Àwọn ìdílé l’órílẹ̀-èdè Kenya fi ara kááṣá látàrí ipa ìfọjọ́-kún ilé-ìwé tí ó wà ní títì pa

Ọ̀rọ̀ Olóòtú: Àgbéjádè yìí jẹ́ àjùmọkọ aládàásí Ohùn Àgbááyé Bonface Witaba, aládàásí àlejò Sri Ranjini Mei Hua, aṣèwádìí àti òǹkọ̀wé láti Singapore. 

Ní oṣù Èrèlé, ìjọba ilẹ̀ Kenya kéde àfàró àwọn ilé-ìwé ilẹ̀ náà gẹ́gẹ́ bí ọ̀kan nínú àwọn ọ̀nà láti dẹ́kun ìtànkálẹ̀ àrùn COVID-19. Ìkéde yìí da àwọn àlàkálẹ̀ ẹ̀kọ́ ní àwọn ilé-iwé ilẹ̀ náà rú, léyìí tí ó ṣe àkóbá fún ẹgbẹẹgbẹ̀rún 18 àwọn akẹ́kọ̀ọ́ jákèjádò orílẹ̀-èdè náà. Ó gbégi dínà ìtẹ̀síwájú sísọ ètò-ẹ̀kọ́ di tọ́rọ́ fọ́n kálé, ìdọ́gba àti ètò-ẹ̀kọ́ tó mọ́nyánlórí gẹ́gẹ́ bí ó ṣe wà nínú Àgbéṣe 4 ti Ìgbéró Ìlépa Ìdàgbàsókè Àjọ Ìsọ̀kan Àgbáyé.

Lára àwọn ìgbìyànjú wọn láti rí i pé ẹ̀kọ́kíkọ́ ń tẹ̀síwájú bí wọ́n ṣe ń dáàbò bo ìlera, ìgbéláìléwu, àti ìgbáyégbádùn àwọn akẹ́kọ̀ọ́ àti olùkọ́, ni Ilé-iṣẹ́ Ètò-ẹ̀kọ́ ilẹ̀ náà pẹ̀lú àjọṣepọ̀ àwọn àjọ elétò ẹ̀kọ́ mìíràn ṣe ìdásílẹ̀ Àjọ elétò ẹ̀kọ́ ìpìlẹ̀, abetíwéré sí ìṣẹlẹ pàjáwìrì COVID-19 ti ilẹ̀ Kenya pẹ̀lú èròǹgbà láti mú ìdàgbàsókè bá ẹ̀kọ́ àtẹ̀yin yàrá ìkẹ́kọ̀ọ́ kọ́ pẹ̀lú ìṣàmúlò ẹ̀rọ̀ asọ̀rọ̀mágbèsì, amóhùnmáwòran, ìgbéṣẹ́ sórí àwọ̀-sánmà, àti àwọn ẹ̀rọ ìbánisọ̀rọ̀ ìléwọ́ alágbèéká.

Ní ọ̀ní, pẹ̀lú akitiyan Àjọ tí o ń mú ìdàgbàsókè bá àlàkalẹ̀ ètò-ẹ̀kọ́ ní ilẹ̀ Kenya (KICD) láti fẹ ìkẹ́kọ̀ọ́ orí ẹ̀rọ ayárabíàṣá lójú sí i, ìdá 80 àwọn akẹ́kọ̀ọ́ ni àwọn tí kò rí àǹfààní ẹ̀kọ orí afẹ́fẹ́ yìí jẹ síbẹ̀, gẹ́gẹ́ bí èsì ìwádìí tí Àgbéṣe Usawa gbé jáde (gbàgede ajẹmẹ́kọ̀ọ́ orí ẹ̀rọ-ayélujára).

Èyí wáyé látàrí àìdọ́gbà òòrè-ọ̀fẹ́ sí ìlò irinṣẹ́ ìmọ̀-ẹ̀rọ amúṣẹ́yá bí i ẹ̀rọ̀-ayárabíàṣá, ẹ̀rọ̀ ayárabíàṣá àgbélétantẹ̀, tàbí àwọn èrọ̀-ìbánisọ̀rọ̀ ìléwọ́ ayárabíàṣá tí ó fi mọ́ ọ̀hángógó iye owó ìṣàmúlò èrọ ayélujára àti kùdìẹ̀kudiẹ nídìí ìṣàmúlò èrọ ayélujára pàápàá jùlọ fún àwọn akẹ́kọ̀ọ́ láti àwọn ìdílé tí wọn kò rí jájẹ àti àwọn ìlú tí wọn kò kàsí. Kódà níbi tí ẹ̀rọ ti wà lárọ̀ọ́wọ́tó gan-an, àìmáatọ́ àwọn ọmọ sọ́nà nídìí ìṣàmúlò ẹ̀rọ ayélujára gan-an alára jẹ́ ohun tí ó ń kọ ènìyàn lóminú.

Kí ìtípa yìí tó bẹ̀rẹ̀, àwọn akẹ́kọ̀ọ́ ní ooreọ̀fẹ́ sí ouńjẹ ọ̀fé ní ilé-ìwé. Àwọn òmọdébìnrin inú wọn ní oore-ọ̀fẹ́ sí àṣọ ìlédìí ìsé-nǹkan-àlejò ti ètò kan fún ìpèsè àṣọ ìsé-nǹkan-àlejò. Pẹ̀lú bí ìtìpa yìí ṣe ti gùn sì, Akọ̀wé Ìgbìmọ̀ Ètò-ẹ̀kọ́ George Magoha ti kéde pé àwọn àlàkalè ilé-ìwé ti “bómi lọ”, tí ó túnmọ̀ sí wí pé àwọn ilé-ìwé yóò wà ní títìpa síbẹ̀ títí di ọdún 2021, léyìí tí yóò sọ ọ̀pọ̀ àwọn akẹ́kọ̀ọ́ sí ipò òṣì pẹ̀lú bí àwọn ẹbí wọn kò ṣe lè pèsè ouńjẹ àti àwọn ohun èlò tí  ó ṣe kókó látàrí àìríṣẹ́ṣe ẹnu lọ́wọ́lọ́wọ́ yìí.

Ní ìlú Kibra, fún àpẹẹrẹ, agbègbè tí wọ́n rí gẹ́gẹ́ bí ibi tí ìṣẹ́ àti ìyà sodo sí jùlọ ní Nairobi (àti ní ilẹ̀ Adúláwọ̀) ọ̀pọ̀ àwọn akẹ́kọ̀ọ́ ni wọn kò ní oore-ọ̀fẹ́ sí àlàkalẹ̀ ẹ̀kọ́ àtẹ̀yìn yàrá ìkẹ́kọ̀ọ́ kọ́ àjọ KCID, bẹ́ẹ̀ ni ọ̀pọ̀ kò tilẹ̀ ní ibi tí wọn ó ti kẹ́kọ̀ọ́ áḿbèlètàsé ibi eré ìdarayá.

(Láti ọ̀pọ̀ ọdún séyìn, agbègbè yìí ti ń jẹ́ pípẹ̀ ní “Kibera” tí í ṣe àṣìpè Kibra tí ó túmọ̀ sí “igbó kìjikìji” ní èdè Nubia. Fífi ọmọ peni lérú ni àwọn ara agbègbè Nubia ní Kenya máa ń rí lílo “Kibera” sí)

Nínú ìfọ̀rọ̀wánilẹ́nuwò lórí Skype pẹ̀lú Asha Jaffar, akọ̀rọ̀yìn tí ó ń gbé ní Kibra, ẹni tí ó gbé ìròyìn nípa ewu tí ó wu àwọn agbègbè Kibra, Jaffar sọ fún Ohùn Àgbáyé pé  àwọn yàrá ìkàwé lọ́fẹ̀ẹ́ tí ó lè gba àwọn akẹ́kọ̀ọ́ mẹ́wàá ní ẹ̀ẹ̀kan ṣoṣo kò tó nǹkan. Àmọ́, àwọn akẹ́kọ̀ọ́ wọ̀nyí ní láti máa fi àyè wọn sílẹ̀ lẹ́yìn bíi wákàtí kan kí ọ̀wọ́ àwọn akẹ́kọ̀ọ́ mìíràn lè ṣàmúlò àwọn àyè náà. Ó fi kún un pé iná ètò fún owó ilé-ìwé ọ̀fẹ́ fún àwọn akẹ́kọ̀ọ́ ní láti jó rẹ̀yìn nítorí òfin jíjìnnà síraẹni láwùjọ tí ìjọba àti àwọn ikọ̀ elétò ìlera kàn nípá.


Asha Jaffar, akọ̀rọ̀yìn àti olùgbé Kibra ń nawọ́ sí àwọn ibùgbé Kibra. Àwòrán láti Ètò ìpèsè Ouńjẹ ọ̀fé Kibra, Oṣù Ògún, ọdún 2020. Àworan jẹ́ lílò pẹ̀lú ìyọ̀nda.

Ipa ìtìpa ọlọ́jọ́ gbọọrọ àwọn ilé-ìwé náà ti ń kọjá agbára bẹ́ẹ̀ ni ó sì ń lapa burúkú lórí àwọn ìdílé tí wọn kò rọ́wọ́ họrí. Pẹ̀lú bí aáyan àtijẹ-àtimu ṣe borí aáyan ètò- ẹ̀kọ́, àwọn akẹ́kọ̀ọ́ pàápàá àwọn omọdébìnrin àti àwọn abilékọ kékèké láti àwọn ìdílé tí ìṣẹ́ ń bá fínra nílò láti ṣe iṣẹ́ oko dídá àti àwọn iṣẹ́ ilé tàbí iṣẹ́ àgbàtọ́ dípò ẹ̀kọ́ ìwé kíkọ́. Èyí wáyé nínú ìtìpa yìí tí ó ṣe déédé pẹ̀lú àkókò tí ọ̀gbìn ṣíṣe wọ́pọ̀ jùlọ ní oṣù Ẹrẹ́nà.

Àwọn ọmọdébìnrin mìíràn gan-an le tibẹ̀ ti kékeré lọ́kọ léyìí tí yóò sọ wọ́n sínú ewu pípa ilé-ìwé tì láti ara oyún àpàpàndodo. Nítorí náà, ètò-ẹ̀kọ́ nínú àwọn ìdílé tí ìṣẹ́ ń bá fínra yóò lami, ìdí ni pé ọ̀pọ̀ nínú wọn ni kò rí ìdí pàtàkì tí ó fi yẹ kí àwọn ó darí àwọn ọmọ àwọn padà sí ilé-ìwé tí àwọn ilé-ìwé bá di ṣísí padà.

Ní oṣù Ẹrénà, Jaffar ṣe ìfilọ́lẹ̀ Ìpèsè Ouńjẹ ọ̀fé Kibra, láti lé ebi jìnà sí agbègbè Kibra pẹ̀lú fífi àpọ̀ kékèké tí ó kún fún oríṣìíríṣìí oúnjẹ ta àwọn ìdílé kòlàkòṣagbe lọ́ọrẹ. Ó bẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú wíwá àwọn ìtọrẹ àánú lórí M-pesa (àpò owó orí èrọ ìbánisọ̀rọ̀ alágbèéká) pẹ̀lú èrọ̀ngbà láti bọ́ àwọn ìdílé tí kò ń ọ̀pọ́n pọ́n là 100 fún ọ̀ṣẹ̀ kan, ṣùgbọ́n pẹ̀lú bí àwọn tí wọ́n nílò ìrànlọ́wọ́ ṣe ń pọ̀ si, ètò yìí ti bọ́ ìdílé tí ó tó 2400 títí di Ọjọ 5, Oṣù Ògún. Jaffar rí i mọ̀ pé ìpèsè oúnjẹ ọ̀fẹ́ kò tó nítorí pé àwọn ìdílé yìí nílò àtìlẹ́yìn láti bẹ̀rẹ̀ oko-òwò kéékèèké. Àmọ́ ṣá o, orọ̀ ajé agbègbè yìí dùró gbọhin pẹ̀lú bí káràkátà ṣe ti wara ro.

Afínúfẹ́dọ̀ pín oúnjẹ fún àwọn ènìyàn ibùgbé Kibra láti Ètò ìpèsè Ouńjẹ ọ̀fé Kibra, Kenya, Oṣù Ògún, ọdún 2020. Àwòrán láti Ètò ìpèsè Ouńjẹ ọ̀fé Kibra. Àworan jẹ́ lílò pẹ̀lú ìyọ̀nda.

Kenya ń retí ọdún ètò-ẹ̀kọ́ tuntun nì ọdún 2021Ṣùgbọ́n èyí tún wà lọ́wọ́ iye ènìyàn tí àrùn COVID-19 bá kọlù —  gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ Magoha, Akọ̀wé Ìgbìmọ̀ Ètò-ẹ̀kọ́.

Ọ̀pọ̀ àwọn amòye nídìí ètò ẹ̀kọ́ sọ báyìí pé àkókò yìí jé oore-ọ̀fẹ́ fún ìjọba láti ṣe ìgbéléwọ̀n ètò-ẹ̀kọ́, kí wọn ó sì tún iná ìpèsè ẹ̀kọ́ fún tẹ̀rútọmọ dá gẹ́gẹ́ bí àfojúsùn àjọ elétò ẹ̀kọ́ ìpìlẹ, abetíwéré sí ìṣẹ̀lè pàjáwìrì COVID-19 ti ilẹ̀ Kenya. Ìgbésẹ̀ àkọ́kọ́, yóò jẹ́ ìya owó sọ́tọ̀ láti mú ìdàgbàsókè bá ilé-ìwé nípa ìpèsè iná, àwọn tábìlì ìkàwé, àga ìjókòó àti iná mọ̀nàmọ́ná tó ṣeé fọkàn tán, pàápàá jùlọ ní àwọn ìgbèríko. Léyìn èyí, ìjọba lè mú àdínkù bá owó iná àti owó omi ní àwọn ilé ìwé nítorí pé bí ó ṣe gbérí yìí ń pa iṣẹ́ wọn lára.

Léyin bí àwọn ohun tí ó ṣe kókó wọ̀nyí bá ti di yíyanjú nìkan ni ìgbìyànjú le bẹ̀rẹ̀ lórí Iṣẹ́ àkànṣe ìkàwé ìgbàlódé alápilẹ̀rọ tí ìjọba gbé jáde ni ọdún 2013. Ètò Mọ̀ọ́kọ-mọ̀ọ́kà Ẹ̀rọ-ayárabíàṣá yìí gbèrò láti rí i wí pé àwọn akẹ́kọ̀ọ́ ilé-ìwé alákọ̀ọ́bẹ̀rẹ̀ (onípò 1-3) lè lo àwọn èrọ ìgbàlódé àti àwọn ohun èlò ìbáraẹnisọ̀rọ̀ pẹ̀lú èròǹgbà láti mú kí ètò ẹ̀kọ́ ilẹ̀ Kenya ó bá ti ọgọ́rùn-ún ọdún 21 mu.

Iṣẹ́ àkànṣe náà fẹ́rẹ̀ẹ́ má gbéra sọ bí wọ́n ṣe kọ́kọ́ múra sí i tó pẹ̀lú bí àwọn àfojúsùn wọn ṣe kùnà àti bí ìmúrasílẹ̀ àwọn olùkọ́ ṣe mẹ́hẹ. Láti le kẹ́sẹ járí, ètò yìí nílò kí wọn ó dá àwọn olùkọ́ lẹ́kọ̀ọ́ ìlò àwọn ẹ̀rọ ìgbàlódé kí wọn ó bà lè ṣàmúlò àwọn ẹ̀rọ náà bí ó ti yẹ.

Ọ̀pọ́n Orílẹ̀-èdè Kenya ti sún láti ìṣètò Ẹ̀kọ́ alákọ̀ọ́bẹ̀ẹ̀rẹ̀ káàkiri àgbáyé (UPE) sí àgbéṣe Ẹ̀kọ́-ìwé fún gbogbo ènìyàn (EFA), UPE tí ó jẹ́ Ìlépa kejì Ilépa ìdàgbàsókè ti Ẹgbẹ̀rún ọdún Àjọ Ìsọ̀kan Àgbáyé tí ó gbèrò láti rí i wí pé nígbà tí ó bá fi máa di ọdún 2015, gbogbo ọmọ ní jákèjádò àgbáyé ni wọn ó ti parí ilé-ìwé alákòóbẹ̀ẹ̀rẹ̀, ṣùgbọ́n EFA ní tirẹ̀ jẹ́ ìpolongo àgbáyé tí àjọ UNESCO léwájú rẹ̀, pẹ̀lú èròǹgbà láti mú àǹfààní ẹ̀kọ́-ìwé tọ “gbogbo ọmọ ìlú ní gbogbo àwọn àwùjọ ”  àgbáyé lọ. Pẹ̀lú àwọn àǹfààní wọ̀nyí, orílẹ̀-èdè Kenya ò gbọdọ̀ fa ọwọ́ aago ìdàgbàsókè yìí sẹ́yìn.

Ìpènijà tí ó kángun sí orílẹ̀-èdè Kenya báyìí ni láti rí i wí pé àwọn akẹ́kọ̀ọ́ ní oore-ọ̀fẹ́ sí àwọn iṣẹ́ àkànṣe ìkàwé ìgbàlódé tí kì í ṣe ẹ̀kọ́-ìwé nìkan ni yóò máa kọ́ni, sùgbọ́n àpapọ̀ ẹ̀kọ́ tí yóò tún máa kọ́ni lọ́gbọ́n àtiṣe lóríṣìiríṣìi, ìmọ̀ àtilèdádúró láti lè bá àfojúsùn wọn àti ìmúṣẹ ìlepa ìgbérò ìdàgbàsókè tí ó bá fi máa di ọdún 2030.

Bẹ̀rẹ̀ ìtàkùrọ̀sọ náà

Òǹkọ̀wé, jọ̀wọ́ àkọsílẹ̀ ìwọlé »

Ìlànà

  • Atukọ̀ yóò ṣ'àtúnwò gbogbo ìsọsí . Máà fi ìsọsíì rẹ sílẹ̀ ju ẹ̀rìnmejì lọ tàbí kí a kà á sí iṣẹ́-ìjẹ́-tí-a-o-fẹ́.
  • Jọ̀wọ́ fi ọ̀wọ̀ fún ẹlòmíràn . A ò ní fi àṣẹ sí ìsọsí ìkórìíra, ìṣekúṣe, àti ìdojú-ìjà-kọ ẹnikẹ́ni k.