‪Ta ni yóò jáwé olúborí nínú Ayẹyẹ ijó ìta-gbangba orílẹ̀-èdè Trinidad àti Tobago ọdún-un 2019?‬

Aparadà ijó ìta-gbangba kan “fò sókè” sí orin soca ní orí ìtàgé ní Queen's Park Savannah, ní Ijó ìta-gbangba  ọjọ́ Ìṣẹ́gun, ọdún-un 2009. Àwòrán láti ọwọ́ọ Georgia Popplewell, a lò ó pẹ̀lú àṣẹ.

Àwọn alárìíyá máa ń gba títì kan ní ọdọọdún fún Ijó ìta-gbangba Ijó ìta-gbangba Trinidad àti Tobago, tí wọn ń ṣe pẹ̀lú orin. Àwọn àṣàyàn orin tí wọ́n máa ń jó sí máa ń jẹ́ àkójọpọ̀ orin soca tí ó mi ìgboro títì nínú ọdún yẹn, àmọ́ Ìwọ́de Ojúnà — orin náà tí máa ń jẹ́ jíjó jù lọ ní àwọn ibi kọ̀ọ̀kan ní ojú ọ̀nà ìyíde — jẹ́ oyè tí ó mú ẹ̀bùn àti iyì ìgbélárugẹ àjogúnbá ohun àtijọ́.

Fún àwọn òṣèré soca, kí ni kan ní í máa mú ni jáwé olúborí nínú Ìwọ́de Ojúnà, kò ju, dídáńgájíá ní oríi òpópónà. Ní ọdún mẹ́wàá sẹ́yìn tàbí nnkan bẹ́ẹ̀ ni wọ́n sọ pé ìdíje náà ní màgòmágó nínú — pẹ̀lu ìlọ́wọ́sí àwọn alẹ́nulọ́rọ̀ tí ó ni ilé iṣẹ́ ìgbóhùnsáfẹ́fẹ́, afiorin-tí-a-ti-ká-sílẹ̀ dá àwọn ènìyàn lára dá àti àwọn aláṣẹ ilé iṣẹ́ orin kíkọ tí a mọ̀ sí “jàndùkú soca” — kò ì yọ́ ìgbàgbọ́ wípé Ìwọ́de Ojúnà jẹ́ ohun àwọn ènìyàn.

Ìràwọ̀ òṣèrée soca Machel Montano, ẹni tí ó ṣe ojúkòkòrò jáwé olúborí nínú Ìwọ́de Ojúnà ní ẹ̀rìnmẹ́sàn-án, ṣe àpèjúwe rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí “orin tí ó máa ń mú àwọn ènìyàn ní ìdùnnú  àti tí máa ń mú àwọn ènìyàn jáde nínú ara wọn” — akọrin wo ni kò ní fẹ́ gba irú oyè bẹ́ẹ̀?

Àmọ́ kí ẹnikẹ́ni máà rò wípé iṣẹ́ ọpọlọ nìkan ni ìrìnàjò sí Ìwọ́de Ojúnà. Orin Ìwọ́de Ojúnà gbọdọ̀ ní àwọn èròjà tí ó ṣe kókó nínú kí ó tó lè kópa:

1. Ó gbọdọ̀ ṣe é jó sí, síbẹ̀ ó ní láti dùn ún ní etí àwọn ènìyàn tí yóò “mú wọn gbàgbé ara” ní orí ìtàgé, pẹ̀lú ọ̀rọ̀ orin tí yóò mú ayọ̀ jáde, èyí tí a mọ Ijó ìta-gbangba mọ́.

2. Ègbè tí àwọn òǹwòran lè kọ tẹ̀lé orin, ní ìdásí àti ìdáhùn tí í ṣe àṣà calinda, tí calypso — àti àdàlù ìgbàlódé, soca — ti wáyé.
3. Orin tí a gbé jáde ní ìgbà tí ó yẹ. Bí orín bá tètè jáde, tí kò sí dúró pẹ́ títí ní ìgboro, orin mìíràn tí ó ń bá a figagbága lè rọ́ ọ sí ẹ̀gbẹ́. Ní ọ̀nà mìíràn, bí orin tí ó dára gan-an bá pẹ́ jù kí ó tó jáde, àwọn ayírapadà lè máà ní àyè tí ó tó fún wọn láti mọ ọ̀rọ̀ orin náà ní ìgbáradì kí ọjọ́ Ijó ìta-gbangba ó tó dé.

Ní ìgbà mìíràn ẹ̀wẹ̀wẹ̀, ìdíje Ìwọ́de Ojúnà máa ń ní orin àyànfẹ́ tí kò ní afigagbága rárá; kò sí rí bẹ́ẹ̀ nígbà mìíràn, ìfigagbága náà máa ń le dé ibi wípé ó máa ń ṣòro láti yan olúborí. Láì wípé ọ̀kan ju ọ̀kan lọ, àwọn wọ̀nyí ni orin tí a rò wípé yóò figagbága nínú Ijó ìta-gbangba Ìwọ́de Ojúnà Trinidad àti Tobago ọdún-un 2019…

1. “Savannah Grass” láti ọwọ́ọ Kes

Pápáa Queen's Park Savannah, ibi tí ó ní ewéko bíi kàá-sí-nǹkan ní àárín gbùngbùn olú ìlú Trinidad, ni ibi tí ayẹyẹ Ijó ìta-gbangba àti ilé ìtàgé àjọ̀dún náà. Orin yìí dá lóríi agbègbè ayẹyẹ náà, àti ìrántí tí ó ti mú bá àwọn ayírapadà tí ó ti ń kópa láti ọdúnmọ́dún.

Orin náà ń fi ọ̀wọ̀ wọ agbègbè náà: bí ẹni wípé Agbègbè Papa náà ni oòrùn ní àárín àgbá-ńlá Ijó ìta-gbangba àti ohun tí ó kù ń yí i ká. “Savannah Grass” jẹ́ ìpè sí ìrírí idán ayée àjọ̀dún yìí. Bẹ́ẹ̀ kọ́, àmọ́ bẹ́ẹ̀ náà ni, ìlù orin náà ba orin náà mú gẹ́gẹ́ bí àwọn olólùfẹ́ẹ Ijó ìta-gbangba tí ó máa ń gbádùn un Ijó ìta-gbangba ṣe máa ń fẹ́ ẹ.

Orin náà dún dáadáa ní etí àti pé ó mú èèyàn gbàgbé ara rẹ̀, ní ọ̀nà tí ó ń mú kí àwọn ayírapadà ó máa gbé ẹsẹ̀ ní ọ̀kọ̀ọ̀kan bí wọ́n ṣe ń rìn/jó ní ojú ọ̀nà. Orin náà ṣe àmúlò àti àfikún àwòrán ìlànà Ijó ìta-gbangba bí a ti ṣe mọ̀ ọ́ ni ìgbà-dé-ìgbà, fídíò orin náà túbọ̀ ṣe àfihàn ìdàgbàsókè orin soca láti ìpilẹ̀ṣẹ̀ tí í ṣe orin calypso. Bí kò bá ti ẹ̀ jáwé olúborí nínú ìdíje Ìwọ́de Ojúnà (bí ó ti lẹ̀ jé pé ó ní àyè tí ó pọ̀!), “Savannah Grass” yóò wà nínú àkópamọ́ orin soca gẹ́gẹ́ bí orin ìgbà-dé-ìgbà tí ó mú inú àwọn olólùfẹ́ẹ Ijó ìta-gbangba ní ibi gbogbo dùn.

2. “Rag Storm” láti ọwọ́ọ Super Blue, pẹ̀lú àjọṣepọ̀ 3 Canal

Ìwà tí ó dùn mọ́ni ti “playing mas'” àti jíjó sí orin ni wípé ní bákan, àwọn èèyàn máa ń ju ọwọ́ sí òkè, pẹ̀lú ohunkóhun tí wọ́n bá mú ní ọwọ́, títì kan ohun-mímu àti aṣọ inujú. Aṣọ inujú yìí ni wọ́n máa ń pè ní “àkísà”, èyí tí wọn máa fi ń nu àágùn bí wọ́n bá ń “fò sókè”. Ìlànà Ijó ìta-gbangba náà kò sọnù ní ara Super Blue, ẹni tí ó kọ “Get Something and Wave”, orin tí ó jáwé olúborí nínú Ìwọ́de Ojúnà ọdún-un 1991.

Ó fọnrere àtinúdá náà ní ọdún tí ó tẹ̀lé oyè tí ó gbà pẹ̀lú “Bacchanal Time”, tí ó pa àṣẹ fún àwọn ayírapadà láti máa “fi ọwọ́” bí àwọn afọnfèrè  brass ṣe ń kọrin “F-jam” tí gbogbo ènìyàn mọ̀ tàbí “tantana” tí ó ń dún ní abẹ́lẹ̀. Super Blue tí ṣe àgbékalẹ̀ ìlànà fún irúfẹ́ orin kan tí ó dára fún ojú ọ̀nà: ó tún jáwé olúborí ní èèkàn sí i ní ọdún-un 1995 pẹ̀lú orin-in rẹ̀ ewì sí agbábọ́ọ̀lù kríkẹ́ẹ̀tì Brian Lara, tí ó pa á ní àṣẹ fún àwọn olùwòran láti “na pátákóo wọn sí òkè kí wọn ó ṣe àríyá”.

“Ìjì Àkísà” ní àwọn ohun tí ó mú soca yàtọ̀ — bíi irúfẹ́ lavway ìpè-àti-ìfèsì, pẹ̀lú àyè tí ó fẹ́ fún àwọn ènìyàn láti fi àkísà. Orin tí ó dára lórí ìtàgé fún àwọn ayírapadà láti tú ara sílẹ̀ àti “ṣeré tìkára wọn”, lè fi hàn kedere wípé kò kì í ń ṣe wàsá láti fi ọwọ́ rọ́ sí ẹ̀gbẹ́ nínú ìdíje Ìwọ́de Ojúnà ti ọdún nìí.

3. “Famalay” lọ́wọ́ọ Machel Montano, Bunji Garlin àti Skinny Fabulous

Bí ó bá ní orin kan tí ń fi gbogbo ọ̀nà wá oyè Ìwọ́de Ojúnà ti ọdún yìí, ni orin yìí tí ó ní àyè láti jáwé olúborí: ìlù “soca tí ó tani jí”, ọ̀rọ̀ orin tí ó sọ nípa ìṣọ̀kan tí àjọ̀dún náà máa ń mú wá, àti ègbé ọlọ́pọlọ tí ó kó gbogbo ẹ̀yà tí ó ń kópa nínú Ijó ìta-gbangba náà pọ̀ — tí ó ń bá òṣìṣẹ́ akọrin kiri, tàbí bí àwọn ọmọ ìbílẹ̀ Trinbago ṣe máa ń sọ, “famalay” rẹ (kí a máà ṣèṣì fi wé “ẹbí”) :

Well, let me tell you one time, famalay is famalay and that different from bloodline
Some say them is blood but them don't want to see the sunshine
Famalay doh ever ‘fraid to have your back at all time…

Ṣé ẹ rí i , ẹ jẹ́ kí n sọ fún un yín ní ẹ̀rìnkan sí i, famalay ni famalay ń jẹ́ àti pé ó yàtọ̀ sí ẹbí tí ènìyàn ti wá

Àwọn kan ní ẹ̀jẹ̀ ni àmọ́ wọn kò fẹ́ rí oòrùn
Famalay kì í bẹ̀rù láyé láti tì ọ́ lẹ́yìn ní ìgbà gbogbo…

Láì pa àṣẹ (yàtọ̀ sí abala kan tí Skinny kọ “fi ọwọ́ọ̀ rẹ hàn mí” àti “wá tẹ̀lé mi”, orin náà dàbí orin ológun. Ègbé soca tí ó dùn ní etí, pẹ̀lú ọ̀rọ̀ orin dancehall díẹ̀díẹ̀, ti ń da orí àwọn ènìyàn rú ní ìtaja Ijó ìta-gbangba.

Bí ó ti lẹ̀ jé pé ó ní àríyànjiyàn bóyá “Famalay” yóò kópa nínú Ìwọ́de Ojúnà tàbí kò ní í kópa, nítorí Skinny wá láti St. Vincent àti Grenadines, òfin sọ wípé bí “ọ̀pọ̀ àwọn akọrin tí ó ń lé orin” yẹ kí “ó jẹ́ ṣíṣe láti ọwọ́ọ ọmọ bíbíi Trinidad àti Tobago”, orin náà lè jẹ́ afigagbága – eléyìí sì jẹ́ ọ̀kan.

Èyí kì í ṣe wípé orin mẹ́ta péré ni ó ń du oyè. Ó ku bí ọ̀sẹ̀ mẹ́ta kí Ijó ìta-gbangba ó wáyé, àwọn orin wọn mìíràn — tí ó ní akọrin obìrin Destra Garcia àti Patrice Roberts —tí yóò mú ìdíje le fún àwọn ọkùnrin, àti bí àwọn akọrin soca ṣì ń gbé àwo orin tuntun jáde, ìfigagbága Ìwọ́de Ojúnà ọdún-un 2019 ṣì ń lọ lọ́wọ́.

Bẹ̀rẹ̀ ìtàkùrọ̀sọ náà

Òǹkọ̀wé, jọ̀wọ́ àkọsílẹ̀ ìwọlé »

Ìlànà

  • Atukọ̀ yóò ṣ'àtúnwò gbogbo ìsọsí . Máà fi ìsọsíì rẹ sílẹ̀ ju ẹ̀rìnmejì lọ tàbí kí a kà á sí iṣẹ́-ìjẹ́-tí-a-o-fẹ́.
  • Jọ̀wọ́ fi ọ̀wọ̀ fún ẹlòmíràn . A ò ní fi àṣẹ sí ìsọsí ìkórìíra, ìṣekúṣe, àti ìdojú-ìjà-kọ ẹnikẹ́ni k.