‘Boca de Rua': Ìwé ìròyìn ilẹ̀ brazil láti ọwọ́ àwọn ènìyàn tí ó ń gbé ní ojú òpópónà

Marcos Scher ń ta ìwé ìròyìn náà nínú ìdádúró iná adarí ọkọ̀ kí àjákálẹ́ àrùn ó tó bẹ̀rẹ̀. Àwòrán: Charlotte Dafol/ a gba àṣẹ kí a tó lò ó

Ní ọdún mọ́kàndínlógún sẹ́yìn ní Porto Alegre, ní gúúsù orílẹ̀-èdè Brazil, ìwé ìròyìn kan tí àgbáríjọ àwọn tí wọn ń sun ìta àdúgbò ẹsẹ̀kùkú náà bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ ìròyìn títẹ̀ jáde. Boca de Rua (Ẹnu Asùnta, tí a tún mọ̀ sí ìwé ìròyìn Boca) jẹ́ ọgbọ́n orí ọ̀wọ́ àwọn akọ̀ròyìn kan láti pèsè ọ̀nà tí àwọn asùnta àdúgbò yìí fi lè máa fi sọ̀rọ̀ fún ara wọn.

Ní ọdún 2000 ni wọ́n bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ àkànṣe yìí, lẹ́yìn ọdún kan lásìkò ìpàdé àkọ́kọ́ Ẹgbẹ́ Àwùjọ Àgbáyé, ni wọ́n ṣe ìfilọ́lẹ̀ àkọ́kọ́já ewé rẹ̀. Ní òní, ìwé ìròyìn yìí nìkan ni ó jẹ́ ọmọ ẹgbẹ́ Àwọn Ìwé Ìròyìn Ẹsẹ̀kùkú Àgbáyé (INSP) tí àwọn ẹni tí ó ń sùnta ń ṣe jáde.

Àwọn asùnta wọ̀nyí tìkara wọn ni ó pilẹ̀ àwọn ọgbọ́n ìkọ̀tàn, ìfọ̀rọ̀wánilẹ́nuwò àti ti ìbéèrè. Àwọn akọ̀rọ̀yìn méjì kan tí wọ́n ti ń tì kín àwọn asùnta wọ̀nyí lẹ́yìn láti ìgbà tí iṣẹ́ àkànṣe náà ti bẹ̀rẹ̀ ni wọ́n máa ń ṣe gbogbo àwọn àtẹ̀jáde tuntun. Ọ̀wọ́ àwọn afínúfẹ́dọ̀ṣiṣẹ́ kan náà máa ń ṣe àtìlẹyìn nípa gbígba ohùn ìpàdé sílẹ̀, níní àwọn ajábọ̀ ìrọ̀yìn níran àwọn ohun tí ó ṣe kókó àti kíkọ ohùn tí a ká sílẹ̀ ní ọ̀rọ̀ sórí ẹ̀rọ-ayárabíàṣá.

Ìgbàdégbà oṣù mẹ́tamẹ́ta ni ìwé ìròyìn náà ń jẹ́ títẹ̀ jáde. Àwọn ibi tí Boca na ìyẹ́ dé bẹ̀rẹ̀ lórí ìfìyàjẹ tàbí ìjìyà àwọn tí wọ́n wà ní àárín ojú pópó títí kan àwọn ìròyìn rere mìíràn. Láàárin oṣù mẹ́ta, ọ̀wọ́ yìí, pinnu àwọn ohun tí wọn yóò kọ nípa rẹ̀, wọ́n jáde lọ sí oko ìwádìí, wọ́n fi ọ̀rọ̀ wá àwọn ènìyàn lẹ́nu wò, wọ́n ya àwòrán, wọ́n sì kó àwọn ẹ̀rí jọ fún àwọn ìròyìn wọn. Àwọn ọmọ ẹgbẹ́ jáde lọ́pọ̀ yanturu fún iṣẹ́ yìí, ó fẹ́rẹ̀ẹ́ tó ènìyàn 50 tí wọn ń ṣiṣẹ́ lórí àtẹ̀jáde kọ̀ọ̀kan ní àpapọ̀ lórí ìwé ìròyìn ẹlẹ́ẹ̀mẹrin lọ́dún yìí.

Lẹ́yìn tí wọ́n bá tẹ ìwé ìròyìn náà jáde tán, àwọn ọmọ ẹgbẹ́ yóò gbá ìpín láti lọ tà ní àárín àdúgbò Porto Alegre, tí èrè yóò sì lọ sí ọ̀dọ̀ àwọn akọ̀ròyìn/atàwé-ìròyìn. Àtẹ̀jádè yìí tún máa ń rí ìgbọ̀wọ́ láti ọ̀dọ̀ àwọn olólùfẹ́ ìwé ìròyìn yìí, ọ̀pọ̀ nínú wọn ni kò fẹ́ kí orúkọ wọn ó di mímọ̀.

Rosina Duarte, ọ̀kan nínú àwọn tí wọ́n ń ṣẹ̀dá Boca de Rua àti Ilé-ṣẹ́ tí-kìí-ṣe-ti-ìjọba ALICE (Àjọ ọ̀fẹ́ fún ètò ìgbéròyìnsíta, ijọ́mọìlú àti ètò ẹ̀kọ́-ìwé) èyí tí ìwé ìròyìn yìí so mọ́ sọ pé ohun tí àwọ́n gbà lérò tẹ́lẹ̀ ni “láti fi ohùn fún àwọn tí ko ní ohùn”.  Ó sọ wí pé, lẹ́yìn èyí ni àwọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ wá rí i pé ìlérò lásánlàsàn ni, nítorí kò sí ìgbà tí àwọn ènìyàn kì í fọhùn, àwùjọ ló kàn kọ̀ láti tẹ́tí sí wọn.

Nínú ìfọ̀rọ̀wánilẹ́nuwò orí ẹ̀rọ-ìbánisọ̀rọ̀ pẹ̀lú Ohùn Àgbáyé, Rosina sọ pé:

Quando nós chegamos, a gente tinha ainda aquele discurso bonito, que carrega muito resquício do “preconceito bonzinho”, como eu digo, que é o de querer dar algo a eles, de ajudar. Mas a gente percebeu que nós é que tínhamos que ser alfabetizadas na linguagem da rua. Eles não tinham a alfabetização da linguagem escrita, mas nós éramos analfabetas completas sobre a vida na rua.

Nígbà tí a bẹ̀rẹ̀, a máa ń lo àwọn ọ̀rọ̀ tí ó lẹ́wà gan-an ni, èyí tí ó mú kí ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ènìyàn abẹ́lé ó máa  hu ìwa “yíyin ẹni láigba tẹni ọ̀hún” bi mo ṣe lè pè é nìyẹn, tí í ṣe ọ̀nà tí yóò jẹ́ ìrànlọ́wọ́ fún wọn. Ṣùgbọ́n a rí i pé àwa ni ó yẹ kí a di ọ̀mọ̀wẹ́ èdè àmúlò àwùjọ wọn. Wọn kò ní ìmọ̀-mọ̀-ọ́n-kọ mọ̀-ọ́n-kọ̀ bẹ́ẹ̀ ni àwa náà kò sì ní òye ìgbéayé àwọn tí wọ́n ń gbé ní títì rárá.

Catarina àti Daniel wọ aṣọ ìbomúbẹnu tí ó ní àmì ìdámọ̀ Boca lára | Àwòrán: Luiz Abreu / a gba àṣẹ kí a tó lò ó

Èrò àwọn akọ̀ròyìn yìí ní ìbẹ̀rẹ̀pẹ̀pẹ̀ ni láti ṣe ìdásílẹ̀ ètò orí rédíò tí wọn yóò sì darí afẹ́fẹ́ ètò náà sórí àwọn gbohùngbohùn tí wọn yóò gbé sí orí àwọn òpó iná ẹ̀bà títì ní àárín ìgboro. Ṣùgbón nígbà tí wọ́n bá ọ̀wọ́ àwọn ènìyàn kan tí wọn kò tilẹ̀ nílé lórí sọ̀rọ̀, wọ́n ranrí pé àwọn kò fẹ́, ariwo: “A fẹ́ ìwé ìròyìn tí yóò máa sọ nípa wa” ni wọ́n ń pa. Rosina sọ pé èrò yìí kọ́kọ́ kọ òun lóminú, ṣùgbọ́n ó padà bùṣe gàdà.

Quando eles disseram que queriam um jornal, fomos atrás de financiamento, ainda tateando no escuro, sem saber o que fazer. Mas um dia caiu a ficha: ao contar o que acontecia nas ruas, eles faziam notícia. E, se eles tivessem consciência disso, o texto se organizava de uma forma muito clara. Porque a gente faz notícia o tempo inteiro. Tem os que fazem de uma forma mais objetiva, outros menos objetiva, mas a gente faz.

Nígbà tí wọ́n sọ pé àwọn fẹ́ ìwé ìròyìn, a bẹ̀rẹ̀ sí ní wá owó kiri, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé inú òkùnkùn ni a wà tí a kò sì mọ ohun tí a ó gbámú ṣe. Sùgbọ́n èyí padà dópin lọ́jọ́ kan: pẹ̀lú bí a ṣe ròyìn ohun tí ó ń lọ ní ojú pópó, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí ní gbé ìròyìn yìí kiri. Bí wọ́n bá sì ti mọ̀ nípa rẹ̀, ọ̀nà à á gbà di lílà fúnra rẹ̀ nìyẹn. Ìdí ni pé gbogbo ìgbà ni a máa ń ṣiṣẹ́ lórí ìròyìn. Àwọn kan ń ṣe é láì fi-igbá-kan-bọ-ìkan-nínú, àwọn kan kò sì náání òtítọ́, ṣùgbọ́n à ń ṣe é.

Nígbà tí ó yá ìwé ìròyìn yìí di ohun tí a lè pè ní ẹgbẹ́ àwùjọ. Ẹgbẹ́ náà ń pàdé lọ́sọ̀ọ̀ọ̀sẹ̀ láti jíròrò lórí ìbèèrè fún ẹ̀tọ́ àti àwọn ọ̀nà tí wọ́n lè gbà ran àwọn ọmọ ẹgbẹ́ lọ́wọ́. Wọ́n tilẹ̀ so pẹ̀ mọ́ oríṣìíríṣìí ẹgbẹ́ bí i Movimento Nacional da População de Rua (Àgbáríjọ àwọn ènìyàn ojú títì lórílẹ̀-èdè) àti Amada Massa (Loving Dough) ilé-iṣẹ́ adínkàrà tí èròǹgbà rẹ jẹ́ láti sọ àwọn tí wọ́n ti pẹ́ ní  àdúgbo esẹ̀kùkú Porto Alegre di òmìnira ara wọn.

Ní ìbàmu pẹ̀lú àkóónú ìwé ìròyìn náà, Rosina sọ pé:

Parece que é só sofrimento, parece que é só dificuldade. E não é. Descobrimos essa alegria, essa resistência, valorizamos essa imensa, fantástica capacidade de sobreviver, não só de se manter vivo, mas de manter viva a esperança, a alegria, o afeto e todas essas questões.

Ó fara jọ ìyà ni kì í ṣe ìyà, ó fojú jọ ìṣòro ni kì í ṣe ìṣoro. A ti ṣàwárí ayọ̀ yìí, ìtakò yìí, nínú rẹ̀ bẹ́ẹ̀ ni a mọ rírì agbára dáradára tí kò jẹ́ kí ó kú, kì í ṣe pé ti àìkú rẹ̀ nìkan bíkò ṣe mímú ìrètí, ayọ̀ àti àwọn ohun mìíràn tí ó ti wà pẹ̀lú rẹ̀ wà láàyè.

.

Ohùn láti àdúgbò ẹsẹ̀kùkú

Nínú ìfọ̀rọ̀wánilẹ́nuwò orí ẹ̀rọ-ìbánisọ̀rọ̀ pẹ̀lú Ohùn Àgbáyé, Elisângela Escalante, tí ó dara pọ̀ mọ́ ẹgbẹ́ náà ní ọdún mẹ́fà sẹ́yìn nígbà tí òun náà ń sun ìta tẹnumọ́ ipa tí ìwé ìròyìn náà ti kó nínú ayé òun.

Muita coisa aconteceu comigo através do jornal. Ele me tirou da rua. Porque eu vivi três anos e meio na rua e eu saí depois de uns meses indo pro jornal. Eu fui guardando um dinheiro e comecei a alugar o meu espaço. Antes eu não ganhava o meu dinheiro, dependia do meu companheiro pra tudo. Faz diferença pra mim, eu gosto de ter meu dinheiro.

Mẹ́wàá ṣẹlẹ̀ sí mi láti ara ìwé ìròyìn yìí. Òhun ni kò jẹ́ kí n sun ìta mọ́. Ìdí ni pé ìta ni mò ń sùn fún odidi ọdún mẹ́ta àti ààbọ̀, mi ò sì sun ìta mọ́ lẹ́yin bí oṣù mélòó kan tí mo dara pọ̀ mọ́ ìwé ìròyìn yìí. Mo bẹ̀rẹ̀ sí ní fi owó pamọ́ láti gba ilé tí èmi náà yóò máa gbé. Tẹ́lẹ̀, mí ò ní ọ̀nà ìpawówọlé kankan, ọkọ mi ni mo máa ń wojú rẹ̀ fún ohun gbogbo. Ó yí ayé mi padà torí èmi pẹ̀lú fẹ́ ní owó ti ara mi.

Ojúewé ìta ìtẹ̀jáde tí ó ṣe àgbéyẹ̀wò ìpèníjà tí ó ń kojú àwọn ìyá tí ó ń gbé ní títì. Àwòrán: Agência ALICE/Boca de Rua, a gba àṣẹ kí a tó lò ó.

Elisângela rántí ọ̀kan pàtó nínú àwọn àtẹ̀jáde ìgbàdégbà wọn èyí tí àkọ́lé òke rẹ̀ jẹ́: “Kí ló dé tí a ò le jẹ́ ìyá? Àtẹ̀jáde yìí sọ̀rọ̀ lórí ìṣòro tí àwọn obìnrin tí ó ń  tọ́ ọmọ ní ojú òpópónà ń kojú.

Elisângela sọ pé: Nígbà tí a ń ṣe èyí lọ́wọ́ àwọn tí wọ́n jẹ́ ìyá nínú àwọn ọmọ ẹgbẹ́ gbìyànjú láti kàn sí àwọn ọmọ wọn tí wọn kò bá sọ̀rọ̀ láti àìmọye ọdún sẹ́yìn.

Eu acho que o que a gente fala [no jornal] é a verdade. É o que a gente sente e o que a gente vive dentro da sociedade. Se não fosse o Boca, não teria outra maneira de fazer isso e ser ouvido por tanta gente. Através dele eu consegui muitas coisas e ajudei muitas pessoas também.

Mo lérò wí pé òtítọ́ ni ohun tí a sọ [ìyẹn nínú ìwé ìròyìn]. Ó jẹ́ ìrírí àti ohun tí à ń là kọjá ní àárín àwùjọ. Bí kò bá sí Boca, kò bá tí sí ọ̀nà mìíràn tí n ó gbé èyí gbà tí ọ̀pọ̀ ènìyàn ó sì gbọ́ mi tó báyìí. Pẹ̀lú rẹ̀ mo jẹ ọ̀pọ̀ àǹfààní, mo sì ṣe ìrànlọ́wọ́ fún ọ̀pọ̀ ènìyàn bákan náà.

Fún ìgbà àkọ́kọ́ nínú ìtan, ìwé ìròyìn yìí di èyí tí a kò le tà ní àárín àdúgbò látàrí àjàkálẹ̀ àrùn COVID-19. Nínú akitiyan láti ṣe ìgbésókè sí owó tí ó ń wọlé fún àwọn ajábọ̀ ìròyìn, Boca de Rua ti gbé aṣọ tuntun wọ̀, ó ti bọ́ sórí ẹ̀rọ ìgbàlódé fún kíkà lórí ẹ̀rọ ayélujára.

Pẹ̀lú ìdáwójọ iye òwó tí ó tó 20BRL owó ilẹ̀ Brazil (tí ó ń lọ bi 3.75 owó dọ́là ilẹ̀ America) ní osù mẹ́tamẹ́ta àwọn ọ̀nkàwé máa ń rí àyè ka àgbéjáde Boca tuntun náà, tí ó fi mọ́ ti tẹ́lẹ̀ àti àwọn nǹkan mìíran.

Ohun tí ó ṣe pàtàkì jù fún àwọn aládàásí àti àwọn ajábọ̀ ìròyìn ni pé ohùn àwọn tí ó fi títì ṣe ibùgbé ń di gbígbọ́ ketekete síbẹ̀ ní àsìkò àjàkálẹ̀ àrùn yìí. Nínú ìtàkùrọ̀sọ orí ẹ̀rọ-ìbánisọ̀rọ̀ nípa ohun tí ó rí sí ìwé ìròyìn náà, Marcos Sher, ọmọ ọdún 13 tí ó jẹ́ ògbóntarìgì Boca sọ báyìí pé:

Pra mim é bom, muito bom. Pra você ver que eu não largo, né? Às vezes eu dou um tempo, mas eu volto de novo. Pra mim o jornal foi uma maneira de sair do tráfico [de drogas] e voltar a trabalhar. É bom porque é alguma coisa pra fazer, pra me tirar de casa. Ter alguma coisa pra fazer é muito importante pra mim.

Ní tèmi ó dára, ó dára gidi ni. Ẹ̀yín náà rí i pé èmí náà kò gbé e tì, àbí irọ́ ni mo pa? Nígbà mìíràn mo máa ń pa á tì, ṣùgbọ́n mà á tún bẹ̀rẹ̀ rẹ̀ padà níbi tí mo fi tì sí. Ní tèmi, ìwé ìròyìn yìí jẹ́ ọ̀nà láti bọ́ kúrò nínú oògùn olóró gbígbé ó sì dá mi padà sí ẹnu iṣẹ́. Ó dára nítorí pé ènìyàn ń rí nǹkan ṣe tí ènìyàn bá kúrò nílé. Rírí nǹkan máa ṣe bí iṣẹ́ ṣe pàtàkì sími púpọ̀.

Ìfiyèsí olóòtú: Talita Fernandes ń ṣiṣẹ́ pẹ̀lú ìwé ìròyìn Boca de Rua (Porto Alegre, Rio Grande do Sul) ó sì kọ àpilẹ̀kọ kan “Ojú títì, ọ̀rọ̀-orúkọ ti ìwà obìnrin: àwọn obìnrin nínú ìgbésẹ̀ àti ìjà-fún-ẹ̀tọ́ sí ti ara ní ìlú”, láti ọwọ́ Ifásitì Ìjọba Àpapọ̀ Rio Grande do Sul (UFRGS).

Bẹ̀rẹ̀ ìtàkùrọ̀sọ náà

Òǹkọ̀wé, jọ̀wọ́ àkọsílẹ̀ ìwọlé »

Ìlànà

  • Atukọ̀ yóò ṣ'àtúnwò gbogbo ìsọsí . Máà fi ìsọsíì rẹ sílẹ̀ ju ẹ̀rìnmejì lọ tàbí kí a kà á sí iṣẹ́-ìjẹ́-tí-a-o-fẹ́.
  • Jọ̀wọ́ fi ọ̀wọ̀ fún ẹlòmíràn . A ò ní fi àṣẹ sí ìsọsí ìkórìíra, ìṣekúṣe, àti ìdojú-ìjà-kọ ẹnikẹ́ni k.