Ìròyìn nípa Brazil
Àwọn ọmọ ìbílẹ̀ Brazili ra ìpín ìdókòòwò ní iléeṣẹ́ reluwé láti bá a wí fún ìkùnà ojúṣe àyíkáa rẹ̀
Ìlépa alájọpín-ìdókòòwòo wọn kì í ṣe fún ti èrè ìdókòòwò, àmọ́ láti mú kí ohùn-un wọn ó dé etí ìgbọ́ àwọn olùdókòòwòo iléeṣẹ́ náà.
Fún ìgbà àkọ́kọ́ ní orílẹ̀-èdèe Brazil, ọmọ ìbílẹ̀ lóbìnrin di ọmọ ìgbìmọ̀ ìjọba
Joenia ni ọmọ ìbílẹ̀ lóbìnrin àkọ́kọ́ tí ó kẹ́kọ̀ọ́ gboyè nínú ẹ̀kọ́ ìmọ̀ òfin ní Brazil, òun sì ni agbẹjọ́rò tí ó jẹ́ ọmọ ìbílẹ̀ àkọ́kọ́ tí yóò gbejọ́rò ní Ilé-ẹjọ́ Gíga jùlọ.