọ́wọ́ àyípadà àti ìdẹ́kun ìpàwọ̀dà iyùn ni kí á fi fún un, ó sọ wípé, pàápàá jù lọ “iṣẹ́ ń bẹ” fún àwọn tí ó ń ṣe òṣèlú:

Bí a ṣe ń wò ó, kò ní jẹ́ ohun tí ó rọrùn, àmọ́ ọ̀nà àbáyọ mìíràn ń bẹ.

Bẹ̀rẹ̀ ìtàkùrọ̀sọ náà

Òǹkọ̀wé, jọ̀wọ́ àkọsílẹ̀ ìwọlé »

Ìlànà

  • Atukọ̀ yóò ṣ'àtúnwò gbogbo ìsọsí . Máà fi ìsọsíì rẹ sílẹ̀ ju ẹ̀rìnmejì lọ tàbí kí a kà á sí iṣẹ́-ìjẹ́-tí-a-o-fẹ́.
  • Jọ̀wọ́ fi ọ̀wọ̀ fún ẹlòmíràn . A ò ní fi àṣẹ sí ìsọsí ìkórìíra, ìṣekúṣe, àti ìdojú-ìjà-kọ ẹnikẹ́ni k.