Ilẹ̀-Adúláwọ̀ rí àbọ̀ ẹgbẹẹgbẹ̀rún-lọ́nà-ẹgbẹ̀rún owóo dollar láti ọ̀dọ̀ Ilé-ìfowópamọ́sí ńláńlá fún ìgbéfúkẹ́ Iléeṣẹ́ ọgbọ́n àtinudá

Àgékù àwòrán ọ̀kọrin ọmọ orílẹ̀-èdèe Nàìjíríà D'banj ń sọ̀rọ̀ níbi ètò Ọjọ́ Ìsinmi CAX ní Cairo, Egypt, ọdún-un 2018. Dbanj sọ fún olùdókoòwò wípé “iṣẹ́ àtinúdá ni epo rọ̀bì tí ọpọ́n sún kàn” tí ó sì yẹ kí a bu ìyìn fún.

Ó ti pẹ́ tí àwọn iléeṣẹ́ ìgbélárugẹ àṣà àti ọgbọ́n àtinudá ti ń ṣe ohun mèremère ní ti ìdàgbàsókè ọrọ̀ Ajé, ní ti ipa tí wọ́n ń kó àti agbára tí ó wà níkàáwọ́ wọn láti mú àyípadà dé bá àwùjọ àti ìpàṣípààrọ̀ àṣà.

Lọ́dún-un 2013, iléeṣẹ́ ìgbélárugẹ àṣà àti ọgbọ́n àtinudá (CCI) rí owó ẹgbẹẹgbẹ̀rún-lọ́nà-ẹgbẹ̀rún 2,250 dollar ti Ìṣọ̀kan Orílẹ̀-èdèe Amẹ́ríkà àti iṣẹ́ tí ẹgbẹẹgbẹ̀rún 29.5 kárí ayé [àmọ́] ìdá 3 àwọn iṣẹ́ wọ̀nyí wá láti Ilẹ̀-Adúláwọ̀ àti Àárín gbùngbùn Ìlà-Oòrùn tí ó jẹ́ agbègbè àwọn aráa Lárúbáwá, ìyẹn gẹ́gẹ́ bí ìwádìí àyẹ̀wò fínnífínní Àjọ Ìṣọ̀kan Àgbáyé fún Ẹ̀kọ́, Ìwádìí Ìjìnlẹ̀ àti Àṣà (UNESCO) ọdún-un 2013 tí a pè ní “Àsìkò Àṣà” kan ti ṣe fi hàn.

Torí ìdí èyí, Ilé-ìfowópamọ́sí Ọjà títa sókè òkun-àti-kíkó ọjà wọlé (Afreximbank) pẹ̀lú àbáṣepọ̀ọ UNESCO àti Ẹgbẹ́ Ilé-ìfowópamọ́sí Ìdàgbàsókè Ilẹ̀-Adúláwọ̀, ṣe àgbékalẹ̀ Ìpàṣípààrọ̀ Ọgbọ́n Àtinudá Ilẹ̀-Adúláwọ̀ – Creative Africa Exchange (CAX)  tí yóò “dúró gẹ́gẹ́ bíi ohun tí yóò ṣe àmúpapọ̀ àwọn nǹkan ọrọ̀ àti àlùmọ́nì tí ó wà nínú iléeṣẹ́ ọgbọ́n àtinudá” tí yóò ṣe àgbéró, mú owó wọlé àti lapa rere lára àwọn ọlọ́gbọ́n àtinudá àti àwọn oníṣẹ́ àṣà, bí ibùdó ìtakùn àgbáyé CAX ṣe ní i lákọsílẹ̀. Ọdún-un 2018 ni ìfilọ́lẹ̀ CAX wáyé ní ibi Ìpàtẹ Ọjà Inú Ilẹ̀-Adúláwọ̀ ní ìlúu Cairo, orílẹ̀-èdèe Egypt, nínú oṣù Ọ̀pẹ̀ ọdún-un 2018.

Àwọn ọlọ́gbọ́n àtinudá gbogbo láti ẹ̀ka orin kíkọ, iṣẹ́ ọnà, àwòṣe, ẹ̀ṣọ́, ewì, ìwé títẹ̀, àwòrán-olóhùn àti òṣìṣẹ́ ẹ̀rọ amóhùnmáwòràn parojọ fún Ọjọ́ Ìsinmi Ìpàṣípààrọ̀ Ọgbọ́n Àtinudá ní Kigali, ní orílẹ̀-èdèe Rwanda, ní ọjọ́ 16-18 oṣù kìíní, Ọdún-un 2020. Ó polówó araa rẹ̀ gẹ́gẹ́ bíi “ayẹyẹ àkọ́kọ́ tí yóò kó àwọn ọmọ ilẹ̀ adúláwọ̀ jọ tí ń ṣe ìgbélárugẹ ìpàṣípààrọ̀ láàárín àwọn ọlọ́gbọ́n àtinudá àti aṣàgbélárugẹ àṣà ní Ilẹ̀-Adúláwọ̀,” tí ó ní àwọn akópa tí ó tó bíi 2,000 láti orílẹ̀-èdè 68.

Ní ọjọ́ kejì ayẹyẹ náà ní Kigali, ọ̀jọ̀gbọ́n Benedict Oramah, ààrẹ Ilé-ìfowópamọ́sí Ọjà títa sókè òkun-àti-kíkó wọlé (Afreximbank) kéde owó ìrànwọ́ ẹgbẹẹgbẹ̀rún 500 owó dollar Amẹ́ríkà “tí yóò ṣe àtìlẹ́yìn ìgbéjáde àti káràkátà nǹkan tí ó jẹ mọ́ ti àṣà àti ọgbọ́n àtinudá Ilẹ̀-Adúláwọ̀” fún ọdún méjì gbáko, New Times Rwanda jíyìn ìròhìn.

Omarah gbé e sí àwọn àlejò tí ó wà níkàlẹ̀ níbi ayẹyẹ náà létí wípé owó ìrànwọ́ náà, tí yóò bù kún iṣẹ́ tí Ilé-ìfowópamọ́sí náà ti ń ṣe tẹ́lẹ̀, yóò wà ní àrọ̀wọ́tó ní àwọn Ilé-ìfowópamọ́sí, tí yóò jẹ́ lílò fún àwọn tí ó fẹ́ ẹ. Ó sọ wípé “bí Ilẹ̀-Adúláwọ̀ ti ṣe ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọlọ́gbọ́n àtinudá tó, kò sí ohun èlò tí yóò mú kí wọn ó “ká èso ọrọ̀ tí ó pọ̀ tí ó ń dúró fún kíká, ìyẹn bí Afreximbank ti ṣe ṣàlàyé. Ó sọ̀rọ̀ síwájú sí i :

Nítorí àìtó ìdókoòwò nínú iléeṣẹ́ ọgbọ́n àtinudá àti àṣà, Ilẹ̀-Adúláwọ̀ kò sí nínú ọjà iṣẹ́ ọpọlọ, àti ìdáraáwò púpọ̀ gẹ́gẹ́ bí a ti fi hàn nínú orin, eré ìtàgé, ewì, àwòrán-àtohùn àti ètò orí ẹ̀rọ amóhùnmáwòrán àgbáyé. Àwọn orílẹ̀-èdè Ilẹ̀-Adúláwọ̀ máa ń kó ọjà ọgbọ́n àtinudá wọlé ju èyí tí wọ́n tà sókè òkun tàbí láàárin ara wọn.

Ó gbóṣùbàa sàńdákátà fún orílẹ̀-èdèe Egypt ní ti “ìdàgbàsókèe ìtàsókè òkun ọgbọ́n àtinudá láàárín ọdún mẹ́wàá tí ó ré kọjá.” Nínú oṣù Ọ̀pẹ̀ ọdún-un 2019, a dá Afreximbank lọ́lá níbi Ìfàmìẹ̀yẹdánilọ́lá Ìṣaralọ́ṣọ̀ọ́ Àgbáyé International Fashion Awards (IFA) ní Cairo fún ipa tí ó ń kó níbi ti ìtìlẹ́yìn-in iléeṣẹ́ ọgbọ́n àtinudá Ilẹ̀-Adúláwọ̀. Bákan náà ni Omarah gbóríyìn fún iléeṣẹ́ eré orí ìtàgé Nollywood ti Nàìjíríà.

Lóríi gbàgede Twitter, àwọn òṣèré tó wà níbi àpérò náà dúpẹ́ fún àpéjọ náà tí ó wáyé ní gbọ̀ngan Intare tí ó wà ní Kigali:

Siki Jo-An, ọ̀kọrin láti South Africa, pe ayẹyẹ náà ní “ìyanu:”

Àwọn alágbèékalẹ̀ Ọjọ́ Ìsinmi CAX sọ nípa eré-ṣíṣe Marina Debol, akọrin ọmọ Rwanda:

Nínú ọ̀rọ̀-ọ rẹ̀ níbi ayẹyẹ Ọjọ́ Ìsinmi CAX 2018 ní Cario, ọ̀kọrin ọmọ orílẹ̀-èdèe Nàìjíríà D'Banj sọ fún àwọn òṣìṣẹ́ Ilé-ìfowópamọ́sí àti olùdókoòwò:

Ohun tí a nílò láti ọ̀dọ̀ọ yín ní fún un yín láti lóye wípé iṣẹ́ àtinudá ni epo rọ̀bì tí ọpọ́n sún kàn tí ó sì yẹ kí a bu ìyìn fún iléeṣẹ́ náà.

Ọ̀sẹ̀-ẹ CAX tí yóò ṣe pẹ̀kí-ǹ-rẹ̀kí pẹ̀lú Ìpàtẹ Ọjà Inú Ilẹ̀-Adúláwọ̀ (IATF2020) láti Ọjọ́ 1-7 kẹsàn-án ní Kigali, yóò tẹ̀lé Ọjọ́ Ìsinmi CAX 2020 tí ó ṣẹ̀ṣẹ̀ tẹnu bọ epo.

Bẹ̀rẹ̀ ìtàkùrọ̀sọ náà

Òǹkọ̀wé, jọ̀wọ́ àkọsílẹ̀ ìwọlé »

Ìlànà

  • Atukọ̀ yóò ṣ'àtúnwò gbogbo ìsọsí . Máà fi ìsọsíì rẹ sílẹ̀ ju ẹ̀rìnmejì lọ tàbí kí a kà á sí iṣẹ́-ìjẹ́-tí-a-o-fẹ́.
  • Jọ̀wọ́ fi ọ̀wọ̀ fún ẹlòmíràn . A ò ní fi àṣẹ sí ìsọsí ìkórìíra, ìṣekúṣe, àti ìdojú-ìjà-kọ ẹnikẹ́ni k.