Ilé ẹ̀kọ́ ìmọ̀ orin kíkọ kan ṣoṣo ní Zanzibar ti fẹ́ di títì pa

Àwọn akẹ́kọ̀ọ́ láti Iléèwé Orin kíkọ Àwọn Orílẹ̀-èdèe Dhow (DCMA) ń fi qanun, fèrè, ìlù àti dùrù ní Ilé Àwọn Ẹ̀ṣọ́ Aṣọ́bodè Àtijọ́, ní Stone Town, Zanzibar, 2019. DCMA ló ni àwòrán.

Ẹgbẹẹgbẹ̀rún àlejò tí ó ń rọ́ wìtìwìtì wá sí ìlú Stone Town, Zanzibar tí ó kún fún ìṣẹ̀lẹ̀ àtẹ̀yìnwá, ti tẹ̀lé ìró orin Iléèwé Orin kíkọ Àwọn Orílẹ̀-èdèe Dhow (DCMA), ilé ẹ̀kọ́ orin kíkọ tí ó ń ṣe ìgbélárugẹ àti ìpamọ́ àwọn àṣà orin erékùṣù náà tí ó sún mọ́ Swahili ní ẹ̀báa Omi Òkun India. Láti ọdún-un 2002, ilé ẹ̀kọ́ náà ti ṣe ìgbélárugẹ àti ìpamọ́ àkójọpọ̀ orin Lárúbáwá, India àti Ilẹ̀ Adúláwọ̀ tí kò lẹ́lẹ́gbẹ́.

Lẹ́yìn-in ọdún kẹtàdínlógún, iléèwé náà kò rí owó tí ó tówó nínú àpò ìkówó sí tí ó sì leè fa kí iléèwé náà ó di títì pa. Nínú ìwé ìgbéròyìnjáde tí àwọn aláṣẹ DCMA tẹ̀ jáde, ìdá àádọ́rin nínú àwọn ọgọ́rin akẹ́kọ̀ọ́ ni kò rí owó iléèwé wọn tí ó tó bíi $13 USD lóṣù san. Pẹ̀lú àtìlẹ́yìn àwọn onínúure tí ó ti dáwó fún iléèwé náà, owó tí ó kù ní sísan ṣì pọ̀ tó bẹ́ẹ̀ tí ó fi jẹ́ wípé, ó ṣe é ṣe kí ilẹ̀kùn-un iléèwé náà tí ó wà nínú Ilé Àwọn Ẹ̀ṣọ́ Aṣọ́bodè Àtijọ́.

Láìsí owó tí ó tówó nílẹ̀ láti tẹ̀síwájú, àwọn akẹ́kọ̀ọ́ DCMA àti òṣìṣẹ́ ń fòyà kí ìró amọ́kànbalẹ̀ tí ó ń sun jáde láti inúu gbọ̀ngán olókìkí ilé ẹ̀kọ́ yìí tí ó mú erékùṣù yìí kọrin — leè wọ òkùnkùn. Orin àti ìgbélárugẹ àṣà àti àjogúnbá nìkan kọ́ ni ilé ẹ̀kọ́ náà fi gbajúmọ̀, àmọ́ ó jẹ́ ilé fún àwọn ọ̀dọ́ tí ó ń wà ibi tí wọn yóò ti fi ìmọ̀ kún ìmọ̀.

Akẹ́kọ̀ọ́ DCMA kan ń kọ́ qanun, ohun èlò orin ayédáadé orin taarab. Àwòrán láti iléèwé DCMA.

“A [ti bẹ̀rẹ̀] sí í ní rí ìdojúkọ ìgbà tí ó nira,” alákòóso àgbàa DCMA, Alessia Lombardo sọ, nínúu àwòrán fídíò DCMA kan. “Láti ìsinsìnyí lọ títí di oṣù mẹ́fà sí àsìkò yìí, a kò rí àrídájú tí ó rinlẹ̀ wípé a ó leè san owó oṣù àwọn olùkọ́ni àti òṣìṣẹ́ẹ.”

Ní àkókò tí a wà yìí, àwọn àkàwé-gboyè olùkọ́ 19 àti àwọn òṣìṣẹ́ mìíràn ti ṣiṣẹ́ fún oṣù mẹ́ta gbáko láì gba owó lọ sílé nítorí àìsí owó nínúu kóló iléèwé. Gẹ́gẹ́ bí Ilé Ìfowópamọ́ Àgbáyé ṣe ti ṣàlàyé wípé, pẹ̀lú bí a ti ṣe mọ agbègbè tí iléèwé náà wà fún ibi ìrìn-àjò ìgbafẹ́ nítorí àwọn etíkun àtijọ́ àti ilé ìtura olówó ńláńlá tí ó kángun síbẹ̀, ọ̀gọ̀rọ̀ àwọn ọmọ ìbílẹ̀ ló ń bá àìníṣẹ́ lọ́wọ́ pò ó pàápàá bí ìṣẹ́ ṣe ti gbé fúkẹ́ ju ti ìgbà kan lọ.

Fún ọdún mẹ́tàdínlógún, DCMA ti ṣiṣẹ́ àṣekúdórógbó nípa lílo orin ṣe ìgbélárugẹ tòun ìpamọ́ ọ̀rọ̀ àjogúnbá àti àṣà Zanzibar. Orírun àwọn olóhùn-iyò akọrin taarabSiti Binti Saad àti Fatuma Binti Baraka, tí a tún mọ̀ sí Bi. Kidude, Zanzibar ni ilé èyí-ò-jọ̀yìí orin tí ó ti inúu ìbàṣepapọ̀ àṣà àti àjọṣe ọlọ́dún gbọgbọrọ tí ó wà láàárín àwọn àdúgbò ẹ̀ka Swahili. Láyé òde òní, akẹ́kọ̀ọ́ leè kọ́ orin ìbílẹ̀ bíi taarab, ngoma àti kidumbak, pẹ̀lú àfikún àwọn ohun èlò ìkọrin bíi ìlù ní oníranànran, qanun àti oud, gẹ́gẹ́ bí alápamọ́ — àti òǹgbifọ̀ — àṣà àti ìṣe.

Neema Surri, a ta violin ní DCMA, ti ń kọ́ bí a ti ṣe ń ta ohun èlòo violin láti ọmọdún mẹ́sàn-án mẹ́nu lé ọ̀rọ̀ nínú àwòrán fídíò DCMA náà. “Mo mọ àwọn ọ̀dọ́mọdé tí ó máa nífẹ̀ẹ́ sí kíkọ́ orin ṣùgbọ́n wọn kò leè san owó ìmẹ̀kọ tí ó jẹ́ owó iléèwé nítorí wípé wọn kúṣẹ̀ẹ́ wọn kò sì ní iṣẹ́ lọ́wọ́.”

Àwọn akẹ́kọ̀ọ́ọ DCMA ń fi ohun èlò ìkọrin olókùn tín-ín-rín kọrin nínú Ilé Àwọn Ẹ̀ṣọ́ Aṣọ́bodè Àtijọ́, níbití iiléèwé náà fi ìkàlẹ̀ sí, ní Stone Town, Zanzibar, lọ́dún-un 2019. Àwòrán jẹ́ ti iléèwée DCMA.

Ní ìparí àwọn ìdánilẹ́kọ̀ọ́ọ DCMA, tí wọ́n ti gba ìwé ẹ̀rí àti ní òpin ẹ̀kọ́ ọlọ́dún kan, púpọ̀ nínú àwọn akẹ́kọ̀ọ́ọ DCMA ni ó ti di àgbà ọ̀jẹ́ tí wọ́n sì í ṣeré lórí ìtàgé kárí ayé. Ọmọ bíbíi Zanzibar, tí ó jẹ́ akẹ́kọ̀ọ́ọ DCMA nígbà kan rí, tí ó jẹ́ olùkọ́ni ní iléèwé kan náà báyìí, Amina Omar Juma tòun ti ìlú mọ̀ọ́ká ẹgbẹ́ akọrin rẹ̀, tí ó ń “fi àṣà ìró orin ìbílẹ̀” taarab papọ̀ mọ́ ti ìgbàlódélonígbàńlò kọrin, ìyẹn “Siti àti Ẹgbẹ́“, ṣẹ̀ṣẹ̀ padà wọ̀lú láti ìrìnàjò orin kíkọ kan ní orílẹ̀-èdèe South Africa. Òun, àwọn díẹ̀ nínú ẹgbẹ́ akọrin rẹ̀ àti àpapọ̀ àwọn akẹ́kọ̀ọ́ DCMA ní ìgbà kan rí ṣe àgbéjáde àwo orin wọn àkọ́kọ́, “Fusing the Roots,” ní ọdún-un 2018, tí ó mú wọn oi ng o òǹwòran lára yá ní Sauti za Busara, tí í ṣe àjọ̀dún orin kíkọ tí ó gbàràdá jù lọ ní Ìlà-oòrùn Ilẹ̀ Adúláwọ̀.

Híhàyín ni orin Siti àti Ẹgbẹ́ “Nielewe” (“Gbó mi yéké”) àti àwòrán orin náà, tí ó ṣe àfihàn-an àwòrán-an, tí ó sọ ìtàn obìnrin kan tí ó ń rí ìdojúkọ abẹ̀-ilé, tí ó sì ń dárò ara rẹ̀. Ìtàn náà jọ ti Omar Juma fúnra rẹ̀:

Ìtàn nípa àyálò àṣà àti àjọṣepọ̀

Ó tó ẹgbẹ̀rún mẹ́ẹ̀ẹ́dógún àlejò ni ó ti wo eré, gba ìdánilẹ́kọ̀ọ́ àti bá àwọn akọrin lóríṣiírísí ọjọ́ ọ̀la ní iléèwé olókìkí náà ní gbólóhùn rí. Iléèwé náà ti ṣe àyálò àti àmúpapọ̀ ọ̀kan-ò-jọ̀kan àṣà “àwọn orílẹ̀-èdè dhow,” tí ó wà ní ìtòsíi Òkun India àti Ọ̀gbùn-un Persia.

Agbègbèe Omani Sultanate, tí ó jẹ́ ” ibi gbòógì àwọn alágbára atukọ̀ orí omi ní ọgọ́rùn-ún Ọdún-un kẹtàdínlógún sí kọkàndínlógún sẹ́yìn,” gbé àga agbára rẹ̀ láti Muscat sí Zanzibar ní ọdún-un 1840. Láti Stone Town, àwọn ọba Omani ń tukọ̀ọ okòwò orí omi ìgbà náà tí ó fẹjú, títí kan kànáfùrù, wúrà, àti aṣọ , látàrí àwọn ìjì líle tí ń tu àwọn ọkọ̀ ìbílẹ̀ẹ Lárúbáwáa — dhows — ní oríi Òkun Indian, láti India sí Oman títí lọ dé Ìlà-Oòrùn Ilẹ̀ Adúláwọ̀.

Àwọn ọ̀dọ́ ní Zanzibar mọ rírìi ìṣẹ̀lẹ̀ àtẹ̀yìnwá tí ó ní ohun ńlá ní í ṣe fún ọjọ́ ọ̀la wọn, ni wọ́n fi ń ṣe àdàlù èyí tí a rí nínú àwọn orin òde òní tí wọn ń gbé jáde. Àwọn akẹ́kọ̀ọ́ àti olùkọ́ni DCMA ṣe ìdásílẹ̀ẹ “TaraJazz” láì pẹ́ yìí, èyí tí ó jẹ́ àdàlù orin ìbílẹ̀ taarab àti orin Jazz òde òní. Ata violin, Felician Mussa, ọmọ ogún ọdún, ti ń kọ́ ohun èlò ìkọrin olókùn tín-ín-rín náà fún ọdún mẹ́ta àtààbọ̀; TaraJazz jẹ́ ọ̀kan nínú àwọn ẹgbẹ́ akọrin tí ó àwọn ènìyàn máa ń pè sí òde jù lọ ní àwọn erékùṣù náà, ni ó wà nínú àwòrán tí ayàwòrán tí Aline Coquelle yà:

 

Wo àtẹ́jádé yìí ní oríi Instagram

 

#groovy #evenings pẹ̀lú #Tarajazz #Taraab #jazz #gang @dcmazanzibar #alinecoquelle #Zanzibar #Music #beating #Heart #Stonetown #IndianOcean #Africa #Islanders

Àtẹ̀jáde kan láti ọwọ́ọ Aline Coquelle Photoreporter (@alinecoquelle) on

Agbègbèe Swahili sọ ìtàn pàṣípààrọ àṣà ìbílẹ̀ tí DCMA ṣì ń tẹ̀síwájú nínúu rẹ̀ pẹ̀lú àjọṣepọ̀ àwọn orin-in rẹ̀. Lọ́dòọdún, iléèwé náà máa ń gbàlejò fún ètò tí a pè ní “Ìkọlù Swahili,” tí ó mú àgbárijọpọ̀ọ àgbà akọrin láti Ilẹ̀-Adúláwọ̀, Ìlú Abẹ́-àkóso Lárúbáwá, Ilẹ̀ Éróòpù àti Àríwá Amẹ́ríkà pẹ̀lú àwọn akẹ́kọ̀ọ́ DCMA láti ṣe orin láàárín ọ̀sẹ̀ kan. Ní ìgbẹ̀yìngbẹ́yín “ìkọlù” náà, àgbárijọpọ̀ tuntun náà yóò ta bí elégbé ní Sauti za Busara, tí àjọṣepọ̀ wọ̀nyí yóò sì di ìbáṣepọ̀ ọlọ́jọ́ pípẹ́ tí kò mọ ìyàtọ̀ èdè àti àṣà, tí ó fi hàn gbangba wálíà wípé èdè kan náà tí gbogbo ayé gbọ́ ni orin.

DCMA máa ń ṣe àgbékalẹ̀ ètò orin kíkọ tí ó ń ṣe ìgbélárugẹ ẹ̀bùn orin kíkọ àwọn akẹ́kọ̀ọ́ àti àfihàn àjọṣepọ̀ pẹ̀lú ọ̀kọrin àlejò hàn ní, Stone Town, Zanzibar, 2019. DCMA ni ó ni àwòrán.

DCMA mọ rírì orin gẹ́gẹ́ bí ohun tí ó leè ró àwọn ènìyàn lágbára àti gẹ́gẹ́ bí ohun tí ó lè mú ìṣọ̀kan àti ìrẹ́pọ̀ bá àwọn ènìyàn láì wo ti àṣà — ó sì tún ń pèsè àǹfààní iṣẹ́ fún àwọn ọ̀dọ́ tí ó ní ẹ̀bùn àmọ́ tí ó ń tiraka láti jẹ. Fún àwọn akẹ́kọ̀ọ́ 1,800 tí ó ti gba ìdánilẹ́kọọ́ ní DCMA, èyí nìkan ni ibi ilé orin tí wọ́n mọ̀, níbi tí wọ́n ti ń kọ́ ẹ̀kọ́ tí wọ́n sì ti ń ní àlékún ìmọ̀ nípa iṣẹ́ orin kíkọ àti bí a ṣe ń di òǹkọrin.

Arìnrìn-àjò kan láti Spain, tó bẹ DCMA wò ní kò pẹ́ yìí, kọ sí oríi TripAdvisor: “Ní tèmi, ìṣalábàápàdée àwọn akọrin ni ìgbà tí ó meet jù lọ fún mi ní erékùṣù yìí.”

Bí ẹ̀ka ìrìn-àjò afẹ́ẹ Zanzibar ṣe ń gbèrò sí i, DCMA nígbàgbọ́ wípé orin ní ipa kan gbòógì ní í ṣe nínú àjọyọ̀, ìpamọ́ àti ìgbélárugẹ tòun ìpolongo àṣà, àjogúnbá àti ìṣẹ̀lẹ̀ àtẹ̀yìnwáa Swahili. Zanzibar ju àwọn etíkun àti ilé ìtura olówó iyebíye rẹ̀ lọ — ó jẹ́ ibi tí ó kún fún àwọn ènìyàn ọlọ́pọlọ tí ó ní ẹ̀bùn ní poolo orí wọn látàrí àjọṣepọ̀ ọlọ́jọ́ pípẹ́ tí ó mú agbègbè náà dá yàtọ̀ gedegbe.

Ìfiyèsí Alákòóso Ìwé Títẹ̀: Òǹkọ̀wé àtẹ́jádé yìí ti ṣiṣẹ́ ọ̀fẹ́ pẹ̀lú DCMA.

Bẹ̀rẹ̀ ìtàkùrọ̀sọ náà

Òǹkọ̀wé, jọ̀wọ́ àkọsílẹ̀ ìwọlé »

Ìlànà

  • Atukọ̀ yóò ṣ'àtúnwò gbogbo ìsọsí . Máà fi ìsọsíì rẹ sílẹ̀ ju ẹ̀rìnmejì lọ tàbí kí a kà á sí iṣẹ́-ìjẹ́-tí-a-o-fẹ́.
  • Jọ̀wọ́ fi ọ̀wọ̀ fún ẹlòmíràn . A ò ní fi àṣẹ sí ìsọsí ìkórìíra, ìṣekúṣe, àti ìdojú-ìjà-kọ ẹnikẹ́ni k.