‘Ohùn-un Jamaica fún Àyípadà Ojú-ọjọ́’ fi orin jíṣẹ́ẹ wọn

Àwòrán láti fídíò oríi YouTube “Ohùn fún Àyípadà Ojú-ọjọ́ fún Ẹ̀kọ́ Àyípadà Ojú-ọjọ́ – Ìpolongo ọdún 2019,” tí Panos Caribbean tẹ̀ jáde. Iléeṣẹ́ náà ti ṣe ìfilọ́lẹ̀ ìpolongo ìkéde àyípadà ojú-ọjọ́ ní agbègbè mẹ́rin ní àárín-in Jamaica:  Rocky Point àti Lionel Town ní ẹ̀ka ìlúu Clarendon, Ridge Red Bank ní St. Elizabeth àti White River ní St Ann.

Bí orin reggae àti dancehall ṣe ń lọ ni àwọn ìpolongo tí ó ń sọ nípa ohun gbogbo láti ọṣẹ ìfọṣọ àbùfọ̀ sí oúnjẹ àsèsílẹ̀, orin ni ènìyán lè gbà dé ọkàn ọmọ Jamaica — èyí ló mú Panos Caribbean, ẹni tí ó ní ilé iṣẹ́ ìròyìn tí kì í ṣe ti ìjọba, láti fi orin kéde nípa ọ̀rọ̀ àyíká. Iléeṣẹ́ náà ti yege nínúu ìtànká àwọn ìkéde tí ó ṣe kókó nípasẹ̀ẹ iṣẹ́ Ohùn fún Àyípadà Ojú-ọjọ́.

Kedere ni ohùn ń jáde láti inú ilé àpérò ìlú-mọ̀ńká United Nations Conference ní Paris (COP21) lọ́dún-un 2015. Níbẹ̀, ọ̀kọrin ọmọ Jamaica Aaron Silk darapọ̀ mọ́ àwọn olórin mìíràn — pẹ̀lú eléré Belizean Adrian Martinez — láti ṣe alágbàáwí ìdínkù fún ìgbóná àgbáyé sí ìwọ̀n-ọn ojúàmì 1.5.

Ìfiránṣẹ́ olórin náà, tí ó ṣe àtìlẹ́yìn, ipòo ti ìdásílẹ̀ Ìpínlẹ̀ Erékùṣù Kéékèèké Tí-ó-ń-gòkè, jẹ́ ohun àfiyèsí, tí ó ń ní ipa nínúu ìwé-ìpamọ́ ìkẹyìn-in ti COP21.

Ọdún gorí ọdún, iṣẹ́ “1.5 túbọ̀ ń rinlẹ̀ sí i ní ìlà-oòrùn Caribbean, níbi tí àwọn ọ̀kọrin ti ṣe àlọ́pọ̀ ọ̀rọ̀ akéwì St. Lucian Kendel Hippolyte’s pẹ̀lú orin-in ti wọn láti ṣe àrídájú wípé iṣẹ́ náà dé ibi tí ó yẹ kí ó dé.

Olùyàwòrán agbègbè Sammy Junior, láti Rocky Point, Clarendon (agbègbè tí ìrúsókè-odò ọ̀sà àti àgbàrá ibi tí ó súnmọ́ omi ti kó bá) níbi ìdánilẹ́kọ̀ọ́ tí ó dá lóríi Ìfiṣẹ́ránṣẹ́ Àyípadà Ojú-ọjọ́ ní Jamaica ní ọjọ́ 14 oṣù Ẹrẹ́nà, ọdún-un 2019. Àwòrán-an Emma Lewis, pẹ̀lú àṣẹ ni a fi lò ó.

Wàhálà àyípadà ojú-ọjọ́ ní ọdún-un 2019 jẹ́ ohun tí ó nílò àbójútó kíákíá ju ti ìdúnrin lọ, àti ní Jamaica, àwọn ará ìgbèríko tí ó jẹ́ àgbẹ̀, àwọn apẹja ń gbọ́ ìpè itanijí yìí. Akọrin, ọmọ ilé ìwé àti àwọn aládùúgbò péjọ ní — Kingston, Lionel Town, Ridge Red Bank àti White River — fún ìdánilẹ́kọ̀ọ́ ọlọ́jọ́ mẹ́rin nínúu oṣù Ẹrẹ́nà àti Igbe. Níbẹ̀, wọ́n fi ẹ̀kọ́ kún ẹ̀kọ́ ìmọ̀ ìtàkùrọ̀sọ àti kọ́ nípa ipa àyípadà ojú-ọjọ́. Ọ̀rọ̀ orin tí ó lágbára gbérí, ọgbọ́n ń tayọ àti ìrìnàjò ìṣíjú ojú ẹsẹ̀:

Mama Earth she a bawl
Deep inna di forest weh di trees dem a fall
Look pan di reef, see di fish dem small,
Give dem little time, mek dem grow big and tall.

Ìyá Ilẹ̀-ayé ń ké tantan
Nínú igbó kìjikìji níbi tí àwọn igi ń wó sí
Wo òkúta ìsàlẹ̀ òkun, wo ẹja bí ó ṣe kéré
Fún wọn ní àsìkò, jẹ́ kí wọ́n dàgbà àti ga

Àwọn akọrin láti Kingston, Clarendon àti Spanish Town ń ṣiṣẹ́ pọ̀ lóríi ọ̀rọ̀ orin níbi ìdánilẹ́kọ̀ọ́ Ìfiṣẹ́ránṣẹ́ Àyípadà Ojú-ọjọ́. Àwòrán-an Emma Lewis, a lò ó pẹ̀lú àṣẹ.

Pẹ̀lú ìfilọ́lẹ̀ẹ Panos fún àkòrí orin tuntun fún Caribbean fún Àyájọ́ Ilẹ̀-ayé, ẹgbẹ́ẹ  Jamaica náà ti ṣe tán láti ṣe eré ní iléèwé àti ní àdúgbò, láì yọ Kàwé Jákèjádò Jamaica sílẹ̀ àti iṣẹ́ igi gbíngbìn. Àwọn orin báwọ̀nyí, tí a kọ sí orí ìlú reggae àtijọ́ tí a fi àlùjó kún, ṣe kẹ̀rẹ̀kẹ̀rẹ̀ mi ìgboro:

Ìyá Ìṣẹ̀dá ń kérora fún ìwàláàyè
Bí àwọn iléeṣẹ́ ṣe ń ṣiṣẹ́, ìyá ń ké.
Ìgbà wo ni a óò kọ́ ẹ̀kọ́, tí a ó fi gbọ́n?
Bí omi-dídì ilé ayé ṣe ń yọ́, òkun ń kún.

Bẹ̀rẹ̀ ìtàkùrọ̀sọ náà

Òǹkọ̀wé, jọ̀wọ́ àkọsílẹ̀ ìwọlé »

Ìlànà

  • Atukọ̀ yóò ṣ'àtúnwò gbogbo ìsọsí . Máà fi ìsọsíì rẹ sílẹ̀ ju ẹ̀rìnmejì lọ tàbí kí a kà á sí iṣẹ́-ìjẹ́-tí-a-o-fẹ́.
  • Jọ̀wọ́ fi ọ̀wọ̀ fún ẹlòmíràn . A ò ní fi àṣẹ sí ìsọsí ìkórìíra, ìṣekúṣe, àti ìdojú-ìjà-kọ ẹnikẹ́ni k.